وَإِذۡ نَجَّيۡنَٰكُم مِّنۡ ءَالِ فِرۡعَوۡنَ يَسُومُونَكُمۡ سُوٓءَ ٱلۡعَذَابِ يُذَبِّحُونَ أَبۡنَآءَكُمۡ وَيَسۡتَحۡيُونَ نِسَآءَكُمۡۚ وَفِي ذَٰلِكُم بَلَآءٞ مِّن رَّبِّكُمۡ عَظِيمٞ 49
Ẹyin arọmọdọmọ Isirẹli, ẹ ranti igba ti A yọ yin kuro lọwọ awọn olutẹle Fir'aona, awọn ti wọn fun yin ni oniran iya jẹ, debi wipe wọn npa awọn ọmọ yin ni diduubu, ti ẹ ko fi nii ni olusẹku kankan, wọn si nfi awọn ọmọbinrin yin silẹ ni aaye, ki wọn o le maa ba se ẹru sin wọn, ni ẹni ti o mọọmọ lati yẹpẹrẹ yin ati lati dagunla si yin nibi lilayin kuro nibi ijiya Fir'aona ati awọn ọmọlẹyin rẹ, adanwo nla ni lati ọdọ Ọlọhun Ọba yin, ki ẹ le baa dupẹ.
وَإِذۡ فَرَقۡنَا بِكُمُ ٱلۡبَحۡرَ فَأَنجَيۡنَٰكُمۡ وَأَغۡرَقۡنَآ ءَالَ فِرۡعَوۡنَ وَأَنتُمۡ تَنظُرُونَ 50
Ẹ ranti awọn idẹkun Wa ti A se leyin lori pẹlu wipe A la odo si meji fun yin, A si se oju ọna gbígbẹ fun yin ninu rẹ, ti ẹ nrin nibẹ, A si waa la yin, A si tẹ ọta yin Fir'aona ri ati awọn ti wọn tẹle niwaju yin, ti ẹyin si nwo.
وَإِذۡ وَٰعَدۡنَا مُوسَىٰٓ أَرۡبَعِينَ لَيۡلَةٗ ثُمَّ ٱتَّخَذۡتُمُ ٱلۡعِجۡلَ مِنۢ بَعۡدِهِۦ وَأَنتُمۡ ظَٰلِمُونَ 51
Ẹ ranti ninu awọn idẹkun naa, adehun Wa pẹlu Muusa fun ogoji oru, ki isọkalẹ taoreeta le pe pẹlu imọlẹ ati itọsọna, lẹyin naa nkankan ko ti ọdọ yin wa ju wipe ẹ nsin ogedengbe maalu lọ ni asiko naa, alabosi ni yin pẹlu nkan ti ẹ se yii.
ثُمَّ عَفَوۡنَا عَنكُم مِّنۢ بَعۡدِ ذَٰلِكَ لَعَلَّكُمۡ تَشۡكُرُونَ 52
Lẹyin igba naa, A se amojukuro fun yin lẹyin tituuba yin, A ko gba yin mu, ki ẹ le dupẹ fun Ọlọhun Allah pẹlu pe ki ẹ le se ijọsin ti o dara fun Un ati ki ẹ si tẹle asẹ Rẹ.
وَإِذۡ ءَاتَيۡنَا مُوسَى ٱلۡكِتَٰبَ وَٱلۡفُرۡقَانَ لَعَلَّكُمۡ تَهۡتَدُونَ 53
Ẹ ranti ninu awọn idẹkun naa wipe A fun Muusa (ki ọla Ọlọhun maa ba) ni Taoreeta ni ohun ti nse opinya laarin irọ ati otitọ, ki o si le se adayanri laarin imọna ati ami, ki ẹ le mọna lati ara rẹ lọ si ibi ododo.
وَإِذۡ قَالَ مُوسَىٰ لِقَوۡمِهِۦ يَٰقَوۡمِ إِنَّكُمۡ ظَلَمۡتُمۡ أَنفُسَكُم بِٱتِّخَاذِكُمُ ٱلۡعِجۡلَ فَتُوبُوٓاْ إِلَىٰ بَارِئِكُمۡ فَٱقۡتُلُوٓاْ أَنفُسَكُمۡ ذَٰلِكُمۡ خَيۡرٞ لَّكُمۡ عِندَ بَارِئِكُمۡ فَتَابَ عَلَيۡكُمۡۚ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلتَّوَّابُ ٱلرَّحِيمُ 54
Ẹ tun ranti ninu awọn idẹkun naa wipe Allah fi yin se kongẹ tituuba kuro nibi jijọsin fun ogedengbe rakunmi, nigbati Anọbi Muusa (ki ọla Ọlọhun maa ba) ti nsọ fun yin wipe: dajudaju ẹ ti se abosi ẹmi ara yin pẹlu wipe ẹ mu ogedengbe rakunmi ni Ọlọhun, Ẹ nsin ni Ọlọhun ti ẹ njọsin fun, ẹ yara tuuba, ki ẹ si sẹri lọ si ọdọ Ọlọhun Ọba ti O da yin, ti O si nmu yin bẹ, ohun ni wipe ki apakan maa pa apaakan, tituuba lori isesi bayi ni o loore fun yin ju ki ẹ maa tẹsiwaju ninu keferi lọ, eyi ti o le mu yin se gbere ninu ina, ẹ si bẹrẹ si nii se pẹlu kongẹ lati ọdọ Ọlọhun Allah ati iranlọwọ, O si gba iforijin toripe O jẹ ọpọlọpọ alaforijin ati olukẹ ẹru Rẹ.
وَإِذۡ قُلۡتُمۡ يَٰمُوسَىٰ لَن نُّؤۡمِنَ لَكَ حَتَّىٰ نَرَى ٱللَّهَ جَهۡرَةٗ فَأَخَذَتۡكُمُ ٱلصَّٰعِقَةُ وَأَنتُمۡ تَنظُرُونَ 55
Ẹ ranti ni igbati awọn baba yin ndoju ọrọ kọ Muusa pẹlu akin, a ko nii gba ọ gbọ titi ti a o fi ri Ọlọhun Allah ni rimi nri ọ, ti nkankan ko nii bo wa loju, ina tii joni si gba yin mu, apakan yin si nwo apakan.
ثُمَّ بَعَثۡنَٰكُم مِّنۢ بَعۡدِ مَوۡتِكُمۡ لَعَلَّكُمۡ تَشۡكُرُونَ 56
Lẹyin igba ti A ta yin ji lẹyin iku yin, ki ẹ le baa dupẹ fun Ọlọhun Allah lori idẹkun Rẹ yii ti O se leyin lori.
وَظَلَّلۡنَا عَلَيۡكُمُ ٱلۡغَمَامَ وَأَنزَلۡنَا عَلَيۡكُمُ ٱلۡمَنَّ وَٱلسَّلۡوَىٰۖ كُلُواْ مِن طَيِّبَٰتِ مَا رَزَقۡنَٰكُمۡۚ وَمَا ظَلَمُونَا وَلَٰكِن كَانُوٓاْ أَنفُسَهُمۡ يَظۡلِمُونَ 57
Ninu awọn idẹkun Wa leyin lori, ohun ni wipe A ran ẹsujo ti o sẹji bo yin kuro nibi igbona ooru nigbati o daa mu lori ile, A si sọkalẹ fun yin ninu idẹkun Wa nkan mimu ti o dun gẹgẹ bi oyin, ati ẹyẹ kekere ti baasi ẹran rẹ dun ti o jẹ ẹyẹ okudu, A waa sọ fun yin pe, ẹ maa jẹ ninu ohun ti o mọ, ti A se fun yin, ko din nkankan ku lara Wa pẹlu jija idẹkun naa ni iyàn ati sise aimoore sii sugbọn wọn se abosi si ẹmi ara wọn pẹlu dindin ipin rẹ ku ninu ẹsan sisẹri rẹ si iya.
Titobi ati pipọ idẹkun Ọlọhun Allah lori awọn arọmọdọmọ Isirẹli sibẹ naa, ko le nkankan kun fun wọn lọ ju igberaga ati isori kunkun.
Gbigbaaye atẹmọra Ọlọhun Allah ati ikẹ Rẹ lori awọn ẹru Rẹ koda bi awọn ẹsẹ wọn tobi.
Imisi jẹ opinya laarin ododo ati ibajẹ.