قَالَ يَٰبُنَيَّ لَا تَقۡصُصۡ رُءۡيَاكَ عَلَىٰٓ إِخۡوَتِكَ فَيَكِيدُواْ لَكَ كَيۡدًاۖ إِنَّ ٱلشَّيۡطَٰنَ لِلۡإِنسَٰنِ عَدُوّٞ مُّبِينٞ 5
Ya'quub sọ fun ọmọ rẹ Yuusuf: irẹ ọmọ mi, mase sọ ala rẹ fun awọn ọmọ iya rẹ ki wọn ma ba gbọ ye, ki wọn si ma ba se keeta rẹ, ti wọn yoo fi waa da ete niti keeta lati ọdọ rẹ si ọ, dajudaju esu jẹ ọta ti o fi oju han fun ọmọniyan.
وَكَذَٰلِكَ يَجۡتَبِيكَ رَبُّكَ وَيُعَلِّمُكَ مِن تَأۡوِيلِ ٱلۡأَحَادِيثِ وَيُتِمُّ نِعۡمَتَهُۥ عَلَيۡكَ وَعَلَىٰٓ ءَالِ يَعۡقُوبَ كَمَآ أَتَمَّهَا عَلَىٰٓ أَبَوَيۡكَ مِن قَبۡلُ إِبۡرَٰهِيمَ وَإِسۡحَٰقَۚ إِنَّ رَبَّكَ عَلِيمٌ حَكِيمٞ 6
Gẹgẹ bi mo se ri ala naa ni wipe wọn sa ọ lẹsa - irẹ yuusuf - Ọlọhun Ọba rẹ, o si fẹ fi alaye ala mọ ọ, ki o si tun pe idẹkun rẹ le ọ lori pẹlu siọ ọ di anọbi, gẹgẹ bi O se pe idẹkun rẹ lori awọn baba rẹ siwaju rẹ: Ibrahim ati Ishaq, dajudaju Ọlọhun Ọba rẹ jẹ onimimọ nipa ẹda Rẹ, ọjọgbọn nibi idari Rẹ.
۞لَّقَدۡ كَانَ فِي يُوسُفَ وَإِخۡوَتِهِۦٓ ءَايَٰتٞ لِّلسَّآئِلِينَ 7
Paapaa ariwoye ati isiti wa nibi iro Yuusuf ati iro awọn ọmọ iya rẹ fun awọn onibeere nipa iro wọn.
إِذۡ قَالُواْ لَيُوسُفُ وَأَخُوهُ أَحَبُّ إِلَىٰٓ أَبِينَا مِنَّا وَنَحۡنُ عُصۡبَةٌ إِنَّ أَبَانَا لَفِي ضَلَٰلٖ مُّبِينٍ 8
Nigbati awọn ọmọ baba rẹ nsọ ni aarin ara wọn: fun yuusuf ati ọmọ iya rẹ wipe: awọn mejeeji ni baba wa fẹran ju wa lọ, a si jẹ ijọ kanna pẹlu onka kanna, bawo ni o se wa gbe ọla fun awọn mejeeji le wa lori, dajudaju awa ri ninu asise ti o fi oju han nitoripe o gbe ọla fun awọn mejeeji laisi idi ti o han si wa.
ٱقۡتُلُواْ يُوسُفَ أَوِ ٱطۡرَحُوهُ أَرۡضٗا يَخۡلُ لَكُمۡ وَجۡهُ أَبِيكُمۡ وَتَكُونُواْ مِنۢ بَعۡدِهِۦ قَوۡمٗا صَٰلِحِينَ 9
Ẹ pa yuusuf tabi ki ẹ mu jinna kuro lori ilẹ; baba yin yoo gboju wo yin nikan, yoo si maa fẹran yin ni ifẹ ti o pe, ẹ o wa pada di ijọ ẹniire lẹyin igbati ẹ ba ti pa a tan tabi ẹ gbe e jinna nigbati ẹ ba ronu piwada kuro nibi ẹsẹ yin.
قَالَ قَآئِلٞ مِّنۡهُمۡ لَا تَقۡتُلُواْ يُوسُفَ وَأَلۡقُوهُ فِي غَيَٰبَتِ ٱلۡجُبِّ يَلۡتَقِطۡهُ بَعۡضُ ٱلسَّيَّارَةِ إِن كُنتُمۡ فَٰعِلِينَ 10
Ọkan ninu awọn ọmọ baba sọ wipe: ẹ mase pa yuusuf sugbọn ẹ ju sinu ọgbun kanga, apakan awọn onirin ajo yoo mu, awọn ti wọn ba re kọja nibẹ, eleyi fuyẹ ninu inira ju ki ẹ pa lọ, ti ẹ ba pinnu lori nkan ti ẹ sọ wipe ẹ fẹẹ se.
قَالُواْ يَٰٓأَبَانَا مَالَكَ لَا تَأۡمَ۬نَّا عَلَىٰ يُوسُفَ وَإِنَّا لَهُۥ لَنَٰصِحُونَ 11
Nigbati wọn panupọ lori mimu jinna tan, wọn wa sọ fun baba wọn yakub: irẹ baba wa, kilode ti iwọ ko se wa ni ẹni ifọkanbalẹ lori yuusuf? Bẹẹ ni awa o maa se aanu, a o si maa kiyesi nibi ohun ti o le ko inira ba a, a o si maa si i leti lori idaabobo itọju titi yoo fi sẹri pada si ọdọ rẹ ni alaafia, kinni ohun ti nkọ fun ọ lati mase ran an pẹlu wa na?
أَرۡسِلۡهُ مَعَنَا غَدٗا يَرۡتَعۡ وَيَلۡعَبۡ وَإِنَّا لَهُۥ لَحَٰفِظُونَ 12
Yọnda fun wa ki a mu pẹlu wa lọla, ki o maa gbadun ounjẹ lki ko si maa yọ, dajudaju awa yoo jẹ oludaabobo fun un nibi gbogbo suta ti o le su e.
قَالَ إِنِّي لَيَحۡزُنُنِيٓ أَن تَذۡهَبُواْ بِهِۦ وَأَخَافُ أَن يَأۡكُلَهُ ٱلذِّئۡبُ وَأَنتُمۡ عَنۡهُ غَٰفِلُونَ 13
Ya'quub sọ fun awọn ọmọ rẹ: yoo bami ninu jẹ ki o ba yin lọ; toripe emi ko nii le se suuru lori ipinya rẹ, mo si npaya le lori ki ikoko mase jẹ ẹ, bẹẹ ni ẹyin yoo ti gbagbe nigbati ẹ ba ndaran lọ, ti ẹ si nsere.
قَالُواْ لَئِنۡ أَكَلَهُ ٱلذِّئۡبُ وَنَحۡنُ عُصۡبَةٌ إِنَّآ إِذٗا لَّخَٰسِرُونَ 14
Wọn sọ fun baba wọn: titi ikoko ba jẹ yuusuf, ti a si sọ wipe nkankan naa jọ ni wa, o fi han wipe ko si oore lara wa, awa gan ti sofo nigbati a ko ba le kọ fun ikoko kuro lọdọ rẹ.
Ririnlẹ ala lila lati inu ofin ẹsin ati titọ sise alaye rẹ.
Sise lofin sise afipamọ apakan awọn nkan ti o jẹ ododo, ti o ba ja si wipe suta yoo jade lẹyin sise afihan rẹ.
Sise alaye ọla ti nbẹ fun arọmọdọmọ ara ile Ibrahim ati sisan wọn lẹsan lori awọn eniyan yoku nibi jijẹ anọbi.
Fifi si ọdọ ẹnikan ninu awọn ọmọ niti ifẹ ma njogun ọta ati keeta laarin awọn ọmọ iya naa.