مَّا لَهُم بِهِۦ مِنۡ عِلۡمٖ وَلَا لِأٓبَآئِهِمۡۚ كَبُرَتۡ كَلِمَةٗ تَخۡرُجُ مِنۡ أَفۡوَٰهِهِمۡۚ إِن يَقُولُونَ إِلَّا كَذِبٗا 5
Ko si fun awọn ti wọn da adapa irọ imọ tabi ẹri lori ohun ti wọn npe apemọra rẹ nipa fifi ọmọ ti si ọdọ Allah, ko si si imọ kankan fun awọn baba wọn ti wọn nkọse wọn nibi eleyi, gbolohun eyiti o njade ni ẹnu wọn yii laise laakaye tobi ni buburu, wọn ko sọ nkankan ju ọrọ irọ lọ, ko si ipilẹ fun un, ko si si atilẹyin naa.
فَلَعَلَّكَ بَٰخِعٞ نَّفۡسَكَ عَلَىٰٓ ءَاثَٰرِهِمۡ إِن لَّمۡ يُؤۡمِنُواْ بِهَٰذَا ٱلۡحَدِيثِ أَسَفًا 6
O seesee ki iwọ - irẹ ojisẹ - ko iparun ba ẹmin rẹ niti ibanujẹ ati kikẹdun ti wọn ko ba nigbagbọ si Alukuraani yii, mase se bẹẹ, ko jẹ dandan fun ọ imọna wọn, eyiti o jẹ dandan fun ọ ni imudopin.
إِنَّا جَعَلۡنَا مَا عَلَى ٱلۡأَرۡضِ زِينَةٗ لَّهَا لِنَبۡلُوَهُمۡ أَيُّهُمۡ أَحۡسَنُ عَمَلٗا 7
Dajudaju Awa se ẹwa fun gbogbo ohun ti o nbẹ ni ori ilẹ ni ẹda, ki A le dan wọn wo ẹniti yoo se isẹ rere eyiti yoo yọ Ọlọhun Ọba ninu ninu wọn ati ẹniti isẹẹrẹ yoo buru ju, ki a le san ẹnikọọkan lẹsan ohun ti o tọ si i.
وَإِنَّا لَجَٰعِلُونَ مَا عَلَيۡهَا صَعِيدٗا جُرُزًا 8
Dajudaju Awa yoo sọ gbogbo ohun ti o nbẹ ni ori ilẹ ni ẹda di yerupẹ ti ko nii si irugbin kankan nibẹ eleyi jẹ lẹyin igbati ti titan ba de ba isẹmin ohun ti o wa lori rẹ ni ẹda, ki wọn yaa woye si eleyi.
أَمۡ حَسِبۡتَ أَنَّ أَصۡحَٰبَ ٱلۡكَهۡفِ وَٱلرَّقِيمِ كَانُواْ مِنۡ ءَايَٰتِنَا عَجَبًا 9
Mase lero wipe - irẹ ojisẹ - dajudaju itan awọn ara Kaafi ati ọpọn wọn eyiti wọn kọ awọn orukọ wọn si ninu awọn amin wa eyiti o jẹ eemọ bikosepe ohun ti o yatọ si i seni leemọ ju u lọ, gẹgẹ bi dida sanmọ ati ilẹ.
إِذۡ أَوَى ٱلۡفِتۡيَةُ إِلَى ٱلۡكَهۡفِ فَقَالُواْ رَبَّنَآ ءَاتِنَا مِن لَّدُنكَ رَحۡمَةٗ وَهَيِّئۡ لَنَا مِنۡ أَمۡرِنَا رَشَدٗا 10
Ranti - irẹ ojisẹ - nigbati awọn ọdọ olugbagbọ ododo lugọ niti sisa pẹlu ẹsin wọn ti wọn wa sọ ninu adua wọn fun Ọlọhun wọn: Ọlọhun wa, fun wa ni ikẹ lati ọdọ Rẹ pẹlu ki O fi ori awọn ẹsẹ wa jin wa, ki O si la wa kuro nibi awọn ọta wa, sise imọna fun wa lọsi oju ọna ododo ati deede nibi alamọri ise irin ajo kuro ni ọdọ awọn keferi ati igbagbọ.
فَضَرَبۡنَا عَلَىٰٓ ءَاذَانِهِمۡ فِي ٱلۡكَهۡفِ سِنِينَ عَدَدٗا 11
Lẹyin irin wọn ati lilugọ wọn si inu koto kaafu, a fi gaga si eti wọn lati maa gbọ awọn ohun, a si kun wọn loorun fun ọdun ti o pọ.
ثُمَّ بَعَثۡنَٰهُمۡ لِنَعۡلَمَ أَيُّ ٱلۡحِزۡبَيۡنِ أَحۡصَىٰ لِمَا لَبِثُوٓاْ أَمَدٗا 12
Bakanna lẹyin oorun wọn ti o gun, a ta wọn ji ki a le mọ - imọ ti o han - awọn ikọ meji ti wọn nfa nkan mọ ara wọn lọwọ nipa iye igbati wọn lo ninu koto kaafu, taani o nimọ ju nipa odiwọn asiko naa.
نَّحۡنُ نَقُصُّ عَلَيۡكَ نَبَأَهُم بِٱلۡحَقِّۚ إِنَّهُمۡ فِتۡيَةٌ ءَامَنُواْ بِرَبِّهِمۡ وَزِدۡنَٰهُمۡ هُدٗى 13
Awa ni a o fi han ọ - irẹ ojisẹ - iru wọn niti ododo ti ko si iyemeji pẹlu rẹ, dajudaju wọn jẹ ọdọ ti o nigbagbọ si Ọlọhun wọn, wọn si se isẹ titẹle E, a si lekun imọna ati irinlẹ wọn lori ododo.
وَرَبَطۡنَا عَلَىٰ قُلُوبِهِمۡ إِذۡ قَامُواْ فَقَالُواْ رَبُّنَا رَبُّ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ لَن نَّدۡعُوَاْ مِن دُونِهِۦٓ إِلَٰهٗاۖ لَّقَدۡ قُلۡنَآ إِذٗا شَطَطًا 14
A si fun ọkan wọn lagbara pẹlu igbagbọ ati ifẹsẹrinlẹ le lori ati suuru lori jijinna si awọn ilu nibẹ nigbati wọn naro ni ẹniti o nkede igbagbọ wọn si Ọba Allah nikan soso niwaju ọba keferi, wọn wa sọ fun wipe: Ọlọhun wa eyiti a nigbagbọ si, ti na si nsin In ni Ọba sanmọ ati ilẹ, a ko ni sin nkan miran yatọ si I gẹgẹ bi awọn ọlọhun ti wọn nlero rẹ niti irọ, paapaa a ti sọ - ti a ba sin nkan miran yatọ si I - gbolohun abosi ti o jinna si ododo.
هَٰٓؤُلَآءِ قَوۡمُنَا ٱتَّخَذُواْ مِن دُونِهِۦٓ ءَالِهَةٗۖ لَّوۡلَا يَأۡتُونَ عَلَيۡهِم بِسُلۡطَٰنِۢ بَيِّنٖۖ فَمَنۡ أَظۡلَمُ مِمَّنِ ٱفۡتَرَىٰ عَلَى ٱللَّهِ كَذِبٗا 15
Lẹyin eyi ni apakan wọn gboju wo apakan ni ẹniti o nsọ bayi wipe: awọn wọnyi ni ijọ wa ti wọn mu ẹniti o yatọ si Allah ni olujọsin ti wọn si nsin in, wọn ko si nikapa awijare ti o fi oju han lori ijọsin wọn, ko si ẹnikankan ti o se abosi to ẹniti o hun irọ mọ Allah nibi fifi ikẹgbẹ ti si lọdọ.
Imudopin ati igbiyanju dogongo di dandan fun olupepe si ọdọ Allah bi o ba se rọ ọ lọrun si pẹlu igbarale Allah nibi eleyi, ti wọn ba mọ ọna eleyi dara, ti ko ba si ri bẹẹ, ko gbọdọ banujẹ tabi kẹdun.
Nibi imọ odiwọn asiko ti awọn ara hiho kaafi lo jẹ ọna lati mọ isiro ati lati mọ pipe Ọlọhun Ọba Allah ti O ga, ati ọgbọn Rẹ ati ikẹ Rẹ.
Ẹri ti o fi oju han lori sisa pẹlu ẹsin ati jijinna si ara ile ẹni ati awọn ọmọ ati awọn alasunmọ ati awọn ọrẹ ati awọn ilu ati awọn dukia wa ninu awọn aayah naa: niti ipaya idaamun
Jijẹ dandan kiko itọju awọn ọdọ si aya; nitoripe awọn ni ọkan wọn mọ ju, awọn si ni ẹmin wọn mọ kanga, awọn si ni igbarata wọn pọ ju, ọdọ wọn si ni idagbasoke awọn ijọ duro le lori.