يَقُولُ أَءِنَّكَ لَمِنَ ٱلۡمُصَدِّقِينَ 52
O sọ fun wọn niti titako ati ifinise yẹyẹ: njẹ iwọ -irẹ sootọ sootọ- wa ninu awọn olupe ajinde awọn oku ni ootọ bi?
أَءِذَا مِتۡنَا وَكُنَّا تُرَابٗا وَعِظَٰمًا أَءِنَّا لَمَدِينُونَ 53
Ti a ba ku, ti a si di yeepẹ ati eegun ti o ti kẹfun, se wọn yoo gbe wa dide, ti wọn yoo si tun wa san wa lẹsan lori isẹ wa eyiti a se ni ile aye?
قَالَ هَلۡ أَنتُم مُّطَّلِعُونَ 54
Alasunmọ rẹ ti o jẹ olugbagbọ ododo sun fun awọn eniyan ninu awọn ẹni ọgba idẹra: ẹ naga pẹlu mi, ki a jọ wo ibudarisi akẹgbẹ eyiti o ntako igbende?
فَٱطَّلَعَ فَرَءَاهُ فِي سَوَآءِ ٱلۡجَحِيمِ 55
O naga, o si ri akẹgbẹ rẹ ni arin jahannamọ.
قَالَ تَٱللَّهِ إِن كِدتَّ لَتُرۡدِينِ 56
O sọpe: mo fi Allah bura paapaa o ti sun mọ - irẹ akẹgbẹ - lati pa mi run pẹlu wiwọ ina nitori pipe mi lọ si ibi keferi ati itako ajinde.
وَلَوۡلَا نِعۡمَةُ رَبِّي لَكُنتُ مِنَ ٱلۡمُحۡضَرِينَ 57
Ti kii ba se sise idẹkun Allah le mi lori pẹlu imọna igbagbọ ati kongẹ Rẹ emi ko ba wa ninu ẹniti yoo peju si inu iya naa gẹgẹ bii rẹ. Nigbati o pari ọrọ rẹ pẹlu akẹgbẹ rẹ ninu ina, o da oju kọ biba awọn akẹgbẹ rẹ ninu ọgba idẹra sọrọ, o sọ wipe:
Nigbati o pari ọrọ rẹ pẹlu akẹgbẹ rẹ ninu ina, o da oju kọ biba awọn akẹgbẹ rẹ ninu ọgba idẹra sọrọ, o sọ wipe:
أَفَمَا نَحۡنُ بِمَيِّتِينَ 58
Kii se awa - ẹyin ara ọgba idẹra - ni oku.
إِلَّا مَوۡتَتَنَا ٱلۡأُولَىٰ وَمَا نَحۡنُ بِمُعَذَّبِينَ 59
Kii se iku akọkọ wa ni isẹmin aye bikosepe awa wa gbere ninu ọgba idẹra, bẹẹni a kii fi ẹni ifiyajẹ gẹgẹ bi wọn se fi iya jẹ awọn keferi.
إِنَّ هَٰذَا لَهُوَ ٱلۡفَوۡزُ ٱلۡعَظِيمُ 60
Dajudaju eyiti Ọlọhun Ọba wa fi san wa lẹsan yii –gẹgẹ bi wiwọ ọgba idẹra ati sise gbere nibẹ ati lila kuro nibi ina- paapaa o jẹ erenjẹ ti o tobi, ti ko si renjẹ ti o dọgba pẹlu rẹ.
لِمِثۡلِ هَٰذَا فَلۡيَعۡمَلِ ٱلۡعَٰمِلُونَ 61
Nitori apejuwe ẹsan ti o tobi yii, o di dandan fun gbogbo ẹniti o ba fẹ sisẹ ki o se e toripe dajudaju eleyi ni owo ti o lere ninu.
أَذَٰلِكَ خَيۡرٞ نُّزُلًا أَمۡ شَجَرَةُ ٱلزَّقُّومِ 62
Se idẹkun ti a sọ yii eyiti Allah pese fun awọn ẹru Rẹ ti O sa lẹsa fun itẹle asẹ Rẹ ni o loore ti o si lọla ni ibudo ati apọnle tabi igi ṣakuumu ti a ti sẹbi le ninu Alukuraani, ti o si jẹ ounjẹ awọn keferi, ti ko le muni sanra, bẹẹni ko le rọni lọrọ kuro nibi ebi?!
إِنَّا جَعَلۡنَٰهَا فِتۡنَةٗ لِّلظَّٰلِمِينَ 63
A se igi yii ni idaamun ti awọn ti o se abosi pẹlu sise keferi at awọn ẹsẹ yoo ma daamun pẹlu rẹ nibi ti wọn yoo ti sọpe: dajudaju ina jẹ igi, o rọrun ki o wu nibẹ.
إِنَّهَا شَجَرَةٞ تَخۡرُجُ فِيٓ أَصۡلِ ٱلۡجَحِيمِ 64
Dajudaju igi ṣakuumu jẹ igi ti ibuwu rẹ ko dara, o si jẹ igi ti o jade lati isalẹsalẹ jahiimu.
طَلۡعُهَا كَأَنَّهُۥ رُءُوسُ ٱلشَّيَٰطِينِ 65
Eso ti o jade ninu rẹ jẹ ohun ti oju korira, o si da gẹgẹ bi ori awọn esu, biburu riri rẹ jẹ itọka si biburu ohun ti a mu iroyin rẹ wa, eleyi si tumọ sipe eso rẹ ohun ti itọwo rẹ ko dara.
فَإِنَّهُمۡ لَأٓكِلُونَ مِنۡهَا فَمَالُِٔونَ مِنۡهَا ٱلۡبُطُونَ 66
Dajudaju awọn keferi ni ẹniti yoo maa jẹ ninu eso kikoro ti o buru yii, bẹẹni iku wọn ti o sofo yoo si ti ibẹ kun.
ثُمَّ إِنَّ لَهُمۡ عَلَيۡهَا لَشَوۡبٗا مِّنۡ حَمِيمٖ 67
Lẹyin naa nigbati wọn ba jẹ ẹ tan, nkan mimu ti a ti ro mọ aburu ti o fgbona nbẹ fun wọn nibẹ.
ثُمَّ إِنَّ مَرۡجِعَهُمۡ لَإِلَى ٱلۡجَحِيمِ 68
Lẹyin naa ibusẹrisi wọn lẹyin eleyi yoo jẹ ina jahiimu, wọn yoo ma gbera ninu iya kan si iya miran.
إِنَّهُمۡ أَلۡفَوۡاْ ءَابَآءَهُمۡ ضَآلِّينَ 69
Dajudaju awọn keferi wọnyi ni awọn baba wọn ni olusina kuro ni oju ọna imọna, wọn si kọse wọn ni ikọse ti ko si ẹri.
فَهُمۡ عَلَىٰٓ ءَاثَٰرِهِمۡ يُهۡرَعُونَ 70
Wọn tẹle oripa awọn baba wọn nibi anu ni kiakia.
وَلَقَدۡ ضَلَّ قَبۡلَهُمۡ أَكۡثَرُ ٱلۡأَوَّلِينَ 71
Ọpọ ninu awọn ẹni akọkọ si ti sọnu siwaju wọn, kii se ijọ rẹ - irẹ ojisẹ - ni akọkọ ẹniti yoo sọnu ninu awọn ijọ.
وَلَقَدۡ أَرۡسَلۡنَا فِيهِم مُّنذِرِينَ 72
Paapaa a ti ran awọn ojisẹ ninu awọn ijọ akọkọ ti wọn nda ẹru ba wọn lati ibi iya Allah sugbọn wọn se aimoore.
فَٱنظُرۡ كَيۡفَ كَانَ عَٰقِبَةُ ٱلۡمُنذَرِينَ 73
Ki o woye - irẹ ojisẹ - bi igbẹyin awọn ijọ ti awọn ojisẹ wọn se ikilọ fun wọn se ri, ti ko si jẹpe wọn, dajudaju igbẹyin wọn jẹ wiwọ ina gbere nitori keferi wọn ati pipe awọn ojisẹ wọn nirọ.
إِلَّا عِبَادَ ٱللَّهِ ٱلۡمُخۡلَصِينَ 74
Ayaafi ẹniti Allah ba sa lẹsa fun ninigbagbọ si I, dajudaju awọn ni yoo la kuro nibi iya naa eyiti o jẹ igbẹyin awọn opurọ keferi.
وَلَقَدۡ نَادَىٰنَا نُوحٞ فَلَنِعۡمَ ٱلۡمُجِيبُونَ 75
Anọbi wa ti pe wa tii se Nuha ẹniti ọla nbẹ fun nigbati o nsepe le awọn ijọ rẹ ti wọn pe e nirọ, ko si ohun ti o dara to ifesi wa ti a fesi. Paapaa a yara da a lohun pẹlu adura le wọn lori.
وَنَجَّيۡنَٰهُ وَأَهۡلَهُۥ مِنَ ٱلۡكَرۡبِ ٱلۡعَظِيمِ 76
Paapaa a la a ati awọn ara ile rẹ ati awọn olugbagbọ ododo si kuro nibi suta ijọ rẹ ati itẹri si inu okun tuufaanu ti o tobi eyiti a ran si awọn keferi inu ijọ rẹ
Jijere pẹlu idẹkun ọgba idẹra ni erenjẹ ti o tobi ju nitori ọrẹnta ati ọla yii, o tọ fun gbogbo ẹniti o ba fẹ sisẹ se e.
Dajudaju ounjẹ awọn ẹni ina ni ṣakuumu eyiti o ni eso ti o koro, ti itọwo ati oorun rẹ ko ni nmi inira, ti o soro lati gbemi, ti o nira lati jẹ.
Allah ti O ga jẹpe adura Nuha ẹniti ọla nbẹ fun pẹlu pipa ijọ rẹ run, Allah ni O dara ju ni ẹniti a le gbero ijẹpe si.