قَالَ عِلۡمُهَا عِندَ رَبِّي فِي كِتَٰبٖۖ لَّا يَضِلُّ رَبِّي وَلَا يَنسَى 52
Musa ti ọla nbẹ fun sọ fun fir'aona: imọ nkan ti awọn ijọ ti o ti re kọja lọ wa ni ori rẹ nbẹ ni ọdọ Ọlọhun Ọba mi, o si rinlẹ ninu ọpọn ti a daabobo, Ọlọhun Ọba mi ko nii se asise nibi imọ Rẹ, ko si nii gbagbe ohun ti O mọ nipa rẹ.
ٱلَّذِي جَعَلَ لَكُمُ ٱلۡأَرۡضَ مَهۡدٗا وَسَلَكَ لَكُمۡ فِيهَا سُبُلٗا وَأَنزَلَ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءٗ فَأَخۡرَجۡنَا بِهِۦٓ أَزۡوَٰجٗا مِّن نَّبَاتٖ شَتَّىٰ 53
O nbẹ ni ọdọ Ọlọhun Ọba mi ti O sọ ilẹ di pẹrẹsẹ fun yin ki ẹ le maa sẹmin nibẹ, o si se oju ọna ti o dara fun rinrin nibẹ fun yin, O si nsọ omin ojo kalẹ fun yin lati sanmọ, A si nti ibi omi naa mu awọn oniranran irugbin jade ti o yatọ si ara wọn.
كُلُواْ وَٱرۡعَوۡاْ أَنۡعَٰمَكُمۡۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّأُوْلِي ٱلنُّهَىٰ 54
Ki ẹ maa jẹ - ẹyin eniyan - ninu ohun ti a mu jade, ki ẹ si maa fun awọn ẹranko yin ni ounjẹ, dajudaju nibi eyi ti a sọ yii ninu idẹkun jẹ itọka si agbara Allah ati ijọkan soso rẹ fun awọn ti o ni laakaye.
۞مِنۡهَا خَلَقۡنَٰكُمۡ وَفِيهَا نُعِيدُكُمۡ وَمِنۡهَا نُخۡرِجُكُمۡ تَارَةً أُخۡرَىٰ 55
Ninu yepẹ ile ni a ti da baba yin Aadamọ ẹniti ọla nbẹ fun, ibẹ naa ni A o si da yin pada si fun sinsin nigbati ẹ ba ku, ibẹ naa ni A o ti mu yin jade ni igba miran fun ajinde ni ọjọ igbende.
وَلَقَدۡ أَرَيۡنَٰهُ ءَايَٰتِنَا كُلَّهَا فَكَذَّبَ وَأَبَىٰ 56
Paapaa a ti fi awọn amin Wa mẹsan patapata han fun fir'aona, o si ri i, bẹẹni o tun pe e nirọ, o si taku lati jẹpe lọsi ibi igbagbọ ninu Allah.
قَالَ أَجِئۡتَنَا لِتُخۡرِجَنَا مِنۡ أَرۡضِنَا بِسِحۡرِكَ يَٰمُوسَىٰ 57
Fir'aona sọpe: se o waa ba wa lati mu wa kuro ni ilu Misirọ pẹlu idan rẹ ti o muwa - irẹ Musa - ki ọla bẹ le sẹku fun ọ?
فَلَنَأۡتِيَنَّكَ بِسِحۡرٖ مِّثۡلِهِۦ فَٱجۡعَلۡ بَيۡنَنَا وَبَيۡنَكَ مَوۡعِدٗا لَّا نُخۡلِفُهُۥ نَحۡنُ وَلَآ أَنتَ مَكَانٗا سُوٗى 58
Paapaa a o mu wa fun ọ - irẹ Musa - idan kan ti o jẹ iru idan rẹ, fi adehun kan si aarin wa ni asiko kan ti a mọ ati aaye kan pato ti awa ko nii yapa rẹ, bẹẹ ni iwọ naa ko nii yapa rẹ, ki aaye naa si jẹ laarin meji ipin mejeeji niti deedee.
قَالَ مَوۡعِدُكُمۡ يَوۡمُ ٱلزِّينَةِ وَأَن يُحۡشَرَ ٱلنَّاسُ ضُحٗى 59
Musa ẹniti ọla nbẹ fun sọ fun fir'aona: asiko naa laarin wa ati ẹyin jẹ ọjọ ọdun nigbati awọn eniyan yoo kojọ lati maa se ọdun wọn ni iyalẹta.
فَتَوَلَّىٰ فِرۡعَوۡنُ فَجَمَعَ كَيۡدَهُۥ ثُمَّ أَتَىٰ 60
Fir'aona pẹyin da ni ẹniti o nlọ, o si ko ete rẹ ati ọgbọn rẹ jọ lẹyin naa ni o wa ni asiko naa ati aaye ti wọn jọ fi ẹnu ko si lati le bori.
قَالَ لَهُم مُّوسَىٰ وَيۡلَكُمۡ لَا تَفۡتَرُواْ عَلَى ٱللَّهِ كَذِبٗا فَيُسۡحِتَكُم بِعَذَابٖۖ وَقَدۡ خَابَ مَنِ ٱفۡتَرَىٰ 61
Musa sọrọ ni ẹniti o nse isiti fun awọn pidan pidan fir'aona: ki ẹ sọrọ, ẹ mase hun irọ mọ Allah pẹlu ohun ti ẹ fi ntan awọn eniyan jẹ ninu idan, ki Ọlọhun ma ba fi iya ti o tan yanyan jẹ yin, paapaa awọn ti o hun irọ mọ Allah ti sofo.
فَتَنَٰزَعُوٓاْ أَمۡرَهُم بَيۡنَهُمۡ وَأَسَرُّواْ ٱلنَّجۡوَىٰ 62
Awọn pidan pidan naa woye nigbati wọn gbọ ọrọ Musa ẹniti ọla nbẹ fun, wọn si ba ara wọn sọrọ kẹlẹkẹlẹ ni kọrọ.
قَالُوٓاْ إِنۡ هَٰذَٰنِ لَسَٰحِرَٰنِ يُرِيدَانِ أَن يُخۡرِجَاكُم مِّنۡ أَرۡضِكُم بِسِحۡرِهِمَا وَيَذۡهَبَا بِطَرِيقَتِكُمُ ٱلۡمُثۡلَىٰ 63
Apakan awọn pidan pidan naa sọ fun apakan wọn ni kọrọ: dajudaju Musa ati haruna jẹ pidan pidan meji kan, awọn mejeeji gbero lati mu yin jade kuro ni ilu misirọ pẹlu idan wọn eyiti wọn mu wa, ki wọn si mu isesi yin ti o ga ninu isẹmin aye kuro, ki wọn si le mu yin de ibi giga.
فَأَجۡمِعُواْ كَيۡدَكُمۡ ثُمَّ ٱئۡتُواْ صَفّٗاۚ وَقَدۡ أَفۡلَحَ ٱلۡيَوۡمَ مَنِ ٱسۡتَعۡلَىٰ 64
Ki ẹ yaa ronu si ọrọ yin, ki ẹ mase yapa nibẹ, lẹyin naa ki ẹ gbawaju ni ẹniti nse afọmọ, ki ẹ maa ju ohun ti o wa lọdọ yin ni ẹẹkannaa silẹ, paapaa o ti jere ohun ti a nfẹ loni nibi bibori onija a rẹ.
Mimu oniranran irugbin jade ti o jẹ alawọ ti o yapa si ara wọn ni inu ilẹ jẹ itọka ti o lori agbara Allah ti O ga ati bibẹ ẹniti o se e.
Wọn sọ awọn amin ti o jẹ itọka laakeye meji ti o fi oju han lori wiwaye pada: mimu irugbin jade ninu ilẹ lẹyin iku rẹ ati mimu awọn ti a la ofin bọ lọrun jade ninu rẹ ati mimu wọn bẹ.
Keferi fir'aona jẹ keferi ori kunkun; nitoripe ori awọn amin ni riri oju ti kii iro, o si gba tito pẹlu rẹ ninu jido jindo ẹmin rẹ.
Musa sẹsa ọjọ ọdun; ki gbolohun Allah le baa ga ati ki ẹsin rẹ le ba hande, ki keferi si le wo ni oju awọn eniyan lapapọ ni akojọ ti o kari, ki iro naa le ba tan ka.