وَنَٰدَيۡنَٰهُ مِن جَانِبِ ٱلطُّورِ ٱلۡأَيۡمَنِ وَقَرَّبۡنَٰهُ نَجِيّٗا 52
A pe e ni ẹgbẹ oke ọtun ni ibamun si aaye ti Musa ẹniti ọla nbẹ fun wa, a si sun mọ wa niti dida lohun nibi ki Allah mu gbọ ọrọ Rẹ.
وَوَهَبۡنَا لَهُۥ مِن رَّحۡمَتِنَآ أَخَاهُ هَٰرُونَ نَبِيّٗا 53
A si fun - ninu ikẹ Wa ati idẹkun Wa le lori - ọmọ iya rẹ Haruuna gẹgẹ bi anọbi; niti jijẹpe adua rẹ nigbati o beere eleyi ni ọdọ Ọlọhun rẹ.
وَٱذۡكُرۡ فِي ٱلۡكِتَٰبِ إِسۡمَٰعِيلَۚ إِنَّهُۥ كَانَ صَادِقَ ٱلۡوَعۡدِ وَكَانَ رَسُولٗا نَّبِيّٗا 54
Tun ranti - irẹ ojisẹ - ninu Alukuraani ti a sọkalẹ fun ọ iranti nipa Ismaheel ẹniti ọla nbẹ fun, dajudaju o jẹ ẹniti o ni adehun ododo, kii se adehun kankan ayaafi ki o pe e, o si jẹ ojisẹ ati anọbi.
وَكَانَ يَأۡمُرُ أَهۡلَهُۥ بِٱلصَّلَوٰةِ وَٱلزَّكَوٰةِ وَكَانَ عِندَ رَبِّهِۦ مَرۡضِيّٗا 55
O jẹ ẹniti o pa ara ile rẹ lasẹ pe ki o maa gbe irun duro ati mima yọ saka, o si tun jẹ ẹni iyọnu ni ọdọ Ọlọhun Ọba rẹ.
وَٱذۡكُرۡ فِي ٱلۡكِتَٰبِ إِدۡرِيسَۚ إِنَّهُۥ كَانَ صِدِّيقٗا نَّبِيّٗا 56
Tun ranti - irẹ ojisẹ - ninu Alukuraani ti a sọkalẹ fun ọ itan Idris ẹniti ọla nbẹ fun, dajudaju o jẹ ọlọpọ ododo ati ẹniti o ma ngba awọn amin Ọlọhun Ọba rẹ lododo, o si tun jẹ anọbi ninu awọn anọbi Allah.
وَرَفَعۡنَٰهُ مَكَانًا عَلِيًّا 57
A si gbe iranti rẹ ga pẹlu fifun ni ijẹ Anọbi, o si ni ipo ti o ga.
أُوْلَٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ أَنۡعَمَ ٱللَّهُ عَلَيۡهِم مِّنَ ٱلنَّبِيِّۧنَ مِن ذُرِّيَّةِ ءَادَمَ وَمِمَّنۡ حَمَلۡنَا مَعَ نُوحٖ وَمِن ذُرِّيَّةِ إِبۡرَٰهِيمَ وَإِسۡرَٰٓءِيلَ وَمِمَّنۡ هَدَيۡنَا وَٱجۡتَبَيۡنَآۚ إِذَا تُتۡلَىٰ عَلَيۡهِمۡ ءَايَٰتُ ٱلرَّحۡمَٰنِ خَرُّواْۤ سُجَّدٗاۤ وَبُكِيّٗا۩ 58
Awọn ti a darukọ ninu suura ni ibẹrẹ pẹlu Zakariya ni ipari pẹlu idris ẹniti ọla nbẹ fun, awọn ni ẹniti Allah se idẹkun le lori pẹlu sise wọn ni Anọbi ninu awọn ọmọ Aadamọ ẹniti ọla nbẹ fun, ati ninu awọn ọmọ ẹniti a gbe si inu ọkọ oju omin pẹlu Nuha ẹniti ọla nbẹ fun ati ninu awọn ọmọ Ibrahim ati awọn ọmọ ya'quub ẹniti ọla nbẹ fun ati ninu awọn ẹniti a fi imọna se kongẹ rẹ lọsi inu Islam, a si sa wọn lẹsa, bẹẹ ni a se wọn ni Anọbi, wọn jẹ ẹniti o ja si wipe ti wọn ba gbọ awọn aayah Ọlọhun Ọba ti wọn nka, wọn yoo fi ori balẹ fun Allah ni sisunkun lati ara ipaya Rẹ.
۞فَخَلَفَ مِنۢ بَعۡدِهِمۡ خَلۡفٌ أَضَاعُواْ ٱلصَّلَوٰةَ وَٱتَّبَعُواْ ٱلشَّهَوَٰتِۖ فَسَوۡفَ يَلۡقَوۡنَ غَيًّا 59
Awọn olutẹle buruku ati anu si wa lẹyin awọn anọbi ti a sa lẹsa yii, wọn ra irun lare, wọn kii mu wa ni ojupọnna ti a fẹ, wọn si ngun le ohun ti ẹmin wọn nfa si ninu awọn ẹsẹ gẹgẹ bi agbere, wọn yoo pada pade aburu ninu jahannamọ ati ofo.
إِلَّا مَن تَابَ وَءَامَنَ وَعَمِلَ صَٰلِحٗا فَأُوْلَٰٓئِكَ يَدۡخُلُونَ ٱلۡجَنَّةَ وَلَا يُظۡلَمُونَ شَيۡٔٗا 60
Ayaafi ẹniti o ba ronu piwada ninu aseeto ati aseju rẹ, ti o si tun nigbagbọ ninu Allah, ti o si tun nse isẹẹre, awọn wọnyi ni a royin pẹlu awọn iroyin yii, wọn yoo wọ ọgba idẹra, wọn ko si nii din ẹsan isẹẹre wọn kankan ku, ko baa kere.
جَنَّٰتِ عَدۡنٍ ٱلَّتِي وَعَدَ ٱلرَّحۡمَٰنُ عِبَادَهُۥ بِٱلۡغَيۡبِۚ إِنَّهُۥ كَانَ وَعۡدُهُۥ مَأۡتِيّٗا 61
Awọn ọgba idẹra niti wiwa nibẹ ati ririnlẹ eyiti Ọba Ajọkẹ aye se adehun rẹ fun awọn ẹru Rẹ ti o jẹ ẹniire ni kọkọ wipe Yoo ki wọn bọ inu rẹ, wọn ko si ri sugbọn wọn gba a gbọ, adehun Ọlọhun Allah pẹlu Alujannah yii - koda bi o jẹ nkan kọkọ - yoo wa ti ko si ibuyẹ nibẹ.
لَّا يَسۡمَعُونَ فِيهَا لَغۡوًا إِلَّا سَلَٰمٗاۖ وَلَهُمۡ رِزۡقُهُمۡ فِيهَا بُكۡرَةٗ وَعَشِيّٗا 62
Wọn ko nii gbọ ọrọ iyẹpẹrẹ nibẹ, bẹẹ ni ọrọ ibajẹ bikosepe wọn yoo maa gbọ ọla apakan wọn si apakan wọn ati ikini ọla awọn Malaika fun wọn, ohun ti wọn nifẹ si ninu ounjẹ yoo maa wa ba wọn ni aarọ ati irọlẹ.
تِلۡكَ ٱلۡجَنَّةُ ٱلَّتِي نُورِثُ مِنۡ عِبَادِنَا مَن كَانَ تَقِيّٗا 63
Ọgba idẹra ti a royin pẹlu awọn iroyin yii, ohun ni A o jogun fun awọn ẹru Wa eyiti o ba tẹle asẹ, ti o si jinna si awọn ohun ti A kọ.
Nigbati Ọlọhun Allah sọ ẹsan awọn olupaya Rẹ, O tun sọ wipe dajudaju ipaya ni ki eniyan duro pẹlu asẹ Rẹ, O wa sọ wipe:
وَمَا نَتَنَزَّلُ إِلَّا بِأَمۡرِ رَبِّكَۖ لَهُۥ مَا بَيۡنَ أَيۡدِينَا وَمَا خَلۡفَنَا وَمَا بَيۡنَ ذَٰلِكَۚ وَمَا كَانَ رَبُّكَ نَسِيّٗا 64
Tun sọ - irẹ jibril - fun Muhammad ti ikẹ ati ọla nbẹ fun: dajudaju awọn Malaika wọn kii sọkalẹ fun ara wọn, bikosepe wọn ma nsọkalẹ pẹlu asẹ Allah, ohun ti a o ba pade ninu alamọri ọrun jẹ ti Allah, bakanna naa ohun ti a ba fi silẹ ninu alamọri ọrọ ile aye ati ohun ti nbẹ ni aarin aye ati ọrun, Ọlọhun rẹ kii se olugbagbe fun ohunkihun - irẹ ojisẹ -.
Olupepe ni bukaata ni gbogbo si alaranse ti yoo maa kun lọwọ nibi ipepe rẹ.
Fifi iroyin ọrọ sisọ ti si ọdọ Allah ti ọla Rẹ ga.
Adehun ododo jẹ iroyin daadaa, o si jẹ ninu iwa awọn anọbi ati awọn ojisẹ, idakeji rẹ ni yiyapa adehun ti se iroyin ti ko dara.
Dajudaju awọn Malaika jẹ awọn ojisẹ Allah pẹlu imisi, wọn kii sọkalẹ fun ẹnikẹni ninu awọn anọbi ati awọn ojisẹ ninu abara ayaafi pẹlu asẹ Allah.