ثُمَّ إِنَّكُمۡ أَيُّهَا ٱلضَّآلُّونَ ٱلۡمُكَذِّبُونَ 51
Lẹyin naa dajudaju ẹyin jẹ - ẹyin opurọ nipa ajinde, ẹni anu kuro ni oju ọna ti o duro tọ.
لَأٓكِلُونَ مِن شَجَرٖ مِّن زَقُّومٖ 52
Ẹ o jẹ olujẹ eso igi Zaqquumu ni ọjọ igbende, ohun si ni eso ti o buru, ti o si bajẹ ju.
فَمَالُِٔونَ مِنۡهَا ٱلۡبُطُونَ 53
Ikun yin ti o pa lofo yoo di kikun fun igi ti o koro naa.
فَشَٰرِبُونَ عَلَيۡهِ مِنَ ٱلۡحَمِيمِ 54
Wọn yoo maa mu omin gbigbona ti o le koko ni igbona le lori.
فَشَٰرِبُونَ شُرۡبَ ٱلۡهِيمِ 55
Wọn yoo pọ ni mimu rẹ gẹgẹ bi rakunmi se ma npọ ni mimu nitori arun wọbiha.
هَٰذَا نُزُلُهُمۡ يَوۡمَ ٱلدِّينِ 56
Ounjẹ kikoro ti a darukọ yii ati omin gbigbona naa jẹ ikona alejo wọn eyiti wọn yoo fi ko wọn loju ni ọjọ ẹsan.
نَحۡنُ خَلَقۡنَٰكُمۡ فَلَوۡلَا تُصَدِّقُونَ 57
Awa ni a da yin - ẹyin opurọ - lẹyin ti ẹ ti jẹ aisi, se ẹ ko nii gba lododo wipe awa ni a o ta yin ji ni alaaye lẹyin iku yin bi?!
أَفَرَءَيۡتُم مَّا تُمۡنُونَ 58
Se ẹ ri - ẹyin eniyan - aatọ eyiti ẹ nfi si inu apo ibi awọn obinrin yin bi?!
ءَأَنتُمۡ تَخۡلُقُونَهُۥٓ أَمۡ نَحۡنُ ٱلۡخَٰلِقُونَ 59
Se ẹyin ni ẹyin ni ẹ da aatọ naa ni tabi Awa ni A da a?!
نَحۡنُ قَدَّرۡنَا بَيۡنَكُمُ ٱلۡمَوۡتَ وَمَا نَحۡنُ بِمَسۡبُوقِينَ 60
Awa ni a nikapa iku laarin yin, ẹnikọọkan ninu yin ni o si ni asiko ti ko le gba iwaju rẹ, bẹẹni ko si le kẹyin, awa kii si se olukagara.
عَلَىٰٓ أَن نُّبَدِّلَ أَمۡثَٰلَكُمۡ وَنُنشِئَكُمۡ فِي مَا لَا تَعۡلَمُونَ 61
Lati mu iyipada ba ohun ti ẹ wa lori rẹ ninu isẹda ati iyaworan nibi ohun ti ẹ mọ, ki ẹ si tun sẹda yin nibi ohun ti ẹ ko mọ ni ẹda ati iyaworan.
وَلَقَدۡ عَلِمۡتُمُ ٱلنَّشۡأَةَ ٱلۡأُولَىٰ فَلَوۡلَا تَذَكَّرُونَ 62
Paapaa ẹ si mọ bi a se da yin ni isẹda alakọkọ, se ẹ ko le woye ni wipe ẹniti o da yin ni igba akọkọ ni agbara lati ta yin ji lẹyin iku yin bi?!
أَفَرَءَيۡتُم مَّا تَحۡرُثُونَ 63
Se ẹ ri ohun ti ẹ nju ninu irugbin si ilẹ?!
ءَأَنتُمۡ تَزۡرَعُونَهُۥٓ أَمۡ نَحۡنُ ٱلزَّٰرِعُونَ 64
Se ẹyin ni ẹniti o nmu irugbin naa hun tabi awa ni a nmu hun bi?!
لَوۡ نَشَآءُ لَجَعَلۡنَٰهُ حُطَٰمٗا فَظَلۡتُمۡ تَفَكَّهُونَ 65
Ti a ba fẹ lati sọ irugbin naa di ohun ti o run, a ba sọọ di rirun lẹyin igbati o ti fẹẹ gbo, ti ọwọ ti fẹẹ to, ẹ o wa di ẹniti yoo maa se eemọ nibi ohun ti o sẹlẹ si i.
إِنَّا لَمُغۡرَمُونَ 66
Ẹ o maa sọpe: dajudaju a jẹ ẹni ifiyajẹ nitori isofo ohun ti a na.
بَلۡ نَحۡنُ مَحۡرُومُونَ 67
Bikosepe wọn se arisiki leewọ fun wa.
أَفَرَءَيۡتُمُ ٱلۡمَآءَ ٱلَّذِي تَشۡرَبُونَ 68
Se ẹ ri omin ẹyiti ẹ nmu nigbati oungbẹ ba gbẹ yin bi?
ءَأَنتُمۡ أَنزَلۡتُمُوهُ مِنَ ٱلۡمُزۡنِ أَمۡ نَحۡنُ ٱلۡمُنزِلُونَ 69
Se ẹyin ni ẹ nsọ kalẹ ninu ẹsujo sanmọ tabi awa ni a nsọkalẹ bi?!
لَوۡ نَشَآءُ جَعَلۡنَٰهُ أُجَاجٗا فَلَوۡلَا تَشۡكُرُونَ 70
Ti a ba fẹ lati sọ omin naa di ohun ti o tẹ gidi lẹnu, ti ko si se anfaani mimu tabi fun nkan miran mu, a ko ba se ni ohun ti o tẹ gidigidi, ti kii ba se wipe ẹ ndupẹ fun Allah lori sisọkalẹ rẹ ni didun ni o fi jẹ ikẹ fun yin.
أَفَرَءَيۡتُمُ ٱلنَّارَ ٱلَّتِي تُورُونَ 71
Se ẹ ri ina ẹyiti ẹ nko fun anfaani yin bi?!
ءَأَنتُمۡ أَنشَأۡتُمۡ شَجَرَتَهَآ أَمۡ نَحۡنُ ٱلۡمُنشُِٔونَ 72
Se ẹyin ni ẹ nmu igi naa bẹ ti ẹ fi nkona tabi awa ni ẹniti o nmu u bẹ niti aanu si yin?!
نَحۡنُ جَعَلۡنَٰهَا تَذۡكِرَةٗ وَمَتَٰعٗا لِّلۡمُقۡوِينَ 73
Awa ni a se ina yii ni iranti fun yin, ti yoo maa mu yin ranti ina ti ọrun, a si se e ni anfaani fun awọn oluserina jo ninu yin.
فَسَبِّحۡ بِٱسۡمِ رَبِّكَ ٱلۡعَظِيمِ 74
Ọlọhun rẹ ti o tobi mọ kanga - irẹ ojisẹ - kuro nibi ohun ti ko lẹtọ si I.
۞فَلَآ أُقۡسِمُ بِمَوَٰقِعِ ٱلنُّجُومِ 75
Allah fi awọn aaye irawọ ati ibuduro si rẹ bura.
وَإِنَّهُۥ لَقَسَمٞ لَّوۡ تَعۡلَمُونَ عَظِيمٌ 76
Atipe dajudaju ibura pẹlu awọn aaye yii - ti ẹ ba mọ titobi rẹ - paapaa ko ba tobi; nitori awọn amin ati awọn ariwoye ti ko see ka ti o wa nibẹ.
Titọka isẹda alakọkọ si rirọrun ajinde ti o han.
Sisọ omin kalẹ ati mimu irugbin jade ni ilẹ ati ina eyiti awọn eniyan nse anfaani nibẹ jẹ awọn idẹkun ti o di dandan fun awọn eniyan lati dupẹ fun Ọlọhun Ọba lori rẹ, Allah jẹ ẹniti o lagbara lati ja a gba nigbati O ba fẹ.
Didi adisọkan wipe oripa nibi sisọkalẹ awọn ojo fun awọn irawọ jẹ keferi, o si jẹ ninu awọn isesi awọn alamọkan.