وَمَا نُرِيهِم مِّنۡ ءَايَةٍ إِلَّا هِيَ أَكۡبَرُ مِنۡ أُخۡتِهَاۖ وَأَخَذۡنَٰهُم بِٱلۡعَذَابِ لَعَلَّهُمۡ يَرۡجِعُونَ 48
A ko fi han fir'aona ati awọn ẹni iyi ninu ijọ rẹ awijare lori lilalaafia ohun ti Musa ẹniti ọla nbẹ fun mu wa ayaafi wipe o jẹ awijare ti o tobi ju ohun ti siwaju rẹ lọ, a si fi iya gba wọn mu ni aye; ni irankan ki wọn le sẹri kuro nibi keferi ti wọn wa sugbọn ko se anfaani.
وَقَالُواْ يَٰٓأَيُّهَ ٱلسَّاحِرُ ٱدۡعُ لَنَا رَبَّكَ بِمَا عَهِدَ عِندَكَ إِنَّنَا لَمُهۡتَدُونَ 49
Wọn wa sọrọ nigbati apakan iya kan wọn fun Musa ẹniti ọla nbẹ fun: irẹ pidanpidan, pe Ọlọhun Ọba rẹ fun wa lori ohun ti o sọ fun ọ nipa mimu iya kuro fun wa ti a ba gbagbọ, awa yoo mọna lọsi ọdọ Rẹ ti O ba mu kuro fun wa.
فَلَمَّا كَشَفۡنَا عَنۡهُمُ ٱلۡعَذَابَ إِذَا هُمۡ يَنكُثُونَ 50
Nigbati a mu iya kuro fun wọn, lẹyin naa ni wọn ja adehun wọn, wọn ko si mu u sẹ.
وَنَادَىٰ فِرۡعَوۡنُ فِي قَوۡمِهِۦ قَالَ يَٰقَوۡمِ أَلَيۡسَ لِي مُلۡكُ مِصۡرَ وَهَٰذِهِ ٱلۡأَنۡهَٰرُ تَجۡرِي مِن تَحۡتِيٓۚ أَفَلَا تُبۡصِرُونَ 51
Fir'aona pepe ninu ijọ rẹ lati fi ọna rẹ se iyanran ni ẹniti o sọpe: ẹyin ijọ mi, se kii se emi ni mo ni ọla misirọ ni, awọn odo yii si nsan ni abẹ orule mi? Se ẹ ko ri ọla mi tabi ẹ ko mọ titobi mi ni?!
أَمۡ أَنَا۠ خَيۡرٞ مِّنۡ هَٰذَا ٱلَّذِي هُوَ مَهِينٞ وَلَا يَكَادُ يُبِينُ 52
Emi loore ju Musa ẹniti a le, ọlẹ eyiti ko le sọrọ daadaa lọ.
فَلَوۡلَآ أُلۡقِيَ عَلَيۡهِ أَسۡوِرَةٞ مِّن ذَهَبٍ أَوۡ جَآءَ مَعَهُ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ مُقۡتَرِنِينَ 53
Se Allah ko le ju ẹgba ọrun wura si ẹniti o ni ran nisẹ ni; ki o le se adayanri wipe ojisẹ Rẹ ni tabi ki awọn Malaika wa pẹlu rẹ ti apakan yoo maa tẹle apakan.
فَٱسۡتَخَفَّ قَوۡمَهُۥ فَأَطَاعُوهُۚ إِنَّهُمۡ كَانُواْ قَوۡمٗا فَٰسِقِينَ 54
Fir'aona mu itanjẹ ba awọn ijọ rẹ, wọn si tẹle nibi anu rẹ, dajudaju wọn jẹ ijọ ti o jade kuro nibi itẹle ti Allah.
فَلَمَّآ ءَاسَفُونَا ٱنتَقَمۡنَا مِنۡهُمۡ فَأَغۡرَقۡنَٰهُمۡ أَجۡمَعِينَ 55
Nigbati wọn mu inu bi wa nitori itẹsiwaju wọn lori keferi, a gbẹsan lara wọn, a si tẹ gbogbo wọn ri.
فَجَعَلۡنَٰهُمۡ سَلَفٗا وَمَثَلٗا لِّلۡأٓخِرِينَ 56
A si se fir'aona ati ijọ rẹ ni ẹni iwaju ti wọn yoo maa gbawaju fun awọn eniyan, ti awọn keferi ijọ tirẹ yoo si maa tọ oripa naa, a si se wọn ni ariwoye fun ẹniti o ba fẹ woye, ki o ma ba se iru isẹ wọn, ki ohun ti o kan an ma ba kan wọn.
۞وَلَمَّا ضُرِبَ ٱبۡنُ مَرۡيَمَ مَثَلًا إِذَا قَوۡمُكَ مِنۡهُ يَصِدُّونَ 57
Nigbati awọn ẹlẹbọ lero wipe Isa eyiti awọn Nasaara nsin wa ninu apapọ gbolohun Allah ti O ga: (إِنَّكُمۡ وَمَا تَعۡبُدُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ حَصَبُ جَهَنَّمَ أَنتُمۡ لَهَا وَٰرِدُونَ ﱡ) (dajudaju ẹyin ati ohun ti ẹ nsin yatọ si Allah jẹ itẹdi jahannamọ ti ẹyin naa yoo si mu ori wọ ibẹ: 98), paapaa Allah ti kọ lati jọsin fun un gẹgẹ bi O se kọ lati jọsin fun awọn oosa, nigbati awọn ijọ rẹ - irẹ ojisẹ - npariwo igbarata, ti wọn si nda wahala silẹ nibi ija ni ẹniti o nsọ wipe: a yọnu si ki awọn ọlọhun wa ni ipo Isa, Allah wa sọ aayah kalẹ ni ifesi fun wọn: (إِنَّ ٱلَّذِينَ سَبَقَتۡ لَهُم مِّنَّا ٱلۡحُسۡنَىٰٓ أُوْلَٰٓئِكَ عَنۡهَا مُبۡعَدُونَ) (dajudaju awọn ti daadaa ti gbawaju fun ni ọdọ wa, wọn yoo jẹ ẹni ijinna si I: 101).
وَقَالُوٓاْ ءَأَٰلِهَتُنَا خَيۡرٌ أَمۡ هُوَۚ مَا ضَرَبُوهُ لَكَ إِلَّا جَدَلَۢاۚ بَلۡ هُمۡ قَوۡمٌ خَصِمُونَ 58
Wọn sọ wipe: se awọn ti a njọsin fun ni o loore tabi Isa?! Ohun ti ọmọ sibaarọ fi lelẹ fun ọ ati apejuwe rẹ yii jẹ apejuwe ifẹ lati de ibi ododo sugbọn ifẹ iyan ni, wọn jẹ ijọ kan ti a da ija mọ.
إِنۡ هُوَ إِلَّا عَبۡدٌ أَنۡعَمۡنَا عَلَيۡهِ وَجَعَلۡنَٰهُ مَثَلٗا لِّبَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ 59
Isa ọmọ Maryam ko jẹ nkankan ayaafi ẹru kan ninu awọn ẹru Allah, a fi ijẹ anọbi ati isẹ riran se idẹkun fun un, a si se ni apejuwe fun awọn ọmọ isirẹli, ti wọn yoo maa fi se itọka lori agbara Allah nitori isẹda rẹ laisi baba, gẹgẹ bi o se da Adamọ laisi obi mejeeji.
وَلَوۡ نَشَآءُ لَجَعَلۡنَا مِنكُم مَّلَٰٓئِكَةٗ فِي ٱلۡأَرۡضِ يَخۡلُفُونَ 60
Ti A ba fẹ lati pa yin run - ẹyin ọmọ Adamọ - a ko ba pa yin run, a o wa fi awọn Malaaika paarọ yin, ti wọn role yinn ni orilẹ, wọn yoo ma sin Allah, ti wọn ko nii mu nkankan pẹlu Rẹ.
Jija adehun wa ninu iroyin awọn keferi.
Poki jẹ ẹniti laakaye rẹ fuyẹ ti ẹniti o ba gbero lati mu ni fifuyẹ yoo se maa mu.
Ibinu Allah ma nsọ ofo di dandan.
Awọn ẹni anu ma nsare lọ si ibi pipa awọn amin ọrọ Alukuraani rẹ si ibamun ifẹ inu wọn.