وَمَآ أَمۡرُنَآ إِلَّا وَٰحِدَةٞ كَلَمۡحِۢ بِٱلۡبَصَرِ 50
Asẹ Wa ko jẹ nkankan kan nigbati a ba gbero nkankan kan ju ki a sọ gbolohun kan soso lọ, ohun si ni: jẹ bẹ, ki ohun ti a fẹ si yara jẹ bẹẹ gẹgẹ bi isẹju akan.
وَلَقَدۡ أَهۡلَكۡنَآ أَشۡيَاعَكُمۡ فَهَلۡ مِن مُّدَّكِرٖ 51
Paapaa a si ti mu iparun ba apejuwe yin nibi sise keferi ninu awọn ijọ ti o ti re kọja, njẹ a ri oluwoye ti yoo woye pẹlu eleyi, ti yoo si gba ijagbemọ kuro nibi keferi rẹ bi?!
وَكُلُّ شَيۡءٖ فَعَلُوهُ فِي ٱلزُّبُرِ 52
Gbogbo nkan ti awọn ẹru ba se ti jẹ ohun ti A kọ si inu awọn iwe aabo, ti nkankan ko le bọ nibẹ.
وَكُلُّ صَغِيرٖ وَكَبِيرٖ مُّسۡتَطَرٌ 53
Ati gbogbo nkan kekere ninu awọn isẹ ati awọn ọrọ ati gbogbo ohun ti o tobi ninu rẹ: jẹ ohun ti A ti kọ sinu awọn oju ewe awọn isẹ ni inu ọpọn ti a daabobo, wọn yoo si san wọn lẹsan le lori.
إِنَّ ٱلۡمُتَّقِينَ فِي جَنَّٰتٖ وَنَهَرٖ 54
Dajudaju awọn olupaya Ọlọhun Ọba wọn pẹlu mimu awọn asẹ Rẹ sẹ ati jijinna si awọn ohun ti O kọ, yoo wa ninu awọn ọgba idẹra ti wọn yoo maa tri idẹkun nibẹ ati ninu awọn odo ti o nsan.
فِي مَقۡعَدِ صِدۡقٍ عِندَ مَلِيكٖ مُّقۡتَدِرِۢ 55
Ni aaye ododo ti ko nii si ere gele nibẹ, bẹẹni ko nii si ẹsẹ, ni ọdọ olukapa ti o nikapa gbogbo nkan, alagbara ti ko kagara ohunkihun, wọn ko le bi leere ohun ti ọwọ wọn ba tẹ lọdọ Rẹ ninu idẹkun gbere.
سورة (MADANIYYAH)
Iran awọn aljannu ati eniyan leti awon idẹra Allah eyiti o pamo ati eyiti o han, ati awọn oripa ikẹ Rẹ laye ati ọrun.
ٱلرَّحۡمَٰنُ 1
Ajọkẹ Aye Oun ni Onikẹ ti o gbaaye.
عَلَّمَ ٱلۡقُرۡءَانَ 2
O fi Alukuraani mọ ọmọniyan pẹlu rirọ hiha sori rẹ ati sise irọrun agbọye awọn itumọ rẹ.
خَلَقَ ٱلۡإِنسَٰنَ 3
O da ọmọniyan dọgba, o si se aworan rẹ daadaa.
عَلَّمَهُ ٱلۡبَيَانَ 4
O fi bi yoo se maa se alaye ohun ti nbẹ ni ọkan rẹ mọ ọ niti sisọ ọ tabi kikọ ọ silẹ.
ٱلشَّمۡسُ وَٱلۡقَمَرُ بِحُسۡبَانٖ 5
Oorun ati osupa jẹ ohun ti o pebubu awọn mejeeji; mejeeji nlọ ni ibamun isiro ti o jinna; ki awọn eniyan le mọ onka ọdun ati isiro.
وَٱلنَّجۡمُ وَٱلشَّجَرُ يَسۡجُدَانِ 6
Ati ohun ti ko ni ojugun ninu awọn irugbin ati igi jẹ ohun ti mejeeji nfi ori balẹ fun Allah ti mimọ nbẹ fun ni ẹniti wọn ntẹri ba fun Un, ti wọn si jupa jusẹ silẹ fun Un.
وَٱلسَّمَآءَ رَفَعَهَا وَوَضَعَ ٱلۡمِيزَانَ 7
Sanmọ jẹ ohun ti O gbe si oke ilẹ ni aga fun un, O si fi deede rinlẹ ni ilẹ, O si pa awọn ẹru Rẹ lasẹ rẹ.
أَلَّا تَطۡغَوۡاْ فِي ٱلۡمِيزَانِ 8
O fi deede rinlẹ ki ẹ maa ba fi si ibi kan - ẹyin eniyan - ki ẹ maa ba se ijamba nibi osuwọn ati odiwọn.
وَأَقِيمُواْ ٱلۡوَزۡنَ بِٱلۡقِسۡطِ وَلَا تُخۡسِرُواْ ٱلۡمِيزَانَ 9
Ki ẹ gbe osuwọn dide laarin yin pẹlu deedee, ki ẹ mase din osuwọn ati odiwọn ku nigbati ẹ ba wọn ọn tabi ẹ ba se odinwọn rẹ ku fun ẹniti o yatọ si yin.
وَٱلۡأَرۡضَ وَضَعَهَا لِلۡأَنَامِ 10
Ilẹ jẹ ohun ti o tẹ pẹrẹsẹ ni ipese silẹ ki awọn ẹda le rinlẹ le lori.
فِيهَا فَٰكِهَةٞ وَٱلنَّخۡلُ ذَاتُ ٱلۡأَكۡمَامِ 11
Ninu rẹ ni awọn igi eyiti o nso awọn ipapanu wa, ninu rẹ naa si ni ọpẹ eyiti o ni odi ẹyin eyiti awọn eso tamuru wa ninu rẹ.
وَٱلۡحَبُّ ذُو ٱلۡعَصۡفِ وَٱلرَّيۡحَانُ 12
Ninu rẹ ni horo naa wa tii se onipadi gẹgẹ bi eso buru ati eso sẹhiri ninu rẹ si ni awọn irugbin eyiti ẹ nifẹ si oorun rẹ naa wa.
فَبِأَيِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ 13
Ewo ninu idẹkun Allah ti o pọ le yin lori - ẹyin awujọ alujannu ati eniyan - npe nirọ bi?!
خَلَقَ ٱلۡإِنسَٰنَ مِن صَلۡصَٰلٖ كَٱلۡفَخَّارِ 14
O da Aadamọ ẹniti ọla nbẹ fun lati inu amọ ti o gbẹ, ti ẹ yoo maa gbọ gbọn in gbọ in nibẹ gẹgẹ bi amọ ti a ti sun.
وَخَلَقَ ٱلۡجَآنَّ مِن مَّارِجٖ مِّن نَّارٖ 15
O si da baba alujannu lati ibi ahọn sọpọnna ninu eefin.
فَبِأَيِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ 16
Ewo ninu idẹkun Allah ti o pọ le yin lori - ẹyin awujọ alujannu ati eniyan - npe nirọ bi?!
رَبُّ ٱلۡمَشۡرِقَيۡنِ وَرَبُّ ٱلۡمَغۡرِبَيۡنِ 17
Ọba ibuyọ oorun meji ati ibuwọ mejeeji nigba ọyẹ ati igba ooru.
فَبِأَيِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ 18
Ewo ninu idẹkun Allah ti o pọ le yin lori - ẹyin awujọ alujannu ati eniyan - npe nirọ bi?!
Kikọ awọn isẹ kekere rẹ tabi titobi rẹ si inu awọn oju ewe awọn isẹẹre.
Bibẹrẹ Ọba Ajọkẹ aye pẹlu didarukọ awọn idẹkun Rẹ ninu Alukuraani tọka si iyi Alukuraani ati titobi idẹkun lori wiwuwa pẹlu rẹ.
Ipo deedee ninu ẹsin alaafia.
Idẹkun Allah bukaata si jijẹwọ rẹ ati didupẹ rẹ, kii se pipe e nirọ tabi sise aimoore si i.