إِن نَّقُولُ إِلَّا ٱعۡتَرَىٰكَ بَعۡضُ ءَالِهَتِنَا بِسُوٓءٖۗ قَالَ إِنِّيٓ أُشۡهِدُ ٱللَّهَ وَٱشۡهَدُوٓاْ أَنِّي بَرِيٓءٞ مِّمَّا تُشۡرِكُونَ 54
Ohun ti a sọ ni wipe, apakan ohun ti o sẹlẹ si awọn ọlọhun ọba wa gẹgẹ bi aini laakaye ni ohun ti o fi nkọ fun wọn kuro nibi sinsin, Huud sọ wipe: dajudaju mo fi Allah jẹri, ki ẹyin naa si jẹri wipe mo bọpa bọsẹ kuro nibi sinsin ọlọhun ọba yin eyiti ẹ nsin yatọ si Allah, ki ẹ maa da ete si mi ẹyin ati awọn ọlọhun ọba yin ti ẹ nleri wipe o le yẹ laakaye mi, lẹyin igba naa ki ẹ mase lọ mi lara rara.
مِن دُونِهِۦۖ فَكِيدُونِي جَمِيعٗا ثُمَّ لَا تُنظِرُونِ 55
Ohun ti a sọ ni wipe, apakan ohun ti o sẹlẹ si awọn ọlọhun ọba wa gẹgẹ bi aini laakaye ni ohun ti o fi nkọ fun wọn kuro nibi sinsin, Huud sọ wipe: dajudaju mo fi Allah jẹri, ki ẹyin naa si jẹri wipe mo bọpa bọsẹ kuro nibi sinsin ọlọhun ọba yin eyiti ẹ nsin yatọ si Allah, ki ẹ maa da ete si mi ẹyin ati awọn ọlọhun ọba yin ti ẹ nleri wipe o le yẹ laakaye mi, lẹyin igba naa ki ẹ mase lọ mi lara rara.
إِنِّي تَوَكَّلۡتُ عَلَى ٱللَّهِ رَبِّي وَرَبِّكُمۚ مَّا مِن دَآبَّةٍ إِلَّا هُوَ ءَاخِذُۢ بِنَاصِيَتِهَآۚ إِنَّ رَبِّي عَلَىٰ صِرَٰطٖ مُّسۡتَقِيمٖ 56
Dajudaju emi gbarale Ọlọhun Ọba Allah nikan soso, mo gbe ọkan le nibi ọrọ mi, Oun ni Ọlọhun Ọba mi ati Ọlọhun Ọba yin, ko si nkankan ti o nrin ni ori ilẹ ayaafi ki o tẹriba fun Allah ni abẹ ọla Rẹ ati ikapani Rẹ, O ma nse bi o se wu U, dajudaju Ọlọhun Ọba mi wa lori ododo ati deedee, ko le fun yin nikapa lemi lori; nitori wipe dajudaju moi wa lori ododo, emi si wa lori ibajẹ.
فَإِن تَوَلَّوۡاْ فَقَدۡ أَبۡلَغۡتُكُم مَّآ أُرۡسِلۡتُ بِهِۦٓ إِلَيۡكُمۡۚ وَيَسۡتَخۡلِفُ رَبِّي قَوۡمًا غَيۡرَكُمۡ وَلَا تَضُرُّونَهُۥ شَيًۡٔاۚ إِنَّ رَبِّي عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٍ حَفِيظٞ 57
Ti ẹ ba gunri, ti ẹ si pẹyin da kuro nibi ohun ti mo muwa, ko jẹ dandan fun mi ju imudopin lọ, paapaa mo ti fi to yin leti gbogbo ohun ti Ọlọhun Ọba Allah fi ran mi, ti O si pa mi lasẹ ki nmu de ogongo, paapaa, awijare si ti wa le yin lori, Ọlọhun Ọba mi yoo si pa yin run, yoo si mu ẹlomiran wa ti yoo role yin, bẹẹ ni ẹ ko le fi inira kankan kan Allah eyiti o tobi tabi eyiti o kere nitori irọ pipa ati igunri yin; nitori wipe O rọrọ kuro ni ọdọ awọn ẹru Rẹ, dajudaju Ọlọhun Ọba mi jẹ alamojuto gbogbo nkan, Oun ni ẹniti o sọ mi kuro nibi aburu eyiti ẹmin yin nda ete rẹ si mi.
وَلَمَّا جَآءَ أَمۡرُنَا نَجَّيۡنَا هُودٗا وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ مَعَهُۥ بِرَحۡمَةٖ مِّنَّا وَنَجَّيۡنَٰهُم مِّنۡ عَذَابٍ غَلِيظٖ 58
Nigbati asẹ wa lati pa yin run de, a la Huud ati awọn ti wọn nigbagbọ si i nitori ikẹ wa ti o le wọn ba, a si la wọn kuro nibi iya ti o le eyiti a fi jẹ awọn ijọ rẹ ti o jẹ keferi.
وَتِلۡكَ عَادٞۖ جَحَدُواْ بَِٔايَٰتِ رَبِّهِمۡ وَعَصَوۡاْ رُسُلَهُۥ وَٱتَّبَعُوٓاْ أَمۡرَ كُلِّ جَبَّارٍ عَنِيدٖ 59
Ijọ Hadi yii se keferi si awọn amin Olohun Ọba wọn, wọn si sẹ ojisẹ wọn Huud, wọn si tẹle asẹ gbogbo onigberaga si ododo, olukọja ẹnu aala ti ko gba a, bẹẹ ni ko si tẹriba fun un.
وَأُتۡبِعُواْ فِي هَٰذِهِ ٱلدُّنۡيَا لَعۡنَةٗ وَيَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِۗ أَلَآ إِنَّ عَادٗا كَفَرُواْ رَبَّهُمۡۗ أَلَا بُعۡدٗا لِّعَادٖ قَوۡمِ هُودٖ 60
Itiju ati ileni kuro nibi ikẹ Allah le wọn ba ni isẹmi aye, bẹẹ naa ni wọn yoo jẹ olujinna si ikẹ Allah ni ọjọ igbende nitori keferi wọn si Allah, ẹ tẹti gbọ, Ọlọhun Ọba Allah mu wọn takete si gbogbo daadaa, o si mu wọn sun mọ gbogbo aburu.
۞وَإِلَىٰ ثَمُودَ أَخَاهُمۡ صَٰلِحٗاۚ قَالَ يَٰقَوۡمِ ٱعۡبُدُواْ ٱللَّهَ مَا لَكُم مِّنۡ إِلَٰهٍ غَيۡرُهُۥۖ هُوَ أَنشَأَكُم مِّنَ ٱلۡأَرۡضِ وَٱسۡتَعۡمَرَكُمۡ فِيهَا فَٱسۡتَغۡفِرُوهُ ثُمَّ تُوبُوٓاْ إِلَيۡهِۚ إِنَّ رَبِّي قَرِيبٞ مُّجِيبٞ 61
A tun ran ọmọ iya wọn sọlihu si ijọ samudawa o sọ wipe: irẹ ijọ mi, ẹ maa sin Allah nikan soso, ko si fun yin olujọsin fun ti ijọsin tọsi yatọ si I, Oun ni o da yin lati ibi yẹpẹ ilẹ pẹlu dida baba yin aadamọ ninu rẹ, o si se yin ni olumojuto o, ki ẹ ya wa aforijin ni ọdọ rẹ, ki ẹ si sẹri lọ si ọdọ Rẹ pẹlu sise isẹ itẹle asẹ ati gbigbe awọn ẹsẹ ju silẹ, dajudaju Ọba mi jẹ olusunmọ ẹniti o ba se afọmọ ẹsin rẹ, O si jẹ olujẹpe ẹniti o ba pe E.
قَالُواْ يَٰصَٰلِحُ قَدۡ كُنتَ فِينَا مَرۡجُوّٗا قَبۡلَ هَٰذَآۖ أَتَنۡهَىٰنَآ أَن نَّعۡبُدَ مَا يَعۡبُدُ ءَابَآؤُنَا وَإِنَّنَا لَفِي شَكّٖ مِّمَّا تَدۡعُونَآ إِلَيۡهِ مُرِيبٖ 62
Awọn ijo rẹ sọ fun wipe: irẹ sọlihu, o ti jẹ onipo giga laarin wa siwaju ki o to maa pe ipe yii, paapaa a ti nreti ki o jẹ oni laakaye onisiti ati olubajiroro, se iwọ yoo maa kọ fun wa ki –irẹ sọlihu- kuro nibi ijọsin ti awọn baba wa nsin? Awa nse iyemeji si ohun ti o npe wa sibẹ nibi ki a maa si Olohun Ọba Allah nikan soso, eleyi ni o mu wa tẹri sibi ki a pa irọ mọ Allah.
Ninu awọn okunfa awọn ẹlẹbọ nibi sisa fun ojisẹ ni ki a maa fura si fifuyẹ laakaye ati ori didaru.
Lilẹ awọn ẹlẹbọ wa nibi ete wọn ati isọta wọn, wọn jẹ ẹniti o ntẹriba fun Allah ti a o si bori labẹ asẹ rẹ ati ọla Rẹ.
Awọn ẹri lori itọju Ọlọhun fun ẹda ati sise ohun kihun nbẹ nibi ijọkan soso ẹniti a njọsin fun ati gbigbe ohun ti oyatọ si Allah ju silẹ.