وَإِذَا قِيلَ لَهُمۡ تَعَالَوۡاْ يَسۡتَغۡفِرۡ لَكُمۡ رَسُولُ ٱللَّهِ لَوَّوۡاْ رُءُوسَهُمۡ وَرَأَيۡتَهُمۡ يَصُدُّونَ وَهُم مُّسۡتَكۡبِرُونَ 5
Ti wọn ba sọ fun awọn sọbẹ selu yii wipe, ẹ wa si ọdọ ojisẹ Allaah ni ẹniti o nwi awijare nipa ohun ti o ti ọdọ yin jade, ki o le wa aforijin ni ọdọ wa aforijijn ni ọdọ Allah fun awọn ẹsẹ yin, wọn yoo ka ori wọn jọ niti iseyẹyẹ ati amusere, iwọ yoo si ri wọn ti wọn yoo gunri kuro nibi ohun ti wọn pa wọn lasẹ rẹ, wọn jẹ onigberaga lati gba ododo ati itẹriba fun un.
سَوَآءٌ عَلَيۡهِمۡ أَسۡتَغۡفَرۡتَ لَهُمۡ أَمۡ لَمۡ تَسۡتَغۡفِرۡ لَهُمۡ لَن يَغۡفِرَ ٱللَّهُ لَهُمۡۚ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يَهۡدِي ٱلۡقَوۡمَ ٱلۡفَٰسِقِينَ 6
Ibeere se dọgba - irẹ ojisẹ - lori wiwa aforijin fun ẹsẹ wọn ati mima wa aforijin fun wọn, Allah ko nii fi ori ẹsẹ wọn jin wọn, dajudaju Allah ko nii fi ijọ ti o jade kuro nibi titẹle E se kongẹ, awọn ti wọn taku lori iyapa Rẹ.
هُمُ ٱلَّذِينَ يَقُولُونَ لَا تُنفِقُواْ عَلَىٰ مَنۡ عِندَ رَسُولِ ٱللَّهِ حَتَّىٰ يَنفَضُّواْۗ وَلِلَّهِ خَزَآئِنُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَلَٰكِنَّ ٱلۡمُنَٰفِقِينَ لَا يَفۡقَهُونَ 7
Awọn ni awọn ti wọn nsọpe: ẹ mase na dukia yijn fun awọn ti wọn nbẹ ni ọdọ ojisẹ Allah ninu awọn alaini ati awọn larubawa ni agbegbe Madinah titi wọn yo fi fanka kuro lọdọ rẹ, Allah nikan sini pẹpẹ ọrọ gbogbo sanmọ ati awọn pẹpẹ ọrọ ilẹ, o ma nse arisiki Rẹ fun ẹniti o ba wu U ninu awọn ẹru Rẹ, sugbọn awọn sọbẹ selu ko mọ wipe pẹpẹ ọrọ arisiki wa ni ọwọ Rẹ ti mimọ nbẹ fun.
يَقُولُونَ لَئِن رَّجَعۡنَآ إِلَى ٱلۡمَدِينَةِ لَيُخۡرِجَنَّ ٱلۡأَعَزُّ مِنۡهَا ٱلۡأَذَلَّۚ وَلِلَّهِ ٱلۡعِزَّةُ وَلِرَسُولِهِۦ وَلِلۡمُؤۡمِنِينَ وَلَٰكِنَّ ٱلۡمُنَٰفِقِينَ لَا يَعۡلَمُونَ 8
Olori wọn Abdullahi ọmọ Ubayi sọpe: ti a ba sẹri si ilu Madinah, awọn ẹni iyi yoo mu awọn ẹni - awọn si ni emi ati awọn ijọ mi - ẹniyẹpẹrẹ kuro nibẹ; awọn si ni Muhammad ati awọn eniyan rẹ, ti Allah nikan si ni iyi ati fun ojisẹ Rẹ ati fun awọn olugbagbọ ododo, kii si se fun Abdullahi ọmọ Ubayi ati awọn eniyan rẹ, sugbọn awọn sọbẹ selu ko mọ wipe dajudaju iyi jẹ ti Allah ati ojisẹ Rẹ ati awọn olugbagbọ ododo.
Nigbati Allah salaye oju kokoro awọm sọbẹ selu lori ahun pẹlu nina wo lati di oju ọna Allah, O tun se ikilọ fun awọn olugbagbọ ododo nibi eleyi naa, O si pa wọn lasẹ mima na si oju ọna Rẹ, O wa sọpe:
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تُلۡهِكُمۡ أَمۡوَٰلُكُمۡ وَلَآ أَوۡلَٰدُكُمۡ عَن ذِكۡرِ ٱللَّهِۚ وَمَن يَفۡعَلۡ ذَٰلِكَ فَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡخَٰسِرُونَ 9
Mo pe ẹyin ti ẹ nigbagbọ ninu Allah, ti wọn si se ohun ti O se lofin fun wọn, awọn dukia yin ati awọn ọmọ yin ko gbọdọ mu idiwọ ba yin nibi irun ati nkan miran, ninu awọn ọranyan ẹsin alaafia, ẹniti awọn dukia rẹ ati awọn ọmọ rẹ ba di lọwọ nipa ohun ti Allah se lọranyan fun un gẹgẹ bi irun ati nkan miran, awọn wọnyi ni ẹni ofo tootọ, awọn ti o sofo ẹmin ara wọn ati ara ile wọn ni ọjọ igbende.
وَأَنفِقُواْ مِن مَّا رَزَقۡنَٰكُم مِّن قَبۡلِ أَن يَأۡتِيَ أَحَدَكُمُ ٱلۡمَوۡتُ فَيَقُولَ رَبِّ لَوۡلَآ أَخَّرۡتَنِيٓ إِلَىٰٓ أَجَلٖ قَرِيبٖ فَأَصَّدَّقَ وَأَكُن مِّنَ ٱلصَّٰلِحِينَ 10
Ẹ maa na ninu ohun ti Allah se fun yin ni aranse ninu dukia siwaju ki iku to waa ba ẹnikọọkan yin, ti yoo maa sọ fun Ọlọhun rẹ: Ọlọhun mi, se O ko ni lọ mi lara di asiko diẹ ki nle ta ọrẹ, ki nsi wa ninu awọn ẹru Rẹ ti wọn jẹ ẹniire, awọn ti awọn isẹ wọn dara.
وَلَن يُؤَخِّرَ ٱللَّهُ نَفۡسًا إِذَا جَآءَ أَجَلُهَاۚ وَٱللَّهُ خَبِيرُۢ بِمَا تَعۡمَلُونَ 11
Allah ti mimọ nbẹ fun ko nii ra ẹmin kankan lara nigbati asiko iku rẹ ba de, ti ọjọ ori rẹ si ti tan, allah si jẹ olufuni niro ohun ti ẹ nse nisẹ, nkankan ko pamọ fun Un ninu awọn isẹ yin, yoo si san yin lẹsan le lori, ti o ba jẹ daradara yoo gba ẹsan rere, ti o ba si jẹ aburu yoo gba ẹsan aburu.
Igunri kuro nibi atunse ati igberaga wa ninu awọn iroyin sọbẹ selu.
Ninu awọn ọna awọn ọta ẹsin ni sise jijẹ mimu mọ awọn olugbafa.
Ewu awọn dukia ati awọn ọmọ nigbati o ba di wọn lọwọ iranti Allah.