فَقُطِعَ دَابِرُ ٱلۡقَوۡمِ ٱلَّذِينَ ظَلَمُواْۚ وَٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ رَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ 45
Igbẹyin awọn keferi kẹyin sibi pipa wọn rẹ tegbotegbo, aranse si waye fun awọn ojisẹ Ọlọhun, ọpẹ ati ẹyin jẹ ti Ọlọhun Ọba ọkan soso, olutọju gbogbo agbanla aye lori pipa awọn ọta Rẹ run ati sise aranse fun awọn ẹni tirẹ.
قُلۡ أَرَءَيۡتُمۡ إِنۡ أَخَذَ ٱللَّهُ سَمۡعَكُمۡ وَأَبۡصَٰرَكُمۡ وَخَتَمَ عَلَىٰ قُلُوبِكُم مَّنۡ إِلَٰهٌ غَيۡرُ ٱللَّهِ يَأۡتِيكُم بِهِۗ ٱنظُرۡ كَيۡفَ نُصَرِّفُ ٱلۡأٓيَٰتِ ثُمَّ هُمۡ يَصۡدِفُونَ 46
Sọ - ire ojise - fun awọn ọsẹbọ: ẹ fun mi niro ti Ọlọhun Ọba Allah ba sọ yin di aditi pẹlu wipe O mu igbọran yin lọ, tabi O sọ yin di afọju pẹlu ki O mu iriran yin lọ, ki O si fi edidi di ọkan yin, ti ẹ ko le gbọ nkankan ye; ẹniti a njọsin fun ni o le mu ohun ti ẹ padanu rẹ yi wa fun yin? Ronu - ire ojise - si bi a se nse alaye awọn ẹri fun wọn ati oniranran awijare sugbọn wọn tu ngbunri kuro nibẹ!
قُلۡ أَرَءَيۡتَكُمۡ إِنۡ أَتَىٰكُمۡ عَذَابُ ٱللَّهِ بَغۡتَةً أَوۡ جَهۡرَةً هَلۡ يُهۡلَكُ إِلَّا ٱلۡقَوۡمُ ٱلظَّٰلِمُونَ 47
Sọ fun - ire ojise - wipe ẹ fun mi niro ti iya Ọlọhun Ọba Allah ba wa ba yin lojiji nigbati ẹ ko mọ rara, tabi o ti ẹ wa nigbangba, womi nwo ọ, iya naa ko niin mu ẹnikankan ju awọn alabosi lọ nitori keferi wọn si Ọlọhun Ọba Allah ati pipe awọn ojisẹ nirọ.
وَمَا نُرۡسِلُ ٱلۡمُرۡسَلِينَ إِلَّا مُبَشِّرِينَ وَمُنذِرِينَۖ فَمَنۡ ءَامَنَ وَأَصۡلَحَ فَلَا خَوۡفٌ عَلَيۡهِمۡ وَلَا هُمۡ يَحۡزَنُونَ 48
A ko ran ojisẹ ti a ran nisẹ bikose wipe ki o le fun awọn eniyan ti wọn ni igbagbọ, ti wọn si ntẹle asẹ ni iro idunnu, kidẹkun lailai eyiti ko nii tan nigba kankan, ati ki o le dẹruba awọn keferi ẹlẹsẹ nibi iya Wa eyiti o le koko, ẹniti o ba nigbagbọ si awọn ojisẹ, ti o si se atunse isẹ rẹ, ko si ipaya fun nibi nkan ti wọn yoo ba pade ni ọrun, wọn ko nii banujẹ tabi gbarata lori nkan ti o bọ mọ wọn lọwọ lori nkan ipin aye.
وَٱلَّذِينَ كَذَّبُواْ بَِٔايَٰتِنَا يَمَسُّهُمُ ٱلۡعَذَابُ بِمَا كَانُواْ يَفۡسُقُونَ 49
Awọn ti wọn ba pe awọn amin wa nirọ, iwa yoo tọ si wọn nitori jijade wọn kuro nibi itẹle asẹ Ọlọhun Ọba Allah.
قُل لَّآ أَقُولُ لَكُمۡ عِندِي خَزَآئِنُ ٱللَّهِ وَلَآ أَعۡلَمُ ٱلۡغَيۡبَ وَلَآ أَقُولُ لَكُمۡ إِنِّي مَلَكٌۖ إِنۡ أَتَّبِعُ إِلَّا مَا يُوحَىٰٓ إِلَيَّۚ قُلۡ هَلۡ يَسۡتَوِي ٱلۡأَعۡمَىٰ وَٱلۡبَصِيرُۚ أَفَلَا تَتَفَكَّرُونَ 50
Sọ - ire ojise - fun awọn ọlọsẹbọ: nko sọ fun yin: wipe pẹpẹ ọrọ Ọlọhun Ọba Allah ninu arisiki wa ni ọdọ mi, ti maa wa ma se bi o se wu mi nibẹ, bẹẹ ni emi ko sọ fun yin wipe: mo nimọnipa kọkọ ayaafi ohun ti Ọlọhun Ọba Allah ba fi to mi leti ninu imisi, emi ko si sọ fun yin wipe: mo jẹ Malaika kan ninu awọn Malaika, bikose wipe mo jẹ ọkan ninu awọn ojisẹ Ọlọhun Ọba Allah, emi ko tẹle nkankan yatọ si ohun ti wọn ba fi ransẹ si mi lọ, emi ko si pe apemọra nkan ti emi ko jẹ, sọ wipe - ire ojise - njẹ keferi ti iriran rẹ ti fọ kuro nibi ododo ati olugbagbọ ododo eyiti o riran ri ootọ, ti o si nigbagbọ sii jọ ara wọn bi? Se ẹ ko ronu ọpọlọ yin ni - ẹyin ọlọsẹbọ - si awọn nkan ti nbẹ ni ẹgbẹ yin ninu awọn amin.
وَأَنذِرۡ بِهِ ٱلَّذِينَ يَخَافُونَ أَن يُحۡشَرُوٓاْ إِلَىٰ رَبِّهِمۡ لَيۡسَ لَهُم مِّن دُونِهِۦ وَلِيّٞ وَلَا شَفِيعٞ لَّعَلَّهُمۡ يَتَّقُونَ 51
Fi - ire ojise - Alukuraani yii dẹruba awọn ti wọn npaya pe ki awọn ma ko jọ ni ọjọ igbende ni ọdọ Ọlọhun Ọba Allah, ko si alatilẹyin kankan fun wọn Ọlọhun Ọba Allah lọ ti yoo mu anfaani wa fun wọn, ko si si olusipẹ ti yoo mu aburu kuro, ki wọn o le ba paya Ọlọhun Ọba Allah pẹlu titẹle asẹ Rẹ ati jijinna si ohun ti O kọ, awọn wọnyi ni wọn le se anfaani pẹlu Alukuraani.
وَلَا تَطۡرُدِ ٱلَّذِينَ يَدۡعُونَ رَبَّهُم بِٱلۡغَدَوٰةِ وَٱلۡعَشِيِّ يُرِيدُونَ وَجۡهَهُۥۖ مَا عَلَيۡكَ مِنۡ حِسَابِهِم مِّن شَيۡءٖ وَمَا مِنۡ حِسَابِكَ عَلَيۡهِم مِّن شَيۡءٖ فَتَطۡرُدَهُمۡ فَتَكُونَ مِنَ ٱلظَّٰلِمِينَ 52
Majẹ ki - ire ojise - awọ alaini olugbagbọ ododo jinna si ijoko rẹ, awọn ti wọn wa nibi ijọsin Ọlọhun Ọba Allah ni akọkọ ọsan ati ni igbẹyin rẹ, ni ẹniti nse afọmọ ijọsin fun Un, ma mu wọn jinna nitori agbalagba ọlọsẹbọ le wa pẹlu rẹ pẹẹ, isiro awọn keferi yii ko kan ọ, isiro wọn wa ni ọdọ Ọlọhun Ọba Allah, bẹẹ ni isiro tirẹ naa ko kan wọn, ti o ba ti mu wọn jinna si ijoko rẹ, dajudaju o ti wa ninu ẹniti o kọja ẹnu aala Ọlọhun Ọba Allah.
Awọn anọbi Ọlọhun Ọba jẹ abara, wọn ko ni iroyin itọju ẹda lara biotilẹ wu ki o kere mọ, akolekan wọn ko ju mimu ọrọ de ogongo lọ, wọn ko ni ikapa lati se bi o se wu wọn ninu isẹmin aye, wọn ko mọ kọkọ, wọn ko si ni ikapa pẹpẹ ọrọ ati iru rẹ.
Kiko akolekan olupepe si awọn ti wọn ntẹle, pataki julọ awọn ọlẹ ti wọn ko wa nkankan ju ododo lọ, dandan ni fun ki o fa wọn mara, ko gbọdọ gba lati le wọn nitori wiwa iyọnu awọn keferi.
Titọka aayah naa si pataki awọn ijọsin eyiti o waye ni akọkọ ọsan ati igbẹyin rẹ.