وَلَوۡ أَنَّ لِكُلِّ نَفۡسٖ ظَلَمَتۡ مَا فِي ٱلۡأَرۡضِ لَٱفۡتَدَتۡ بِهِۦۗ وَأَسَرُّواْ ٱلنَّدَامَةَ لَمَّا رَأَوُاْ ٱلۡعَذَابَۖ وَقُضِيَ بَيۡنَهُم بِٱلۡقِسۡطِ وَهُمۡ لَا يُظۡلَمُونَ 54
Ti gbogbo nkan ti nbẹ ni ori ilẹ ba nbẹ fun olusebo kan pẹlu Allah ninu awọn dukia ti o niye lori, ki ba fi se idojukọ lati tu ara rẹ silẹ kuro nibi iya Ọlọhun Ọba Allah, ti wọn ba fun ni igbalaaye lati fi di i, awọn ẹlẹbọ se afipamọ abamọ lori keferi wọn nigbati wọn ri iya ni ọjọ igbende, ti Ọlọhun Ọba Allah si se idajọ laarin wọn pẹlu deedee, ti wọn ko si se abosi si wọn rara, ti wọn san wọn lẹsan lori isẹ wọn.
أَلَآ إِنَّ لِلَّهِ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۗ أَلَآ إِنَّ وَعۡدَ ٱللَّهِ حَقّٞ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَهُمۡ لَا يَعۡلَمُونَ 55
Ẹ tẹti dajudaju Allah nikan soso ni o nikapa ohun ti o nbẹ ni sanmọ ati ohun ti o wa ni ilẹ, ẹ tẹti dajudaju adehun Ọlọhun Ọba Allah lati fi iya jẹ awọn keferi ohun ti o yoo sẹlẹ ni, ti ko si iyemeji nibẹ sugbọn ọpọlọpọ wọn wọn ko mọ eleyi, ni wọn fi nse iyemeji.
هُوَ يُحۡيِۦ وَيُمِيتُ وَإِلَيۡهِ تُرۡجَعُونَ 56
Oun ti mimọ nbẹ fun ni yoo gbe awọn oku dide, ti O si le pa awọn alaaye, ọdọ Rẹ nikan ni ẹ o sẹri si ni ọjọ igbende, yoo si san yin lẹsan lori isẹ yin.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ قَدۡ جَآءَتۡكُم مَّوۡعِظَةٞ مِّن رَّبِّكُمۡ وَشِفَآءٞ لِّمَا فِي ٱلصُّدُورِ وَهُدٗى وَرَحۡمَةٞ لِّلۡمُؤۡمِنِينَ 57
Ẹyin eniyan paapaa alukuraani ti wa ba yin, ti iranti iseni loju kokoro, idẹru bani wa nibẹ, o si jẹ iwosan fun aarẹ ti o wa ninu ọkan bii iyemeji ati roiroi ati itọsọna si oju ọna ododo, ikẹ si wa ninu rẹ fun awọn olugbagbọ ododo, awọn ni ẹniti yoo se anfaani pẹlu rẹ.
قُلۡ بِفَضۡلِ ٱللَّهِ وَبِرَحۡمَتِهِۦ فَبِذَٰلِكَ فَلۡيَفۡرَحُواْ هُوَ خَيۡرٞ مِّمَّا يَجۡمَعُونَ 58
Sọ - ire ojise - fun awọn eniyan: nkan ti mo mu wa fun yin ninu Alukuraani jẹ ọla le yin lori, o si tun jẹ ikẹ lati ọdọ Rẹ fun yin nitori ọla Ọlọhun Ọba Allah ti o wa lori yin ati ikẹ Rẹ ti o wa pẹlu yin lati sisọ Alukuraani kalẹ, ki ẹ yaa maa yọ laisi nkan miran yatọ si I, Muhammad ti ikẹ ati ọla nbẹ fun muwa lati ọdọ Ọlọhun Ọba rẹ jẹ oore ju nkan ti ẹ kojọ ninu ọrọ ile aye ti yoo yẹ lọ.
قُلۡ أَرَءَيۡتُم مَّآ أَنزَلَ ٱللَّهُ لَكُم مِّن رِّزۡقٖ فَجَعَلۡتُم مِّنۡهُ حَرَامٗا وَحَلَٰلٗا قُلۡ ءَآللَّهُ أَذِنَ لَكُمۡۖ أَمۡ عَلَى ٱللَّهِ تَفۡتَرُونَ 59
Sọ - irẹ ojisẹ - fun awọn ẹlẹbọ yii, ẹ fun mi niro nipa nkan ti Ọlọhun Ọba se idẹkun rẹ leyin lori nibi sisọ arisiki kalẹ, sugbọn ti ẹ lo ifẹ inu yin nibẹ, ẹ se apakan leewọ, bẹẹ ni ẹ se apakan lẹtọ, sọ fun wọn: se Ọlọhun Ọba ni o se lẹtọ fun yin nibi oun ti ẹ se lẹtọ tabi se leewọ fun yin nibi oun ti ẹ se leewọ, tabi ẹyin ni ẹ da adapa irọ yii?!
وَمَا ظَنُّ ٱلَّذِينَ يَفۡتَرُونَ عَلَى ٱللَّهِ ٱلۡكَذِبَ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِۗ إِنَّ ٱللَّهَ لَذُو فَضۡلٍ عَلَى ٱلنَّاسِ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَهُمۡ لَا يَشۡكُرُونَ 60
Eyikeyi nkan ti awọn onirọ ba lero ni yoo sẹlẹ si wọn ni ọjọ igbende?! Se wọn yoo lero wipe Allah yoo forijin wọn?! Ko le ri bẹẹ, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah jẹ ọlọpọlọpọ ọla lori awọn eniyan pẹlu lilọwọn lara ati aini kanju jẹwọn niya, sugbọn ọpọlọpọ wọn ni wọn njiyan nipa awọn idẹra Ọlọhun Ọba Allah ti o nse fun wọn ti wọn o si dupẹ rẹ.
وَمَا تَكُونُ فِي شَأۡنٖ وَمَا تَتۡلُواْ مِنۡهُ مِن قُرۡءَانٖ وَلَا تَعۡمَلُونَ مِنۡ عَمَلٍ إِلَّا كُنَّا عَلَيۡكُمۡ شُهُودًا إِذۡ تُفِيضُونَ فِيهِۚ وَمَا يَعۡزُبُ عَن رَّبِّكَ مِن مِّثۡقَالِ ذَرَّةٖ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَلَا فِي ٱلسَّمَآءِ وَلَآ أَصۡغَرَ مِن ذَٰلِكَ وَلَآ أَكۡبَرَ إِلَّا فِي كِتَٰبٖ مُّبِينٍ 61
Kinni ohun ti yoo jẹ - ire ojise - idarisi alamọri ati nkan ti o nka ninu alukuraani ati ohun ti ẹ nse ninu isẹ - ẹyin olugbagbọ ododo -, bikose wipe awa nri yin nigbati ẹ nse isẹ, a si ngbọ yin nigbati ẹ bẹrẹ sini se isẹ naa, ti ẹ si nwọ inu rẹ, osunwọn ọmọ inaagun nisanmọ tabi nilẹ ninu imọ ko pamọ fun Ọlọhun Ọba rẹ, koda eyiti o kere ninu osunwọn rẹ tabi eyiti o tobi bikose wipe o jẹ ohun ti a ti de mọlẹ ninu iwe ti o fi oju han, ko ni fi kekere tabi nla silẹ ayaafi ki o ka a.
Titobi ohun ti nreti awọn ẹlẹbọ si Ọlọhun Ọba ninu iya debi wipe wọn yoo maa rankan fifi gbogbo ohun ti nbẹ lori ilẹ da a pada, sugbọn wọn ko nii gba a lọwọ wọn.
Alukuraani jẹ iwosan fun awọn olugbagbọ ododo kuro nibi awọn aarẹ adun ati awọn aarẹ iruju nitori awọn imọna ati awọn itọka laakaye ati awọn ẹri ti o wa ninu rẹ.
O tọ ki olugbagbọ yọ pẹlu idẹkun Islam ati igbagbọ yatọ si nkan miran ninu awọn oore ile aye.
Wiwẹ akiyesi Ọlọhun Ọba Allah fun awọn ẹru Rẹ ati awọn isẹ wọn ati awọn ero ọkan wọn ati awọn adisọkan wọn.