وَلَقَدۡ أَرۡسَلۡنَآ إِلَىٰ ثَمُودَ أَخَاهُمۡ صَٰلِحًا أَنِ ٱعۡبُدُواْ ٱللَّهَ فَإِذَا هُمۡ فَرِيقَانِ يَخۡتَصِمُونَ 45
Paapaa a ti gbe ọmọ iya wọn ninu mọlẹbi tii se Sọlihu ẹniti ọla nbẹ fun si ijọ Thamudaawa wipe ki wọn o maa sin Allah nikan soso sugbọn lẹyin igba ti o pe wọn, wọn pin si ijọ meji: abala kan jẹ olugbagbọ, bẹẹni abala miran jẹ alaimoore, wọn si nse ifanfa ẹniti o wa lori ododo.
قَالَ يَٰقَوۡمِ لِمَ تَسۡتَعۡجِلُونَ بِٱلسَّيِّئَةِ قَبۡلَ ٱلۡحَسَنَةِۖ لَوۡلَا تَسۡتَغۡفِرُونَ ٱللَّهَ لَعَلَّكُمۡ تُرۡحَمُونَ 46
Solihu - ẹniti ọla nbẹ fun - sọ fun wọn wipe: kilode ti ẹ nwa ikanju iya siwaju ikẹ? Se ẹ ko le wa aforijin lọdọ Allah lori ẹsẹ yin ni ki O le ba kẹ yin.
قَالُواْ ٱطَّيَّرۡنَا بِكَ وَبِمَن مَّعَكَۚ قَالَ طَٰٓئِرُكُمۡ عِندَ ٱللَّهِۖ بَلۡ أَنتُمۡ قَوۡمٞ تُفۡتَنُونَ 47
Awọn ijọ rẹ sọ fun nibi titaku kuro nibi ododo: a ro aburu pẹlu rẹ ati awọn ti o wa pẹlu rẹ ninu awọn olugbagbọ ododo, Sọlihu ẹniti ọla nbẹ fun wọn sọ fun wọn wipe: ẹyẹ ti ẹ njagbe mọ lori ohun ti ẹ ko fẹ, ọdọ Allah ni imọ rẹ wa, nkankan ko pamọ fun Un, bikosepe ẹyin jẹ ijọ ti a ndanwo pẹlu rere ti wọn ba tẹ fun yin ati aburu ti o ba kan yin.
وَكَانَ فِي ٱلۡمَدِينَةِ تِسۡعَةُ رَهۡطٖ يُفۡسِدُونَ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَلَا يُصۡلِحُونَ 48
Paapaa o wa ni ilu hijiru ọkunrin mẹsan ti wọn se ibajẹ si ori ile nibi keferi ati awọn ẹsẹ dida; bẹẹni wọn ko le se daadaa nibẹ pẹlu igbagbọ ati isẹ rere.
قَالُواْ تَقَاسَمُواْ بِٱللَّهِ لَنُبَيِّتَنَّهُۥ وَأَهۡلَهُۥ ثُمَّ لَنَقُولَنَّ لِوَلِيِّهِۦ مَا شَهِدۡنَا مَهۡلِكَ أَهۡلِهِۦ وَإِنَّا لَصَٰدِقُونَ 49
Apakan wọn sọ fun apakan: ki ẹni kọọkan ninu yin yaa bura pẹlu Allah wipe a o waa ba ninu ile rẹ loru, a o si pa ati awọn ara ile rẹ, lẹyin naa a o sọ fun ẹniti o ni ikapa ẹjẹ rẹ: a ko wa lati pa Sọlihu ati awọn ara ile rẹ, awa jẹ olotitọ nibi ounti a sọ.
وَمَكَرُواْ مَكۡرٗا وَمَكَرۡنَا مَكۡرٗا وَهُمۡ لَا يَشۡعُرُونَ 50
Wọn si da ete miran pa mọ lati pa Sọlihu ati awọn alatẹle rẹ ninu awọn olugbagbọ ododo wọn, awa naa si ndete lati ranse ati alati la a nibi ete wọn ati iparun awọn keferi ninu ijọ, sugbọn wọn ko mọ eleyi.
فَٱنظُرۡ كَيۡفَ كَانَ عَٰقِبَةُ مَكۡرِهِمۡ أَنَّا دَمَّرۡنَٰهُمۡ وَقَوۡمَهُمۡ أَجۡمَعِينَ 51
Ronu si - irẹ ojisẹ - bi idari wọn ati ete wọn se sẹri si? Dajudaju awa ni a fi iya jẹ wọn fin in fin in lati ọdọ wa, wọn si parun titi de ẹni ikẹyin wọn.
فَتِلۡكَ بُيُوتُهُمۡ خَاوِيَةَۢ بِمَا ظَلَمُوٓاْۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗ لِّقَوۡمٖ يَعۡلَمُونَ 52
Eyi ni ile wọn ti ogiri rẹ ti dawo lori aja rẹ, o wa sẹku fun ẹniti o pa lofo kuro nibi ara ibẹ nitori okunfa abosi wọn, dajudaju ariwoye nbẹ fun awọn ti o gbagbọ nibi iya ti o sẹlẹ si wọn nitori abosi wọn, awọn ni yoo woye pẹlu awọn amin.
وَأَنجَيۡنَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَكَانُواْ يَتَّقُونَ 53
A si la awọn ti wọn nigbagbọ si Allah ninu ijọ Sọlihu ẹniti ọla nbẹ fun, ti wọn si jẹ ẹniti o paya Allah pẹlu titẹle awọn asẹ Rẹ ati jijinna si awọn ohun ti O kọ.
وَلُوطًا إِذۡ قَالَ لِقَوۡمِهِۦٓ أَتَأۡتُونَ ٱلۡفَٰحِشَةَ وَأَنتُمۡ تُبۡصِرُونَ 54
Tun ranti - irẹ ojisẹ - Luth nigbati o sọ fun awọn ijọ rẹ ni ẹniti o nbu wọn, ti o si korira wọn: se ẹyin yoo mu iwa ti ko dara wa ni - oun ni ibọkunrin lopọ - ni awọn igbagede yin ni gbangba, ti apakan yin yoo maa ri apakan?!
أَئِنَّكُمۡ لَتَأۡتُونَ ٱلرِّجَالَ شَهۡوَةٗ مِّن دُونِ ٱلنِّسَآءِۚ بَلۡ أَنتُمۡ قَوۡمٞ تَجۡهَلُونَ 55
Se ẹyin yoo maa lọ ba awọn ọkunrin ni ojupọnna jijẹran laise obirin, ẹ ko gbero amumọra, bẹẹni kii se ti bibimọ, bikosepe lati jẹ igbadun ẹranko ni, ẹ jẹ ijọ alaimọkan nipa ohun ti o jẹ dandan le yin lori ninu igbagbọ ati imọra ati ijina si awọn ẹsẹ.
Wiwa aforijin kuro nibi awọn ẹsẹ jẹ okunfa ikẹ Allah.
Riro aburu si awọn eniyan tabi ohunkihun ko si ninu awọn iroyin awọn olugbagbọ ododo.
Igbẹyin dida ọgbọn lori aburu ati ete si awọn ẹni ododo jẹ aidara.
Kikede ohun ti ko dara buru ju fifi pamọ rẹ lọ.
Titako awọn ẹni poki ati ẹlẹsẹ jẹ dandan.