۞إِلَيۡهِ يُرَدُّ عِلۡمُ ٱلسَّاعَةِۚ وَمَا تَخۡرُجُ مِن ثَمَرَٰتٖ مِّنۡ أَكۡمَامِهَا وَمَا تَحۡمِلُ مِنۡ أُنثَىٰ وَلَا تَضَعُ إِلَّا بِعِلۡمِهِۦۚ وَيَوۡمَ يُنَادِيهِمۡ أَيۡنَ شُرَكَآءِي قَالُوٓاْ ءَاذَنَّٰكَ مَامِنَّا مِن شَهِيدٖ 47
Ọdọ Allah nikan ni imọ asiko ikẹyin nsẹri si; Oun nikan ni O mọ igba ti yoo sẹlẹ, ẹlomiran yatọ si I ko mọ eleyi, eso kankan ko nii jade ninu apo rẹ eyiti a daabobo si, bẹẹni abo kan ko nii loyun tabi bimọ ayaafi pẹlu imọ Rẹ, nkankan ko le bọ mọ lọwọ ninu eleyi ati wipe ni ọjọ ti Allah yoo pe awọn ẹlẹbọ ti wọn nsin oosa pẹlu Rẹ; niti eebu fun wọn lori ijọsin wọn: niboni awọn akẹgbẹ Mi eyiti e lero wipe wọn jẹ akẹgbẹ wa? Awọn ẹlẹbọ yoo sọpe: a jẹwọ niwaju Rẹ, ko si ẹnikankan nisinsin yii wipe akẹgbẹ wa fun Ọ.
وَضَلَّ عَنۡهُم مَّا كَانُواْ يَدۡعُونَ مِن قَبۡلُۖ وَظَنُّواْ مَا لَهُم مِّن مَّحِيصٖ 48
Awọn oosa ti wọn npe yoo wa fi ara pamọ fun wọn, wọn yoo si mọ amọdaju wipe ko si ibusalọ fun awọn kuro nibi iya Allah tabi ibufarapamọ si.
لَّا يَسَۡٔمُ ٱلۡإِنسَٰنُ مِن دُعَآءِ ٱلۡخَيۡرِ وَإِن مَّسَّهُ ٱلشَّرُّ فَئَُوسٞ قَنُوطٞ 49
Ọmọniyan ko le ko susu lati maa beere fun alaafia ati dukia ati ọmọ ati idẹkun ti o yatọ si eleyi, ti o si ba mu tabi aarẹ tabi ohun ti o jọ ọ, yoo pọ ni ijakan ati imọkan kuro nibi ikẹ Allah.
وَلَئِنۡ أَذَقۡنَٰهُ رَحۡمَةٗ مِّنَّا مِنۢ بَعۡدِ ضَرَّآءَ مَسَّتۡهُ لَيَقُولَنَّ هَٰذَا لِي وَمَآ أَظُنُّ ٱلسَّاعَةَ قَآئِمَةٗ وَلَئِن رُّجِعۡتُ إِلَىٰ رَبِّيٓ إِنَّ لِي عِندَهُۥ لَلۡحُسۡنَىٰۚ فَلَنُنَبِّئَنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ بِمَا عَمِلُواْ وَلَنُذِيقَنَّهُم مِّنۡ عَذَابٍ غَلِيظٖ 50
Sugbọn ti a ba fi alaafia ati ọrọ ati idaraya tọ ọ lẹnu wo lẹyin adanwo ati aarẹ ti o kan, paapaa julọ yoo sọ wipe: eleyi jẹ temi; nitoripe mo jẹ ẹni Rẹ, mo si lẹtọ si i, emo ki lero wipe asiko ikẹyin yoo de, ti a ba ka asiko ikẹyin kun ohun ti o de, dajudaju ọrọ ati dukia nbẹ fun mi ni ọdọ Allah gẹgẹ bi O se rọ mi lọrọ ni ile aye nitori lilẹtọ si i mi, yoo se idẹkun fun mi ni ọrun naa, paapaa a o fun awọn ti wọn se keferi si Allah ni iro ohun ti wọn se ninu keferi ati awọn ẹsẹ, bẹẹni paapaa julọ a o fi iya ti o ga ju ni lile tọ wọn lẹnu wo.
وَإِذَآ أَنۡعَمۡنَا عَلَى ٱلۡإِنسَٰنِ أَعۡرَضَ وَنََٔابِجَانِبِهِۦ وَإِذَا مَسَّهُ ٱلشَّرُّ فَذُو دُعَآءٍ عَرِيضٖ 51
Ti a ba se idẹkun fun ọmọniyan pẹlu idẹkun alaafia ati iyara gaga tabi ohun ti o jọ iru rẹ, yoo fọnu kuro nibi iranti Allah ati itẹle e, yoo si gunri kuro ni ọdọ Rẹ niti isegberaga, ti aarẹ ati osi ba kan tabi ohun ti o jọ iru rẹ, yoo wa jẹ aladura ti o pọ si ọdọ Allah, yoo maa pariwo lọsi ọdọ Rẹ nipa ohun ti o kan ki o le mu kuro, ko ni dupẹ fun Ọlọhun rẹ nigbati O ba se idẹkun fun un, bẹẹni ko nii se suuru lori adanwo rẹ nigbati O ba dan wo.
قُلۡ أَرَءَيۡتُمۡ إِن كَانَ مِنۡ عِندِ ٱللَّهِ ثُمَّ كَفَرۡتُم بِهِۦ مَنۡ أَضَلُّ مِمَّنۡ هُوَ فِي شِقَاقِۢ بَعِيدٖ 52
Sọ - irẹ ojisẹ - fun ẹlẹbọ opurọ yii: ẹ fun mi niro ti Alukuraani yii ba jẹ lati ọdọ Allah, lẹyin naa ti ẹ wa se keferi si i, ti ẹ si pe e nirọ, bawo ni isesi yin yoo se ri?! Taani o sọnu to ẹniti o wa ninu orikunkun si ododo pẹlu hihande rẹ ati yiyanju awijare rẹ ati agbara rẹ?!
سَنُرِيهِمۡ ءَايَٰتِنَا فِي ٱلۡأٓفَاقِ وَفِيٓ أَنفُسِهِمۡ حَتَّىٰ يَتَبَيَّنَ لَهُمۡ أَنَّهُ ٱلۡحَقُّۗ أَوَ لَمۡ يَكۡفِ بِرَبِّكَ أَنَّهُۥ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ شَهِيدٌ 53
A o pada fi awọn amin wa han awọn keferi kuraesi ni oferefe ilẹ ninu awọn ohun ti Allah si fun awọn olujupa jusẹ silẹ, a o si tun fi awọn amin Wa han wọn ni ara wọn pẹlu sisi inu Mẹkkah; ti yoo fi han si wọn ninu ohun ti yoo mu iyemeji kuro fun wipe Alukuraani yii jẹ ododo eyiti ko si iyemeji nibẹ, se ko wa to fun awọn ẹlẹbọ yii wipe Alukuraani jẹ ododo lati ara ijẹri Allah wipe dajudaju ọdọ Oun ni o ti wa?! Taani ẹri le to ti Allah bi?! Ti wọn ba gbero ododo wọn ko ba gba tito pẹlu ẹri Ọlọhun wọn.
أَلَآ إِنَّهُمۡ فِي مِرۡيَةٖ مِّن لِّقَآءِ رَبِّهِمۡۗ أَلَآ إِنَّهُۥ بِكُلِّ شَيۡءٖ مُّحِيطُۢ 54
Ẹ tẹti gbọ dajudaju awọn ẹlẹbọ wa ninu iyemeji nipa pipade Ọlọhun wọn ni ọjọ igbende nitori atako wọn si ajinde, wọn ko nigbagbọ ninu ọrun; tori eleyi ni wọn ko fi mura silẹ fun un lati ibi isẹ rere, ẹ tẹti gbọ dajudaju Allah jẹ ẹniti imọ Rẹ ati agbara Rẹ rọkirika gbogbo nkan.
Imọ ọjọ ikẹyin wa ni ọdọ Allah nikan soso.
Ibasepọ kekeri pẹlu idẹkun Allah ati iya Rẹ jẹ ohun ti itẹsẹbọsẹ ati idaru dapọ wa nibẹ.
Rirọkirika imọ ati agbara Allah si gbogbo nkan.