۞وَلَقَدۡ وَصَّلۡنَا لَهُمُ ٱلۡقَوۡلَ لَعَلَّهُمۡ يَتَذَكَّرُونَ 51
Paapaa a ti mu itan ti o ti siwaju de ọdọ awọn ẹlẹbọ ati yahuudi ninu awọn ọmọ isirẹli ati iya ti o jẹ wọn lẹtọ si nitori pipe awọn ojisẹ wa nirọ; ki wọn le ba gbe isiti pẹlu rẹ, ki wọn si le nigbagbọ, ki ohun ti o sẹlẹ si wọn maa ba sẹlẹ si awọn naa.
ٱلَّذِينَ ءَاتَيۡنَٰهُمُ ٱلۡكِتَٰبَ مِن قَبۡلِهِۦ هُم بِهِۦ يُؤۡمِنُونَ 52
Awọn ti wọn duro sinsin lori igbagbọ si taoreeta siwaju ki Alukuraani too sọkalẹ, wọn jẹ ẹniti o nigbagbọ si Alukuraani nitori ohun ti wọn ri ninu iwe wọn nipa iro rẹ ati awọn iroyin rẹ.
وَإِذَا يُتۡلَىٰ عَلَيۡهِمۡ قَالُوٓاْ ءَامَنَّا بِهِۦٓ إِنَّهُ ٱلۡحَقُّ مِن رَّبِّنَآ إِنَّا كُنَّا مِن قَبۡلِهِۦ مُسۡلِمِينَ 53
Ti wọn nka a fun wọn, wọn yoo sọpe: a nigbagbọ si i, dajudaju ododo ni ti ko si iyemeji nibẹ, o sọkalẹ lati ọdọ Ọlọhun wa, awa jẹ olujupajusẹ silẹ siwaju Alukuraani yii nitori igbagbọ wa ti a ni si ohun ti awọn ojisẹ mu wa siwaju rẹ.
أُوْلَٰٓئِكَ يُؤۡتَوۡنَ أَجۡرَهُم مَّرَّتَيۡنِ بِمَا صَبَرُواْ وَيَدۡرَءُونَ بِٱلۡحَسَنَةِ ٱلسَّيِّئَةَ وَمِمَّا رَزَقۡنَٰهُمۡ يُنفِقُونَ 54
Awọn wọnyi ni a royin pẹlu ohun ti a darukọ, Allah yoo fun wọn lẹsan isẹ wọn ni ẹẹmeji nitori suuru wọn lori igbagbọ si tira wọn ati igbagbọ wọn si Muhammad ẹniti ikẹ ati ọla nbẹ fun nigbati wọn gbe e dide, wọn si nfi daadaa sise ti ẹsẹ ti wọn ti da danu, bakanna wọn na ninu ohun ti a se fun wọn si ọna rere.
وَإِذَا سَمِعُواْ ٱللَّغۡوَ أَعۡرَضُواْ عَنۡهُ وَقَالُواْ لَنَآ أَعۡمَٰلُنَا وَلَكُمۡ أَعۡمَٰلُكُمۡ سَلَٰمٌ عَلَيۡكُمۡ لَا نَبۡتَغِي ٱلۡجَٰهِلِينَ 55
Nigbati awọn olugbagbọ ododo yii ba gbọ ibajẹ ninu ọrọ ni ọdọ awọn ti a fun ni tira, wọn yoo gunri kuro nibẹ ni ẹniti ko nii gboju wobẹ, wọn yoo waa maa sọ ni ẹniti o nda oju kọ awọn ẹniirẹ: ẹsan isẹ wa nbẹ fun wa, bẹẹni ẹsan isẹ yin nbẹ fun yin, ẹyin la kuro nibi eebu ati suta ni ọdọ wa, awa ko wa ibasepọ awọn alaimọkan nitori inira ati suta ti nbẹ nibẹ lori ẹsin ati aye.
إِنَّكَ لَا تَهۡدِي مَنۡ أَحۡبَبۡتَ وَلَٰكِنَّ ٱللَّهَ يَهۡدِي مَن يَشَآءُۚ وَهُوَ أَعۡلَمُ بِٱلۡمُهۡتَدِينَ 56
Dajudaju iwọ, - irẹ ojisẹ - o ko le fi ẹniti o ba wu ọ mọna gẹgẹ bi Abu Talib ati ẹniti a yatọ si i niti kongẹ igbagbọ sugbọn Allah nikan ni ẹniti O le fi ẹniti o ba wu U mọna, Oun ni O si nimọ ju nipa ẹniti imọ rẹ ti gbawaju lọdọ rẹ wipe yoo wa ninu ẹni itọsọna lọsi oju ọna ti o duro tọ.
وَقَالُوٓاْ إِن نَّتَّبِعِ ٱلۡهُدَىٰ مَعَكَ نُتَخَطَّفۡ مِنۡ أَرۡضِنَآۚ أَوَ لَمۡ نُمَكِّن لَّهُمۡ حَرَمًا ءَامِنٗا يُجۡبَىٰٓ إِلَيۡهِ ثَمَرَٰتُ كُلِّ شَيۡءٖ رِّزۡقٗا مِّن لَّدُنَّا وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَهُمۡ لَا يَعۡلَمُونَ 57
Awọn ẹlẹbọ ninu awọn ara Mẹkkah sọpe ni ẹniti o nwi awijare nipa titẹle islam ati ini igbagbọ si i: ti a ba tẹle Islam ti o mu wa yii, a o maa ba awọn ọta wa se ifanfa ni ori ile ni kiakia, se awa ko gba awọn ẹlẹbọ yii laaye ni, ni aaye ọwọ eyiti a se tita ẹjẹ leewọ nibẹ ati sise abosi, ti wọn fi ọkan balẹ nibẹ kuro nibi jijalu ẹniti o yatọ si wọn le wọn lori, wọn nmu gbogbo nkan eleso wa sibẹ niti arisiki, ti a ndari rẹ wa ba wọn lati ọdọ Wa?! Sugbọn ọpọ wọn ko mọ ohun ti Allah se ni idẹkun le wọn lori ki wọn le dupẹ rẹ.
وَكَمۡ أَهۡلَكۡنَا مِن قَرۡيَةِۢ بَطِرَتۡ مَعِيشَتَهَاۖ فَتِلۡكَ مَسَٰكِنُهُمۡ لَمۡ تُسۡكَن مِّنۢ بَعۡدِهِمۡ إِلَّا قَلِيلٗاۖ وَكُنَّا نَحۡنُ ٱلۡوَٰرِثِينَ 58
Ọpọ awọn abule ti o se aimoore si idẹkun Allah ti O se fun wọn, ti wọn si kọja aala nibi ẹsẹ ati asise, A wa ran iya si wọn, A si pa wọn run, eleyi jẹ awọn ibugbe wọn ti a ti sọ di gbigbo, ti awọn eniyan nkaọja nibẹ, ti ẹnikankan ko le gbe ibẹ ninu awọn ara ibẹ ayaafi diẹ ninu awọn olurekọja, Awa si ni olujogun, ti yoo jogun sanmọ ati ilẹ ati ohun ti nbẹ ninu mejeeji.
وَمَا كَانَ رَبُّكَ مُهۡلِكَ ٱلۡقُرَىٰ حَتَّىٰ يَبۡعَثَ فِيٓ أُمِّهَا رَسُولٗا يَتۡلُواْ عَلَيۡهِمۡ ءَايَٰتِنَاۚ وَمَا كُنَّا مُهۡلِكِي ٱلۡقُرَىٰٓ إِلَّا وَأَهۡلُهَا ظَٰلِمُونَ 59
Ọlọhun Ọba rẹ ko jẹ -ire ojise- olupa awọn abule run titi ti Yoo fi wa awijare fun awọn ẹni ibẹ pẹlu gbigbe ojisẹ dide ni abule ti o tobi nibẹ gẹgẹ bi O se gbe iwọ dide ni ‘umul kurọ’ ohun si ni mọka, Awa ko gbero lati pa awọn ara abule run nigbati wọn ba duro tọ lori ododo, ohun ti A fi ma npa wọn run ni ti wọn ba jẹ alabosi pẹlu sise keferi ati dida ẹsẹ.
Ọla ti nbẹ fun ẹniti o ba nigbagbọ ninu awọn ti A fun ni tira si anọbi Muhammad ti ikẹ ati ọla nbẹ fun ati wipe dajudaju ẹsan meji nbẹ fun.
Itọsọna kongẹ wa ni ọwọ Allah, ko si ni ọwọ ẹniti o yatọ si I ninu awọn ojisẹ ati ẹniti o yats si wọn.
Titẹle ododo jẹ ọna ifọkanbalẹ, kii se ohun ti o nse okunfa ipaya gẹgẹ bi awọn ẹlẹbọ se nro.
Ewo ti nbẹ nibi ayọpọrọ lori ẹyọ eniyan ati awujọ.
Ninu ikẹ Allah nipe ko nii pa awọn eniyan run ayaafi lẹyin iwa awijare le wọn lori pẹlu riran awọn ojisẹ.