وَيَسۡتَعۡجِلُونَكَ بِٱلۡعَذَابِ وَلَن يُخۡلِفَ ٱللَّهُ وَعۡدَهُۥۚ وَإِنَّ يَوۡمًا عِندَ رَبِّكَ كَأَلۡفِ سَنَةٖ مِّمَّا تَعُدُّونَ 47
Awọn keferi ninu ijọ rẹ yoo maa kan ọ loju iya kiakia - ire ojise - ni ile aye ati iya ti yoo pada sẹlẹ ni ọrun nigbati wọn se ikilọ pẹlu mejeeji, bẹẹ ni Allah ko nii yapa adehun rẹ ti O se fun wọn ninu ohun ti wọn si nkanju rẹ ohun ti o sẹlẹ si wọn ni ọjọ badiri, dajudaju ọjọ kan ninu iya lọrun da gẹgẹ bi ẹgbẹrun ọdun ninu eyiti ẹ nka ninu awọn ọdun ile aye nitori okunfa iya ti o wa nibẹ.
وَكَأَيِّن مِّن قَرۡيَةٍ أَمۡلَيۡتُ لَهَا وَهِيَ ظَالِمَةٞ ثُمَّ أَخَذۡتُهَا وَإِلَيَّ ٱلۡمَصِيرُ 48
Bawo ni awọn abule eyiti a lọra iya ti o si jẹ ẹniti o se abosi lati ibi keferi rẹ se pọ to, bẹẹ ni wọn ko kan an loju rẹ niti didẹ lẹkẹ, lẹyin naa mo wa gba a mu pẹlu iya ti o tan yanyan, ọdọ Mi nikan ni ibusẹri si wọn ni ọjọ igbende, wọn yoo si san wọn lẹsan lori keferi wọn pẹlu iya lailai.
قُلۡ يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ إِنَّمَآ أَنَا۠ لَكُمۡ نَذِيرٞ مُّبِينٞ 49
Sọpe mope ẹyin eniyan dajudaju emi jẹ olukilọ fun yin, mo nfi ounti wọn ran mi de etigbọ yin, ti o si han nibi ikilọ mi.
فَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ لَهُم مَّغۡفِرَةٞ وَرِزۡقٞ كَرِيمٞ 50
Awọn ti wọn nigbagbọ si Allah, ti wọn si nsisẹẹre, aforijin nibi ẹsẹ wọn nbẹ fun wọn lọdọ Ọlọhun Ọba wọn, bẹẹ ni arisiki alapọnle ninu ọgba idẹra ti ko nii ja lailai.
وَٱلَّذِينَ سَعَوۡاْ فِيٓ ءَايَٰتِنَا مُعَٰجِزِينَ أُوْلَٰٓئِكَ أَصۡحَٰبُ ٱلۡجَحِيمِ 51
Awọn ti wọn se igbiyanju nibi pipe awọn amin wa nirọ ni ẹniti o nseto lati ko agara ba Allah ati wipe awọn yoo bọ mọ Ọ lọwọ, ti ko si nii fi iya jẹ wọn, awọn wọnyi jẹ ẹn ina jahiimu, yoo si ba wọn rẹ gẹgẹ bi ọrẹ se ma nba ọrẹ rẹ.
وَمَآ أَرۡسَلۡنَا مِن قَبۡلِكَ مِن رَّسُولٖ وَلَا نَبِيٍّ إِلَّآ إِذَا تَمَنَّىٰٓ أَلۡقَى ٱلشَّيۡطَٰنُ فِيٓ أُمۡنِيَّتِهِۦ فَيَنسَخُ ٱللَّهُ مَا يُلۡقِي ٱلشَّيۡطَٰنُ ثُمَّ يُحۡكِمُ ٱللَّهُ ءَايَٰتِهِۦۗ وَٱللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٞ 52
A ko gbe dide siwaju rẹ -ire ojise- ojisẹ kan tabi anọbi kan ayaafi ki o jase wipe ti o ba ka tira Allah esu yoo ju ohun ti yoo bo awọn eniyan loju sibi kika rẹ lati ma gba pe imisi ni, sugbọn Allah yoo mu ibajẹ ba ohun ti esu naa ju, yoo si fi awọn amin rẹ rinlẹ, Ọlọhun Allah jẹ onimimọ si gbogbo nkan, nkankan ko pamọ fun, Ọjọgbọn nibi isẹda ati ipebubu ati iseto Rẹ.
لِّيَجۡعَلَ مَا يُلۡقِي ٱلشَّيۡطَٰنُ فِتۡنَةٗ لِّلَّذِينَ فِي قُلُوبِهِم مَّرَضٞ وَٱلۡقَاسِيَةِ قُلُوبُهُمۡۗ وَإِنَّ ٱلظَّٰلِمِينَ لَفِي شِقَاقِۢ بَعِيدٖ 53
Esu yoo ju nkan si ibi ohun ti anọbi ba nka ki Ọlọhun Ọba Allah le sọ ohun ti o ju yii di idanwo fun awọn sọbẹselu ati fun awọn ti ọkan wọn le ninu awọn ẹlẹbọ, bẹẹ dajudaju awọn alabosi ninu awọn sọbẹselu ati awọn ẹlẹbọ wa nibi isọta pẹlu Allah ati fun ojisẹ Rẹ ati nibi jijinna si ododo ati itọsọna.
وَلِيَعۡلَمَ ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡعِلۡمَ أَنَّهُ ٱلۡحَقُّ مِن رَّبِّكَ فَيُؤۡمِنُواْ بِهِۦ فَتُخۡبِتَ لَهُۥ قُلُوبُهُمۡۗ وَإِنَّ ٱللَّهَ لَهَادِ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِلَىٰ صِرَٰطٖ مُّسۡتَقِيمٖ 54
Ki awọn ti Ọlọhun Allah fun ni imọ le mọ amọdaju wipe Alukuraani ti a sọkalẹ fun Muhammad jẹ ododo, eyiti Ọlọhun Allah ransẹ imisi rẹ si ọ - irẹ ojisẹ - ki wọn le ba lekun ni igbagbọ si i, ki ọkan wọn si le ba tẹriba fun un ki o si bẹru, ati wipe dajudaju Allah jẹ olufi awọn ti o nigbagbọ si I lọ si oju ọna ododo eyiti o duro tọ, ti ko si wọgunwọgun nibẹ; ki o le jẹ ẹsan fun wọn lori itẹriba wọn fun un.
وَلَا يَزَالُ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ فِي مِرۡيَةٖ مِّنۡهُ حَتَّىٰ تَأۡتِيَهُمُ ٱلسَّاعَةُ بَغۡتَةً أَوۡ يَأۡتِيَهُمۡ عَذَابُ يَوۡمٍ عَقِيمٍ 55
Ki awọn ti wọn se keferi si Allah, ti wọn si tun pe ojisẹ Rẹ nirọ ma yẹ nibi iyemeji nibi ounti Allah sọkalẹ fun ọ ni ẹniti yoo maa tẹsiwaju titi igbende yoo fi to ni ojiji, ti wọn yoo si wa lori eleyi tabi ki iya waa ba wọn ni ọjọ ti ko nii si ikẹ nibẹ fun wọn tabi oore, ohun naa ni ọjọ igbende ni ibamun si fun wọn.
Didẹ awọn alabosi lẹkẹ titi wọn yoo fi maa ba abosi wọn niso jẹ isesi Allah.
Idaabobo Allah fun iwe Rẹ kuro nibi iyipada ati ijiirọ ati yiyi awọn ete oluranlọwọ esu kuro nibẹ.
Sọbẹ selu, lile ọkan jẹ aarẹ meji tii pani.
Igbagbọ jẹ eso imọ, ipaya ati itẹriba fun awọn asẹ Allah jẹ eso igbagbọ.