قُلۡ جَآءَ ٱلۡحَقُّ وَمَا يُبۡدِئُ ٱلۡبَٰطِلُ وَمَا يُعِيدُ 49
Sọ - irẹ ojisẹ - fun ẹlẹbọ opurọ yii: ododo naa de eyiti se Islam, ibajẹ si yẹ eyiti ko si oripa kankan fun un tabi agbara, ko si le sẹri sibi mimu u sẹ.
قُلۡ إِن ضَلَلۡتُ فَإِنَّمَآ أَضِلُّ عَلَىٰ نَفۡسِيۖ وَإِنِ ٱهۡتَدَيۡتُ فَبِمَا يُوحِيٓ إِلَيَّ رَبِّيٓۚ إِنَّهُۥ سَمِيعٞ قَرِيبٞ 50
Sọ - irẹ ojisẹ - fun awọn ẹlẹbọ opurọ yii: ti mo ba sọnu kuro nibi ododo ni ohun ti mo nmu de etigbọ yin, inira isina mi yoo wa lori mi nikan, nkankan ko nii kan yin nibẹ, ti mo ba si mọ ọna lọsi ibẹ, o jẹ nitori okunfa imisi ti Ọlọhun Ọba mi ti mimọ nbẹ fun fi ransẹ si mi, dajudaju O jẹ olugbọ ọrọ awọn ẹru Rẹ, olusunmọni ti a ko le wi awijare le lori nibi gbigbọ ohun ti mo nsọ.
وَلَوۡ تَرَىٰٓ إِذۡ فَزِعُواْ فَلَا فَوۡتَ وَأُخِذُواْ مِن مَّكَانٖ قَرِيبٖ 51
Ti o ba ri - irẹ ojisẹ - nigbati awọn opurọ yii ba njaya, nigbati wọn ba fi oju gan ni iya naa ni ọjọ igbende, ko si ibusalọ funwọn kuro nibẹ, bẹẹni ko si ibulugọ si ti wọn yoo sa pamọ si, wọn yoo gba wọn mu ni aaye ti o sun mọ, ti o rọrun ki ọwọ to o ni igba akọkọ, ti o ba ri eleyi iwọ ko ba ri alamọri eemọ.
وَقَالُوٓاْ ءَامَنَّا بِهِۦ وَأَنَّىٰ لَهُمُ ٱلتَّنَاوُشُ مِن مَّكَانِۢ بَعِيدٖ 52
Wọn sọ nigbati wọn ri ibusẹri si wọn: a nigbagbọ ninu ọjọ ikẹyin, bawo ni ilọla igbagbọ se waa wa fun wọn ati nina wọ si i, paapaa aaye gbigba igbagbọ ti jinna si wọn nitori jijade wọn kuro ni ile aye eyiti o jẹ aaye isẹ ti ko si ẹsan nibẹ lọsi ile ọrun eyiti o jẹ ile ẹsan ti ko si isẹ nibẹ?!
وَقَدۡ كَفَرُواْ بِهِۦ مِن قَبۡلُۖ وَيَقۡذِفُونَ بِٱلۡغَيۡبِ مِن مَّكَانِۢ بَعِيدٖ 53
Bawo ni igbagbọ se fẹẹ wa lati ọdọ wọn, ti wọn yoo si tun gba, paapaa wọn ti se keferi si I ni isẹmin aye, wọn wa nti erongba siwaju ni abala ti o jina si sise deedee ododo, gẹgẹ bi ọrọ wọn ti wọn nsọ nipa ojisẹ - ti ikẹ ati ọla nbẹ fun - pe: opidan ni, alagbigba ni, akọrin ni?!
وَحِيلَ بَيۡنَهُمۡ وَبَيۡنَ مَا يَشۡتَهُونَ كَمَا فُعِلَ بِأَشۡيَاعِهِم مِّن قَبۡلُۚ إِنَّهُمۡ كَانُواْ فِي شَكّٖ مُّرِيبِۢ 54
Wọn kọ fun awọn opurọ yii ki ọwọ wọn tẹ ohun ti wọn nfẹ ninu adun aye ati ironu piwada kuro nibi keferi ati lila ninu ina ati sisẹri pada si isẹmin aye gẹgẹ bi wọn se se fun awọn ijọ opurọ ti o siwaju wọn, dajudaju wọn wa ninu iyemeji ti awọn ojisẹ mu wa ba wọn gẹgẹ bi imu Allah lọkan ati inigbagbọ si ajinde ni iyemeji ti o ma ngbeni de ibi keferi.
سورة (MAKIYYAH)
Alaye aini awọn ẹrusin pẹnbele si Ẹniti o pilẹ isẹda sanmọ ati ile, ati pipe ti o rọrọ kuro lọdọ wọn.
ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ فَاطِرِ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ جَاعِلِ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةِ رُسُلًا أُوْلِيٓ أَجۡنِحَةٖ مَّثۡنَىٰ وَثُلَٰثَ وَرُبَٰعَۚ يَزِيدُ فِي ٱلۡخَلۡقِ مَا يَشَآءُۚ إِنَّ ٱللَّهَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٞ 1
Ọpẹ ni fun Allah ti o da gbogbo sanmọ ati ilẹ lori apejuwe ti ko siwaju, ẹniti o se awọn ojisẹ si inu awọn malaika, wọn nmu awọn asẹ Rẹ ti o ti kadara sẹ, o si wa ninu wọn ti o nmu imisi de etigbọ awọn anọbi, O si nfun wọn ni agbara lori sise ohun ti o fi ọkan tan wọn le lori, o nbẹ ninu wọn oniyẹ meji ati onimẹta ati onimẹrin, o fi nfo ki o le mu ohun ti wọn pa lasẹ sẹ, Allah si ma nse alekun nibi ẹda Rẹ eyiti O ba fẹ gẹgẹ bi orike tabi didara tabi ohun, dajudaju Allah lagbara lori gbogbo nkan, nkankan ko le ko agara ba A.
مَّا يَفۡتَحِ ٱللَّهُ لِلنَّاسِ مِن رَّحۡمَةٖ فَلَا مُمۡسِكَ لَهَاۖ وَمَا يُمۡسِكۡ فَلَا مُرۡسِلَ لَهُۥ مِنۢ بَعۡدِهِۦۚ وَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ 2
Dajudaju awọn kọkọrọ gbogbo nkan wa ni ọwọ Allah; ohun ti Allah ba si ni arisiki fun awọn eniyan tabi imọna tabi oriire ẹnikankan ko lagbara lati kọ ọ fun Un, eyiti o ba si gba mu ninu rẹ, ẹnikankan ko lagbara lati tu silẹ lẹyin gbigbamu rẹ, Oun ni alagbara ti ẹnikankan ko le bori, ọjọgbọn nibi isẹda Rẹ ati ipebubu ati idari.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ ٱذۡكُرُواْ نِعۡمَتَ ٱللَّهِ عَلَيۡكُمۡۚ هَلۡ مِنۡ خَٰلِقٍ غَيۡرُ ٱللَّهِ يَرۡزُقُكُم مِّنَ ٱلسَّمَآءِ وَٱلۡأَرۡضِۚ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَۖ فَأَنَّىٰ تُؤۡفَكُونَ 3
Ẹyin eniyan, ẹ ranti idẹkun Allah ti O se le yin lori pẹlu ọkan yin ati ahọn yin ati sisisẹ pẹlu orikerike ara yin, njẹ adẹda miran nbẹ fun yin yatọ si Allah, ti yoo ran yin se lati sanmọ lati ibi ojo ti o nsọkalẹ le yin lori, ti O si ran yin se lati inu ilẹ pẹlu eso ati irugbin ti o njade nibẹ ati nkan ti o yatọ si? Ko si ẹni ijọsin niti ododo tọsi yatọ si I, bawo ni o se jẹ lẹyin eleyi ti ẹ tun nsẹri kuro nibi ododo yii, ti ẹ si nda adapa irọ mọ Allah, ti ẹ si nlero wipe awọn akẹgbẹ nbẹ fun Allah, Oun ni O si da yin, ti O ran yin se?!
Irisi ipaya awọn keferi ni ọjọ igbende jẹ irisi ti o tobi.
Aaye anfaani igbagbọ ni ile aye; nitoripe o jẹ ile isẹ.
Titobi isẹda awọn Malaika tọka si titobi ẹniti o da wọn ti mimọ nbẹ fun.