وَيَسۡتَعۡجِلُونَكَ بِٱلۡعَذَابِ وَلَوۡلَآ أَجَلٞ مُّسَمّٗى لَّجَآءَهُمُ ٱلۡعَذَابُۚ وَلَيَأۡتِيَنَّهُم بَغۡتَةٗ وَهُمۡ لَا يَشۡعُرُونَ 53
Wọn yoo maa kan ọ loju - irẹ ojisẹ - awọn ẹlẹbọ si iya eyiti mo se ikilọ rẹ fun wọn, ti kii ba sepe Allah se odiwọn asiko fun iya wọn, ti ko si le gbawaju rẹ tabi kẹyin, ohun ti wọn beere ninu iya ko ba waa ba wọn, ko ba si waa ba wọn ni ojiji ti wọn ko si nii fi ọkan si.
يَسۡتَعۡجِلُونَكَ بِٱلۡعَذَابِ وَإِنَّ جَهَنَّمَ لَمُحِيطَةُۢ بِٱلۡكَٰفِرِينَ 54
Wọn yoo maa kan ọ loju iya eyiti o se ni adehun fun wọn, bẹẹni dajudaju jahannamọ eyiti Allah se ni adehun fun awọn keferi yoo yi wọn ka, wọn ko nikapa sisa kuro nibi iya rẹ.
يَوۡمَ يَغۡشَىٰهُمُ ٱلۡعَذَابُ مِن فَوۡقِهِمۡ وَمِن تَحۡتِ أَرۡجُلِهِمۡ وَيَقُولُ ذُوقُواْ مَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ 55
Ni ọjọ ti iya yoo bo wọn daru lati oke wọn, yoo si tun da gẹgẹ bi itẹ lati abẹ ẹsẹ wọn, Allah yoo si maa sọ fun niti eebu si wọn: ẹ maa tọ ẹsan nkan ti ẹ se lẹbọ ati ni awọn ẹsẹ wo.
يَٰعِبَادِيَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِنَّ أَرۡضِي وَٰسِعَةٞ فَإِيَّٰيَ فَٱعۡبُدُونِ 56
Ẹyin ẹrusin mi ti ẹ nigbagbọ si Mi, ẹ se irin ajo kuro ni ori ilẹ ti ẹ ko ni ifọkanbalẹ nibi ijọsin Mi, dajudaju ilẹ Mi gbaaye ki ẹ sin Mi ni Emi nikan, ki ẹ si ma mu ẹnikẹni mọ Mi.
كُلُّ نَفۡسٖ ذَآئِقَةُ ٱلۡمَوۡتِۖ ثُمَّ إِلَيۡنَا تُرۡجَعُونَ 57
Ipaya iku ki o ma kọ fun yin kuro nibi irin ajo naa, dajudaju gbogbo ẹmin ni yoo tọ iku wo, dajudaju ọdọ Wa nikan ni ẹ o sẹri si ni ọjọ igbende fun isiro ati ẹsan.
وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ لَنُبَوِّئَنَّهُم مِّنَ ٱلۡجَنَّةِ غُرَفٗا تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُ خَٰلِدِينَ فِيهَاۚ نِعۡمَ أَجۡرُ ٱلۡعَٰمِلِينَ 58
Awọn ti o nigbagbọ ninu Allah, ti wọn si nse ọpọlọpọ isẹẹre, ti wọn fi nsun mọ Ọ, a o sọ wọn kalẹ si yara kan ninu Alujannah ti awọn akeremọdo nsan ni abẹ rẹ, wọn yoo si maa gbe ibẹ lọ gbere, titan ko nii ba wọn nibẹ, pipataki ẹsan olusisẹ titẹle Allah niti ẹsan yii.
ٱلَّذِينَ صَبَرُواْ وَعَلَىٰ رَبِّهِمۡ يَتَوَكَّلُونَ 59
Pipataki ẹsan olusisẹ titẹle Allah, awọn ti wọn nse suuru lori titẹle E ati sisẹ Ẹ, ti wọn si gbe ara le Oun nikan nibi gbogbo alamọri wọn.
وَكَأَيِّن مِّن دَآبَّةٖ لَّا تَحۡمِلُ رِزۡقَهَا ٱللَّهُ يَرۡزُقُهَا وَإِيَّاكُمۡۚ وَهُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلۡعَلِيمُ 60
Gbogbo awọn ẹda - bi wọn se pọ to - eyiti ko le ko arisiki rẹ jọ tabi gbe e, Allah ni O nse ariski rẹ, ti O si nse arisiki ti yin naa, ko si awijare nibi gbigbe irin ajo naa ju silẹ ni ipaya ti ebi, Oun si ni olugbọ gbogbo ọrọ yin, Onimimọ nipa awọn erongba yin ati awọn isẹ yin, nkankan ko pamọ fun Un ninu eleyi, yoo si san yin lẹsan le lori.
وَلَئِن سَأَلۡتَهُم مَّنۡ خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ وَسَخَّرَ ٱلشَّمۡسَ وَٱلۡقَمَرَ لَيَقُولُنَّ ٱللَّهُۖ فَأَنَّىٰ يُؤۡفَكُونَ 61
Ti o ba beere - irẹ ojisẹ - lọwọ awọn ẹlẹbọ wọnyi: taani o da sanmọ? Taani o si da ilẹ, taani o rọ ọsan ati osupa ti mejeeji npaarọ ara wọn? Paapaa wọn yo sọ wipe: Allah ni O da wọn, bawo ni wọn se wa nyi igbagbọ ninu Allah nikan soso kuro, ti wọn wa nsin nkan miran ti o yatọ si Ọlọhun Ọba, ti ko le se anfaani, bẹẹni ko le mu inira wa?
ٱللَّهُ يَبۡسُطُ ٱلرِّزۡقَ لِمَن يَشَآءُ مِنۡ عِبَادِهِۦ وَيَقۡدِرُ لَهُۥٓۚ إِنَّ ٱللَّهَ بِكُلِّ شَيۡءٍ عَلِيمٞ 62
Allah ni o ngbaaye arisiki fun ẹniti o ba wu U ninu awọn ẹru Rẹ, o si ma nfun mọ ẹniti o ba wu U; nitori ọgbọn kan ti Oun nikan mọ si, dajudaju Allah jẹ Onimimọ nipa gbogbo nkan, nkankan ko pamọ fun UN, bẹẹni gbogbo ohun ti o le se anfaani fun awọn ẹru Rẹ ninu idari ko pamọ fun Un.
وَلَئِن سَأَلۡتَهُم مَّن نَّزَّلَ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءٗ فَأَحۡيَا بِهِ ٱلۡأَرۡضَ مِنۢ بَعۡدِ مَوۡتِهَا لَيَقُولُنَّ ٱللَّهُۚ قُلِ ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِۚ بَلۡ أَكۡثَرُهُمۡ لَا يَعۡقِلُونَ 63
Ti o ba beere - irẹ ojisẹ - lọwọ awọn ẹlẹbọ: taani o nsọ omin kalẹ ni sanmọ, ti o si nmu irugbin jade ni inu ilẹ lẹyin igbati ti o ti sa? Paapaa wọn yoo sọpe: ẹniti o sọ omin kalẹ ni sanmọ, ti o si nmu irugbin jade ninu ilẹ ni Allah, sọ wipe - irẹ ojisẹ -: ọpẹ ni fun Allah eyiti o se afihan awijare le yin lori bikosepe ohun ti o sẹlẹ ni wipe ọpọlọpọ wọn ko se laakaye; nitoripe ti wọn ba se laakaye ni, wọn ko nii mu nkan miran mọ Allah lẹbọ ti ko le se anfaani tabi ko inira bani.
Kikanju iya fun keferi jẹ itọka lori omugọ rẹ.
Ojupọnna irin ajo nitori lila ẹsin si silẹ.
Ọla ti nbẹ fun suuru ati igbarale Allah.
Fifi ijẹ olutọju rinlẹ fun Ọlọhun Ọba laisi ifirinlẹ ẹni a njọsin fun nibẹ, ko le sọ ọla ati igbagbọ di ododo fun ẹni ti o ni i.