وَقَفَّيۡنَا عَلَىٰٓ ءَاثَٰرِهِم بِعِيسَى ٱبۡنِ مَرۡيَمَ مُصَدِّقٗا لِّمَا بَيۡنَ يَدَيۡهِ مِنَ ٱلتَّوۡرَىٰةِۖ وَءَاتَيۡنَٰهُ ٱلۡإِنجِيلَ فِيهِ هُدٗى وَنُورٞ وَمُصَدِّقٗا لِّمَا بَيۡنَ يَدَيۡهِ مِنَ ٱلتَّوۡرَىٰةِ وَهُدٗى وَمَوۡعِظَةٗ لِّلۡمُتَّقِينَ 46
A fi Isa ọmọ Maryam tele awon oripa awọn anọbi arọmọdọmọ Israheel, ni ẹniti o ni igbagbọ si oun ti nbẹ ninu taoreeta, ti o si nse idajọ pẹlu rẹ, a si tun fun ni injiila, eyiti o ko imọna lọsi ibi ododo sinu, o si tun ko gbogbo awọn ẹri ti o le mu iruju kuro sinu, ti yoo si tun yanju awọn wahala ninu idajọ, o si se deede ohun ti o sọkalẹ siwaju rẹ ninu taoreeta, ayaafi diẹ ninu nkan ti o ti pa rẹ ninu awọn idajọ rẹ, a si se injiila ni ọnọọmọ ti awọn oluberu Olohun ntọ, o tun jẹ ikilọ kuro nibi sise ohun ti o jẹ eewọ fun wọn.
وَلۡيَحۡكُمۡ أَهۡلُ ٱلۡإِنجِيلِ بِمَآ أَنزَلَ ٱللَّهُ فِيهِۚ وَمَن لَّمۡ يَحۡكُم بِمَآ أَنزَلَ ٱللَّهُ فَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡفَٰسِقُونَ 47
Ki awọn nasaara yaa ni igbagbọ si ohun ti Ọlọhun Ọba Allah sọkalẹ ninu injiila, ki wọn si maa se idajọ pẹlu rẹ - ninu ohun ti o jẹ ododo, ti Anọbi Muhammad mu fun wọn siwaju ki wọn too gbe dide - ẹniti ko ba se idajọ pẹlu ohun ti Ọlọhun Ọba Allah sọkalẹ, awọn wọnyi ti kuro ninu iẹle asẹ ỌlọhunỌba Allah, wọn si ti gbe odod ju silẹ, bẹẹ ni wọn ti fi si ibi ibajẹ.
Nigbati Ọlọhun Ọba Allah yin taoreeta ati injiila, o tun darukọ Alukuraani, O si yin in, O wa sọ wipe:
وَأَنزَلۡنَآ إِلَيۡكَ ٱلۡكِتَٰبَ بِٱلۡحَقِّ مُصَدِّقٗا لِّمَا بَيۡنَ يَدَيۡهِ مِنَ ٱلۡكِتَٰبِ وَمُهَيۡمِنًا عَلَيۡهِۖ فَٱحۡكُم بَيۡنَهُم بِمَآ أَنزَلَ ٱللَّهُۖ وَلَا تَتَّبِعۡ أَهۡوَآءَهُمۡ عَمَّا جَآءَكَ مِنَ ٱلۡحَقِّۚ لِكُلّٖ جَعَلۡنَا مِنكُمۡ شِرۡعَةٗ وَمِنۡهَاجٗاۚ وَلَوۡ شَآءَ ٱللَّهُ لَجَعَلَكُمۡ أُمَّةٗ وَٰحِدَةٗ وَلَٰكِن لِّيَبۡلُوَكُمۡ فِي مَآ ءَاتَىٰكُمۡۖ فَٱسۡتَبِقُواْ ٱلۡخَيۡرَٰتِۚ إِلَى ٱللَّهِ مَرۡجِعُكُمۡ جَمِيعٗا فَيُنَبِّئُكُم بِمَا كُنتُمۡ فِيهِ تَخۡتَلِفُونَ 48
A sọkalẹ fun ọ - ire ojise - Alukuraani pẹlu ododo, ti ko si iyemeji ati roiroi nibi wiwa lati ọdọ Ọlọhun rẹ, ti npe gbogbo nkan ti o ti siwaju rẹ ootọ, ti o si jẹ nkan ikọnbalẹ si, eyiti o ba se kongẹ nibẹ, ododo ni, bakanna eyiti o ba yapa si, ibajẹ ni, ki o yaa maa se idajọ laarin awọn eniyan pẹlu ohun ti Ọlọhun Ọba Allah sọkalẹ fun ọ ninu rẹ, wọn si tẹle ifẹ inu wọn eyiti wọn gba mu, ki o wa lọọ gbe ju silẹ ohun ti Ọlọhun Ọba rẹ sọkalẹ fun ọ, ti ko si iyemeji nibẹ, paapa a ti se awọn ofin ni o ni isẹ sise ninu fun gbogbo awọn ijọ ati ọna ti han de ti wọn le maa tọ, ti Ọlọhun Ọba Allah ba fẹ ni, ki ba se gbogbo awọn ofin naa ni ọkan, sugbọn O se ofin fun ijọ kọọkan, ki o le se idanwo fun gbogbo eniyan, bayi ni olutẹle yoo han de ati ẹlẹsẹ, ki ẹ yara gaga lọ si ibi awọn isẹẹre ati gbigbe awọn nkan ti a kọ ju silẹ, ọdọ Ọlọhun Ọba Allah nikan ni isẹri si yin ni ọjọ igbende, Yoo si fun yin niro gbogbo nkan ti ẹ nse iyapa si, yoo si san yin lẹsan lori nkan ti ẹ ti siwaju ninu isẹ.
وَأَنِ ٱحۡكُم بَيۡنَهُم بِمَآ أَنزَلَ ٱللَّهُ وَلَا تَتَّبِعۡ أَهۡوَآءَهُمۡ وَٱحۡذَرۡهُمۡ أَن يَفۡتِنُوكَ عَنۢ بَعۡضِ مَآ أَنزَلَ ٱللَّهُ إِلَيۡكَۖ فَإِن تَوَلَّوۡاْ فَٱعۡلَمۡ أَنَّمَا يُرِيدُ ٱللَّهُ أَن يُصِيبَهُم بِبَعۡضِ ذُنُوبِهِمۡۗ وَإِنَّ كَثِيرٗا مِّنَ ٱلنَّاسِ لَفَٰسِقُونَ 49
Ki o maa se idajọ laarin wọn - irẹ ojisẹ - pẹlu ohun ti Ọlọhun Ọba Allah sọkalẹ fun ọ, mase tẹle ero ori wọn eyiti o le jẹ jade lati itẹle ifẹ inu wọn, sọ ra fun wọn ki wọn ma sọ ẹ nu kuro nibi apakan nkan ti A sọkalẹ fun ọ, toripe wọn ko nii jawọ kuro nibi igbiyanju si oju ọna naa, ti wọn ba gunri kuro nibi gbigba idajọ pẹlu ohun ti Ọlọhun Ọba Allah sọkalẹ fun wọn, ki o mọ wipe Ọlọhun Ọba Allah gbero lati fi iya jẹ wọn ni, ni ijiya ti aye lori ẹsẹ wọẹ, Yoo si tun fi iya jẹ wọn lori gbogbo rẹ ni ọrun, dajudaju ọpọlọpọ awọn eniyan wọn ti kuro nibi itẹle asẹ Ọlọhun Ọba Allah.
أَفَحُكۡمَ ٱلۡجَٰهِلِيَّةِ يَبۡغُونَۚ وَمَنۡ أَحۡسَنُ مِنَ ٱللَّهِ حُكۡمٗا لِّقَوۡمٖ يُوقِنُونَ 50
Se wọn yoo maa gunri kuro nibi idajọ rẹ ni, ti wọn yoo maa wa wa idajọ awọn alaimọkan, bi awọn ti nse oosa, awọn ti nse idajọ pẹlu titẹle ifẹ inu? ! Ko si ẹnikẹni ti idajọ rẹ dara to Ọlọhun Ọba Allah ni ọdọ awọn alamọdaju, awọn ti wọn nse laakaye nipa Ọlọhun Ọba Allah ati ohun ti Ọlọhun Ọba Allah sọkalẹ fun ojisẹ Rẹ, kii se awọn alaimọkan ati awọn onifẹẹnu, awọn ti wọn kii gba ju ohun ti o ba tẹ ifẹ wọn lọrun lọ kii baa jẹ ibajẹ.
Awọn Anọbi Ọlọhun Ọba Allah panupọ lori ipilẹ ẹsin ti iyapa ẹnu si nbẹ fun wọn lori awọn ofin wọn ti o jẹ ẹlẹka.
Jijẹ dandan idajọ pẹlu ofin Ọlọhun Ọba Allah ati gigunri kuro ohun ti o ba ti yatọ si ninu ifẹ inu.
Fifi ẹnu agan kan sise idajọ pẹlu idajọ awọn alaimọkan ati awọn asa wọn.