قَالُوٓاْ أَوَ لَمۡ تَكُ تَأۡتِيكُمۡ رُسُلُكُم بِٱلۡبَيِّنَٰتِۖ قَالُواْ بَلَىٰۚ قَالُواْ فَٱدۡعُواْۗ وَمَا دُعَٰٓؤُاْ ٱلۡكَٰفِرِينَ إِلَّا فِي ضَلَٰلٍ 50
Awọn alamojuto ina jahannamọ sọrọ ni ẹniti o nfesi fun awọn keferi: se awọn ojisẹ yin ko wa ti mu awọn awijare ati awọn ẹri ti o fi oju wa ba yin ni?! Awọn keferi sọpe: bẹẹni, wọn ti mu awọn awijare ati ẹri ti o fi oju han wa ba wa, awọn alamojuto sọ fun wọn niti ibinu si wọn: ẹ yaa pe, awa ko nii sipẹ fun awọn keferi, adura keferi ko jẹ nkankan ayaafi ibajẹ ati iralare; nitoripe wọn ko nii gba a lọwọ wọn pẹlu okunfa keferi wọn.
Nigbati Allah sọ itan fir'aona ati ibiti ọrọ rẹ sẹri, ati ọrọ awọn olukọse rẹ ni ile aye ati lọrun, O tun sọ ọrọ awọn ojisẹ ati ọrọ awọn olugbagbọ ododo ati ibi ti wọn yoo sẹri si ninu aranse ati lọrun, O wa sọpe:
إِنَّا لَنَنصُرُ رُسُلَنَا وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ فِي ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا وَيَوۡمَ يَقُومُ ٱلۡأَشۡهَٰدُ 51
Dajudaju Awa yoo maa se aranse fun awọn ojisẹ Wa ati awọn ti wọn nigbagbọ si Allah ati si awọn ojisẹ Rẹ ni ile aye pẹli sise afihan awijare wọn ati ikun wọn lọwọ lori awọn ọta wọn, a o si ran wọn se ni ọjọ igbende pẹlu mimu wọn wọ ọgba idẹra naa, ati fifi iya jẹ awọn olubawọnja ni ile aye pẹlu mimu wọn wọ ina lẹyin igbati awọn anọbi ati awọn Malaaika ati awọn olugbagbọ ododo ba jẹri lori sisẹlẹ imudopin ati pipe awọn ijọ nirọ.
يَوۡمَ لَا يَنفَعُ ٱلظَّٰلِمِينَ مَعۡذِرَتُهُمۡۖ وَلَهُمُ ٱللَّعۡنَةُ وَلَهُمۡ سُوٓءُ ٱلدَّارِ 52
Ọjọ ti awijare awọn alabosi nipa abosi ti wọn se ko nii se anfaani fun wọn pẹlu sise keferi ati awọn ẹsẹ, ilenisa kuro nibi ikẹ Allah si wa fun wọn ni ọjọ naa, ibudarisi aburu naa wa fun wọn lọrun pẹlu ohun ti wọn yoo ba pade ninu iya inira.
وَلَقَدۡ ءَاتَيۡنَا مُوسَى ٱلۡهُدَىٰ وَأَوۡرَثۡنَا بَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ ٱلۡكِتَٰبَ 53
Paapaa a si ti fun Musa ni imọ eyiti awọn ọmọ isirẹli yoo tibẹ mọ ọna lọsi ibi ododo, a si se taoreeta ni iwe kan ti awọn ọmọ isirẹli yoo maa jogun laarin wọn, wọn yoo maa jogun rẹ lati igbadegba.
هُدٗى وَذِكۡرَىٰ لِأُوْلِي ٱلۡأَلۡبَٰبِ 54
O jẹ ọnaamọ lọsi oju ọna ododo ati irannileti fun awọn onilaakaye ti o mọ.
فَٱصۡبِرۡ إِنَّ وَعۡدَ ٱللَّهِ حَقّٞ وَٱسۡتَغۡفِرۡ لِذَنۢبِكَ وَسَبِّحۡ بِحَمۡدِ رَبِّكَ بِٱلۡعَشِيِّ وَٱلۡإِبۡكَٰرِ 55
Ki o se suuru - irẹ ojisẹ - lori ohun ti ẹ nba pade nipa ipeniniirọ awọn ijọ rẹ ati suta wọn, dajudaju adehun Allah fun ọ lori aranse ati ikunlọwọ ododo ko si iyemeji nibẹ, ki o si maa wa aforijin ẹsẹ rẹ, ki o si maa se afọmọ didupẹ fun Ọlọhun Ọba rẹ ni akọkọ ọsan ati igbẹyin rẹ.
إِنَّ ٱلَّذِينَ يُجَٰدِلُونَ فِيٓ ءَايَٰتِ ٱللَّهِ بِغَيۡرِ سُلۡطَٰنٍ أَتَىٰهُمۡ إِن فِي صُدُورِهِمۡ إِلَّا كِبۡرٞ مَّا هُم بِبَٰلِغِيهِۚ فَٱسۡتَعِذۡ بِٱللَّهِۖ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلۡبَصِيرُ 56
Dajudaju awọn ti wọn nja nipa awọn amin Allah niti igbesẹ lati ba a jẹ laisi awijare tabi ẹri ti o wa bawọn lati ọdọ Allah, nkankan ko mu wọn se eleyi ayaafi erongba igapa ati igberaga si ododo, wọn ko si le de ibi ohun ti wọn gba lero nibi igapa naa, ki o ya sadi - irẹ ojisẹ - Allah, dajudaju Oun ni olugbọ gbogbo ọrọ awọn ẹru Rẹ, oluri gbogbo isẹ wọn, nkankan ko le bọ mọ lọwọ nibẹ, yoo si san wọn lẹsan le lori.
لَخَلۡقُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ أَكۡبَرُ مِنۡ خَلۡقِ ٱلنَّاسِ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يَعۡلَمُونَ 57
Paapaa sisẹda gbogbo sanmọ ati ilẹ nibi titobi mejeeji ati gbigbaaye rẹ lagbara ju sisẹda ọmọniyan lọ, ẹniti o da mejeeji bi wọn se tobi to jẹ alagbara lati gbe awọn oku dide lati inu saare wọn ni alaaye, ki o le se isiro wọn, ki o si san wọn lẹsan, sugbọn ọpọ awọn eniyan wọn ko mọ, wọn ko woye si i, wọn ko si fi se itọka lori ajinde pẹlu bi o se han to.
وَمَا يَسۡتَوِي ٱلۡأَعۡمَىٰ وَٱلۡبَصِيرُ وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ وَلَا ٱلۡمُسِيٓءُۚ قَلِيلٗا مَّا تَتَذَكَّرُونَ 58
Ẹniti o nriran ati ẹniti ko riran ko le dọgba, bẹẹni awọn ti wọn nigbagbọ ninu Allah, ti wọn si pe awọn ojisẹ Rẹ lododo, ti wọn si nse isẹ daradara wọn ko le dọgba pẹlu ẹniti o nse isẹ buburu pẹlu adisọkan ibajẹ ati awọn ẹsẹ, wọn ko le ranti ayaafi igba diẹ; nigbati o jasi wipe ti ẹ ba ranti ẹ ko ba mọ iyatọ ti o wa laarin ipin mejeeji, ẹ ko ba si gbe igbesẹ ki ẹ wa ninu awọn ti o nigbagbọ, ti wọn si se awọn isẹ rere lati fi wa iyọnu Allah.
Aranse Allah fun awọn ojisẹ Rẹ ati fun awọn olugbagbọ ododo jẹ isesi Ọlọhun Ọba ti o rinlẹ.
Awijare alabosi ko le se anfaani ni ọjọ igbende.
Pataki suuru nibi dida oju kọ ibajẹ.
Itọka isẹda gbogbo sanmọ ati ilẹ si ajinde; nitoripe dajudaju ẹniti o sẹda ohun ti o tobi jẹ alagbara lati da isẹmin naa pada si ohun ti ko to o.