قَالُوٓاْ أَضۡغَٰثُ أَحۡلَٰمٖۖ وَمَا نَحۡنُ بِتَأۡوِيلِ ٱلۡأَحۡلَٰمِ بِعَٰلِمِينَ 44
Wọn sọ wipe: ala rẹ da oju ru eyiti o ba ri bẹ ko si itumọ fun, awa ko mọ itumọ ala ti o da oju ru.
وَقَالَ ٱلَّذِي نَجَا مِنۡهُمَا وَٱدَّكَرَ بَعۡدَ أُمَّةٍ أَنَا۠ أُنَبِّئُكُم بِتَأۡوِيلِهِۦ فَأَرۡسِلُونِ 45
Ẹniti o nfun ọba ni nkan mu ninu awọn arakunrin meji ti o la ninu ẹwọn sọ wipe: o si tun ranti yusuf ẹniti ọla nbẹ fun ati imọ itumọ ala ti o wa pẹlu rẹ lẹyin asiko diẹ: emi yoo fun yin niro itumọ nkan ti ọba ri lẹyin igbati mo ba beere lọwọ ẹniti o mọ itumọ ala rẹ, gbemi dide - irẹ ọba - lọ si ọdọ Yuusuf ki o le sọ itumọ ala rẹ.
يُوسُفُ أَيُّهَا ٱلصِّدِّيقُ أَفۡتِنَا فِي سَبۡعِ بَقَرَٰتٖ سِمَانٖ يَأۡكُلُهُنَّ سَبۡعٌ عِجَافٞ وَسَبۡعِ سُنۢبُلَٰتٍ خُضۡرٖ وَأُخَرَ يَابِسَٰتٖ لَّعَلِّيٓ أَرۡجِعُ إِلَى ٱلنَّاسِ لَعَلَّهُمۡ يَعۡلَمُونَ 46
Nigbati ẹniti o la yii de ọdọ yusuf o sọ fun wipe: irẹ yusuf, irẹ olododo fun wa niro itumọ ẹniti o ba lala wipe oun ri maalu meje ti o sanra ti o njẹ maalu meje miran ti o ru, ti o si ri erin meje ti o tutu, ti o tu waa ri erin meje miran ti o gbẹ; o seese ti nba pada si ọdọ ọba ati awọn ti wọn nbẹ ni ọdọ rẹ ki wọn o mọ agbekalẹ ala ọba, ki wọn o si tibẹ mọ ọla rẹ ati ipo rẹ.
قَالَ تَزۡرَعُونَ سَبۡعَ سِنِينَ دَأَبٗا فَمَا حَصَدتُّمۡ فَذَرُوهُ فِي سُنۢبُلِهِۦٓ إِلَّا قَلِيلٗا مِّمَّا تَأۡكُلُونَ 47
Yuusuf sọ ẹniti ọla nbẹ fun ni ẹniti nsalaye itumọ ala yii: ki ẹ se ọgbin fun ọdun meje ti o tẹle raa wọn pẹlu igbiyanju, gbogbo ohun ti ẹ ba ko lere ni ọdun kọọkan ninu awọn ọdun meje yii, ki ẹ fi silẹ ninu suku rẹ, ki o le kọ fun yin kuro nibi idaamun ayaafi diẹ ninu ohun ti ẹ ba ni bikaata si ninu awọn horo naa.
ثُمَّ يَأۡتِي مِنۢ بَعۡدِ ذَٰلِكَ سَبۡعٞ شِدَادٞ يَأۡكُلۡنَ مَا قَدَّمۡتُمۡ لَهُنَّ إِلَّا قَلِيلٗا مِّمَّا تُحۡصِنُونَ 48
Lẹyin naa yoo wa lẹyin ọdun meje ikore yii eyiti ẹ gbin nkan nibẹ, ọdun meje miran ti o jẹ ọdun ọda, ti awọn eniyan yoo maa jẹ ohun ti wọn ko lere ninu rẹ ninu awọn ọdun ikore, ayaafi diẹ ninu ohun ti ẹ ba fi pamọ ti o jẹ irugbin.
ثُمَّ يَأۡتِي مِنۢ بَعۡدِ ذَٰلِكَ عَامٞ فِيهِ يُغَاثُ ٱلنَّاسُ وَفِيهِ يَعۡصِرُونَ 49
Lẹyin igba naa yoo wa lẹyin awọn ọdun ọda yii, ọdun ti awọn ojo yoo sọkalẹ nibẹ ti awọn irugbin yoo si hu, ti awọn eniyan yoo si fun nibẹ ohun ti wọn ni bukaata si ninu eso inabi, saetun ati igi ireke.
وَقَالَ ٱلۡمَلِكُ ٱئۡتُونِي بِهِۦۖ فَلَمَّا جَآءَهُ ٱلرَّسُولُ قَالَ ٱرۡجِعۡ إِلَىٰ رَبِّكَ فَسَۡٔلۡهُ مَا بَالُ ٱلنِّسۡوَةِ ٱلَّٰتِي قَطَّعۡنَ أَيۡدِيَهُنَّۚ إِنَّ رَبِّي بِكَيۡدِهِنَّ عَلِيمٞ 50
Ọba wa sọ fun awọn olukunlọwọ rẹ nigbati iru yusuf de etigbọ rẹ nipa ala rẹ: ẹ mu jade kuro lẹ wọn, ki ẹ si ba mi mu wa, nigbati ojisẹ ọba de ọdọ rẹ, o sọ fun wipe: pada si ọdọ ọba rẹ, bi leere nipa itan awọn obinrin ti wọn ni amin ọgbẹ ni ọwọ wọn, ki bibọpa bọsẹ rẹ le han siwaju ki o to jade lẹwọn, dajudaju Ọlọhun Ọba mi jẹ onimimọ lori ohun ti wọn se fun mi lori igbero gba mi, nkankan ko pamọ fun Un nibi eleyi.
قَالَ مَا خَطۡبُكُنَّ إِذۡ رَٰوَدتُّنَّ يُوسُفَ عَن نَّفۡسِهِۦۚ قُلۡنَ حَٰشَ لِلَّهِ مَا عَلِمۡنَا عَلَيۡهِ مِن سُوٓءٖۚ قَالَتِ ٱمۡرَأَتُ ٱلۡعَزِيزِ ٱلۡـَٰٔنَ حَصۡحَصَ ٱلۡحَقُّ أَنَا۠ رَٰوَدتُّهُۥ عَن نَّفۡسِهِۦ وَإِنَّهُۥ لَمِنَ ٱلصَّٰدِقِينَ 51
Ọba sọrọ ni ẹniti o nba awọn obinrin wi: kinni ise yin nigbati ẹ nwa yuusuf pẹlu ete; ki o le se ibajẹ pẹlu gbogbo yin? awon obinrin sọ ni eniti o nda oba lohun: Olohun Oba Allah ko jeki Yuusuf je eniti won yoo ma fura si, Allah ni a fi bura a ko mo aburu mo, nigba naa ni iyawo oba soro ni ẹniti o nfi oun ti o se rinlẹ: nisin sin yi ni ododo han, emi ni mo nwa ọna lati daamu rẹ, kii se ohun ni o nwa ọna lati daamu mi, olootọ lojẹ nibi nkan ti o sọ lati fọ ara rẹ mọ nibi oun ti mo parọ rẹ mọ ọ.
ذَٰلِكَ لِيَعۡلَمَ أَنِّي لَمۡ أَخُنۡهُ بِٱلۡغَيۡبِ وَأَنَّ ٱللَّهَ لَا يَهۡدِي كَيۡدَ ٱلۡخَآئِنِينَ 52
Iyawo ọba sọ wipe: ki Yuusuf le mọ nigbati mo nfi rinlẹ wipe emi ni mo gbero gba a ati wipe dajudaju olootọ nii se, emi ko si da adapa irọ le lori lẹyin rẹ, paapaa o ti han si mi nibi nkan ti o sẹlẹ pe dajudaju Ọlọhun Ọba Allah ko nii fi ẹniti o nparọ, ti o si nda ete se kongẹ.
Ninu pipe ẹkọ ti o wa fun Yuusuf ni wipe o tọka si isẹlẹ awọn obinrin sugbọn ko tọka si isẹlẹ ti iyawo ọba.
Pipe imọ Yuusuf ẹniti ọla nbẹ fun nibi mimọ itumọ ala gbe kalẹ.
Sise lofin ibọpa bọsẹ ẹmin ara ẹni nibi ohun ti wọn ba fi ti si i niti abosi ati wiwa ki ododo han lati se ifirinlẹ ootọ.
Ọla ti nbẹ fun ootọ ati ọrọ ododo ki baa jẹ lori ara ẹni.