قَالَ يَٰنُوحُ إِنَّهُۥ لَيۡسَ مِنۡ أَهۡلِكَۖ إِنَّهُۥ عَمَلٌ غَيۡرُ صَٰلِحٖۖ فَلَا تَسَۡٔلۡنِ مَا لَيۡسَ لَكَ بِهِۦ عِلۡمٌۖ إِنِّيٓ أَعِظُكَ أَن تَكُونَ مِنَ ٱلۡجَٰهِلِينَ 46
Ọlọhun Allah sọ fun Nuuh: irẹ Nuuh dajudaju ọmọ rẹ ti o beere ọla rẹ ko si ninu ara ile rẹ ti Mo se adehun ọla fun; nitori wipe o jẹ keferi, dajudaju ibeere rẹ jẹ isẹ ti ko ba oju mun lati ọdọ rẹ, ko si tọ fun ẹniti o ba wa ni ipo ti o wa, bayi mase bi mi leere nipa nkan ti iwọ ko nimọ nipa rẹ, Mo nse ikilọ fun ọ ki o ma ba wa ninu awọn alaimọkan, ki o ma pada maa beere nkan ti o yapa si imọ Mi ati idajọ Mi.
قَالَ رَبِّ إِنِّيٓ أَعُوذُ بِكَ أَنۡ أَسَۡٔلَكَ مَا لَيۡسَ لِي بِهِۦ عِلۡمٞۖ وَإِلَّا تَغۡفِرۡ لِي وَتَرۡحَمۡنِيٓ أَكُن مِّنَ ٱلۡخَٰسِرِينَ 47
Nuuh ẹniti ọla nbẹ fun sọ wipe: iwọ Ọlọhun Ọba mi, dajudaju ẹmi nlugọ mo si nsa di ọ, ki nma le beere nkan ti emi ko nimọ nipa rẹ, ti o ko ba fi ori jimi, ki O si fi ikẹ Rẹ kẹ mi, emi yoo wa ninu awọn ẹni ofo, awọn ti wọn ti se ofo ipin wọn ni ọrun.
قِيلَ يَٰنُوحُ ٱهۡبِطۡ بِسَلَٰمٖ مِّنَّا وَبَرَكَٰتٍ عَلَيۡكَ وَعَلَىٰٓ أُمَمٖ مِّمَّن مَّعَكَۚ وَأُمَمٞ سَنُمَتِّعُهُمۡ ثُمَّ يَمَسُّهُم مِّنَّا عَذَابٌ أَلِيمٞ 48
Ọlọhun Ọba Allah sọ fun Nuuh ẹniti ọla nbẹ fun: irẹ Nuuh, sọkalẹ ninu ọkọ oju omi pẹlu alaafia ati ifọkanbalẹ ati pẹlu awọn idẹkun Allah ti o pọ le ọ lori, ati lori awọn arọmọdọmọ awọn ti wọn wa pẹlu rẹ ninu ọkọ oju omi naa ninu awọn olugbagbọ ododo naa, ti wọn yoo si wa lẹyin rẹ, awọn ijọ miran ninu awọn arọmọdọmọ rẹ, ti wọn jẹ keferi, a o se idẹkun fun wọn ninu isẹmin aye, a o si fun wọn ni nkan ti wọn yoo fi maa se ẹmin, lẹyin igba naa ni iya onitara yoo kan wọn lati ọdọ Ọlọhun ni ọrun.
تِلۡكَ مِنۡ أَنۢبَآءِ ٱلۡغَيۡبِ نُوحِيهَآ إِلَيۡكَۖ مَا كُنتَ تَعۡلَمُهَآ أَنتَ وَلَا قَوۡمُكَ مِن قَبۡلِ هَٰذَاۖ فَٱصۡبِرۡۖ إِنَّ ٱلۡعَٰقِبَةَ لِلۡمُتَّقِينَ 49
Itan Nuuh yii jẹ ninu awọn imọ kọkọ eyiti iwọ - ire ojise - ko mọ ọ, bẹẹ ni awọn ijọ rẹ ko mọ siwaju imisi yii ti a fi ransẹ si ọ, ki o yaa se suuru lori suta ijọ ati irọ pipa wọn gẹgẹ bi Nuha ẹniti ọla nbẹ fun se se suuru, dajudaju aranse ati ibori nbẹ fun awọn ti wọn ba tẹle asẹ Allah, ti wọn si jinna si awọn nkan ti o kọ.
وَإِلَىٰ عَادٍ أَخَاهُمۡ هُودٗاۚ قَالَ يَٰقَوۡمِ ٱعۡبُدُواْ ٱللَّهَ مَا لَكُم مِّنۡ إِلَٰهٍ غَيۡرُهُۥٓۖ إِنۡ أَنتُمۡ إِلَّا مُفۡتَرُونَ 50
A ran ọmọ iya tii se Huud ẹniti ọla nbẹ fun si ijọ Hadi, o sọ fun wọn: ẹyin ijọ mi, ẹ sin Allah nikan soso, ẹ mase mu ẹnikẹni pẹlu Rẹ, ko si olujọsin fun niti ododo kan yatọ si I ninu Rẹ, ko si si fun yin ni ẹniti ẹ npe ni orogun si I ayaafi awọn opurọ.
يَٰقَوۡمِ لَآ أَسَۡٔلُكُمۡ عَلَيۡهِ أَجۡرًاۖ إِنۡ أَجۡرِيَ إِلَّا عَلَى ٱلَّذِي فَطَرَنِيٓۚ أَفَلَا تَعۡقِلُونَ 51
Ẹyin ijọ mi, wọn ko beere ẹsan lori ohun ti mo fi nto yin leti lati ọdọ Ọlọhun Ọba mi, ti mo si npe yin lọ si ibẹ, ko si ẹsan fun mi ayaafi lati ọdọ ỌLọhun Ọba, ẹniti o da mi, se ẹyin ko se laakaye eleyi ni, ki ẹ si jẹpe ohun ti mo npe yin lọ si ibẹ?
وَيَٰقَوۡمِ ٱسۡتَغۡفِرُواْ رَبَّكُمۡ ثُمَّ تُوبُوٓاْ إِلَيۡهِ يُرۡسِلِ ٱلسَّمَآءَ عَلَيۡكُم مِّدۡرَارٗا وَيَزِدۡكُمۡ قُوَّةً إِلَىٰ قُوَّتِكُمۡ وَلَا تَتَوَلَّوۡاْ مُجۡرِمِينَ 52
Ẹyin ijọ mi, ẹ wa aforijin ni ọdọ Allah, ki ẹ si sẹri lọsi ọdọ Rẹ kuro nibi ẹsẹ yin - eyiti o si tobi ju ninu rẹ naa ni ẹbọ - yoo san yin lẹsan lori eleyi pẹlu sisọ ojo kalẹ ti o pọ, yoo si se alekun iyi lori yin pẹlu ki o fun yin ni arọmọdọmọ ti o pọ ati awọn dukia, ki ẹ si mase gunri kuro nibi ohun ti mo npe yin si, ki ẹ ma ba wa ninu awọn ẹlẹsẹ nitori igunri yin kuro nibi ipepe mi ati sise keferi si Allah ati piparọ mọ ohun ti mo mu wa.
قَالُواْ يَٰهُودُ مَا جِئۡتَنَا بِبَيِّنَةٖ وَمَا نَحۡنُ بِتَارِكِيٓ ءَالِهَتِنَا عَن قَوۡلِكَ وَمَا نَحۡنُ لَكَ بِمُؤۡمِنِينَ 53
Awọn ijọ rẹ sọ wipe: irẹ Huud, iwọ ko mu ẹri ti o gbọngbọn wa ti a fi le nigbagbọ si ọ, awa ko si le fi ijọsin fun awọn ọlọhun wa nitori ọrọ rẹ ti ko ni ẹri, awa ko le gba ọ gbọ sibi nkan ti o npe ara rẹ si wipe ojisẹ ni ọ.
Awọn anọbi ko nikapa ipẹ fun ẹniti o se keferi si Allah koda bi wọn jẹ awọn ọmọ wọn.
Amumọra olupepe ati fifọọmọ kuro nibi ohun ti nbẹ ni ọwọ awọn eniyan ni o sun mọ ju ki wọn o le gba a lọwọ rẹ.
Ọla ti nbẹ fun iwaforijin ati ironu piwada ati wipe dajudaju mejeeji jẹ okunfa isọkalẹ ojo ati alekun arọmọdọmọ ati awọn dukia.