۞قُلۡ كُونُواْ حِجَارَةً أَوۡ حَدِيدًا 50
Sọ fun wọn - irẹ ojisẹ -: ki ẹ jẹ - ẹyin ẹlẹbọ - ti ẹ jẹ okuta ti o le koko ti ẹ ba fẹ tabi ki ẹ jẹ irin nibi lilagbara rẹ, ẹ ko si lagbara eleyi.
أَوۡ خَلۡقٗا مِّمَّا يَكۡبُرُ فِي صُدُورِكُمۡۚ فَسَيَقُولُونَ مَن يُعِيدُنَاۖ قُلِ ٱلَّذِي فَطَرَكُمۡ أَوَّلَ مَرَّةٖۚ فَسَيُنۡغِضُونَ إِلَيۡكَ رُءُوسَهُمۡ وَيَقُولُونَ مَتَىٰ هُوَۖ قُلۡ عَسَىٰٓ أَن يَكُونَ قَرِيبٗا 51
Tabi ki ẹ jẹ ẹda mran ti o tobi ju mejeeji lọ ninu ohun ti o tobi ju ninu ọkan yin, dajudaju Allah yoo mu yin wa pada gẹgẹ bi o se pilẹ yin, yoo si ta yin gẹgẹ bi O se da yin ni igba akọkọ, awọn olutako yii yoo maa wa sọpe: taani yoo sọ wa di alaaye lẹyin iku wa? Sọ fun wọn: Ẹniti O da yin ni igba akọkọ yoo da yin pada lori aworan ti o yatọ si apejuwe ti o siwaju, wọn yoo wa min ori wọn ni ẹniti ti o se yẹyẹ nibi esi ti o fun wọn, wọn yoo waa maa sọ ọrọ niti jijinna ero ọkan wọn: nigba wo ni imupada yii yoo waye?! Sọ fun wọn: o seese ki o sun mọ, gbogbo ohun ti o nbọ ni o sun mọ.
يَوۡمَ يَدۡعُوكُمۡ فَتَسۡتَجِيبُونَ بِحَمۡدِهِۦ وَتَظُنُّونَ إِن لَّبِثۡتُمۡ إِلَّا قَلِيلٗا 52
Ọlọhun Allah yoo da yin pada ni ọjọ ti wọn yoo pe yin lọsi ori ilẹ fun akojọ, ẹ o si jẹpe ni ijupajusẹ fun asẹ Rẹ ni ẹniti o ndupẹ fun Un, ti ẹ o maa lero wipe ẹ ko lo ni ori ilẹ ju asiko kekere lọ.
وَقُل لِّعِبَادِي يَقُولُواْ ٱلَّتِي هِيَ أَحۡسَنُۚ إِنَّ ٱلشَّيۡطَٰنَ يَنزَغُ بَيۡنَهُمۡۚ إِنَّ ٱلشَّيۡطَٰنَ كَانَ لِلۡإِنسَٰنِ عَدُوّٗا مُّبِينٗا 53
Ki o si sọ - irẹ ojisẹ - fun awọn ẹru Mi ti wọn nigbagbọ si Mi, wọn yoo maa sọ ọrọ ti o dara nigbati wọn ba nfi ọrọ jomi toro ọrọ, wọn yoo si maa jinna si gbolohun aida ti o le leni sa; nitoripe esu yoo lo anfaani rẹ yoo waa maa rin laarin wọn pẹlu ohun ti o le ba isẹmin aye wọn ati ọrun wọn jẹ, dajudaju esu jẹ ọta fun ọmọniyan, ti ijọta rẹ si han de, o di ọwọ rẹ ki o sọra fun un.
رَّبُّكُمۡ أَعۡلَمُ بِكُمۡۖ إِن يَشَأۡ يَرۡحَمۡكُمۡ أَوۡ إِن يَشَأۡ يُعَذِّبۡكُمۡۚ وَمَآ أَرۡسَلۡنَٰكَ عَلَيۡهِمۡ وَكِيلٗا 54
Ọlọhun yin - ẹyin eniyan - nimọ nipa yin nkankan ko pamọ fun lọdọ yin, ti o ba fẹ lati kẹyin Yoo kẹyin pẹlu ki O fi yin se kongẹ igbagbọ ati isẹẹre, ti O ba si fẹ lati fi iya jẹ yin, Yoo fiya jẹyin pẹlu ki O mu yin dagunla si igbagbọ, Yoo si payin lori keferi, A ko gbe ọ dide ire ojise ni olusọ le wọn lori, ti o wa maa jẹ wọn nipa lori igbagbọ tabi kọ fun wọn kuro nibi keferi tabi ki o maa kiye si awọn isẹ wọn, o kan jẹ olumude ogongo lati ọdọ Ọlọhun nipa ohun ti O pa wa lasẹ ki o mu dopin ni.
وَرَبُّكَ أَعۡلَمُ بِمَن فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۗ وَلَقَدۡ فَضَّلۡنَا بَعۡضَ ٱلنَّبِيِّۧنَ عَلَىٰ بَعۡضٖۖ وَءَاتَيۡنَا دَاوُۥدَ زَبُورٗا 55
Atipe Ọlọhun rẹ - irẹ ojisẹ - nimọ nipa gbogbo ẹniti o nbẹ ni sanmọ ati ilẹ, O si mọ isesi wọn ati nkan ti wọn lẹtọ si, paapaa A ti gbọla fun apakan awọn Anọbi lori apakan pẹlu pipọ olutẹle wọn ati sisọ awọn tira kalẹ, A si fun Dawuud ni tira kan tii se Sabuur.
قُلِ ٱدۡعُواْ ٱلَّذِينَ زَعَمۡتُم مِّن دُونِهِۦ فَلَا يَمۡلِكُونَ كَشۡفَ ٱلضُّرِّ عَنكُمۡ وَلَا تَحۡوِيلًا 56
Sọ - irẹ ojisẹ - fun awọn ẹlẹbọ yii: ẹ pe - ẹyin ẹlẹbọ - awọn ti ẹ lero pe wọn jẹ ọlọhun yatọ si Allah, ti inira ba sọkalẹ fun wọn, wọn ko lagbara lati mu inira naa kuro fun yin, wọn si tun ni ikapa lati mu ba ẹniti o yatọ si yin nitori ikagara wọn, ẹniti o ba jẹ olukagara ko le jẹ Ọlọhun.
أُوْلَٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ يَدۡعُونَ يَبۡتَغُونَ إِلَىٰ رَبِّهِمُ ٱلۡوَسِيلَةَ أَيُّهُمۡ أَقۡرَبُ وَيَرۡجُونَ رَحۡمَتَهُۥ وَيَخَافُونَ عَذَابَهُۥٓۚ إِنَّ عَذَابَ رَبِّكَ كَانَ مَحۡذُورٗا 57
Awọn ti ẹ npe ninu awọn Malaika ati ẹniti o jọ wọn, awọn naa nwa ohun ti yoo mu wọn sun mọ Allah ninu isẹẹre, wọn si nse ifanfa ẹni wo yoo tete sunmọ pẹlu itẹle asẹ, wọn si nrankan ki o kẹ wọn, wọn si npaya ki o ma fi iya jẹ wọn, dajudaju iya Ọlọhun rẹ - irẹ ojisẹ - wa ninu ohun ti o tọ ki o sọra fun.
وَإِن مِّن قَرۡيَةٍ إِلَّا نَحۡنُ مُهۡلِكُوهَا قَبۡلَ يَوۡمِ ٱلۡقِيَٰمَةِ أَوۡ مُعَذِّبُوهَا عَذَابٗا شَدِيدٗاۚ كَانَ ذَٰلِكَ فِي ٱلۡكِتَٰبِ مَسۡطُورٗا 58
Ko si abule kan tabi ilu kan ayafi ki a sọ iya kalẹ tabi iparun sibẹ ni ile aye nitori keferi wọn tabi ki a dan an wo pẹlu ijiya ti o le pẹlu mima pa ara wọn tabi ounti o yatọ si nitori keferi wọn, iparun yii ati ijiya naa jẹ ẹsan Ọlọhun ti a ti kọ silẹ ninu ọpọn ti a daabobo.
Gbolohun ti o dara ma npepe fun gbogbo iwa ti o dara ati isẹ rere nitoripe ẹniti o ba nikapa ahọn rẹ, yoo kapa gbogbo alamọri rẹ.
Ọlọhun Allah gbe ọla fun awọn Anọbi Rẹ apakan lori apakan pẹlu imọ ati ọgbọn lati ọdọ Rẹ.
Allah kii gbero fun awọn ẹru Rẹ ayafi ohun ti o ba jẹ rere, kii si pa wọn lasẹ ayafi ohun ti anfaani ba wa nibẹ fun wọn.
Amin ifẹ Ọlọhun Allah ni ki ẹru gbiyanju lori gbogbo isẹ ti yoo sun mọ Allah, ti yoo si tun maa se ifanfa nibi sisunmọ pẹlu sise afọmọ awọn isẹ patapata fun Allah ati sise atunse nibẹ.