وَبَدَا لَهُمۡ سَئَِّاتُ مَا كَسَبُواْ وَحَاقَ بِهِم مَّا كَانُواْ بِهِۦ يَسۡتَهۡزِءُونَ 48
Aburu ohun ti o kojọ ni ẹbọ ati awọn ẹsẹ yoo si han si wọn, iya ti o jẹpe ti wọn ba fi dẹru ba wọn ni ile aye, wọn yoo fi se yẹyẹ, yoo si rọkirika wọn.
فَإِذَا مَسَّ ٱلۡإِنسَٰنَ ضُرّٞ دَعَانَا ثُمَّ إِذَا خَوَّلۡنَٰهُ نِعۡمَةٗ مِّنَّا قَالَ إِنَّمَآ أُوتِيتُهُۥ عَلَىٰ عِلۡمِۢۚ بَلۡ هِيَ فِتۡنَةٞ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَهُمۡ لَا يَعۡلَمُونَ 49
Ti aarẹ ba se ọmọniyan ti o jẹ keferi tabi osi tabi ohun ti o jẹ iru rẹ, yoo pe wa ki a le mu ohun ti o kan kuro fun un, lẹyin naa ti a ba fun ni idẹkun kan gẹgẹ bi alaafia tabi dukia keferi yoo sọpe: dajudaju Allah fun mi ni eleyi nitori imọ Rẹ wipe mo lẹtọ si i, eyiti o jẹ ododo si ni pe wọn fi dan an wo ati ẹkẹẹdẹ, sugbọn ọpọ awọn keferi ko mọ eleyi, wọn yoo wa gba itanjẹ pẹlu ohun ti Allah se idẹkun rẹ fun wọn.
قَدۡ قَالَهَا ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡ فَمَآ أَغۡنَىٰ عَنۡهُم مَّا كَانُواْ يَكۡسِبُونَ 50
Awọn keferi ti o siwaju wọn ti sọ gbolohun yii, dukia wọn ati ipo wọn ko rọ wọn lọrọ ti wọn ko jọ ko rọ wọn lọrọ kankan.
فَأَصَابَهُمۡ سَئَِّاتُ مَا كَسَبُواْۚ وَٱلَّذِينَ ظَلَمُواْ مِنۡ هَٰٓؤُلَآءِ سَيُصِيبُهُمۡ سَئَِّاتُ مَا كَسَبُواْ وَمَا هُم بِمُعۡجِزِينَ 51
Ẹsan aburu wọn ti wọn ko jọ ni ẹbọ ati awọn ẹsẹ waa kan wọn, awọn ti o se abosi ẹmin ara wọn nibi sise ẹbọ ati awọn ẹsẹ ninu awọn ti o peju yii, ẹsan aburu wọn ti wọn kojọ gẹgẹ bi awọn ti o re kọja yoo kan wọn, wọn ko le bọ mọ Allah lọwọ, bẹẹni wọn ko le bori Rẹ.
أَوَ لَمۡ يَعۡلَمُوٓاْ أَنَّ ٱللَّهَ يَبۡسُطُ ٱلرِّزۡقَ لِمَن يَشَآءُ وَيَقۡدِرُۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّقَوۡمٖ يُؤۡمِنُونَ 52
Se awọn ẹlẹbọ yii sọ iru ohun ti wọn sọ, ti wọn ko si mọ wipe dajudaju Allah gbaaye arisiki fun ẹniti O ba fẹ dan wo: boya yoo dupẹ tabi yoo se keferi?! Yoo si fun mọ ẹniti O ba fẹ ni idanwo fun un: se yoo se suuru tabi yoo binu si akọsilẹ Allah?! Dajudaju nibi eleyi ti a sọ yii nipa gbigbaaye arisiki tabi fifun un mọ jẹ awọn ẹri lori eto Allah fun awọn ijọ ti wọn nigbagbọ; nitoripe dajudaju awọn ni wọn yoo se anfaani pẹlu awọn itọka, sugbọn awọn keferi nrekọja nibẹ, wọn si ngunri kuro nibẹ.
۞قُلۡ يَٰعِبَادِيَ ٱلَّذِينَ أَسۡرَفُواْ عَلَىٰٓ أَنفُسِهِمۡ لَا تَقۡنَطُواْ مِن رَّحۡمَةِ ٱللَّهِۚ إِنَّ ٱللَّهَ يَغۡفِرُ ٱلذُّنُوبَ جَمِيعًاۚ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلۡغَفُورُ ٱلرَّحِيمُ 53
Sọ - irẹ ojisẹ - fun awọn ẹru mi ti wọn kọja ẹnu aala lori ara wọn pẹlu sise ẹbọ si Allah ati dida awọn ẹsẹ: ẹ mase ja kan kuro nibi ikẹ Allah ati riri aforijin fun ẹsẹ yin dajudaju Allah ma nfi ori gbogbo ẹsẹ jin ẹniti o ba sẹri lọsi ọdọ Rẹ, dajudaju Oun ni oluforijin ẹsẹ awọn oluronu piwada, Onikẹ si wọn.
وَأَنِيبُوٓاْ إِلَىٰ رَبِّكُمۡ وَأَسۡلِمُواْ لَهُۥ مِن قَبۡلِ أَن يَأۡتِيَكُمُ ٱلۡعَذَابُ ثُمَّ لَا تُنصَرُونَ 54
Ẹ sẹri pada si ọdọ Ọlọhun yin pẹlu ironu piwada ati awọn isẹ rere, ki ẹ si tẹriba fun Un siwaju ki iya naa to waa ba yin ni ọjọ igbende, lẹyin naa ẹ ko nii ri ẹniti yoo ran yin se lati la yin kuro nibi iya naa ninu awọn oosa yin ati awọn ara ile yin.
وَٱتَّبِعُوٓاْ أَحۡسَنَ مَآ أُنزِلَ إِلَيۡكُم مِّن رَّبِّكُم مِّن قَبۡلِ أَن يَأۡتِيَكُمُ ٱلۡعَذَابُ بَغۡتَةٗ وَأَنتُمۡ لَا تَشۡعُرُونَ 55
Ẹ tẹle Alukuraani eyiti o dara ju ninu ohun ti Ọlọhun Ọba sọkalẹ fun ojisẹ Rẹ, ẹ se awọn asẹ Rẹ, bẹẹni ki ẹ jinna si awọn nkan ti O kọ siwaju ki iya naa to waa ba yin ni ojiji ti ẹ ko nii fura mọ ọ debi wipe ẹ o mura silẹ fun ironu piwada.
أَن تَقُولَ نَفۡسٞ يَٰحَسۡرَتَىٰ عَلَىٰ مَا فَرَّطتُ فِي جَنۢبِ ٱللَّهِ وَإِن كُنتُ لَمِنَ ٱلسَّٰخِرِينَ 56
Ẹ se eleyi lati sọra ki ẹmin kan ma baa sọ ni ọjọ igbende nipa abamọ ti o le: abamọ mi o lori aseeto si abala ti Allah nipa keferi ati awọn ẹsẹ ti o wa lori rẹ ati lori wipe o jẹ ẹniti o nfi awọn ẹni igbagbọ olutẹle se yẹyẹ.
idẹkun ti o nbẹ lori keferi jẹ idẹnilẹkẹ.
Gbigbaaye ikẹ Allah fun ẹda Rẹ.
Abamọ ti o le se anfaani ohun ni eyiti o wa ni ile aye, ti ironu piwada ti o mọ kanga si tẹle e.