وَكَذَٰلِكَ فَتَنَّا بَعۡضَهُم بِبَعۡضٖ لِّيَقُولُوٓاْ أَهَٰٓؤُلَآءِ مَنَّ ٱللَّهُ عَلَيۡهِم مِّنۢ بَيۡنِنَآۗ أَلَيۡسَ ٱللَّهُ بِأَعۡلَمَ بِٱلشَّٰكِرِينَ 53
Bayi ni a fi apakan dan apakan wo, a si jẹ ki apakan ju apakan lọ ninu ipin aye, a dan wọn bayi, ki awọn keferi ti wọn ni ọrọ le maa sọ fun awọn alaini ninu awọn olugbagbọ ododo: se awọn olosi ti Ọlọhun Ọba Allah fẹ gbe le wa lori niyi nitori imọna ti wọn ni laarin wọn? ! Ti o ba lọ ja si wipe igbagbọ jẹ oore ni, wọn ko nii saaju wa de ibẹ, awa ni ẹni isiwaju, kii wa se wipe Ọlọhun Ọba Allah mọ ẹni ti o ndupẹ lori idẹkun Rẹ bi, ki o le fi wọn se kongẹ igbagbọ, tabi se ko wa mọ awọn ti wọn nse keferi siI, ki O le dagunla si wọn, wọn ko le gbagbọ? ! Bẹẹ ni dajudaju Ọlọhun Ọba Allah ni imọ pẹlu wọn.
وَإِذَا جَآءَكَ ٱلَّذِينَ يُؤۡمِنُونَ بَِٔايَٰتِنَا فَقُلۡ سَلَٰمٌ عَلَيۡكُمۡۖ كَتَبَ رَبُّكُمۡ عَلَىٰ نَفۡسِهِ ٱلرَّحۡمَةَ أَنَّهُۥ مَنۡ عَمِلَ مِنكُمۡ سُوٓءَۢا بِجَهَٰلَةٖ ثُمَّ تَابَ مِنۢ بَعۡدِهِۦ وَأَصۡلَحَ فَأَنَّهُۥ غَفُورٞ رَّحِيمٞ 54
Ti wọ ba wa ba ọ - ire ojise - awọn ti wọn nigbagbọ si awọn amin wa ti njẹri lori ododo ohun ti o mu wa, fesi fun pẹlu sisalamọ apọnle, fun wọn niro idunnu gbigbaaye ikẹ Ọlhun Ọba Allah, paapaa julọ Ọlhun Ọba Allah ti se ikẹ Rẹ ni dandan fun ara Rẹ niti sise ọla, ẹniti o ba da ẹsẹ ninu yin nigba aimọkan ati omugọ, ti o wa ronupiwada lẹyin igbati o ti see tan, ti o si se atunse isẹ rẹ, Ọlọhun Ọba Allah yoo se aforijin ẹsẹ rẹ, Ọlọhun Ọba Allah jẹ oluse aforijin fun ẹniti o ba ronu piwada ninu awọn ẹru Rẹ, O tun jẹ onikẹ si wọn.
وَكَذَٰلِكَ نُفَصِّلُ ٱلۡأٓيَٰتِ وَلِتَسۡتَبِينَ سَبِيلُ ٱلۡمُجۡرِمِينَ 55
Gẹgẹ bi a ti se alaye fun ọ nkan ti wọn sọ, a o se alaye awọn ẹri wa ati awijare wa lori awọn olubilẹjẹ ati lati se adayanri ọna awọn ẹlẹsẹ ati ojupọnna wọn; nitori jijinna sii ati sisọra kuro.
قُلۡ إِنِّي نُهِيتُ أَنۡ أَعۡبُدَ ٱلَّذِينَ تَدۡعُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِۚ قُل لَّآ أَتَّبِعُ أَهۡوَآءَكُمۡ قَدۡ ضَلَلۡتُ إِذٗا وَمَآ أَنَا۠ مِنَ ٱلۡمُهۡتَدِينَ 56
Sọ wipe - ire ojise - dajudaju Ọlọhun Ọba Allah kọ fun mi niti jijọsin fun awọn ohun ti ẹ njọsin fun tii kii se Allah, sọ wipe - ire ojise - emi ko nii tẹle ifẹ yin nibi jijọsin fun ohun ti o yatọ si Allah nitori wipe ti mo ba tẹle ifẹ yin nibi eleyi, maa di ẹni anu kuro ni oju ọna ododo, ti emi ko nii le mọ ọna mọ, eleyi ni isesi gbogbo ẹniti o ba ntẹle ifẹ inu, ti ko si awijare kankan fun lati ọdọ Ọlọhun Ọba Allah.
قُلۡ إِنِّي عَلَىٰ بَيِّنَةٖ مِّن رَّبِّي وَكَذَّبۡتُم بِهِۦۚ مَا عِندِي مَا تَسۡتَعۡجِلُونَ بِهِۦٓۚ إِنِ ٱلۡحُكۡمُ إِلَّا لِلَّهِۖ يَقُصُّ ٱلۡحَقَّۖ وَهُوَ خَيۡرُ ٱلۡفَٰصِلِينَ 57
Sọ - ire ojise - fun awọn ọlọsẹbọ yii: mo wa lori awijare ti o fi oju han lati ọdọ Ọlhun Ọba mi, kii se lori ifẹ yin ẹyin si nparọ pẹlu awijare yii, ko si ijiya ti nkanju rẹ ni ọdọ mi, tabi awọn amin airiri eyiti ẹ nbeere fun, dajudaju eleyi wa ni ọwọ Ọlọhun Ọba Allah, ko si idajọ - ninu ọpọ nkan ti nbeere fun - ayaafi fun Ọlọhun Ọba Allah nikan soso, O ma nsọ ododo, O si ma ndajọ pẹlu rẹ, Oun nikan ti mimọ nbẹ fun ni O tọ lati salaye tabi se adayanri laarin ohun ti o lẹtọ ati ohun ti ko dara.
قُل لَّوۡ أَنَّ عِندِي مَا تَسۡتَعۡجِلُونَ بِهِۦ لَقُضِيَ ٱلۡأَمۡرُ بَيۡنِي وَبَيۡنَكُمۡۗ وَٱللَّهُ أَعۡلَمُ بِٱلظَّٰلِمِينَ 58
Sọ - ire ojise - fun wọn: ti o ba wa ni ọdọ mi ijiya nkan ti ẹ nkanju beere fun, emi ko ba sọ kalẹ fun yin, nigba yii ni ohun ti nbẹ laarin mi ati yin ki ba ni imusẹ, Ọlọhun Ọba ni o nimọ ju nipa awọn alabosi, iye igba ti O fi fẹ lọ wọn lara, ati igbati yoo fi iya jẹ wọn.
۞وَعِندَهُۥ مَفَاتِحُ ٱلۡغَيۡبِ لَا يَعۡلَمُهَآ إِلَّا هُوَۚ وَيَعۡلَمُ مَا فِي ٱلۡبَرِّ وَٱلۡبَحۡرِۚ وَمَا تَسۡقُطُ مِن وَرَقَةٍ إِلَّا يَعۡلَمُهَا وَلَا حَبَّةٖ فِي ظُلُمَٰتِ ٱلۡأَرۡضِ وَلَا رَطۡبٖ وَلَا يَابِسٍ إِلَّا فِي كِتَٰبٖ مُّبِينٖ 59
Ni ọdọ Ọlọhun Ọba Allah nikan ni pẹpẹ ọrọ kọkọ wa, ẹlomiran ko mọ ọ, Oun ni O mọ gbogbo ohun ti nbẹ ni ori ilẹ ninu ẹda ẹranko tabi irugbin, tabi awọn nkan ọbọrọgidi, O si mọ nkan ti nbẹ ninu omi ninu ẹranko, irugbin ati oborogidi, ewe kankan ko nii ja bọ si eyikeyi aaye, bẹẹ ni irugbin kankan ko ni pamọ si inu ilẹ, bẹẹ ni a ko nii ri nkankan tutu tabi gbigbẹ kan ayaafi ki o ti wa ninu iwe ti o fi oju han, ohun naa ni Laohul mahafus.
Ọlọhun Ọba Allah ma nse awọn ẹru kan si idaamu fun awọn ẹru miran, ipele ipele yoo maa wa bẹ fun wọn ninu arisiki ati ise keferi ati igbagbọ, bẹẹ ni sise keferi ati igbagbọ sise kii se okunfa gbigbaaye arisiki ati fifun pinpin rẹ.
Ninu iwa olupepe ni itujuka ati kiki ara ẹni, igbaaye, idunnu pẹlu awọn eniyan.
O di dandan fun ẹniti o npepe ki o jinna si ifẹ inu nibi adisọkan rẹ ati ojupọnna rẹ ati iwa rẹ.
Fifi ijẹ aaso Ọlọhun Ọba Allah rinlẹ ti mimọ nbẹ fun nibi imọ kọkọ, ti ko si si orogun fun Un ati gbigbaaye imọ Rẹ nibi eleyi, ati wipe ko si ohunkiohun ti o tayọ Rẹ nibẹ, ko si se afẹku nkankan ninu ẹda Rẹ ayaafi ki o ti wa ni akọsilẹ ni ọdọ Rẹ, ni alaye wẹlẹwẹlẹ.