وَلَئِنۡ أَرۡسَلۡنَا رِيحٗا فَرَأَوۡهُ مُصۡفَرّٗا لَّظَلُّواْ مِنۢ بَعۡدِهِۦ يَكۡفُرُونَ 51
Ti a ba gbe atẹgun dide lori awọn irugbin wọn si awọn ọgbin wọn ati awọn irugbin wọn ti o nbaa jẹ le wọn lori, ti wọn wa ri awọn nkan ọgbin wọn ni awọ pupa ni fẹsi fẹsi lẹyin igbati o ti jẹ ohun ti o tutu gbọdọgbọdọ, wọn ko ba di alaimoore si idẹkun Allah ti o gbawaju bi o se pọ to lẹyin igbati wọn ba fi oju wọn ri i.
فَإِنَّكَ لَا تُسۡمِعُ ٱلۡمَوۡتَىٰ وَلَا تُسۡمِعُ ٱلصُّمَّ ٱلدُّعَآءَ إِذَا وَلَّوۡاْ مُدۡبِرِينَ 52
Gẹgẹ bi o sẹ jẹpe o ko lagbara lati fun oku lọrọgbọ, ti o ko si lagbara lati fun aditi lọrọ gbọ, paapaa wọn ti takete si ọ ki o le daju aigbọran wọn, gẹgẹ bẹẹ naa ni o ko lagbara lati fi apejuwe awọn eniyan ti o gunri yii mọna ati aikose anfaani.
وَمَآ أَنتَ بِهَٰدِ ٱلۡعُمۡيِ عَن ضَلَٰلَتِهِمۡۖ إِن تُسۡمِعُ إِلَّا مَن يُؤۡمِنُ بَِٔايَٰتِنَا فَهُم مُّسۡلِمُونَ 53
Iwọ ko le fi se kongẹ ẹniti o ba sọnu kuro ni oju ọna ti o duro tọ lọ si titọ oju ọna ti dọgba, o ko le fun lọrọ gbọ gbigbọ sise anfaani pẹlu rẹ ayaafi ẹniti o nigbagbọ si awọn amin wa; toripe oun ni yoo se anfaani pẹlu ohun ti o nsọ, awọn si ni olutẹriba fun asẹ wa, olurẹraẹni nilẹ fun un.
۞ٱللَّهُ ٱلَّذِي خَلَقَكُم مِّن ضَعۡفٖ ثُمَّ جَعَلَ مِنۢ بَعۡدِ ضَعۡفٖ قُوَّةٗ ثُمَّ جَعَلَ مِنۢ بَعۡدِ قُوَّةٖ ضَعۡفٗا وَشَيۡبَةٗۚ يَخۡلُقُ مَا يَشَآءُۚ وَهُوَ ٱلۡعَلِيمُ ٱلۡقَدِيرُ 54
Allah ni Ẹniti O da yin - ẹyin eniyan - ninu omin yẹpẹrẹ lẹyin naa O se yin ni alagbara ọkunrin lẹyin igbati ẹ ti lẹ ni igba kekere yin, lẹyin naa O se yin ni ọlẹ agbalagba ati arugbo lẹyin igbati ẹ jẹ alagbara ọkunrin, Allah ma nda ohun ti o ba wu U nibi ijọlẹ tabi agbara, Oun ni onimimọ nipa gbogbo nkan, nkankan ko pamọ fun Un, O si jẹ alagbara ti nkankan ko le ko agara ba A.
وَيَوۡمَ تَقُومُ ٱلسَّاعَةُ يُقۡسِمُ ٱلۡمُجۡرِمُونَ مَا لَبِثُواْ غَيۡرَ سَاعَةٖۚ كَذَٰلِكَ كَانُواْ يُؤۡفَكُونَ 55
Ọjọ ti igbende yoo to, awọn ẹlẹsẹ yoo maa bura wipe awọn ko lo ju wakati kan lọ ninu saare wọn, ẹgẹ bi wọn se mu wọn kuro nibi ninimọ ondinwọn ti wọn lo ninu saare wọn, bẹẹ naa ni wọn jẹ ẹniti o yi kuro nibi ododo ni ile aye.
وَقَالَ ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡعِلۡمَ وَٱلۡإِيمَٰنَ لَقَدۡ لَبِثۡتُمۡ فِي كِتَٰبِ ٱللَّهِ إِلَىٰ يَوۡمِ ٱلۡبَعۡثِۖ فَهَٰذَا يَوۡمُ ٱلۡبَعۡثِ وَلَٰكِنَّكُمۡ كُنتُمۡ لَا تَعۡلَمُونَ 56
Awọn ti Allah fun ni mimọ yoo maa sọrọ ninu awọn anọbi ati awọn malaika: paapaa ẹ ti lo ounti Allah kọ fun yin ninu imọ Rẹ ti o gba waju lati ọjọ ti O ti da yin titi di ọjọ igbende yin ti ẹ ntako, eleyi ni ọjọ ti wọn yoo gbe awọn eniyan dide ninu saare wọn, sugbọn ẹyin jẹ ẹniti ko mọ wipe dajudaju igbende yoo sẹlẹ ni ẹ se tako o.
فَيَوۡمَئِذٖ لَّا يَنفَعُ ٱلَّذِينَ ظَلَمُواْ مَعۡذِرَتُهُمۡ وَلَا هُمۡ يُسۡتَعۡتَبُونَ 57
Ni ọjọ ti Allah yoo gbe awọn ẹda dide fun isiro ati ẹsan, ohun ti awọn alabosi hun ni awijare ko nii se wọn ni anfaani, wọn ko si nii beere wiwa iyọnu Allah lọwọ wọn pẹlu ironu ipiwada ati isẹri lọsi ọdọ Rẹ; nitori bibọ asiko yii.
وَلَقَدۡ ضَرَبۡنَا لِلنَّاسِ فِي هَٰذَا ٱلۡقُرۡءَانِ مِن كُلِّ مَثَلٖۚ وَلَئِن جِئۡتَهُم بَِٔايَةٖ لَّيَقُولَنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓاْ إِنۡ أَنتُمۡ إِلَّا مُبۡطِلُونَ 58
Paapaa a ti fi lelẹ ninu Alukuraani yii fun awọn eniyan - niti kikọ bi ara si wọn - gbogbo apejuwe; ki ododo le han si wọn kuro nibi ibajẹ, sugbọn ti o ba mu wa ba wọn - irẹ ojisẹ - awijare kan lori jijẹ ododo rẹ awọn ti wọn se keferi si Allah yoo sọpe: ẹ ko jẹ nkankan ju olubilẹjẹ nibi ohun ti ẹ mu wa lọ.
كَذَٰلِكَ يَطۡبَعُ ٱللَّهُ عَلَىٰ قُلُوبِ ٱلَّذِينَ لَا يَعۡلَمُونَ 59
Iru apejuwe edidi ti o wa ni ọkan awọn eniyan wọnyi, ti o ba mu amin kan wa fun wọn, wọn ko nii gba a gbọ, Allah fi ndi ọkan gbogbo awọn ti ko ni imọ wipe ohun ti o mu wa ba wọn jẹ ododo.
فَٱصۡبِرۡ إِنَّ وَعۡدَ ٱللَّهِ حَقّٞۖ وَلَا يَسۡتَخِفَّنَّكَ ٱلَّذِينَ لَا يُوقِنُونَ 60
Se suuru - irẹ ojisẹ - lori irọ ti awọn ijọ rẹ npa mọ ọ, dajudaju adehun Allah fun ọ lori aranse ati igbalaaye jẹ ohun ti o rinlẹ ti ko si iyemeji nibẹ, ki awọn ti ko ni amọdaju wipe wọn yoo gbe awọn dide mase ti ọ lọ si ibi ikanju ati gbigbe suuru ju silẹ.
Ijakan awọn keferi kuro nibi ikẹ Allah ni igba isọkalẹ adanwo.
Itọsọna kongẹ wa ni ọwọ Allah, ko si ni ọwọ ojisẹ naa ti ikẹ ati ọla nbẹ fun.
Awọn igbesẹ ọjọ ori jẹ ariwoye fun ẹniti o mọ oye.
Fifi edidi di ọkan jẹ okunfa ẹsẹ.