۞وَلَا تُجَٰدِلُوٓاْ أَهۡلَ ٱلۡكِتَٰبِ إِلَّا بِٱلَّتِي هِيَ أَحۡسَنُ إِلَّا ٱلَّذِينَ ظَلَمُواْ مِنۡهُمۡۖ وَقُولُوٓاْ ءَامَنَّا بِٱلَّذِيٓ أُنزِلَ إِلَيۡنَا وَأُنزِلَ إِلَيۡكُمۡ وَإِلَٰهُنَا وَإِلَٰهُكُمۡ وَٰحِدٞ وَنَحۡنُ لَهُۥ مُسۡلِمُونَ 46
Ẹ mase ba fi ọrọ jomi toro ọrọ -ẹyin olugbagbọ ododo-, bẹẹni ẹ mase ba yahuudi ati nasaara ja ayaafi pẹlu awọn ọna ti o dara ati ojupanna ti o se kọ se, ohun si ni ipepe pẹlu isiti ati awọn awijare ti o fi o ju han ayaafi awọn ti wọn se abosi ninu wọn pẹlu ori kunkun ati ifaga gbaga ti wọn si kede ogun le yin lori, ki ẹ ya ba wọn ja titi ti wọn yoo fi jupa jusẹ silẹ tabi ki wọn san wo isakọlẹ ni ẹni yẹpẹrẹ, ki ẹ si sọ fun awọn yahuudi ati nasaara: a nigbagbọ si ohun ti Allah sọkalẹ fun wa ninu Alukuraani, bẹẹni atun nigbagbọ si ohun ti wọn sọkalẹ fun yin ninu taoreeta ati injiila, bẹẹni Ọlọhun wa ati Ọlọhun Ọba yin jẹ ọkan soso, ko si orogun fun Un nibi jijọsin fun Un ati itọju RẸ ati pipe Rẹ, Oun nikan ni awa si ntẹriba fun, ti a si nyẹpẹrẹ fun U.
وَكَذَٰلِكَ أَنزَلۡنَآ إِلَيۡكَ ٱلۡكِتَٰبَۚ فَٱلَّذِينَ ءَاتَيۡنَٰهُمُ ٱلۡكِتَٰبَ يُؤۡمِنُونَ بِهِۦۖ وَمِنۡ هَٰٓؤُلَآءِ مَن يُؤۡمِنُ بِهِۦۚ وَمَا يَجۡحَدُ بَِٔايَٰتِنَآ إِلَّا ٱلۡكَٰفِرُونَ 47
Ati gẹgẹ bi a ti sọ awọn tira naa kalẹ fun awọn ti o ti siwaju rẹ ni a se sọ Alukuraani kalẹ fun ọ, bẹẹni apakan awọn eniyan ti wọn nka taoreeta yii - gẹgẹ bi Abdullahi ọmọ Salaam - wọn nigbagbọ si i; nitori iroyin rẹ ti wọn ri ninu tira wọn, ẹnikankan ko nii se aimoore si awọn amin Wa ayaafi awọn keferi ti o jasipe isesi wọn ni keferi, iyan jija si ododo biotiwulẹ ki o han.
وَمَا كُنتَ تَتۡلُواْ مِن قَبۡلِهِۦ مِن كِتَٰبٖ وَلَا تَخُطُّهُۥ بِيَمِينِكَۖ إِذٗا لَّٱرۡتَابَ ٱلۡمُبۡطِلُونَ 48
Iwọ ko ka - irẹ ojisẹ - tira kankan siwaju Alukuraani, bẹẹni iwọ ko kọ ohunkihun pẹlu ọwọ ọtun rẹ; nitoripe alaimọkan ti ko le ka, ti ko le kọ, ti oba jasipe o nka, o nkọ ni, awọn alaimọkan ninu awọn eniyan ko ba se iyemeji si jijẹ anọbi rẹ, wọn ko ba si fi kẹwọ wipe o jẹ ẹniti o nkọ lati inu awọn tira ti o siwaju.
بَلۡ هُوَ ءَايَٰتُۢ بَيِّنَٰتٞ فِي صُدُورِ ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡعِلۡمَۚ وَمَا يَجۡحَدُ بَِٔايَٰتِنَآ إِلَّا ٱلظَّٰلِمُونَ 49
Bikosepe Alukuraani ti A sọkalẹ fun ọ jẹ awọn amin imọ ni ọdọ awọn olugbagbọ ododo, ẹnikan ko si nii ja awọn amin wa niyan ayaafi awọn alabosi si ẹmin ara wọn nibi sise keferi si Allah ati sise ẹbọ pẹlu Rẹ.
وَقَالُواْ لَوۡلَآ أُنزِلَ عَلَيۡهِ ءَايَٰتٞ مِّن رَّبِّهِۦۚ قُلۡ إِنَّمَا ٱلۡأٓيَٰتُ عِندَ ٱللَّهِ وَإِنَّمَآ أَنَا۠ نَذِيرٞ مُّبِينٌ 50
Awọn ẹlẹbọ sọpe: se wọn ko nii sọkalẹ fun Muhammad ni awọn amin lati ọdọ Ọlọhun Ọba rẹ gẹgẹ bi ohun ti o sọkalẹ fun awọn ojisẹ siwaju rẹ, sọ - irẹ ojisẹ - fun awọn olumu imọran wa yii: dajudaju awọn amin wa ni ọwọ Allah ti mimọ nbẹ fun, O nsọ ọ kalẹ nigbati O ba fẹ, kii se ọdọ mi ni sisọkalẹ rẹ ti wa, dajudaju emi kan jẹ olusekilẹ fun yin kuro nibi iya Allah, ni ikilọ ti o fi oju han.
أَوَ لَمۡ يَكۡفِهِمۡ أَنَّآ أَنزَلۡنَا عَلَيۡكَ ٱلۡكِتَٰبَ يُتۡلَىٰ عَلَيۡهِمۡۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَرَحۡمَةٗ وَذِكۡرَىٰ لِقَوۡمٖ يُؤۡمِنُونَ 51
Se ko wa to fun awọn olumumọra wa yii lori awọn amin wipe awa ni a nsọ ọ kalẹ - irẹ ojisẹ - Alukuraani ti o nka fun wọn dajudaju ikẹ ati isiti nbẹ fun awọn ti o nigbagbọ ninu Alukuraani ti A sọkalẹ fun wọn, awọn ni ẹniti yoo se anfaani pẹlu ohun ti nbẹ nibẹ, ohun ti wọn sọkalẹ fun wọn loore ju ohun ti wọn damọran rẹ ninu iro ohun ti A sọkalẹ fun awọn ojisẹ ti o kọja lọ.
قُلۡ كَفَىٰ بِٱللَّهِ بَيۡنِي وَبَيۡنَكُمۡ شَهِيدٗاۖ يَعۡلَمُ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۗ وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ بِٱلۡبَٰطِلِ وَكَفَرُواْ بِٱللَّهِ أُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡخَٰسِرُونَ 52
Sọ - irẹ ojisẹ - Allah ti mimọ nbẹ fun to ni olujẹri nibi ijododo mi nibi ohun ti mo mu wa ati lori iro ti ẹ npa mọ Ọ, O mọ ohun ti o wa ni sanmọ, O si mọ ohun ti o wa ninu ilẹ, nkankan ko pamọ fun Un ninu mejeeji, awọn ti o si nigbagbọ ninu ibajẹ nibi gbogbo ohun ti wọn nsin yatọ si Allah, ti wọn si nse aimoore si Allah ti Oun nikan lẹtọ ijọsin fun, awọn wọnyi ni ẹni ofo; nitori pipaarọ igbagbọ si keferi.
Jijiyan pẹlu awọn ti a fun ni tira gbọdọ jẹ pẹlu ọna ti o dara.
Igbagbọ si gbogbo awọn ojisẹ ati awọn iwe laisi opinya jẹ majẹmu lilalaafia igbagbọ.
Alukuraani Alapọnle jẹ amin gbere ati ẹri lailai lori ododo anọbi ẹniti ikẹ ati ọla nbẹ fun.