۞يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تَتَّخِذُواْ ٱلۡيَهُودَ وَٱلنَّصَٰرَىٰٓ أَوۡلِيَآءَۘ بَعۡضُهُمۡ أَوۡلِيَآءُ بَعۡضٖۚ وَمَن يَتَوَلَّهُم مِّنكُمۡ فَإِنَّهُۥ مِنۡهُمۡۗ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يَهۡدِي ٱلۡقَوۡمَ ٱلظَّٰلِمِينَ 51
A pe ẹyin olugbagbọ ododo ninu Ọlọhun Ọba Allah ati ojisẹ Rẹ, ma fi ololufẹ ati aayo yin sinu yahuudi ati nassara, ti ẹ o wa maa mu wọn ni aayo, awọn yahuudi kii mu ni aayo ju eeyan wọn lọ, bẹẹ ni awọn nasaara kii mu ni aayo ju awọn eniyan wọn lọ, awọn ipin mejeeji ni ki ẹ gbe si ipo ọta yin, ẹniti o ba mu wọn ni aayo ninu yin, o ti wa ninu onka wọn ni, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah ko nii fi ijọ alabosi mọna, nitori mimu awọn keferi ni aayo.
فَتَرَى ٱلَّذِينَ فِي قُلُوبِهِم مَّرَضٞ يُسَٰرِعُونَ فِيهِمۡ يَقُولُونَ نَخۡشَىٰٓ أَن تُصِيبَنَا دَآئِرَةٞۚ فَعَسَى ٱللَّهُ أَن يَأۡتِيَ بِٱلۡفَتۡحِ أَوۡ أَمۡرٖ مِّنۡ عِندِهِۦ فَيُصۡبِحُواْ عَلَىٰ مَآ أَسَرُّواْ فِيٓ أَنفُسِهِمۡ نَٰدِمِينَ 52
Iwọ yoo ri - ire ojise - awọn sọbẹ-selo ti wọn jẹ ọlẹ ninu igbagbọ, wọn nyara gaga lati mu yahuudi ati nassara ni aayo ni ẹniti wọn nsọ wipe: a npaya ki awọn eniyan wọnyi ma ni ipin, ki agbara ma baa wa fun wọn, ti a fi maa ri ohun ti ọkan wa kọ lati ọdọ wọn, o sunmọ ki Ọlọhun Ọba Allah se erenjẹ fun ojisẹ Rẹ ati awọn olugbagbọ ododo, tabi ki asẹ kan wa lati ọdọ Rẹ, ti yoo kọ di agbara awọn yahuudi ati awọn ti wọn mu ni aayo, bayi ni awọn ti wọn nsare tete lọsi ibi imu wọn laayo yoo di ẹni ibamọ lori ohun ti wọn fipọ lori sọbẹ-selu ninu ọkan wọn; nitori aidara nkan ti wọn so pọ mọ ninu awọn okunfa ti ko ni asunsi.
وَيَقُولُ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ أَهَٰٓؤُلَآءِ ٱلَّذِينَ أَقۡسَمُواْ بِٱللَّهِ جَهۡدَ أَيۡمَٰنِهِمۡ إِنَّهُمۡ لَمَعَكُمۡۚ حَبِطَتۡ أَعۡمَٰلُهُمۡ فَأَصۡبَحُواْ خَٰسِرِينَ 53
Awọn olugbagbọ ododo nsọ ni ẹniti nseemọ ninu isesi awọn sọbẹ-selu: se awọn ti wọn nbura, ti wọn si nkanpa mọ ibura wọn: pe dajudaju awọn wa pẹlu yin - ẹyin olugbagbọ ododo - nibi igbagbọ, aranse ati imulaayo? ! Isẹ wọn ti bajẹ, wọn si ti di ẹni ofo nitorierongba wọb ti o ti bọ, ati nitori ohun ti Ọlọhun Ọba Allah pese fun wọn ninu iya.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ مَن يَرۡتَدَّ مِنكُمۡ عَن دِينِهِۦ فَسَوۡفَ يَأۡتِي ٱللَّهُ بِقَوۡمٖ يُحِبُّهُمۡ وَيُحِبُّونَهُۥٓ أَذِلَّةٍ عَلَى ٱلۡمُؤۡمِنِينَ أَعِزَّةٍ عَلَى ٱلۡكَٰفِرِينَ يُجَٰهِدُونَ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ وَلَا يَخَافُونَ لَوۡمَةَ لَآئِمٖۚ ذَٰلِكَ فَضۡلُ ٱللَّهِ يُؤۡتِيهِ مَن يَشَآءُۚ وَٱللَّهُ وَٰسِعٌ عَلِيمٌ 54
Ẹyin olugbagbọ ododo, ẹniti o ba sẹri kuro ninu ẹsin rẹ lọsi keferi, Ọlọhun Ọba Allah yoo mu ijọ miran wa ninu wọn, ti Ọlọhun Ọba Allah yoo nifẹ wọn, ti awọn naa yoo nifẹ Rẹ nitori iduro sinsin wọn, wọn jẹ onikẹ si awọn olugbagbọ ododo, ẹniti o le koko mọ awọn keferi, wọn ngbiyanju pẹlu awọn dukia wọn ati ẹmin wọn, ki gbolohun Ọlọhun Ọba Allah jẹ ohun ti o ga ju lọ, ẹ mase paya ilekoko awọn ti wọn lekoko mọ nitori gbigbe iyẹnu Ọlọhun lori iyẹnu awọn ẹda ti a da, eyi jẹ ninu ọrẹnta Ọlọhun Ọba Allah, eyiti O ma nfun ẹniti o ba wu U ninu awọn ẹru Rẹ, Ọlọhun Ọba Allah jẹ ẹniti o gbaaye ni ọla ati agbara, O si jẹ onimọ pẹlu ẹniti ọla Rẹ tọ si, bẹẹ ni Yoo ta lọrẹ, ati ẹniti ko tọ si, yoo si se ni eewọ fun un.
Nigbati Ọlọhun Ọba Allah kọ nibi mima mu yahuudi ati nassara ni aayo ati ẹniti o yatọ si wọn ninu awọn keferi, O mu iro wa nipa awọn ti wọn se adayanri awọn olugbagbọ ododo ni aayo, o wa sọ wipe:
إِنَّمَا وَلِيُّكُمُ ٱللَّهُ وَرَسُولُهُۥ وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ ٱلَّذِينَ يُقِيمُونَ ٱلصَّلَوٰةَ وَيُؤۡتُونَ ٱلزَّكَوٰةَ وَهُمۡ رَٰكِعُونَ 55
Yahuudi ati nassara ati awọn ti o yatọ si wọn ninu awọn keferi, wọn kii se awọn aayo yin, bikose wipe aayo yin ati alaranse yin, Oun ni Allah ati ojisẹ ati awọn olugbagbọ ododo, ti wọn nnkirun ni pipe, ti wọn nyọ saka ninu dukia wọn, ti wọn ntẹriba fun Ọlọhun Ọba Allah niti iyẹpẹrẹ.
وَمَن يَتَوَلَّ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥ وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ فَإِنَّ حِزۡبَ ٱللَّهِ هُمُ ٱلۡغَٰلِبُونَ 56
Ẹniti o ba mu Ọlọhun Ọba Allah ati ojisẹ Rẹ ati awọn olugbagbọ ododo ni aayo pẹlu sise aranse, o jẹ ọkan ninu ọmọ ogun Ọlọhun Ọba Allah, bẹẹ ni awọn ọmọ ogun Ọlọhun Ọba Allah ni yoo bori; nitori Ọlọhun Ọba Allah yoo se aranse fun wọn.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تَتَّخِذُواْ ٱلَّذِينَ ٱتَّخَذُواْ دِينَكُمۡ هُزُوٗا وَلَعِبٗا مِّنَ ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡكِتَٰبَ مِن قَبۡلِكُمۡ وَٱلۡكُفَّارَ أَوۡلِيَآءَۚ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ إِن كُنتُم مُّؤۡمِنِينَ 57
Ẹyin olugbagbọ ododo, ẹ mase mu awọn ti wọn nfi ẹsin yin se yẹyẹ, ti wọn si nfi sere ninu awọn ti a fun ni tira siwaju yin, bii yahuudi, nasaara ati awọn ọlọsẹbọ ni ololufẹ ati aayo, ẹ paya Ọlọhun Ọba Allah pẹlu jijinna si ohun ti O kọ fun yin, nibi mimu wọn ni aayo ti ẹ ba jẹ olugbagbọ ododo siI, ati si ohun ti O sọkalẹ fun yin.
Itaniji lori adisọkan imulaayo ati igbafunni eyiti o pamọ sinu imunilaayo ati inifẹ si Ọlọhun Ọba , ojisẹ Rẹ ati si awọn olugbagbọ ododo ati kikorira awọn keferi, bakanna ni jijinna si ifẹ wọn.
Ninu iroyin awọn sọbẹ-selu: ohun ni mimu awọn ọta Ọlọhun Ọba Allah ni aayo.
Idagunla ati sise aseeto nibi aranse ẹsin le bi ipaarọ nkan ti a se aseeso rẹ ati mimu nkan miran wa ati mimu iyi aranse ẹsin kuro.
Sise ikilọ kuro nibi awọn olufi ẹsin se yẹyẹ bi awọn keferi ati awọn sọbẹ-selu, ati nibi mimu wọn ni aayo.