۞وَمَآ أُبَرِّئُ نَفۡسِيٓۚ إِنَّ ٱلنَّفۡسَ لَأَمَّارَةُۢ بِٱلسُّوٓءِ إِلَّا مَا رَحِمَ رَبِّيٓۚ إِنَّ رَبِّي غَفُورٞ رَّحِيمٞ 53
Bayi ni iyawo ọba tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ ni ẹniti o sọ bayi wipe: emi ko fọ ẹmin mi mọ nibi gbigbero aburu, emi ko gbero lati fọ ẹmin mi mọ pẹlu eleyi; nitori wipe isesi ẹmin ọmọniyan ti o pa lasẹ aburu lọpọ igba, nitori wipe ẹmin rẹ yoo maa fi si ibi ti o wu, yoo si soro fun lati kora nijani kuro nibẹ ayaafi eyiti Ọlọhun Ọba Allah ba fẹ ninu awọn ẹmin, ti o si sọ kuro nibi pipalasẹ aburu, dajudaju Ọlọhun Ọba mi jẹ alaforijin fun ẹniti o ba ronu piwada ninu awọn ẹru Rẹ, O si jẹ onikọ si wọn.
وَقَالَ ٱلۡمَلِكُ ٱئۡتُونِي بِهِۦٓ أَسۡتَخۡلِصۡهُ لِنَفۡسِيۖ فَلَمَّا كَلَّمَهُۥ قَالَ إِنَّكَ ٱلۡيَوۡمَ لَدَيۡنَا مَكِينٌ أَمِينٞ 54
Ọba sọ fun awọn olukunlọwọ rẹ nigbati o han si bibọpa bọsẹ Yuusuf ati imọ rẹ: ẹ mu wa fun mi, ki nsaa lẹsa fun ra mi, wọn si mu wa, nigbati o ba sọrọ, ti o wa mọ amọdaju imọ ati laakaye rẹ, o sọ fun wipe: dajudaju iwọ - irẹ Yuusuf - o ti di ẹniti o ni ipo lọdọ wa loni ati iyi ati ẹni ifọkan balẹ si lọdọ.
قَالَ ٱجۡعَلۡنِي عَلَىٰ خَزَآئِنِ ٱلۡأَرۡضِۖ إِنِّي حَفِيظٌ عَلِيمٞ 55
Yuusuf sọ fun ọba: fimi si ibi idaabobo lori ile owo ati awọn ounjẹ ni ilu misirọ, dajudaju mo jẹ olumojuto ẹni ifọkan balẹ, onimimọ ati ẹniti o riran ri nkan ti mo ba nmojuto.
وَكَذَٰلِكَ مَكَّنَّا لِيُوسُفَ فِي ٱلۡأَرۡضِ يَتَبَوَّأُ مِنۡهَا حَيۡثُ يَشَآءُۚ نُصِيبُ بِرَحۡمَتِنَا مَن نَّشَآءُۖ وَلَا نُضِيعُ أَجۡرَ ٱلۡمُحۡسِنِينَ 56
Gẹgẹ bi a se se idẹkun fun Yuusuf lori bibọpa bọsẹ ati lila kuro ninu ẹwọn, a tun se idẹkun fun un pẹlu gbigba laaye ni ilu misirọ, o nsọkalẹ, o si ngbe ni aaye ti o ba wu u, a ma nfun ẹniti o ba wu wa ni ile aye ninu awọn ẹru ni ikẹ wa, awa kii ra lare ẹsan awọn oluse daadaa bikose wipe a o fun wọn ni pipe laisi ẹdinku.
وَلَأَجۡرُ ٱلۡأٓخِرَةِ خَيۡرٞ لِّلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَكَانُواْ يَتَّقُونَ 57
Paapaa ẹsan Ọlọhun Ọba eyiti o pese ni ọrun loore ju ẹsan ti aye lọ fun awọn ti wọn nigbagbọ ninu Allah ti wọn si nbẹru Rẹ lati ibi itẹel awọn asẹ Rẹ ati ijinna si awọn nkan ti O kọ.
وَجَآءَ إِخۡوَةُ يُوسُفَ فَدَخَلُواْ عَلَيۡهِ فَعَرَفَهُمۡ وَهُمۡ لَهُۥ مُنكِرُونَ 58
Awọn ọmọ baba Yuusuf lọ si ilu misirọ pẹlu ọja wọn, wọn si wọ ibẹ, o si mọ wipe awọn ọmọ baba oun ni wọn, sugbọn awọn ko mọ ọ wipe ọmọ baba awọn ni; nitori asiko ti o ti gun ati isesi rẹ ti o ti yi pada; toripe o jẹ ọmọde nigbati wọn ju si inu kanga.
وَلَمَّا جَهَّزَهُم بِجَهَازِهِمۡ قَالَ ٱئۡتُونِي بِأَخٖ لَّكُم مِّنۡ أَبِيكُمۡۚ أَلَا تَرَوۡنَ أَنِّيٓ أُوفِي ٱلۡكَيۡلَ وَأَنَا۠ خَيۡرُ ٱلۡمُنزِلِينَ 59
Nigbati o fun wọn ni nkan ti wọn beere fun ninu ounjẹ irin ajo ati esenpa, o wa sọ fun wọn lẹyin igbati wọn ti fun niro wipe awọn ni ọmọ baba kan ti awọn fi silẹ ni ọdọ baba rẹ: ẹ mu ọmọ baba yin naa wa fun mi, emi yoo se alekun ẹru yin, se ẹ ko ri wipe mo npe osunwọn, bẹẹ ni emi ko din ku, mo si dara ni olugbalejo.
فَإِن لَّمۡ تَأۡتُونِي بِهِۦ فَلَا كَيۡلَ لَكُمۡ عِندِي وَلَا تَقۡرَبُونِ 60
Ti ẹ ko ba mu wa fun mi, o han wipe irọ ni ẹ npa wipe ẹ ni ọmọ baba kan ni, emi ko nii wọn ounjẹ fun yin, ki ẹ si mase sun mọ ilu mi.
قَالُواْ سَنُرَٰوِدُ عَنۡهُ أَبَاهُ وَإِنَّا لَفَٰعِلُونَ 61
Awọn ọmọ baba rẹ da lohun bayi wipe: a o wa lọdọ baba wa, ao si gbiyanju le lori dajudaju a o se ohun ti o paya lasẹ laisi ẹdinku.
وَقَالَ لِفِتۡيَٰنِهِ ٱجۡعَلُواْ بِضَٰعَتَهُمۡ فِي رِحَالِهِمۡ لَعَلَّهُمۡ يَعۡرِفُونَهَآ إِذَا ٱنقَلَبُوٓاْ إِلَىٰٓ أَهۡلِهِمۡ لَعَلَّهُمۡ يَرۡجِعُونَ 62
Yusuf naa wa sọ fun awọn osisẹ rẹ: ẹ da ẹru awọn eniyan yi pada si ọdọ wọn titi ti wọn yoo fi mọ wipe a ko ra a lọwọ wọn, eleyi yoo jẹ wọn nipa lati pada lẹẹkeji ti ọmọ baba yoo si wa lọwọ wọn; ki wọn le fi rinlẹ fun yusuf ododo wọn, ki o si le gba ọja lọwọ wọn.
فَلَمَّا رَجَعُوٓاْ إِلَىٰٓ أَبِيهِمۡ قَالُواْ يَٰٓأَبَانَا مُنِعَ مِنَّا ٱلۡكَيۡلُ فَأَرۡسِلۡ مَعَنَآ أَخَانَا نَكۡتَلۡ وَإِنَّا لَهُۥ لَحَٰفِظُونَ 63
Nigbati wọn pada si ọdọ baba wọn, ti wọn sọ itan apọnle ti wọn ba pade lọdọ yusuf, wọn sọ wipe: irẹ baba wa, iwọnsunwọn wa bọ mọ wa lọwọ, ti a ko ba mu ọmọ baba wa yi dani, sugbọn ki o gbe dide pẹlu wa, dajudaju ti o ba gbe dide pẹlu wa, a o wọn ounjẹ ti o pọ, dajudaju a nse adehun fun ọ lori sisọ ọ titi ti yoo fi pada si ọdọ rẹ ni alaafia.
Ninu awọn ọta olugbagbọ ododo: ẹmin rẹ eyiti o nbẹ ni igbaaya rẹ; tori eleyi ni o fi di dandan ki o maa sọ ọ, ki o si mu duro dọgba.
Sise imọ ati ifọkantan ni majẹmu fun ẹniti o ba fẹ bọ si ipo lati se atunse alamọri awọn eniyan lapapọ.
Sise alaye wipe ọla Ọlọhun ti nbẹ ni ọrun ohun ni o loore ti yoo si sẹku, ti o si tun lọla ju fun awọn onigbagbọ.
Titọ ki ọkunrin beere fun ipo, ki o si yin ara rẹ fun nigbati bukaata ba beere, ti o si jẹ ẹniti o ngbero daadaa ati atunse.