ٱلۡمُلۡكُ يَوۡمَئِذٖ لِّلَّهِ يَحۡكُمُ بَيۡنَهُمۡۚ فَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ فِي جَنَّٰتِ ٱلنَّعِيمِ 56
Ọla ni ọjọ igbende - ọjọ ti ohun ti wọn se ni adehun iya fun awọn eniyan wọnyi yoo wa ba wọn - ti Allah nikan soso ni, olubafa a ko si Oun ti mimọ nbẹ fun ni yoo se idajọ laarin awọn olugbagbọ ododo ati keferi, yoo se idajọ fun gbogbo wọn pẹlu ohun ti wọn lẹtọ si, awọn ti o nigbagbọ ninu Allah, ti wọn si nsisẹ re, ẹsan ti o tobi nbẹ fun wọn, ohun ni ọgba idẹkun ti yoo maa wa ti ko nii ja.
وَٱلَّذِينَ كَفَرُواْ وَكَذَّبُواْ بَِٔايَٰتِنَا فَأُوْلَٰٓئِكَ لَهُمۡ عَذَابٞ مُّهِينٞ 57
Awọn ti wọn si se keferi si Allah, ti wọn si npe awọn amin wa ti a sọkalẹ fun ojisẹ Wa ni irọ, iya iyẹpẹrẹ nbẹ fun wọn, Ọlọhun Allah yoo fi yẹpẹrẹ wọn ninu jahanamọ.
وَٱلَّذِينَ هَاجَرُواْ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ ثُمَّ قُتِلُوٓاْ أَوۡ مَاتُواْ لَيَرۡزُقَنَّهُمُ ٱللَّهُ رِزۡقًا حَسَنٗاۚ وَإِنَّ ٱللَّهَ لَهُوَ خَيۡرُ ٱلرَّٰزِقِينَ 58
Awọn ti wọn gbe ile ati ilu wọn ju silẹ lati wa iyọnu Allah ati lati mu iyi ba ẹsin Rẹ, lẹyin naa wọn pa wọn si ibi igbiyanju si oju ọna Rẹ tabi wọn ti ẹ ku - Allah yoo maa ran wọn se ninu Alujannah ni aranse ti o dara, ni gbogbo igba ti ko si nii ja, ati wipe dajudaju Allah ti mimọ nbẹ fun jẹ ẹniti o loore ju ni alaranse.
لَيُدۡخِلَنَّهُم مُّدۡخَلٗا يَرۡضَوۡنَهُۥۚ وَإِنَّ ٱللَّهَ لَعَلِيمٌ حَلِيمٞ 59
Allah yoo fi wọn wọ sinu aaye ti yoo yọ wọn ninu ohun si ni Alujannah, dajudaju Allah jẹ onimimọ si isẹ wọn ati adisọkan wọn, alatẹmọra nitoripe ko kanju fi iya jẹ wọn lori aseju wọn.
۞ذَٰلِكَۖ وَمَنۡ عَاقَبَ بِمِثۡلِ مَا عُوقِبَ بِهِۦ ثُمَّ بُغِيَ عَلَيۡهِ لَيَنصُرَنَّهُ ٱللَّهُۚ إِنَّ ٱللَّهَ لَعَفُوٌّ غَفُورٞ 60
Eyi ti a sọ yii; nipa mimu awọn oluse irin ajo si oju ọna Allah wọ ọgba idẹra ati nibi yiyọnda ki a fi koju ẹniti o kọja ẹnu aala deede ohun ti o fi kọja rẹ, ti ko si nii si ẹsẹ fun un lori eleyi, ti ẹniti o kọja ẹnu aala ba tun sẹri si ibi ikọja ẹnu aala rẹ, dajudaju Allah yoo se aranse fun ẹniti o kọja ẹnu aala si i, dajudaju Allah jẹ alamojukuro nibi awọn ẹsẹ olugbagbọ ododo, o si jẹ alaforijin fun wọn.
ذَٰلِكَ بِأَنَّ ٱللَّهَ يُولِجُ ٱلَّيۡلَ فِي ٱلنَّهَارِ وَيُولِجُ ٱلنَّهَارَ فِي ٱلَّيۡلِ وَأَنَّ ٱللَّهَ سَمِيعُۢ بَصِيرٞ 61
Aranse yii fun ẹniti wọn kọja ẹnu aala si nitoripe dajudaju Allah lagbara lori ohun ti O ba fẹ, ninu si ni kiki oru bọ inu ọsan ati kiki ọsan bọ inu oru; pẹlu sise alekun ikini keji wọn ati dindin omiran ku, ati wipe dajudaju Allah jẹ olugbọ awọn ọrọ ẹru Rẹ, onimimọ si isẹ wọn, nkankan ko pamọ fun Un ninu rẹ, yoo si san wọn lẹsan le lori.
ذَٰلِكَ بِأَنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلۡحَقُّ وَأَنَّ مَا يَدۡعُونَ مِن دُونِهِۦ هُوَ ٱلۡبَٰطِلُ وَأَنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلۡعَلِيُّ ٱلۡكَبِيرُ 62
Eyiti a sọ nipa ki Ọlọhun Ọba Allah ki oru bọ inu ọsan yii ati ọsan bọ inu oru; nitoripe dajudaju Allah jẹ ododo, ẹsin Rẹ naa si jẹ ododo, bẹẹ ni adehun Rẹ naa jẹ ododo, aranse Rẹ fun awọn olugbagbọ ododo jẹ ododo, ati wipe dajudaju ohun ti awọn ẹlẹbọ nsin ninu oosa jẹ ibajẹ, ti ko si ipilẹ fun ati wipe dajudaju Allah ni ẹniti o ga julọ lori ẹda Rẹ nibi bibẹ, agbara ati ibori, ẹniti o tobi, ti isemotomoto nbẹ fun ati titobi ati gbigbọngbọn.
أَلَمۡ تَرَ أَنَّ ٱللَّهَ أَنزَلَ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءٗ فَتُصۡبِحُ ٱلۡأَرۡضُ مُخۡضَرَّةًۚ إِنَّ ٱللَّهَ لَطِيفٌ خَبِيرٞ 63
Se iwọ ko ri ni - irẹ ojisẹ - dajudaju Allah sọ oju kalẹ lati sanmọ, bẹẹni ilẹ yoo di nkan tutu lati ibi irugbin ti o ba jade ni ibẹ lẹyin igba ti ojo ba sọkalẹ le lori, dajudaju Allah jẹ alaanu si ẹru Rẹ nitori ojo ti o nsọkalẹ fun un, O si jẹ ki ilẹ hu irugbin, O jẹ oniro si nkan ti yoo se wọn ni anfaani, nkankan ko pamọ fun wọn nibẹ.
لَّهُۥ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِۚ وَإِنَّ ٱللَّهَ لَهُوَ ٱلۡغَنِيُّ ٱلۡحَمِيدُ 64
Oun nikan ni o ni ọla ohun ti nbẹ ni sanmo ati eyiti ti nbẹ ni ilẹ, ati wipe dajudaju Oun ni Ọlọrọ eyiti kii tosi lọsi ọdọ awọn ẹda kankan ninu awọn ẹda Rẹ, ẹniti a ma nyin ni gbogbo isesi.
Ipo Hijira ninu ẹsin Islam ati alaye nipa ọla rẹ.
Titọ fifi iya jẹni ni deede rẹ.
Aranse Allah fun awọn ti wọn kọja ẹnu aala si yoo maa bẹ fun ẹniti wọn ba kọja ẹnu aala si ni ile aye tabi ni ọrun,.
Fifi awọn iroyin giga rinlẹ fun Allah gẹgẹ bi o se tọ si I, gbigbọngbọn Rẹ; gẹgẹ bi imọ, gbigbọ, iriran ati giga.