وَتَرَىٰهُمۡ يُعۡرَضُونَ عَلَيۡهَا خَٰشِعِينَ مِنَ ٱلذُّلِّ يَنظُرُونَ مِن طَرۡفٍ خَفِيّٖۗ وَقَالَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِنَّ ٱلۡخَٰسِرِينَ ٱلَّذِينَ خَسِرُوٓاْ أَنفُسَهُمۡ وَأَهۡلِيهِمۡ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِۗ أَلَآ إِنَّ ٱلظَّٰلِمِينَ فِي عَذَابٖ مُّقِيمٖ 45
Iwọ yoo ri - irẹ ojisẹ - awọn alabosi naa nigbati wọn ba sẹri wọn si ina, wọn yoo jẹ ẹni yẹpẹrẹ ẹni itiju, wọn yoo maa ji awọn eniyan wo nitori lilekoko ipaya ti o nbẹ fun wọn, awọn ti wọn nigbagbọ ninu Allah ati si awọn ojisẹ Rẹ yoo sọpe: dajudaju awọn ẹni ofo tootọ, awọn eniti o sofo ẹmin wọn ati ara ile wọn ni ọjọ igbende nitori ohun ti wọn ba pade ninu iya Allah, ẹ tẹti gbọ dajudaju awọn ti wọn se abosi si ẹmin ara wọn pẹlu sise keferi ati awọn ẹsẹ yoo wa ninu iya gbere ti ko nii ja lailai.
وَمَا كَانَ لَهُم مِّنۡ أَوۡلِيَآءَ يَنصُرُونَهُم مِّن دُونِ ٱللَّهِۗ وَمَن يُضۡلِلِ ٱللَّهُ فَمَا لَهُۥ مِن سَبِيلٍ 46
Ko nii si alatilẹyin ti yoo ran wọn se fun wọn pẹlu ki o yọ wọn kuro ninu iya llah ni ọjọ igbende, ẹniti Allah ba dagunla si kuro nibi ododo, ti o si sọ ọ nu, ko si oju ọna ti o fi le de imọna fun laialai lọ si ibi ododo.
ٱسۡتَجِيبُواْ لِرَبِّكُم مِّن قَبۡلِ أَن يَأۡتِيَ يَوۡمٞ لَّا مَرَدَّ لَهُۥ مِنَ ٱللَّهِۚ مَا لَكُم مِّن مَّلۡجَإٖ يَوۡمَئِذٖ وَمَا لَكُم مِّن نَّكِيرٖ 47
Ẹ jẹpe - ẹyin eniyan - fun Ọlọhun yin pẹlu yiyara lọ si mimu awọn asẹ Rẹ sẹ ati ijinna si awọn nkan ti o kọ, ati gbigbe isunsiwaju ju silẹ siwaju ki ọjọ igbende too to eyiti o jasipe ti o ba de ko si oludina rẹ, ko si ibusasi fun yin ti ẹ o sa si, ko si si itako ti ẹ le fi tako awọn ẹsẹ yin eyiti ẹ ti se ni ile aye.
فَإِنۡ أَعۡرَضُواْ فَمَآ أَرۡسَلۡنَٰكَ عَلَيۡهِمۡ حَفِيظًاۖ إِنۡ عَلَيۡكَ إِلَّا ٱلۡبَلَٰغُۗ وَإِنَّآ إِذَآ أَذَقۡنَا ٱلۡإِنسَٰنَ مِنَّا رَحۡمَةٗ فَرِحَ بِهَاۖ وَإِن تُصِبۡهُمۡ سَيِّئَةُۢ بِمَا قَدَّمَتۡ أَيۡدِيهِمۡ فَإِنَّ ٱلۡإِنسَٰنَ كَفُورٞ 48
Ti wọn ba gunri kuro nibi ohun ti o pa wọn lasẹ rẹ, a ko gbe ọ dide - irẹ ojisẹ - ni olusọ le wọn lori ti yoo maa sọ awọn isẹ wọn, ko si ohun ti o jẹ dandan fun ọ lọ imudopin ohun ti wọn pa ọ lasẹ ki o mu de ogongo lọ, isiro isẹ wọn si wa ni ọdọ Allah, dajudaju igbati Awa ba fi ikẹ tọ ọmọniyan wo lati ọdọ Wa gẹgẹ bi ọrọ ati alaafia ati ohun ti o jọ iru rẹ, yoo yọnu si i, sugbọn ti adanwo ba kan ọmọniyan ninu ohun ti ko nifẹ si lati ibi ẹsin wọn; dajudaju adamọ wọn ni sise aimoore wọn si awọn idẹkun Allah ati aidupẹ ati bibinu si ohun ti Allah ba pebubu fun un lati ibi ọgbọn rẹ.
لِّلَّهِ مُلۡكُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۚ يَخۡلُقُ مَا يَشَآءُۚ يَهَبُ لِمَن يَشَآءُ إِنَٰثٗا وَيَهَبُ لِمَن يَشَآءُ ٱلذُّكُورَ 49
Ti Allah ni ikapa gbogbo sanmọ ati ikapa ilẹ, O da ohun ti o wu U lakọ tabi labo tabi ohun ti o yatọ si eleyi, O wa nfun ẹniti o ba wu U ni abo ti ko si nii fun ni akọ, O si ma nfun ẹniti o ba wu U ni akọ ti ko si nii fun ni abo tabi ki o se fun ẹniti o ba wu U ni akọ ati abo papọ, o si ma nsọ ẹniti o ba wu U di agan ti ko nii bimọ, dajudaju Oun jẹ onimimọ pẹlu ohun ti nsẹlẹ lọwọlọwọ ati ohun ti yoo sẹlẹ ni ọjọ iwaju, eleyi si jẹ ninu pipe imọ ati kikun ọgbọn Rẹ, nkankan ko pamọ fun Un, bẹẹni nkankan ko ko agara ba A.
أَوۡ يُزَوِّجُهُمۡ ذُكۡرَانٗا وَإِنَٰثٗاۖ وَيَجۡعَلُ مَن يَشَآءُ عَقِيمًاۚ إِنَّهُۥ عَلِيمٞ قَدِيرٞ 50
Ti Allah ni ikapa gbogbo sanmọ ati ikapa ilẹ, O da ohun ti o wu U lakọ tabi labo tabi ohun ti o yatọ si eleyi, O wa nfun ẹniti o ba wu U ni abo ti ko si nii fun ni akọ, O si ma nfun ẹniti o ba wu U ni akọ ti ko si nii fun ni abo tabi ki o se fun ẹniti o ba wu U ni akọ ati abo papọ, o si ma nsọ ẹniti o ba wu U di agan ti ko nii bimọ, dajudaju Oun jẹ onimimọ pẹlu ohun ti nsẹlẹ lọwọlọwọ ati ohun ti yoo sẹlẹ ni ọjọ iwaju, eleyi si jẹ ninu pipe imọ ati kikun ọgbọn Rẹ, nkankan ko pamọ fun Un, bẹẹni nkankan ko ko agara ba A.
۞وَمَا كَانَ لِبَشَرٍ أَن يُكَلِّمَهُ ٱللَّهُ إِلَّا وَحۡيًا أَوۡ مِن وَرَآيِٕ حِجَابٍ أَوۡ يُرۡسِلَ رَسُولٗا فَيُوحِيَ بِإِذۡنِهِۦ مَا يَشَآءُۚ إِنَّهُۥ عَلِيٌّ حَكِيمٞ 51
Ko tọ fun abara kan ki Allah ba a sọrọ ayaafi imisi pẹlu inuni nimọ tabi ohun ti o yatọ si i tabi ki o ba a sọrọ ni ọna ti yoo maa gbọ ọrọ Rẹ sugbọn ko nii ri I, tabi ki o ran malaika ni ojisẹ si gẹgẹ bi Jibirilu, yoo wa ran imisi si ojisẹ naa ti o jẹ abara pẹlu iyọnda Allah ẹniti o ba wu U ki imisi naa lọ ba, dajudaju Oun ti mimọ nbẹ fun jẹ ẹniti O ga niti bibẹ Rẹ ati awọn iroyin Rẹ, O jẹ ọjọgbọn nibi isẹda Rẹ ati ipebubu Rẹ ati isofin Rẹ.
Jijẹ dandan yiyara lọsi bi mimu awọn asẹ Allah sẹ ati jijnna si awọn nkan ti o kọ.
Pataki ojisẹ ni ommudogongo, abajade si wa ni ọwọ Ọlọhun.
Itanilọrẹ akọ tabi abo tabi kiko mejeeji papọ wa ni ibamun si imọ Allah pẹlu ohun ti yoo se anfaani fun awọn ẹru Rẹ, ko si ẹsan kankan nibi jijẹ akọ yatọ si abo.
Allah ti o ga ma nransẹ imisi si awọn anọbi Rẹ ni ojupọnna orisirisi; nitori awọn ọgbọn ti mimọ Rẹ nimọ si.