أَمۡ تَحۡسَبُ أَنَّ أَكۡثَرَهُمۡ يَسۡمَعُونَ أَوۡ يَعۡقِلُونَۚ إِنۡ هُمۡ إِلَّا كَٱلۡأَنۡعَٰمِ بَلۡ هُمۡ أَضَلُّ سَبِيلًا 44
Ati o lero pe - irẹ ojisẹ - wipe ọpọlọpọ awọn ti o npe lọsi ibi mimọ Allah lọkan ati itẹle ngbọ ni gbigbọ gbigba abi wọn se laakaye si awọn awijare ati awọn ẹri ni?! Wọn kii se nkankan ju apejuwe awọn ẹranko lọ nibi gbigbọ ati sise laakaye ati agbọye koda awọn ni wọn sọnu ju kuro ni oju ọna ju awọn ẹranko lọ.
أَلَمۡ تَرَ إِلَىٰ رَبِّكَ كَيۡفَ مَدَّ ٱلظِّلَّ وَلَوۡ شَآءَ لَجَعَلَهُۥ سَاكِنٗا ثُمَّ جَعَلۡنَا ٱلشَّمۡسَ عَلَيۡهِ دَلِيلٗا 45
Se o ko ri ni - irẹ ojisẹ - awọn oripa ẹda Allah nigbati o tẹ booji naa si ori ilẹ, ti o ba fẹ ni lati se wọn ni ohun ti yoo dakẹ rọrọ, ti ko nii mira, ki ba se e bẹ ẹ, lẹyin naa ni a sọ oorun di itọka le lori, ti o ntibẹ gun tabi kuru.
ثُمَّ قَبَضۡنَٰهُ إِلَيۡنَا قَبۡضٗا يَسِيرٗا 46
Lẹyin naa a gba ooji mu pẹlu dindin in ku, ti o wa ndagba soke diẹdiẹ ni igbamun kekere ni ibamun si giga oorun naa.
وَهُوَ ٱلَّذِي جَعَلَ لَكُمُ ٱلَّيۡلَ لِبَاسٗا وَٱلنَّوۡمَ سُبَاتٗا وَجَعَلَ ٱلنَّهَارَ نُشُورٗا 47
Ọlọhun Allah ẹniti o sọ oru di aaye iwọsọ ti o nboyin lasiri, o si tun bo awọn nkan miran ni asiri, O nna si ni o tun sọ oorun di isimi fun yin, ti ẹ nsinmin nibẹ kuro nibi awọn nkan idiwọ yin, O nna si ni o si tun sọ ọsan di asiko ti ẹ fi ngbepa gbesẹ lọ si ibi awọn isẹ yin.
وَهُوَ ٱلَّذِيٓ أَرۡسَلَ ٱلرِّيَٰحَ بُشۡرَۢا بَيۡنَ يَدَيۡ رَحۡمَتِهِۦۚ وَأَنزَلۡنَا مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءٗ طَهُورٗا 48
O nni ẹniti o gbe atẹgun naa dide lati fun yin niro sisọkalẹ ojo eyiti o jẹ ninu ikẹ Rẹ fun awọn ẹru Rẹ, a si sọ omin ojo kalẹ lati sanmọ ni ohun ti o mọ, ti ẹ si fi nse imọra.
لِّنُحۡـِۧيَ بِهِۦ بَلۡدَةٗ مَّيۡتٗا وَنُسۡقِيَهُۥ مِمَّا خَلَقۡنَآ أَنۡعَٰمٗا وَأَنَاسِيَّ كَثِيرٗا 49
Ki a le maa fi omin ti o sọkalẹ naa ji ilẹ ti o ti sa ti ko si irugbin nibẹ pẹlu mimu awọn oniranran irugbin jade ati fifan awọn nkan titun kalẹ ti o tutu gbọdọ kalẹ, a ti ki a le fun ninu ohun ti a da lẹranko ati abara ni omin naa mu ni ọpọlọpọ.
وَلَقَدۡ صَرَّفۡنَٰهُ بَيۡنَهُمۡ لِيَذَّكَّرُواْ فَأَبَىٰٓ أَكۡثَرُ ٱلنَّاسِ إِلَّا كُفُورٗا 50
Paapa a ti salaye, a si mu oniranran awijare ati awọn ẹri wa ki wọn le woye pẹlu rẹ, sugbọn ọpọ awọn eniyan tako bikose sise keferi si ododo ati sise ajoji si i.
وَلَوۡ شِئۡنَا لَبَعَثۡنَا فِي كُلِّ قَرۡيَةٖ نَّذِيرٗا 51
Ti a ba fẹ a ko ba gbe ojisẹ kọọkan dide ninu abule kan ti yoo maa se ikilọ fun wọn, ti yoo si maa dẹru ba wọn nibi iya Allah, sugbọn awa ko fẹ eleyi bikosepe a gbe Muhammad ti ikẹ ati ọla nbẹ fun dide si gbogbo awọn eniyan.
فَلَا تُطِعِ ٱلۡكَٰفِرِينَ وَجَٰهِدۡهُم بِهِۦ جِهَادٗا كَبِيرٗا 52
Mase tẹle awọn keferi nibi ohun ti wọn nbeere lọdọ rẹ nibi ki o maa fi ruju ruju bo wọn loju ati nibi awọn imọran ti o nti siwaju fun wọn, ki Alukuraani ti a sọkalẹ yii ba wọn jiyan ni ijiyan ti o tobi pẹlu sise suuru lori suta wọn ati mimu wahala nipe wọn si ọdọ Ọlọhun Allah mọra.
۞وَهُوَ ٱلَّذِي مَرَجَ ٱلۡبَحۡرَيۡنِ هَٰذَا عَذۡبٞ فُرَاتٞ وَهَٰذَا مِلۡحٌ أُجَاجٞ وَجَعَلَ بَيۡنَهُمَا بَرۡزَخٗا وَحِجۡرٗا مَّحۡجُورٗا 53
Ọlọhun Ọba Allah ti mimọ nbẹ fun ni ẹniti o nda odo meji pọ, o da eyiti o dun ninu wọn pọ mọ eyiti o tẹ lẹnu, o si se gaga ati ebibo ti o kọdi, ti o si kọ fun lati ma u papọ.
وَهُوَ ٱلَّذِي خَلَقَ مِنَ ٱلۡمَآءِ بَشَرٗا فَجَعَلَهُۥ نَسَبٗا وَصِهۡرٗاۗ وَكَانَ رَبُّكَ قَدِيرٗا 54
Oun ni o si nda abara lati ibi aatọ ọkunrin ati obirin, ẹniti o da abara ni o se isopọ isunmọ ati isopọ idana, Ọlọhun Ọba rẹ jẹ - irẹ ojisẹ - alagbara ti nkankan ko ko agara ba A, ninu agbara Rẹ ni dida ọmọ ẹda eniyan lati ibi aatọ akọ ati obirin.
وَيَعۡبُدُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ مَا لَا يَنفَعُهُمۡ وَلَا يَضُرُّهُمۡۗ وَكَانَ ٱلۡكَافِرُ عَلَىٰ رَبِّهِۦ ظَهِيرٗا 55
Awọn keferi nsin ohun ti o yatọ si Allah ni oosa, ko le se wọn ni anfaani ti wọn ba tẹle e, ko si le ko inira ba wọn ti wọn ba yapa rẹ, bẹẹni keferi jẹ olutẹle esu lori ohun ti yioo bi Ọlọhun Ọba Allah ti mimọ nbẹ fun ninu.
Sisọkalẹ keferi si ipo ti ko to ipo ẹranko nitori sise keferi rẹ si Allah.
Iwoyesi oji jẹ amin kan ninu awọn amin Allah ti o ntọka si agbara Rẹ.
Mimu awọn ẹri ati awọn awijare wa ni oniranran jẹ ojupọnna ikọnilẹkọ ti o yege.
Fifi Alukuraani pepe wa ninu aworan igbiyanju si oju ọna Allah.