وَيُكَلِّمُ ٱلنَّاسَ فِي ٱلۡمَهۡدِ وَكَهۡلٗا وَمِنَ ٱلصَّٰلِحِينَ 46
Ati wipe yoo si maa ba awọn eniyan sọrọ, ti o si jẹ ọmọkekere siwaju ki asiko ọrọ too to, ati wipe yoo maa ba wọn sọrọ ni ẹniti o dagba, ti agbara ati jijẹ ọkunrin rẹ si ti pe ni paapaa, yoo maa da oju ọrọ kọ wọn pẹlu ohun ti daadaa alamọri ẹsin wọn ati ti aye wọn nbẹ nibẹ, ati wipe Oun wa ninu awọn ẹniire, nibi awọn gbolohun wọn ati awọn isẹ wọn.
قَالَتۡ رَبِّ أَنَّىٰ يَكُونُ لِي وَلَدٞ وَلَمۡ يَمۡسَسۡنِي بَشَرٞۖ قَالَ كَذَٰلِكِ ٱللَّهُ يَخۡلُقُ مَا يَشَآءُۚ إِذَا قَضَىٰٓ أَمۡرٗا فَإِنَّمَا يَقُولُ لَهُۥ كُن فَيَكُونُ 47
Maryam sọ ni ẹniti nse iyalenu wipe ọmọ yoo wa fun laini ọkọ: ba wo ni ọmọ yoo se wa fun mi, ti eniyan kankan ko si ni sun mọ mi, ko jẹ ibi ẹtọ, ko si jẹ ibi eewọ? ! Malaika waa sọ fun wipe: apẹrẹ bi Ọlọhun Ọba Allah yoo se da ọmọ fun ọ laini baba, O ma nda oun ti O ba fẹ ninu awọn nkan ti yoo yatọ si oun ti a ti ba rẹ ati adamọ, ti O ba gbero alamọri kan, Yoo sọ fun wipe maa bẹ (kun) , yoo si maa bẹ, nkankan ko si le ko agara ba.
وَيُعَلِّمُهُ ٱلۡكِتَٰبَ وَٱلۡحِكۡمَةَ وَٱلتَّوۡرَىٰةَ وَٱلۡإِنجِيلَ 48
Ati wipe Yoo si fi tira mọọ ati ise deede ati kongẹ nibi gbolohun ati isẹ, ati wipe Yoo si fi Taoraata mọọ, eyiti Ọlọhun Ọba Allah sọkalẹ fun Muusa (ki ọla maa jẹ tirẹ) , ati wipe Yoo fi Injeela mọọ, eyiti yoo pada sọkalẹ le lori.
وَرَسُولًا إِلَىٰ بَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ أَنِّي قَدۡ جِئۡتُكُم بَِٔايَةٖ مِّن رَّبِّكُمۡ أَنِّيٓ أَخۡلُقُ لَكُم مِّنَ ٱلطِّينِ كَهَيَۡٔةِ ٱلطَّيۡرِ فَأَنفُخُ فِيهِ فَيَكُونُ طَيۡرَۢا بِإِذۡنِ ٱللَّهِۖ وَأُبۡرِئُ ٱلۡأَكۡمَهَ وَٱلۡأَبۡرَصَ وَأُحۡيِ ٱلۡمَوۡتَىٰ بِإِذۡنِ ٱللَّهِۖ وَأُنَبِّئُكُم بِمَا تَأۡكُلُونَ وَمَا تَدَّخِرُونَ فِي بُيُوتِكُمۡۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗ لَّكُمۡ إِن كُنتُم مُّؤۡمِنِينَ 49
Ati wipe Yoo se - bakanna - ni ojisẹ si ọdọ ọmọ isirẹli, ni aaye ti yoo ti maa sọ fun wọn wipe: dajudaju emi jẹ ojisẹ Ọlọhun Ọba Allah si ọdọ yin, paapaa mo de waa ba yin pẹlu amin eyiti ntọka lori jijẹ ododo ijẹ Anọbi mi, ohun naa ni pe: dajudaju emi, maa mọ ya aworan fun yin lati ibi akojọ amọ̀, gẹgẹ bi aworan ẹyẹ, ti maa wa fẹ atẹgun sibẹ, ti yoo si di ẹyẹ ti yoo maa sẹmi pẹlu iyanda Ọlọhun Ọba Allah, ati wipe maa mọ se iwosan ẹniti wọn bi ni afọju, ti yoo si pada riran, ati ẹniti ẹtẹ mu, ti awọ rẹ yoo si pada ni alaafia, ati wipe maa si maa ji ẹniti o ti ku, gbogbo nkan naa pẹlu iyọnda Ọlọhun Ọba Allah ni, ati wipe maa si mọ fun yin ni iro pẹlu ohun ti ẹyin yoo maa jẹ, ati ohun ti ẹyin yoo maa bo mọlẹ si inu awọn ile yin, ninu ounjẹ ti ẹ o si fi pamọ, dajudaju o nbẹ nibi ohun ti mo sọ fun yin, ninu awọn alamọri ti o tobi yii, eyiti abara ko lee lagbara lori rẹ, bikose wipe amin ti o fi oju han lori wipe dajudaju emi jẹ ojisẹ kan lati ọdọ Ọlọhun Ọba Allah si yin, ti ẹ ba jẹ ẹniti o niilo igbagbọ, ti ẹ si tun gba awọn ẹri gbọ.
وَمُصَدِّقٗا لِّمَا بَيۡنَ يَدَيَّ مِنَ ٱلتَّوۡرَىٰةِ وَلِأُحِلَّ لَكُم بَعۡضَ ٱلَّذِي حُرِّمَ عَلَيۡكُمۡۚ وَجِئۡتُكُم بَِٔايَةٖ مِّن رَّبِّكُمۡ فَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَأَطِيعُونِ 50
Ati wipe mo de waa ba yin - bakanna - ni ẹniti nsọ ododo ohun ti o sọkalẹ siwaju mi ninu Taoraata, ati wipe mo de waa ba yin, ki nle ba sọ di ẹtọ fun yin apakan ohun ti wọn se ni eewọ fun yin siwaju, ni ise irọrun ati igbe ọrọ ni fifuyẹ fun yin, ati wipe mo de waa ba yin pẹlu ẹri ti o daju lori nini alaafia ohun ti mo sọ fun yin, ki ẹ ya paya Ọlọhun Ọba Allah pẹlu mimaa mu awọn asẹ Rẹ wa si imusẹ, ati jijina si awọn ohun ti O kọ, ati wipe ki ẹ tẹle mi nibi ohun ti mo npe yin sibẹ.
إِنَّ ٱللَّهَ رَبِّي وَرَبُّكُمۡ فَٱعۡبُدُوهُۚ هَٰذَا صِرَٰطٞ مُّسۡتَقِيمٞ 51
Nkan naa wa bẹẹ nitoripe dajudaju Ọlọhun Ọba Allah ni Ọlọhun Ọba mi ati Ọlọhun Ọba yin, Oun nikan soso ni Ẹniti O lẹtọ si ki wọn maa tẹle, ki wọn si tun maa paya Rẹ, ki ẹ ya maa sin In ni Oun nikan soso, eleyi ni nkan ti mo payin lasẹ rẹ, nibi ijọsin Ọlọhun Ọba Allah ati pipaya Rẹ, ohun naa ni oju ọna ti o tọ, eyiti ko si ọgbun nibẹ.
۞فَلَمَّآ أَحَسَّ عِيسَىٰ مِنۡهُمُ ٱلۡكُفۡرَ قَالَ مَنۡ أَنصَارِيٓ إِلَى ٱللَّهِۖ قَالَ ٱلۡحَوَارِيُّونَ نَحۡنُ أَنصَارُ ٱللَّهِ ءَامَنَّا بِٱللَّهِ وَٱشۡهَدۡ بِأَنَّا مُسۡلِمُونَ 52
Nigbati Anọbi Isa (ki ọla maa jẹ tirẹ) mọ lati ọdọ wọn isorikunkun lori aigbagbọ, o sọ ni ẹniti nba awọn ọmọ Isirẹli sọrọ wipe: taani ẹniti yoo ran mi se nibi ipepe lọsi ọdọ Ọlọhun Ọba Allah, awọn ẹni mimọ ninu awọn olutẹle rẹ sọ wipe, awa ni alaranse ẹsin Ọlọhun Ọba Allah, a si ni igbagbọ pẹlu Ọlọhun Ọba Allah, a si tẹle ọ, waa jẹri - irẹ Isa - pe dajudaju awa tẹriba fun Ọlọhun Ọba Allah pẹlu sise ni aaso ati titẹle.
Iyi kikọ nkan ati mimaa kọ ati giga ipo awọn mejeeji ni aye ti Ọlọhun Ọba Allah (ti ọla Rẹ ga) ti bẹrẹ dida orukọ awọn nkan mejeeji siwaju awọn ohun ti o yatọ si awọn mejeeji.
Ninu awọn ilana Ọlọhun Ọba Allah (ti ọla Rẹ ga) , ni ki O kun awọn ojisẹ Rẹ lọwọ pẹlu awọn arisami eyiti yoo maa tọka lori isododo wọn ninu awọn nkan ti abara ko ni agbara lori rẹ.
Isa (ki ọla maa jẹ tirẹ) wa pẹlu gbigbe ọrọ ni fifuyẹ fun awọn ọmọ isirẹli nibi oun ti wọn le mọ wọn nibẹ, nibi apakan awọn ofin Taoraata, o nbẹ nibi eleyi, itọkasi lori sisẹlẹ iparẹ laarin awọn ofin Ṣhẹria.