فَلَا تُعۡجِبۡكَ أَمۡوَٰلُهُمۡ وَلَآ أَوۡلَٰدُهُمۡۚ إِنَّمَا يُرِيدُ ٱللَّهُ لِيُعَذِّبَهُم بِهَا فِي ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا وَتَزۡهَقَ أَنفُسُهُمۡ وَهُمۡ كَٰفِرُونَ 55
Mase jẹ ki o jọ ẹ loju - ire ojise - dukia awọn sọbẹ selu ati awọn ọmọ wọn, wọn si kaa kun daadaa toripe igbẹyin duki ati ọmọ wọn jẹ aburu, Ọlọhun Ọba Allah se ni ijiya fun wọn pẹlu idaamu, wahala ki wọn le maa ko o jọ, ati orisirisi adanwo ti sẹlẹ si wọn titi ti Ọlọhun Ọba Allah yoo fi gba ẹmin wọn lori sise keferi wọn, yoo waa jẹ wọn niya ni wiwa gbere nisalẹ salẹ ina.
وَيَحۡلِفُونَ بِٱللَّهِ إِنَّهُمۡ لَمِنكُمۡ وَمَا هُم مِّنكُمۡ وَلَٰكِنَّهُمۡ قَوۡمٞ يَفۡرَقُونَ 56
Awọn sọbẹ selu yoo si maa bura fun yin - ẹyin olugbagbọ ododo - ni ẹniti nparọ: dajudaju ninu yin awọn wa, sugbọn wọn ko si lara yin ninu ikun wọn, ti wọn ba se afihan wipe awọn wa ninu yin sugbọn wọn jẹ ijọ ti nbẹru ki ohun ti o sẹlẹ si awọn ọlọsẹbọ maa sẹlẹ si wọn, bii piparọ ati mimu wọn lẹru, wọn o waa maa se afihan Islam niti isọra.
لَوۡ يَجِدُونَ مَلۡجًَٔا أَوۡ مَغَٰرَٰتٍ أَوۡ مُدَّخَلٗا لَّوَلَّوۡاْ إِلَيۡهِ وَهُمۡ يَجۡمَحُونَ 57
Ti awọn sọbẹ selu yii ba ri aaye ibusasi lati sọ ẹmin wọn tabi ki wọn ri iho kan ninu oke ti wọn fi ara pamọ si, tabi ki wọn o ri aaye kan ti wọn le lugọ si, wọn ko ba fi ara pamọ sibẹ, wọn ko ba si wọ ibẹ ni kiakia.
وَمِنۡهُم مَّن يَلۡمِزُكَ فِي ٱلصَّدَقَٰتِ فَإِنۡ أُعۡطُواْ مِنۡهَا رَضُواْ وَإِن لَّمۡ يُعۡطَوۡاْ مِنۡهَآ إِذَا هُمۡ يَسۡخَطُونَ 58
O nbẹ ninu awọn sọbẹ selu ti wọn nbu ọ - ire ojise - nibi saara ti o npin nigbati ohun ti wọn fẹ ko tẹ wọn lọwọ nibẹ, ti o ba fun wọn nibẹ nkan ti wọn nfẹ, wọn yoo kuro ni ọdọ rẹ, ti o ko ba fun wọn ni ohun ti wọn nfẹ, wọn yoo se afihan eebu.
وَلَوۡ أَنَّهُمۡ رَضُواْ مَآ ءَاتَىٰهُمُ ٱللَّهُ وَرَسُولُهُۥ وَقَالُواْ حَسۡبُنَا ٱللَّهُ سَيُؤۡتِينَا ٱللَّهُ مِن فَضۡلِهِۦ وَرَسُولُهُۥٓ إِنَّآ إِلَى ٱللَّهِ رَٰغِبُونَ 59
Ti o ba ja si wipe awọn sọbẹ selu yii ba nbu ọ nibi saara ti o pin, wọn yoo yọnu si ohun ti Ọlọhun Ọba ba pin fun wọn, ati ohun ti ojisẹ naa ba fun wọn ninu rẹ, wọn yoo wa sọ wipe: Ọlọhun Ọba Allah to wa, yoo fun wa ninu ọla Rẹ ohun ti o ba fẹ, ojisẹ Rẹ naa yoo si fun wa ninu ohun ti Allah ba fun un, dajudaju ọdọ Ọlọhun Ọba Allah ni a nrankan si ki o fun wa ninu ọla Rẹ, ti wọn ba se eleyi, ki ba jẹ oore fun wọn, ju ki wọn o maa bu ọ lọ.
Nigbati wọn bu ojisẹ Ọlọhun ti ikẹ ati ọla nbẹ fun lori ipin rẹ, yoo han si wọn ibiti wọn nna si ati awọn ti o lẹtọ si niti fifọ ojisẹ Rẹ mọ, o wa sọ wipe:
۞إِنَّمَا ٱلصَّدَقَٰتُ لِلۡفُقَرَآءِ وَٱلۡمَسَٰكِينِ وَٱلۡعَٰمِلِينَ عَلَيۡهَا وَٱلۡمُؤَلَّفَةِ قُلُوبُهُمۡ وَفِي ٱلرِّقَابِ وَٱلۡغَٰرِمِينَ وَفِي سَبِيلِ ٱللَّهِ وَٱبۡنِ ٱلسَّبِيلِۖ فَرِيضَةٗ مِّنَ ٱللَّهِۗ وَٱللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٞ 60
Dajudaju awọn saka ọranyan jẹ ohun ti o di dandan ki a na fun awọn alaini, awọn ni awọn ti wọn ni bukaata, ti wọn ni owo lati ibi isẹ ọwọ ati isẹ abase sugbọn ti ko wọn, ti awọn eniyan ko si kọ ibi ara si isesi wọn, bakanna ni awọn alaini awọn ti wọn ko ni nkankan, ti isesi wọn ko pamọ si ẹnikankan nitori isesi ti wọn wa ati ọrọ ẹnu wọn, ati awọn ti nlọ ti nbọ, ti asiwaju wọn lati gba a jọ, ati fun awọn keferi ti a fi nfa wọn lọkan ki wọn le gba Islam, tabi nitori lilẹ igbagbọ, ki igbagbọ wọn lagbara, tabi fun awọn ti a nna fun lati le aburu wọn jinna, ati nina si awọn ti a fẹ bọ okun lọrun wọn, ati fun awọn onigbese ti kii se ina apa tabi ẹsẹ, ti wọn ko ba ri ọna lati san ohun ti nbẹ lọrun wọn lati san gbese, ati nina si ipalese fun awọn olusegbbiyanju si oju ọna ti Ọlọhun, ati fun awọn oluse irin ajo ti nkan ina wọn ti tan, didari saka lori awọn eniyan wọnyi nikan jẹ lati ọd Ọlọhun Ọba Allah, Ọlọhun Ọba Allah ni O nimọ nipa ohun ti o le wulo fun awọn ẹru Rẹ, O si jẹ ọjọgbọn nibi idari ati ofin Rẹ.
وَمِنۡهُمُ ٱلَّذِينَ يُؤۡذُونَ ٱلنَّبِيَّ وَيَقُولُونَ هُوَ أُذُنٞۚ قُلۡ أُذُنُ خَيۡرٖ لَّكُمۡ يُؤۡمِنُ بِٱللَّهِ وَيُؤۡمِنُ لِلۡمُؤۡمِنِينَ وَرَحۡمَةٞ لِّلَّذِينَ ءَامَنُواْ مِنكُمۡۚ وَٱلَّذِينَ يُؤۡذُونَ رَسُولَ ٱللَّهِ لَهُمۡ عَذَابٌ أَلِيمٞ 61
O wa ninu awọn sọbẹ selu ti o nfi suta se ojisẹ Ọlọhun Ọba lati ibi ọrọ, wọn yoo maa sọ nigbati wọn ba ri suuru rẹ ti ikẹ ati ọla nbẹ fun: o kan ngbọrọ lọdọ ẹnikẹni, o si ngbaa gbọ, ko se iyatọ laarin ododo ati ibajẹ, sọ fun wọn - ire ojise - dajudaju ojisẹ naa ko nii gbọ ju daradara lọ, o gba Ọlọhun Ọba lododo, o si nkan ti awọn olugbagbọ ododo tootọ mu niro wa lododo, o si nkẹ wọn, dajudaju gbigbe dide jẹ ikẹ fun ẹniti o ba nigbagbọ si i, awọn ti wọn nfi suta se e ki ikẹ ati ọla maa bẹ fun ni eyikeyi oniranran suta, iya ẹlẹta elero nbẹ fun wọn.
Dukia ati awọn owo le jẹ okunfa iya ni ile aye yii, o si le jẹ okunfa iya ni ọrun, ki ẹru yaa maa fi mejeeji se ohun ti yoo yọ Ọlọhun Ọba rẹ ninu, ki o le ri ọla lati ara mejeeji.
Yiyọ saka jẹ ohun ti a la bọ igbiyanju awọn adari lọrun, ti yoo maa fi si aaye ti o tọ si ibamun si bukaata awọn eniyan ati ibamun si pipọ dukia.
Fifi suta se ojisẹ naa ti ikẹ ati ọla nbẹ fun lori isẹ ti wọn ran jẹ keferi sise, iya ti o le koko si wa le lori.
O tọ fun ẹru ki ẹti rẹ jẹ eti rere, ki o ma jẹ eti buburu, ki o maa gbọ nkan atunse ati daradara, ki o si gunri kuro nibi igberaga, ki o si tako lati maa gbọ aburu ati ibajẹ.