وَلَوۡ أَنَّهُمۡ صَبَرُواْ حَتَّىٰ تَخۡرُجَ إِلَيۡهِمۡ لَكَانَ خَيۡرٗا لَّهُمۡۚ وَٱللَّهُ غَفُورٞ رَّحِيمٞ 5
Ti o ba jasi wipe awọn ti o npe ọ yii - irẹ ojisẹ - ni ẹyin yara awọn iyawo rẹ ba se suuru, ti wọn ko pe ọ niti o fi jade si wọn, ti wọn wa ba ọ sọrọ ni irẹlẹ ohun wọn; eleyi ki ba loore fun wọn ju pipe ọ ni ẹyin rẹ lọ; nitori ọwọ ati igbetitobi ti o wa nibẹ, Allah si jẹ oluforijin ẹsẹ ẹniti o ba sẹri ninu wọn, ati ẹniti o yatọ si wọn, yoo fi ori jin wọn nitori aimọkan wọn, O tun jẹ onikẹ si wọn.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِن جَآءَكُمۡ فَاسِقُۢ بِنَبَإٖ فَتَبَيَّنُوٓاْ أَن تُصِيبُواْ قَوۡمَۢا بِجَهَٰلَةٖ فَتُصۡبِحُواْ عَلَىٰ مَا فَعَلۡتُمۡ نَٰدِمِينَ 6
Mo pe ẹyin ti ẹ nigbagbọ ninu Allah, ti wọn si se ohun ti wọn se lofin, ti poki kan ba wa fun yin niro nipa ijọ kan, ẹ ri amọdaju ilalaafia iro naa, ẹ mase gba a lododo niti ipaya ki ẹsẹ ma ba kan - nigbati ẹ ba gba iro rẹ lododo laini ifẹsẹ rinlẹ - awọn ijọ, ti ẹ yin si jẹ alaimọkan nipa paapaa ọrọ wọn, ki ẹ ma ba waa di olukabamọ nigbati irọ iro na ba han si yin lẹyin igbati ẹ ti fi ọwọ kan wọn.
وَٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّ فِيكُمۡ رَسُولَ ٱللَّهِۚ لَوۡ يُطِيعُكُمۡ فِي كَثِيرٖ مِّنَ ٱلۡأَمۡرِ لَعَنِتُّمۡ وَلَٰكِنَّ ٱللَّهَ حَبَّبَ إِلَيۡكُمُ ٱلۡإِيمَٰنَ وَزَيَّنَهُۥ فِي قُلُوبِكُمۡ وَكَرَّهَ إِلَيۡكُمُ ٱلۡكُفۡرَ وَٱلۡفُسُوقَ وَٱلۡعِصۡيَانَۚ أُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلرَّٰشِدُونَ 7
ẹ si lọọ mọ - ẹyin olugbagbọ ododo - pe dajudaju ojisẹ Allah nbẹ ninu yin ti imisi nsọkalẹ fun un, ki ẹ sọra lati ma parọ, ki imisi ma ba sọkalẹ fun un ti yoo fun niro irọ pipa yin, Oun ni o si nimọ ju ohun ti yoo se yin lanfaani, ti o ba tẹle yin nipa ọpọ nkan ti ẹ nmu imọran rẹ wa, ẹ ba bọ sinu wahala eyiti ko yọnu si fun yin sugbọn Allah ninu ọla Rẹ fi ifẹ igbagbọ si yin lọkan, O si se lọsọ ninu ọkan yin ni ẹ fi nigbagbọ, O si korira keferi fun yin ati jijade kuro nibi titẹle ti Rẹ, O si tun korira yiyapa Rẹ fun yin, awọn ti a fi awọn iroyin yii royin ni awọn ti o ntọ oju ọna itọsọna ati eyiti o ba mu.
فَضۡلٗا مِّنَ ٱللَّهِ وَنِعۡمَةٗۚ وَٱللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٞ 8
Eyiti o sẹlẹ si yin - nipa titun iro se ninu ọkan yin ati kikorira aburu - dajudaju o jẹ ọla lati ọdọ Allah ti O fi se ọla le yin lori ati idẹkun kan ti O se le yin lori, Allah si jẹ onimimọ ẹniti o ndupẹ fun ninu awọn ẹru Rẹ, yoo wa fi se kongẹ, O tun jẹ ọjọgbọn nitoripe O nfi gbogbo nkan si aaye ti o bamu.
وَإِن طَآئِفَتَانِ مِنَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ ٱقۡتَتَلُواْ فَأَصۡلِحُواْ بَيۡنَهُمَاۖ فَإِنۢ بَغَتۡ إِحۡدَىٰهُمَا عَلَى ٱلۡأُخۡرَىٰ فَقَٰتِلُواْ ٱلَّتِي تَبۡغِي حَتَّىٰ تَفِيٓءَ إِلَىٰٓ أَمۡرِ ٱللَّهِۚ فَإِن فَآءَتۡ فَأَصۡلِحُواْ بَيۡنَهُمَا بِٱلۡعَدۡلِ وَأَقۡسِطُوٓاْۖ إِنَّ ٱللَّهَ يُحِبُّ ٱلۡمُقۡسِطِينَ 9
Ti awọn ipin meji ninu awọn olugbagbọ ododo ba nba ra wọn ja, ki ẹ ya se atunse - ẹyin olugbagbọ ododo - laarin wọn pẹlu ki ẹ pe wọn lọsi bi idajọ ofin Allah nibi iyapa wọn, ti ọkan ninu wọn ba tako atunse, ti o wa kọja ẹnu aala, ẹ ba olukọja ẹnu aala naa ja titi ti yoo fi sẹri si ibi idajọ Allah, ti o ba sẹri si ibi idajọ Allah, ki ẹ ya se atunse laarin wọn pẹlu deedee ati dọgba, ẹ se deedee nibi idajọ yin laarin wọn, dajudaju Alah nifẹ si awọn onideedee nibi idajọ wọn.
إِنَّمَا ٱلۡمُؤۡمِنُونَ إِخۡوَةٞ فَأَصۡلِحُواْ بَيۡنَ أَخَوَيۡكُمۡۚ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ لَعَلَّكُمۡ تُرۡحَمُونَ 10
Dajudaju awọn olugbagbọ ododo jẹ ọmọ iya ninu ẹsin alaafia, ijẹ ọmọ iya ninu ẹsin alaafia si ni bukaata si ki ẹ se atunse - ẹyin olugbagbọ ododo - laarin awọn ọmọ iya yin ti wọn nse ifanfa, ki ẹ si paya Allah pẹlu mimu awọn asẹ Rẹ sẹ ati jijinna si awọn nkan ti o kọ; ni irankan ki wọn le kẹ yin.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا يَسۡخَرۡ قَوۡمٞ مِّن قَوۡمٍ عَسَىٰٓ أَن يَكُونُواْ خَيۡرٗا مِّنۡهُمۡ وَلَا نِسَآءٞ مِّن نِّسَآءٍ عَسَىٰٓ أَن يَكُنَّ خَيۡرٗا مِّنۡهُنَّۖ وَلَا تَلۡمِزُوٓاْ أَنفُسَكُمۡ وَلَا تَنَابَزُواْ بِٱلۡأَلۡقَٰبِۖ بِئۡسَ ٱلِٱسۡمُ ٱلۡفُسُوقُ بَعۡدَ ٱلۡإِيمَٰنِۚ وَمَن لَّمۡ يَتُبۡ فَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلظَّٰلِمُونَ 11
Mo pe ẹyin ti ẹ nigbagbọ ninu Allah, ti wọn si nse ohun ti wọn se lofin, ijọ kan ko gbọdọ fi ijọ miran se yẹyẹ ninu yin, o seese ki ẹniti wọn fi nse yẹyẹ jẹ ẹniti o loore lọdọ Allah, iwoye si jẹ ẹniti o ba wa ni ọdọ Allah, awọn obinrin kan naa ko si gbọdọ fi obinrin miran se yẹyẹ, o seese ki ẹniti wọn fi nse yẹyẹ ninu wọn loore ni ọdọ Allah, ẹ mase sọ aleebu awọn ọmọ iya yin nitoripe ipo ara yin gan gan ni wọn wa, apakan ko si gbọdọ maa bu apa miran pẹlu alajẹ ti o korira gẹgẹ bi o se jẹ isesi apakan awọn alaranse ẹsin siwaju ki ojisẹ Allah ti ikẹ ati ọla nbẹ fun too de, ẹniti o ba se ẹeleyi ninu yin jẹ poki, iroyin yii buru tii se iroyin poki lẹyin igbagbọ, ẹniti ko ba sẹri ninu awọn ẹsẹ yii, awọn yii ni labosi si ẹmin ara wọn nitori mimu wọ aaye iparun pẹlu idi ohun ti wọn se ninu awọn ẹsẹ.
Jijẹ dandan lilalaafia awọn iro paapaa julọ eyiti wọn ba mu ni ọdọ ẹniti a ba nfura poki si.
Jijẹ dandan isetunse laarin awọn ti wọn ba ara wọn ja ninu awọn olugbafa ati sise lofin biba apakan eyiti o taku lori isọta ja, ti o si kọ atunse.
Ninu ẹtọ ọmọ iya igbagbọ: ni atunse laarin oluja meji ati jijnna kuro nibi ohun ti o ba le tabuku ẹni gẹgẹ bi yẹyẹ sise tabi aleebu tabi imọ pe ni ni alajẹ ki alajẹ.