لِيَوۡمٍ عَظِيمٖ 5
Fun isiro ati ẹsan ni ọjọ ti o tobi nitori wahala ati awọn ibẹru ti o wa nibẹ.
يَوۡمَ يَقُومُ ٱلنَّاسُ لِرَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ 6
Ọjọ ti awọn eniyan yoo dide fun Ọlọhun gbogbo ẹda lapapọ; fun isiro.
كَلَّآ إِنَّ كِتَٰبَ ٱلۡفُجَّارِ لَفِي سِجِّينٖ 7
Ọrọ ko ri bi ẹ se nyaworan rẹ wipe ko si ajinde lẹyin iku, dajudaju iwe awọn ẹni poki ati awọn keferi ati awọn sọbẹ selu yoo wa ninu ofo lori ilẹ yẹpẹrẹ.
وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا سِجِّينٞ 8
Kinni yoo fi mọ ọ - irẹ ojisẹ - ohun ti o nse ‘sijiinu’.
كِتَٰبٞ مَّرۡقُومٞ 9
Dajudaju iwe wọn wa ni akọsilẹ ti ko nii yẹ, wọn ko si nii se alekun nibẹ tabi dinku.
وَيۡلٞ يَوۡمَئِذٖ لِّلۡمُكَذِّبِينَ 10
Iparun ati ofo ni ọjọ naa jẹ ti awọn opurọ.
ٱلَّذِينَ يُكَذِّبُونَ بِيَوۡمِ ٱلدِّينِ 11
Awọn ti wọn npe ọjọ ẹsan eyiti Allah yoo sẹsan fun awọn ẹru Rẹ lori awọn isẹ wọn ni ile aye nirọ.
وَمَا يُكَذِّبُ بِهِۦٓ إِلَّا كُلُّ مُعۡتَدٍ أَثِيمٍ 12
Ẹnikan ko nii pe ọjọ yii nirọ ayaafi gbogbo olukọja ẹnu aala Allah ọlọpọ ẹsẹ.
إِذَا تُتۡلَىٰ عَلَيۡهِ ءَايَٰتُنَا قَالَ أَسَٰطِيرُ ٱلۡأَوَّلِينَ 13
Ti wọn ba ka awọn amin Wa ti a sọkalẹ fun ojisẹ Wa fun un yoo sọpe: o wa ninu awọn itan awọn ijọ akọkọ, kii se lati ọdọ Allah.
كَلَّاۖ بَلۡۜ رَانَ عَلَىٰ قُلُوبِهِم مَّا كَانُواْ يَكۡسِبُونَ 14
Ọrọ ko ri bi awọn opurọ yii se nyaworan rẹ bikosepe ohun ti wọn kojọ ninu ẹsẹ ni o bori laakaye wọn, ti o si bo o daru wọn ko ri ododo pẹlu ọkan wọn.
كَلَّآ إِنَّهُمۡ عَن رَّبِّهِمۡ يَوۡمَئِذٖ لَّمَحۡجُوبُونَ 15
Lododo wọn yoo se ni eewọ fun wọn nipa riri Ọlọhun wọn ni ọjọ igbende.
ثُمَّ إِنَّهُمۡ لَصَالُواْ ٱلۡجَحِيمِ 16
Lẹyin naa wọn yoo wọ ina ti wọn yoo fi ara kin igbona rẹ.
ثُمَّ يُقَالُ هَٰذَا ٱلَّذِي كُنتُم بِهِۦ تُكَذِّبُونَ 17
Wọn yoo tun sọ fun wọn ni ọjọ igbende lẹyin naa niti didẹru ba wọn: eleyi ni iya ti ẹ pade yii ni ohun ti ẹ npe nirọ ni ile aye, nigbati ojisẹ yin fun yin niro rẹ.
كَلَّآ إِنَّ كِتَٰبَ ٱلۡأَبۡرَارِ لَفِي عِلِّيِّينَ 18
Ọrọ ko ri bi ẹ se nyaworan rẹ nipa wipe ko si isiro tabi ẹsan, dajudaju iwe awọn olutẹle asẹ wa ni aaye giga.
وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا عِلِّيُّونَ 19
Kinni o fi aaye giga naa mọ ọ - irẹ ojisẹ - ?!
كِتَٰبٞ مَّرۡقُومٞ 20
Dajudaju iwe wọn jẹ ohun ti a kọ, ti ko nii yẹ, wọn ko si nii lekun nibẹ tabi dinku.
يَشۡهَدُهُ ٱلۡمُقَرَّبُونَ 21
Awọn ti o sun mọ sanmọ ninu awọn Malaaika ni wọn yoo pesẹ sibi iwe naa.
إِنَّ ٱلۡأَبۡرَارَ لَفِي نَعِيمٍ 22
Dajudaju awọn ti wọn tẹle asẹ ni ọpọ yoo wa ninu idẹkun gbere ni ọjọ igbende.
عَلَى ٱلۡأَرَآئِكِ يَنظُرُونَ 23
Lori awọn ibusun ti a se lọsọ ti wọn yoo maa wo Ọlọhun wọn ati gbogbo ohun ti yoo mu idunnu ba ẹmin wọn, ti yoo si dun mọ wọn ninu.
تَعۡرِفُ فِي وُجُوهِهِمۡ نَضۡرَةَ ٱلنَّعِيمِ 24
Ti o ba ri wọn, iwọ yoo ri oripa igbadun ti o dara, ti o si ni imọlẹ ni oju wọn.
يُسۡقَوۡنَ مِن رَّحِيقٖ مَّخۡتُومٍ 25
Awọn ọmọ ọdọ wọn yoo fun wọn ni ọti ti a de igba rẹ mu.
خِتَٰمُهُۥ مِسۡكٞۚ وَفِي ذَٰلِكَ فَلۡيَتَنَافَسِ ٱلۡمُتَنَٰفِسُونَ 26
Oorun alimisiki yoo ma run jade nibẹ de opin rẹ nibi iru ẹsan yii ti o ni apọnle ni o di dandan fun gbogbo olugbawaju ki o gbawaju sibẹ pẹlu sise isẹ ti yoo yọ Allah ninu ati gbigbe ohun ti yoo bi ninu ju silẹ.
وَمِزَاجُهُۥ مِن تَسۡنِيمٍ 27
Wọn yoo ro nkan mimu onideri yii papọ mọ ẹsun ‘tẹsniim’
عَيۡنٗا يَشۡرَبُ بِهَا ٱلۡمُقَرَّبُونَ 28
O si jẹ ẹsun ni oke ọgba idẹra naa ti awọn alasunmọ yoo mu nibẹ ni ohun ti o mọ pọrangandan, awọn olugbagbọ ododo lapapọ naa yoo mu nibẹ, ti wọn ro nkan miran naa papọ mọ.
إِنَّ ٱلَّذِينَ أَجۡرَمُواْ كَانُواْ مِنَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ يَضۡحَكُونَ 29
Dajudaju awọn ẹlẹsẹ pẹlu keferi ti wọn wa lori rẹ yoo maa rẹrin niti ifini se yẹyẹ fun awọn ti wọn nigbagbọ.
وَإِذَا مَرُّواْ بِهِمۡ يَتَغَامَزُونَ 30
Ti wọn ba re kọja lọdọ awọn olugbagbọ ododo, apakan wọn yoo yimun si apa miran niti yẹyẹ ati sise ajoji.
وَإِذَا ٱنقَلَبُوٓاْ إِلَىٰٓ أَهۡلِهِمُ ٱنقَلَبُواْ فَكِهِينَ 31
Ti wọn ba si pada si ọdọ ara wọn, wọn yoo pada niti yiyọ lori keferi ti wọn wa ati fifi awọn olugbagbọ ododo se yẹyẹ.
وَإِذَا رَأَوۡهُمۡ قَالُوٓاْ إِنَّ هَٰٓؤُلَآءِ لَضَآلُّونَ 32
Ti wọn ba si ri awọn olugbafa, wọn yoo sọpe: dajudaju awọn wọnyi ni ẹniti o sọnu kuro ni oju ọna ododo nitoripe wọn gbe ẹsin awọn baba wọn ju silẹ.
وَمَآ أُرۡسِلُواْ عَلَيۡهِمۡ حَٰفِظِينَ 33
Allah ko la sisọ isẹ wọn bọ wọn lọrun ti wọn fi nsọ gbolohun wọn yii.
Ewu awọn ẹsẹ lori awọn ọkan.
Sise riri Ọlọhun wọn ni ọjọ igbende leewọ fun awọn keferi.
Yẹyẹ lati ọdọ ẹni ẹsin jẹ iroyin kan ninu awọn iroyin awọn keferi.