۞تُرۡجِي مَن تَشَآءُ مِنۡهُنَّ وَتُٔۡوِيٓ إِلَيۡكَ مَن تَشَآءُۖ وَمَنِ ٱبۡتَغَيۡتَ مِمَّنۡ عَزَلۡتَ فَلَا جُنَاحَ عَلَيۡكَۚ ذَٰلِكَ أَدۡنَىٰٓ أَن تَقَرَّ أَعۡيُنُهُنَّ وَلَا يَحۡزَنَّ وَيَرۡضَيۡنَ بِمَآ ءَاتَيۡتَهُنَّ كُلُّهُنَّۚ وَٱللَّهُ يَعۡلَمُ مَا فِي قُلُوبِكُمۡۚ وَكَانَ ٱللَّهُ عَلِيمًا حَلِيمٗا 51
O nlọlara - irẹ ojisẹ - ẹniti o wu ọ lati mu ipin kẹyin ninu awọn obinrin rẹ, ti o ko nii sun pẹlu rẹ, o si nmu mọ ọdọ ninu wọn ẹniti o wu ọ, ti o si nsun pẹlu rẹ, ẹniti o ba wa lati mu mọ ọdọ ninu awọn ti o ti fi kẹyin, ko si ẹsẹ fun ọ nibi eleyi, eleyi jẹ isẹsa ati igbani laaye fun ọ, o si sun mọ lati tutu oju awọn obinrin rẹ ati ki wọn le yọnu si ohun ti o ba fẹ fun wọn lapapọ nitori imọ wọn loi wipe o ko gbe ọranyan ju silẹ, bẹẹni o ko si se ahun pẹlu ododo, Allah mọ ohun ti o wa ninu ọkan yin - ẹyin ọkunrin - nibi fifi si apakan awọn obinrin yin ju apakan lọ, Allah jẹ Ẹniti o nimọ nipa isẹ awọn ẹru Rẹ, nkankan ko pamọ fun Un nibẹ, o si jẹ alatẹmọra ti ko nii kanju iya wọn boya wọn le ronu piwada lọ si ọdọ Rẹ.
لَّا يَحِلُّ لَكَ ٱلنِّسَآءُ مِنۢ بَعۡدُ وَلَآ أَن تَبَدَّلَ بِهِنَّ مِنۡ أَزۡوَٰجٖ وَلَوۡ أَعۡجَبَكَ حُسۡنُهُنَّ إِلَّا مَا مَلَكَتۡ يَمِينُكَۗ وَكَانَ ٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ رَّقِيبٗا 52
Ko tọ fun ọ - irẹ ojisẹ - ki o fẹ awọn obinrin ti kii se awọn iyawo rẹ, awọn ti wọn bẹ ni abẹ idaabobo rẹ, bẹẹni ko si tọ fun ọ ki o kọ wọn tabi ki o kọ apakan ninu wọn ki o le mu ẹlomiran ninu awọn obinrin ti o yatọ si wọn, koda ki didara ẹniti o nifẹ si lati fẹ ninu awọn obinrin miran ti o yatọ si wọn jẹ ohun ti o jọ ẹ loju, sugbọn o tọ fun ọ ki o maa fẹ ninu awọn ti nikapa ninu ẹru ni aini ẹnu aala ninu onka, Ọlọhun Ọba Allaj jẹ olusọ lori gbogbo nkan, bẹẹni idajọ yii ntọka si ọla ti o wa fun awọn iya olugbagbọ ododo, paapaa wọn se kikọ wọn leewọ tabi fifẹ le wọn lori.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تَدۡخُلُواْ بُيُوتَ ٱلنَّبِيِّ إِلَّآ أَن يُؤۡذَنَ لَكُمۡ إِلَىٰ طَعَامٍ غَيۡرَ نَٰظِرِينَ إِنَىٰهُ وَلَٰكِنۡ إِذَا دُعِيتُمۡ فَٱدۡخُلُواْ فَإِذَا طَعِمۡتُمۡ فَٱنتَشِرُواْ وَلَا مُسۡتَٔۡنِسِينَ لِحَدِيثٍۚ إِنَّ ذَٰلِكُمۡ كَانَ يُؤۡذِي ٱلنَّبِيَّ فَيَسۡتَحۡيِۦ مِنكُمۡۖ وَٱللَّهُ لَا يَسۡتَحۡيِۦ مِنَ ٱلۡحَقِّۚ وَإِذَا سَأَلۡتُمُوهُنَّ مَتَٰعٗا فَسَۡٔلُوهُنَّ مِن وَرَآءِ حِجَابٖۚ ذَٰلِكُمۡ أَطۡهَرُ لِقُلُوبِكُمۡ وَقُلُوبِهِنَّۚ وَمَا كَانَ لَكُمۡ أَن تُؤۡذُواْ رَسُولَ ٱللَّهِ وَلَآ أَن تَنكِحُوٓاْ أَزۡوَٰجَهُۥ مِنۢ بَعۡدِهِۦٓ أَبَدًاۚ إِنَّ ذَٰلِكُمۡ كَانَ عِندَ ٱللَّهِ عَظِيمًا 53
A pe ẹyin olugbagbọ ninu Allah, ti wọn si se ohun ti wọn se lofin fun wọn, ẹ ko gbọdọ wọ inu ile anaọbi ayaafi lẹyin igbati wọn ba yọnda fun yin ki ẹ wọ ibẹ pẹlu pipe yin sibi onjẹ, ẹ ko si gbọdọ pẹ ni ijoko ni ẹniti o nreti jijinna onjẹ sugbọn ti wọn ba pe wọn lọ si ibi onjẹ ki ẹ wọle, ti ẹ ba si jẹun tan ki ẹ pẹyin da, ki ẹ mase wa nibẹ lẹyin naa fun fifi ọrọ naju apakan yin pẹlu apakan, dajudaju npipẹ nibẹ jẹ ohun ti nfi suta se anọbi ti ikẹ ati ọla nbẹ fun, yoo si maa tiju lati wa pipẹyinda lati ọdọ yin, bẹẹni Allah kii tiju lati pa asẹ ododo, O wa pa yin lasẹ ki ẹ pẹyin da kuro ni ọdọ rẹ, ki ẹ ma ba fi suta se e ti ikẹ ati ọla nbẹ fun nibi wiwa nibẹ, ti ẹba nwa bukaata kan gẹgẹ bi abọ ounjẹ ni ọdọ awọn iyawo anọbi ti ikẹ ati ọla nbẹ fun tabi ohun ti o jọ iru rẹ, ki ẹ ya wa ohun ti ẹ nino yii ni ẹyin gaga, ẹ mase wa lọdọ wọn ni idojukọra, ki oju yin ma baa se rin wọn; ki o le jẹ idaabobo fun wọn; nitori ipo ojisẹ Allah ti ikẹ ati ọla nbẹ fun, bibeere lẹyin gaga yin ni o le fọ ọkan yin mọ ati ọkan ti wọn ju; ki esu ma ba ri ọna wọ inu ọkan yin ati ọkan wọn pẹlu royiroyi ati sise lọsọ ohun ti ko dara, ko si tọ fun - ẹyin olugbagbọ ododo - ki ẹ maa fi suta se ojisẹ Allah nibi wiwa nibẹ fun ọrọ, bẹẹni ko tọ ki ẹ fẹ awọn iyawo rẹ lẹyin iku rẹ, awọn jẹ iya gbogbo olugbagbọ ododo, ko si tọ fun ẹnikẹni ki o fẹ iya rẹ, dajudaju ifisuta seni yii -ninu rẹ ni ki ẹ fẹ awọn iyawo rẹ lẹyin iku rẹ - eewọ ni o jẹ ati ẹsẹ ti o tobi ni a kaa a kun ni ọdọ Allah.
إِن تُبۡدُواْ شَيًۡٔا أَوۡ تُخۡفُوهُ فَإِنَّ ٱللَّهَ كَانَ بِكُلِّ شَيۡءٍ عَلِيمٗا 54
Ti ẹ se afihan nkankan ninu awọn isẹ yin tabi ẹ ba fi pamọ si inu ọkan yin nkankan ko le pamọ fun Allah nibẹ, dajudaju Allah jẹ onimimọ nipa gbogbo nkan, nkankan ko pamọ fun Un nibi awọn isẹ yin ati nkan miran, yoo si san yin lẹsan lori awọn yin, ti o ba jẹ rere yoo san yin lẹsan rere, ti o ba jẹ aburu yoo san yin lẹsan aburu.
Titobi ipo anọbi - ti ikẹ ati ọla nbẹ fun - lọdọ Ọlọhun Ọba rẹ, nitori rẹ ni o fi bu awọn ọmọlẹyin rẹ - ki Allah yọnu siwọn nibi pipẹ ninu ile rẹ eyiti o nse ni suta.
Ririnlẹ iroyin meji naa: imọ ati atẹmọra fun Allah ti O ga.
Itiju wa ninu awọn iwa anọbi ti ikẹ ati ọla nbẹ fun.
Sisọ ipo awọn iya awọn olugbagbọ ododo ninu awọn iyawo anọbi - ti ikẹ ati ọla nbẹ fun -.