إِذۡ دَخَلُواْ عَلَيۡهِ فَقَالُواْ سَلَٰمٗا قَالَ إِنَّا مِنكُمۡ وَجِلُونَ 52
Nigbati wọn wọle tii, wọn waa sọ fun wipe: alaafia, o si da wọn lohun pẹlu eyiti o dara ju kiki wọn lọ, o si gbe ẹran yiyan fun wọn ki wọn le jẹ ẹ, paapaa o ti lero wipe abara ni wọn, sugbọn nigbati wọn ko jẹ ẹ nibẹ, o sọ wipe: dajudaju awa nbẹru yin.
قَالُواْ لَا تَوۡجَلۡ إِنَّا نُبَشِّرُكَ بِغُلَٰمٍ عَلِيمٖ 53
Awọn ojisẹ ninu awọn Malaika sọ wipe: mase bẹru awa yoo fun niro nkan ti yoo dun ọ ninu wipe ọmọkunrin onimimọ yoo bẹ fun ọ.
قَالَ أَبَشَّرۡتُمُونِي عَلَىٰٓ أَن مَّسَّنِيَ ٱلۡكِبَرُ فَبِمَ تُبَشِّرُونَ 54
Ibrahim sọ fun wọn - paapaa o ti se eemọ nibi iro idunnu ti wọn fun un lori ọmọ -: se ẹyin yoo fun mi niro idunnu pẹlu ọmọ ti mo si ti dagba, ti mo si tun ti dogbo, ojupọnna wo ni ẹ fẹ gba fun ni niro naa?
قَالُواْ بَشَّرۡنَٰكَ بِٱلۡحَقِّ فَلَا تَكُن مِّنَ ٱلۡقَٰنِطِينَ 55
Awọn ojusẹ ninu awọn Malaika sọ fun Ibrahim: iro ododo ni a fun ọ eyiti ko si iyemeji nibẹ, mase wa ninu olujakan nibi iro idunnu ti a fun ọ.
قَالَ وَمَن يَقۡنَطُ مِن رَّحۡمَةِ رَبِّهِۦٓ إِلَّا ٱلضَّآلُّونَ 56
Ibrahim sọ wipe: se ẹnikan le jakan kuro nibi ikẹ Allah ayaafi ẹniti o ti gunri kuro ni oju ọna Allah ti o duro tọ?!
قَالَ فَمَا خَطۡبُكُمۡ أَيُّهَا ٱلۡمُرۡسَلُونَ 57
Ibrahim sọ wipe: kinni o mu yin wa ẹyin ojisẹ lati ọdọ Allah ti O ga?
قَالُوٓاْ إِنَّآ أُرۡسِلۡنَآ إِلَىٰ قَوۡمٖ مُّجۡرِمِينَ 58
Awọn ojisẹ ninu awọn Malaika sọ wipe: dajudaju Ọlọhun Allah ran wa nisẹ lati pa ijọ onibajẹ nla run, alaburu nla, awọn naa ni ijọ Luth.
إِلَّآ ءَالَ لُوطٍ إِنَّا لَمُنَجُّوهُمۡ أَجۡمَعِينَ 59
Ayaafi awọn ara ile Luth ati awọn ti wọn ntẹle ninu awọn olugbagbọ ododo, iparun ko nii kan wọn, dajudaju awa yoo la wọn lapapọ nibẹ.
إِلَّا ٱمۡرَأَتَهُۥ قَدَّرۡنَآ إِنَّهَا لَمِنَ ٱلۡغَٰبِرِينَ 60
Ayaafi iyawo rẹ, paapaa a ti se idajọ wipe yoo wa ninu awọn ti yoo sẹku, ti aburu yoo kan.
فَلَمَّا جَآءَ ءَالَ لُوطٍ ٱلۡمُرۡسَلُونَ 61
Nigbati awọn Malaika ti a ran nisẹ de ọdọ Luth, ni aworan ọkunrin.
قَالَ إِنَّكُمۡ قَوۡمٞ مُّنكَرُونَ 62
Luth ẹniti ọla nbẹ fun sọ fun wọn wipe: awọn ijọ yii jẹ ẹniti a ko mọ.
قَالُواْ بَلۡ جِئۡنَٰكَ بِمَا كَانُواْ فِيهِ يَمۡتَرُونَ 63
Awọn ojisẹ ninu awọn Malaika sọ fun Luth: ma paya, a wa ba ọ - irẹ Luth - pẹlu iya ti awọn ijọ rẹ nse iyemeji si wipe yoo pa awọn run.
وَأَتَيۡنَٰكَ بِٱلۡحَقِّ وَإِنَّا لَصَٰدِقُونَ 64
A si waa ba ọ pẹlu ododo ti ko si awada nibẹ, bẹẹ ni a jẹ sootọ sootọ nibi iro ti a mu wa ba ọ.
فَأَسۡرِ بِأَهۡلِكَ بِقِطۡعٖ مِّنَ ٱلَّيۡلِ وَٱتَّبِعۡ أَدۡبَٰرَهُمۡ وَلَا يَلۡتَفِتۡ مِنكُمۡ أَحَدٞ وَٱمۡضُواْ حَيۡثُ تُؤۡمَرُونَ 65
Mu awọn eniyan rẹ rin nigbati ilẹ ba su diẹ, ki o si maa rin lẹyin wọn, ki ẹnikẹni ninu yin mase bo oju wẹyin lati wo ohun ti o sẹlẹ si wọn, ki ẹ maa lọ sibi ti Ọlọhun Allah pa yin lasẹ wipe ki ẹ lọ,
وَقَضَيۡنَآ إِلَيۡهِ ذَٰلِكَ ٱلۡأَمۡرَ أَنَّ دَابِرَ هَٰٓؤُلَآءِ مَقۡطُوعٞ مُّصۡبِحِينَ 66
A fi mọ Luth ni ojupọnna imisi asẹ eyiti a bebubu fun un, ohun naa ni wipe awọn eniyan wọnyi yoo di ẹni iparun tan yan an yan an, titi de ori ẹni ikẹyin wọn nigbati ilẹ ba mọ ba wọn.
وَجَآءَ أَهۡلُ ٱلۡمَدِينَةِ يَسۡتَبۡشِرُونَ 67
Awọn idile Saduumu de ni ẹniti ndunnu pẹlu awọn alejo Luth; ti wọn si nrankan lati se ibajẹ.
قَالَ إِنَّ هَٰٓؤُلَآءِ ضَيۡفِي فَلَا تَفۡضَحُونِ 68
Luth sọ fun wọn: dajudaju awọn ijọ yii ni awọn alejo mi, ẹ mase da oju ti mi pẹlu ohun ti ẹ fẹẹ se fun wọn.
وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَلَا تُخۡزُونِ 69
Ki ẹ si paya Allah pẹlu gbigbe ibajẹ yii ju silẹ, ẹ ma yẹpẹrẹ mi pẹlu isẹ aida yin yii.
قَالُوٓاْ أَوَ لَمۡ نَنۡهَكَ عَنِ ٱلۡعَٰلَمِينَ 70
Awọn ijọ rẹ sọ fun wipe: se a ko kọ fun ọ ki o mase gba alejo kankan ninu eniyan ni?
Kikọ ẹkọ alejo nipa ikini ati sisalamọ nigbati a ba fẹẹ de ọdọ awọn ẹlomiran.
Ẹniti Allah ba se idẹkun imọna ati imọ ti o tobi fun, ko tọ ki o jakan kuro nibi ikẹ Allah.
Ọlọhun Allah kọ fun Luth ati awọn ti wọn ntẹle lati mase boju wo ẹyin ni asiko ti iya nsọkalẹ fun ijọ Luth, ki aanu wọn ma ba se wọn.
Dide leti ijọ Luth lori dida ẹsẹ pẹlu awọn alejo wọnyi jẹ itọka lori kiku adamọ wọn ati biburu ibajẹ wọn.