وَلَقَدۡ جِئۡنَٰهُم بِكِتَٰبٖ فَصَّلۡنَٰهُ عَلَىٰ عِلۡمٍ هُدٗى وَرَحۡمَةٗ لِّقَوۡمٖ يُؤۡمِنُونَ 52
Paapaa ati mu Alukuraani yii wa fun wọn eyiti o jẹ iwe kan ti sọkalẹ fun Muhammad ti ikẹ ati ọla nbẹ fun, paapaa a si ti se alaye rẹ pẹlu imọ, o si jẹ itọnisọna fun awọn olugbagbọ ododo lọ si oju ọna ọgban ati ododo, o tun jẹ ikẹ fun wọn nitori itọka si awọn oore aye ati ti ọrun ti o wa nibẹ.
هَلۡ يَنظُرُونَ إِلَّا تَأۡوِيلَهُۥۚ يَوۡمَ يَأۡتِي تَأۡوِيلُهُۥ يَقُولُ ٱلَّذِينَ نَسُوهُ مِن قَبۡلُ قَدۡ جَآءَتۡ رُسُلُ رَبِّنَا بِٱلۡحَقِّ فَهَل لَّنَا مِن شُفَعَآءَ فَيَشۡفَعُواْ لَنَآ أَوۡ نُرَدُّ فَنَعۡمَلَ غَيۡرَ ٱلَّذِي كُنَّا نَعۡمَلُۚ قَدۡ خَسِرُوٓاْ أَنفُسَهُمۡ وَضَلَّ عَنۡهُم مَّا كَانُواْ يَفۡتَرُونَ 53
Awọn keferi mko reti nkankan ayaafi sisẹlẹ iya ẹlẹta elero ti wọn ti fun wọn niro wipe yoo sẹlẹ, eyi ti ọrọ wọn yoo dari si ni ọrun, ni ọjọ ti ohun ti wọn fun ni niro yii yoo sẹlẹ, ati iro ti wọn fun awọn olugbagbọ ododo ninu ẹsan, awọn ti wọn gbagbe alukuraani ni ile aye yoo maa sọ wipe, ti wọn ko si lo nkan ti Alukuraani mu wa: paapaa awọn ojisẹ wa ti wa pẹlu ododo eyiti ko si roiroi nibẹ, ko si si iyemeji lori wipe ọdọ Ọlọhun Ọba Allah ni o ti wa, o ma se fun wa ti ko si alagata ti o le sipẹ wa ni ọdọ Ọlọhun, ki o le se amojukuro fun wa nibi iya naa, tabi o se fun wa ti a ko le pada si ibi isẹmi aye, ki a le sisẹẹ re dipo aida ti a se, awọn keferi wọnyi ti padanu ẹmin ara wọn, nitori wipe wọn ti ko si iparun latari keferi wọn, awọn nkan ti wọn nsin yatọ si Ọlọhun Ọba Allah ti sa fun wọn, wọn ko se wọn ni anfaani.
إِنَّ رَبَّكُمُ ٱللَّهُ ٱلَّذِي خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ فِي سِتَّةِ أَيَّامٖ ثُمَّ ٱسۡتَوَىٰ عَلَى ٱلۡعَرۡشِۖ يُغۡشِي ٱلَّيۡلَ ٱلنَّهَارَ يَطۡلُبُهُۥ حَثِيثٗا وَٱلشَّمۡسَ وَٱلۡقَمَرَ وَٱلنُّجُومَ مُسَخَّرَٰتِۢ بِأَمۡرِهِۦٓۗ أَلَا لَهُ ٱلۡخَلۡقُ وَٱلۡأَمۡرُۗ تَبَارَكَ ٱللَّهُ رَبُّ ٱلۡعَٰلَمِينَ 54
Dajudaju Ọlọhun Ọba yin - ẹyin eniyan -, Oun ni ẹniti o da sanmọ, O si da ilẹ laisi apejuwe kan siwaju ni ọjọ mẹfa pere, lẹyin igba naa ni Ọlọhun Ọba ti ọla Rẹ ga waa ga, O si gun wa lori pẹpẹ alaarasi Rẹ ni giga ti o tọ si gbigbọngbọ Rẹ, ti a ko le mọ bi o se ri, O mu okunkun oru lọ pẹlu imọlẹ ọsan bẹẹ ni O mu imọlẹ ọsan pẹlu okunkun oru, ikini nwa ikeji niti kiakia, ikankan ko gbẹyin nibi ikeji, ti eleyi ba lọ omiran yoo wọle, Ọba ti mimọ nbẹ fun ni O da oorun, O si da osupa, O tun da awọn irawọ ni nkan ti o rọ ara rẹ, ti o si nse anfaani fun wa, ti Ọlọhun Ọba ọkan soso nikan ni dida ẹda, njẹ oluda kan yatọ siI wa bi? ! Oun nikan ni asẹ nbẹ fun, oore Rẹ tobi, daadaa Rẹ si pọ, Oun ni ẹniti a lẹtọ lati maa fi gbigbọngbọn ati pipe royin, O jẹ olutọju gbogbo ẹda.
ٱدۡعُواْ رَبَّكُمۡ تَضَرُّعٗا وَخُفۡيَةًۚ إِنَّهُۥ لَا يُحِبُّ ٱلۡمُعۡتَدِينَ 55
ẹ maa pe - ẹyin olugbagbọ ododo - Ọlọhun Ọba yin ni iyẹpẹrẹ ti o pe, ati itẹriba ni ipamọ ati kọkọ, ni isafọmọ adua laini se sekaarimi ati laini se ẹbọ pẹlu Rẹ nibi adua, dajudaju Ko nifẹ awọn olukọja ẹnu aala nibi adua sise, ninu eyiti o tobi ju ninu ikọja ẹnu aala nibi adua sise ni pipe ẹlomiran pẹlu Rẹ gẹgẹ bi awọn ọlọsẹbọ se ma nse.
وَلَا تُفۡسِدُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ بَعۡدَ إِصۡلَٰحِهَا وَٱدۡعُوهُ خَوۡفٗا وَطَمَعًاۚ إِنَّ رَحۡمَتَ ٱللَّهِ قَرِيبٞ مِّنَ ٱلۡمُحۡسِنِينَ 56
Ẹ ma ba ilẹ jẹ pẹlu mima da ẹsẹ lẹyin igbati Ọlọhun Ọba ti tun ilẹ se pẹlu riran awọn ojisẹ wa ati fifi awọn ti yoo maa tẹle asẹ Rẹ si ori ilẹ, Ẹ maa pe Ọlọhun Ọba Allah nikan soso ni ẹniti yoo maa fura mọ ipaya kuro nibi iya Rẹ, ti yoo si maa reti sisẹlẹ ẹsan Rẹ, dajudaju ikẹ Ọlọhun Ọba Allah sun mọ awọn oluse daradara, ẹ yara wa ninu wọn.
وَهُوَ ٱلَّذِي يُرۡسِلُ ٱلرِّيَٰحَ بُشۡرَۢا بَيۡنَ يَدَيۡ رَحۡمَتِهِۦۖ حَتَّىٰٓ إِذَآ أَقَلَّتۡ سَحَابٗا ثِقَالٗا سُقۡنَٰهُ لِبَلَدٖ مَّيِّتٖ فَأَنزَلۡنَا بِهِ ٱلۡمَآءَ فَأَخۡرَجۡنَا بِهِۦ مِن كُلِّ ٱلثَّمَرَٰتِۚ كَذَٰلِكَ نُخۡرِجُ ٱلۡمَوۡتَىٰ لَعَلَّكُمۡ تَذَكَّرُونَ 57
Ọlọhun Ọba Allah ti mimọ nbẹ fun, ni O ran atẹgun wa lati fun wa niro idunnu ojo titi ti atẹgun naa yoo fi gbe esu ojo ti o wuwo pẹlu omi, a o dari ẹsu ojo lọsi ilẹ ọlọda, a o wa sọ omi kalẹ si ilẹ naa, ẹ o wa fi omi mu oniranran eso jade, ni apejuwe mimu eso tamuru jade ni aworan rẹ, a nmu oku jade ninu saare wọn ni alaaye, a nse eleyi ni ireti wipe ẹyin yoo - ẹyin eniyan - ranti agbara Ọlọhun Ọba Allah, ati adayeba isẹ Rẹ, ati wipe O lagbara lati ji awọn oku.
Alukuraani Alapọnle jẹ iwe imọna, alaye gbogbo nkan ti ọmọ ẹda eniyan nfẹ wa nibẹ, o jẹ ikẹ ati ọnọọma lati ọdọ Ọlọhun fun awọn ti wọn ba fi ọkan ododo da oju kọ Ọ.
Ọlọhun Ọba Allah da sanmọ ati ilẹ ni ọjọ mẹfa nitori ọgbọn kan ti ọba ti mimọ nbẹ fun gbero, ti O ba fẹ ni ki ba kan sọ fun: wipe jẹbẹ, yoo si maa ri bẹẹ.
O jẹ majẹmu fun awọn olugbagbọ ododo ki wọn maa pe Ọlọhun Ọba Allah pẹlu ipaya ati ifararolẹ titi ti yoo fi jẹ ipe wọn ninu ọla Rẹ.
Ibajẹ lori ilẹ ni gbogbo eyikeyi aworan ati eyikeyi ẹka jẹ ohun ti a kọ fun ni kuro nibẹ.