وَلَقَدۡ صَرَّفۡنَا فِي هَٰذَا ٱلۡقُرۡءَانِ لِلنَّاسِ مِن كُلِّ مَثَلٖۚ وَكَانَ ٱلۡإِنسَٰنُ أَكۡثَرَ شَيۡءٖ جَدَلٗا 54
Paapaa a ti salaye, a si se oniranran apejuwe ninu Alukuraani ti a sọkalẹ fun Muhammad ti ikẹ ati ọla nbẹ fun ki o le ba se iranti, ki wọn si gba isiti, sugbọn ọmọ ẹda eniyan –paapaa julọ keferi- ohun ti o pọ ju ti o ma nhan ni ọdọ rẹ ni iyan laisi lori ododo.
وَمَا مَنَعَ ٱلنَّاسَ أَن يُؤۡمِنُوٓاْ إِذۡ جَآءَهُمُ ٱلۡهُدَىٰ وَيَسۡتَغۡفِرُواْ رَبَّهُمۡ إِلَّآ أَن تَأۡتِيَهُمۡ سُنَّةُ ٱلۡأَوَّلِينَ أَوۡ يَأۡتِيَهُمُ ٱلۡعَذَابُ قُبُلٗا 55
Ko si ohun ti o kọ fun awọn keferi olori kunkun lati mase ni igbagbọ si Muhammad ti ikẹ ati ọla nbẹ fun lati ọdọ Ọlọhun rẹ, didinku alaye ko kọ fun wọn lati mase wa aforijin lọsi ọdọ Ọlọhun nibi ẹsẹ wọn, paapaa wọn ti fi apejuwe ti o pọ lile ninu Alukuraani fun wọn, bẹẹni awọn ẹri ti o fi oju han si waa ba wọn sugbọn ohun ti o kọ fun wọn ni - pẹlu sise orikunkun - bibọ sinu iya awọn ijọ ti o ti siwaju wọn le wọn lori ati fifi oju ri iya eyiti wọn se ni adehun fun wọn.
وَمَا نُرۡسِلُ ٱلۡمُرۡسَلِينَ إِلَّا مُبَشِّرِينَ وَمُنذِرِينَۚ وَيُجَٰدِلُ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ بِٱلۡبَٰطِلِ لِيُدۡحِضُواْ بِهِ ٱلۡحَقَّۖ وَٱتَّخَذُوٓاْ ءَايَٰتِي وَمَآ أُنذِرُواْ هُزُوٗا 56
A ko gbe dide awọn ti a gbe dide ninu awọn ojisẹ wa ayaafi ki wọn le jẹ olufunwọn niro idunnu fun awọn ti o nigbagbọ, ti wọn si ntẹle asẹ Wa ati ki wọn le jẹ oludẹruba awọn keferi ati ẹsẹ, ko si ijẹgaba lori ọkan ti yoo gbe wọn lọ si ibi imọna, ki o si tun le jẹ oluba awọn ti wọn se keferi si Allah ja ati awọn ojisẹ pẹlu awọn ẹri ti o fi oju han si wọn, ki wọn le ododo ti o sọkalẹ fun Muhammad ti ikẹ ati ọla nbẹ fun mu ibajẹ kuro, wọn si sọ Alukuraani ati ohun ti wọn fi ndẹru ba wọn di nkan irẹrin ati yẹyẹ.
وَمَنۡ أَظۡلَمُ مِمَّن ذُكِّرَ بَِٔايَٰتِ رَبِّهِۦ فَأَعۡرَضَ عَنۡهَا وَنَسِيَ مَا قَدَّمَتۡ يَدَاهُۚ إِنَّا جَعَلۡنَا عَلَىٰ قُلُوبِهِمۡ أَكِنَّةً أَن يَفۡقَهُوهُ وَفِيٓ ءَاذَانِهِمۡ وَقۡرٗاۖ وَإِن تَدۡعُهُمۡ إِلَى ٱلۡهُدَىٰ فَلَن يَهۡتَدُوٓاْ إِذًا أَبَدٗا 57
Ko si ẹnikẹni ti o se abosi to ẹniti wọn darukọ awọn amin Ọlọhun Ọba rẹ ti ko si ka a kun pẹlu adehun iya ti nbẹ ni ninu rẹ, ti o si tun gunri kuro nibi isiti pẹlu rẹ, ti o si gbagbe ohun ti o ti siwaju ninu isẹmin aye gẹgẹ bi keferi ati ẹsẹ, ti ko si sẹri nibẹ, dajudaju a se abibo lori awọn ọkan ti a fi eleyi royin, ti yoo kọ fun un lati ma gbọ Alukuraani ye, bẹẹni edidi nbẹ ni eti wọn, wọn ko le gbọ ọ ni agbọgba, ti wọn ba pe wọn lọ si ibi igbagbọ, wọn ko ni jẹpe ohun ti wọn pe wọn lailai, ni okuru igbati ebibo ba nbẹ ni ori ọkan, ti edidi si wa ni awọn eti wọn.
وَرَبُّكَ ٱلۡغَفُورُ ذُو ٱلرَّحۡمَةِۖ لَوۡ يُؤَاخِذُهُم بِمَا كَسَبُواْ لَعَجَّلَ لَهُمُ ٱلۡعَذَابَۚ بَل لَّهُم مَّوۡعِدٞ لَّن يَجِدُواْ مِن دُونِهِۦ مَوۡئِلٗا 58
Nitori ki Anọbi ti ikẹ ati ọla nbẹ fun ma ba wo ipọnju awọn opurọ si iya, Ọlọhun Ọba Allah sọ fun: Ọlọhun rẹ -ire ojise- jẹ oluforijinni fun ẹsẹ awọn ẹru Rẹ ti wọn ba ronu piwada, onikẹ eyiti o gbaaye debi gbogbo nkan, ninu ikẹ Rẹ nipe O ma nlọ ẹlẹsẹ lara boya wọn yoo sẹri pada si ọdọ Rẹ, ti o ba jẹ pe Oun ti O ga julọ ba fi iya jẹ awọn ti wọn gunri yii, ki ba kanju fi iya jẹ wọn ni isẹmin aye, sugbọn O jẹ Onitẹmọra, Onikẹ, O lọ iya wọn lara ki wọn le ronu piwada, bẹẹni aaye ati asiko ti a fi aala si wa nibẹ ti wọn yoo san wọn ni ẹsan nibẹ lori keferi wọn ati igunri wọn ti wọn ko ba sẹri pada, wọn ko le ri ibusẹrisi ti wọn yoo sẹri si yatọ si I.
وَتِلۡكَ ٱلۡقُرَىٰٓ أَهۡلَكۡنَٰهُمۡ لَمَّا ظَلَمُواْ وَجَعَلۡنَا لِمَهۡلِكِهِم مَّوۡعِدٗا 59
Abule keferi eyiti o sun mọ yin yii gẹgẹ bi awọn abule ijọ Huud ati Sọlihu ati Shuayb a pa wọn run nigbati wọn se abosi ẹmin ara wọn pẹlu sise keferi ati ẹsẹ, a si asiko pato fun piwọn run.
وَإِذۡ قَالَ مُوسَىٰ لِفَتَىٰهُ لَآ أَبۡرَحُ حَتَّىٰٓ أَبۡلُغَ مَجۡمَعَ ٱلۡبَحۡرَيۡنِ أَوۡ أَمۡضِيَ حُقُبٗا 60
Ki ẹ ranti - irẹ ojisẹ - nigbati Musa ẹniti ọla nbẹ fun sọ fun ọmọ ọdọ rẹ Yusau ọmọ Nuunu: emi ko nii yẹ ni ẹniti nlọ titi ti maa fi de ibi ti odo meji ti pade, tabi ki nmaa lọ fun asiko gigun titi maa fi pade ẹru rere naa ki nle kẹkọ ni ọdọ rẹ.
فَلَمَّا بَلَغَا مَجۡمَعَ بَيۡنِهِمَا نَسِيَا حُوتَهُمَا فَٱتَّخَذَ سَبِيلَهُۥ فِي ٱلۡبَحۡرِ سَرَبٗا 61
Awọn mejeeji nlọ nigbati wọn de ibupade omin meji, wọn gbagbe ẹjẹ wọn eyiti wọn mu dani ni esenpa fun wọn, Ọlọhun Ọba Allah si ta ẹja naa ji, o si mu ọna kan tọ ninu omin gẹgẹbi palapolu inu ilẹ ti omin ko pade mọ ọ.
Titobi Alukuraani ati gbigbọngbọn rẹ ati kikari rẹ; toripe gbogbo ọna nbẹ nibẹ ti o le muni lọ si ibi awọn imọ ati oriire lailai ati gbogbo ọna ti o le lani kuro nibi aburu.
Ninu ọgbọn Allah ati ikẹ Rẹ ni ki O gba olubilẹjẹ, oluja ododo niyan pẹlu ibajẹ laaye, o si wa ninu okunfa ti o tobi lati jẹ ki ododo han ati ki ibajẹ ati aidara le hande.
O nbẹ ninu awọn amin idẹruba fun ẹniti o gbe ododo ju silẹ lẹyin ti o mọ idigaga laarin ohun ati ododo, ko si le rọ ọ lọrun lẹyin eleyi, ounti o tobi ni idẹrubani ati ijagbemọni kọja eleyi.
Ọla imọ ati irin ajo lati le wa rirọrọ pẹlu pipade awọn ẹni ọla ati awọn onimimọ koda bi agbegbe wọn jinna.
Gbolohun Huutu jẹ ohun ti a nlo fun ẹja kekere ati ninla, bẹẹni gbolohun samaku ko wa ninu Alukuraani, eyi ti o wa ni Huutu, Nuun ati ekiri yiyi.