لِيَكۡفُرُواْ بِمَآ ءَاتَيۡنَٰهُمۡۚ فَتَمَتَّعُواْ فَسَوۡفَ تَعۡلَمُونَ 55
Mimu orogun pẹlu Allah ni o mu wọn se aimoore si idẹkun Allah ti o wa ni ori wọn, ninu rẹ si ni mimu inira kuro; tori eleyi ni wọn se sọ fun wọn: ẹ maa gbadun pẹlu igbadun ti ẹ wa ninu rẹ titi ti iya Allah yoo fi waa ba yin ni aye ati ni ọrun.
وَيَجۡعَلُونَ لِمَا لَا يَعۡلَمُونَ نَصِيبٗا مِّمَّا رَزَقۡنَٰهُمۡۗ تَٱللَّهِ لَتُسَۡٔلُنَّ عَمَّا كُنتُمۡ تَفۡتَرُونَ 56
Awọn ẹlẹbọ nwa fun oosa wọn eyiti ko mọ nkankan - nitoripe ọbọrọgidi ni ko le se anfaani, ko si le se inira - ipin kan ninu dukia wọn eyiti A rọ wọn lọrọ rẹ, wọn fi nse asunmọ lọsi ọdọ rẹ, Ọlọhun Allah yoo si beere paapaa julọ - ẹyin ẹlẹbọ - ni ọjọ igbende nipa nkan ti ẹ lero wipe awọn oosa yii jẹ ọlọrun ati wipe o ni ipin kan ninu dukia yin.
وَيَجۡعَلُونَ لِلَّهِ ٱلۡبَنَٰتِ سُبۡحَٰنَهُۥ وَلَهُم مَّا يَشۡتَهُونَ 57
Awọn ẹlẹbọ nse afiti ọmọbinrin fun Allah, wọn si ndi adisọkan wipe awọn ni awọn Malaika, wọn nse afiti ọmọ si I lọdọ, wọn se lẹsa fun Un ohun ti awọn ko nifẹ si fun ara wọn, mimọ kanga Rẹ ati fifọ mọ tan yan yan kuro nibi ohun ti wọn ngbee fun Un, wọn gbe fun wọn ohun ti ẹmin wọn nfi si ninu awọn ọmọkunrin, ẹsẹ wo ni o tobi to eleyi bi?!
وَإِذَا بُشِّرَ أَحَدُهُم بِٱلۡأُنثَىٰ ظَلَّ وَجۡهُهُۥ مُسۡوَدّٗا وَهُوَ كَظِيمٞ 58
Nigbati wọn ba fun ọkan ninu awọn ẹlẹbọ yii niro bibi obinrin, oju rẹ yoo dudu nitori ikorira ti o lagbara si ohun ti wọn fun un niro rẹ, ọkan rẹ yoo si kun fun ẹdun ọkan ati ibanujẹ, lẹyin igba naa yoo wa maa fi ti si ọdọ Allah nkan ti ko yọnu si fun ẹmin rẹ!
يَتَوَٰرَىٰ مِنَ ٱلۡقَوۡمِ مِن سُوٓءِ مَا بُشِّرَ بِهِۦٓۚ أَيُمۡسِكُهُۥ عَلَىٰ هُونٍ أَمۡ يَدُسُّهُۥ فِي ٱلتُّرَابِۗ أَلَا سَآءَ مَا يَحۡكُمُونَ 59
Yoo fi ara pamọ, yoo si se afẹku kuro ni ọdọ awọn ijọ rẹ nitori aburu oun ti wọn fun niro nipa bibi obinrin, ẹmin rẹ yoo maa baa sọrọ: se ki o gbe ọmọbinrin yii lori iyẹpẹrẹ ati ikoti ara tabi ki o si boo mọ ilẹ, ki o wa fi pamọ si inu yẹpẹ? Ki ni o buro to idajọ ti awọn ẹlẹbọ nse yii nibi sise idajọ fun Ọlọhun wọn nibi oun ti wọn korira fun ẹmin ara wọn.
لِلَّذِينَ لَا يُؤۡمِنُونَ بِٱلۡأٓخِرَةِ مَثَلُ ٱلسَّوۡءِۖ وَلِلَّهِ ٱلۡمَثَلُ ٱلۡأَعۡلَىٰۚ وَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ 60
Iroyin aburu nibi bukaata si ọmọ ati aimọkan ati keferi nbẹ fun awọn keferi ti ko nigbagbọ si ọjọ ikẹyin, Ọlọhun Ọba Allah ni o si ni awọn iroyin ẹyin ti o ga gẹgẹ bi gbigbọngbọn ati pipe ati ọrọ ati imọ, Oun ti mimọ nbẹ fun si ni alagbara nibi ọla Rẹ eyiti ẹnikẹni ko le bori rẹ, Ọjọgbọn nibi idẹda Rẹ ati idari Rẹ ati isofin Rẹ.
وَلَوۡ يُؤَاخِذُ ٱللَّهُ ٱلنَّاسَ بِظُلۡمِهِم مَّا تَرَكَ عَلَيۡهَا مِن دَآبَّةٖ وَلَٰكِن يُؤَخِّرُهُمۡ إِلَىٰٓ أَجَلٖ مُّسَمّٗىۖ فَإِذَا جَآءَ أَجَلُهُمۡ لَا يَسۡتَٔۡخِرُونَ سَاعَةٗ وَلَا يَسۡتَقۡدِمُونَ 61
Ti Allah ti mimọ nbẹ fun ba fẹ fi iya jẹ awọn eniyan nitori abosi wọn ati keferi wọn ko nii sẹ eniyan kankan tabi ẹranko ti nrin lori ilẹ ku, sugbọn Oun ti mimọ nbẹ fun lọ wọn lara titi di asiko kan ti A fi aala si ninu imọ Rẹ, nigbati asiko ti A fi aala si ninu imọ Rẹ yi ba de, wọn ko le lọọ lara, wọn ko si le gba iwaju ki baa se asiko kekere.
وَيَجۡعَلُونَ لِلَّهِ مَا يَكۡرَهُونَۚ وَتَصِفُ أَلۡسِنَتُهُمُ ٱلۡكَذِبَ أَنَّ لَهُمُ ٱلۡحُسۡنَىٰۚ لَا جَرَمَ أَنَّ لَهُمُ ٱلنَّارَ وَأَنَّهُم مُّفۡرَطُونَ 62
Wọn ngbe bibi obinrin fun Allah ti mimọ nbẹ fun eyiti wọn korira sise afiti si ọdọ ara wọn, ahọn wọn si nsọ irọ wipe awọn ni ipo daradara ni ọdọ Allah, ti o ba jasi wipe wọn yoo gbe wọn dide gẹgẹ bi wọn se nsọ, ni ododo dajudaju ina nbẹ fun wọn, bẹẹ ni dajudaju wọn yoo pa wọn ti sibẹ, wọn koo nii jade nibẹ lailai.
تَٱللَّهِ لَقَدۡ أَرۡسَلۡنَآ إِلَىٰٓ أُمَمٖ مِّن قَبۡلِكَ فَزَيَّنَ لَهُمُ ٱلشَّيۡطَٰنُ أَعۡمَٰلَهُمۡ فَهُوَ وَلِيُّهُمُ ٱلۡيَوۡمَ وَلَهُمۡ عَذَابٌ أَلِيمٞ 63
Mo fi Allah bura, paapaa julọ A ti gbe awọn ojisẹ dide si awọn ijọ wọn siwaju tirẹ -ire ojise-, esu si se isẹ aburu wọn lọsọ fun wọn gẹgẹ bi ẹbọ, keferi ati awọn ẹsẹ, oun ni alaranse wọn ti wọn nlero ni ọjọ igbende, ki wọn ya wa a ni alaranse, iya itara si nbẹ fun wọn ni ọjọ igbende.
وَمَآ أَنزَلۡنَا عَلَيۡكَ ٱلۡكِتَٰبَ إِلَّا لِتُبَيِّنَ لَهُمُ ٱلَّذِي ٱخۡتَلَفُواْ فِيهِ وَهُدٗى وَرَحۡمَةٗ لِّقَوۡمٖ يُؤۡمِنُونَ 64
A ko sọ Alukuraani kalẹ fun ọ - irẹ ojisẹ - ayaafi ki o le alaye fun gbogbo nkan ti wọn nyapa le lori ni mimọ Ọlọhun Ọba lọkan ati igbende ati awọn idajọ ofin ati ki Alukuraani le jẹ imọna ati ikẹ fun gbogbo awọn olugbagbọ ododo ninu Allah ati ojisẹ Rẹ ati pẹlu ohun ti Alukuraani mu wa, awọn ni ẹniti yoo se anfaani pẹlu ododo.
Ninu aimọkan awọn ẹlẹbọ: ni fifi ọmọbinrin ti si ọdọ Allah ti O ga ati fifi ọmọkunrin ti si ọdọ ara wọn, ati yiyiwọ kuro ni ọdọ awọn obinrin, ati yiyi pada oju wọn niti ibanujẹ ati ironu lori ọmọbinrin, ati fifi ara pamọ ẹnikan ninu wọn ati sise afẹku ni iwaju awọn ijọ nitori lile koko ibanujẹ ati biburu idojuti ati aleebu ati itiju ti yoo ba a nitori obinrin ti o bi.
Ninu isesi Allah ni didẹ awọn keferi lẹkẹ ati mimọ kanju fifi iya jẹ wọn, ki O le fi aaye silẹ fun inigbagbọ ati ironu piwada.
Ikolekan Anọbi ti ikọ ati ọla nbẹ fun ti o tobi julọ ni sise alaye ohun ti o wa ninu Alukuraani ati sise alaye ohun ti awọn onilana orisirisi ati awọn onifẹẹnu nyapa le lori ninu ẹsẹ ati awọn idajọ, awijare yoo wa maa bẹ le wọn lori lati ara alaye rẹ.