خَٰشِعَةً أَبۡصَٰرُهُمۡ تَرۡهَقُهُمۡ ذِلَّةٞۖ وَقَدۡ كَانُواْ يُدۡعَوۡنَ إِلَى ٱلسُّجُودِ وَهُمۡ سَٰلِمُونَ 43
Ni ẹniti iriran wọn kọlẹ, ti iyẹpẹrẹ ati abamọ si bo wọn daru, paapaa wọn ti jẹ ẹniti wọn beere fun ki wọn fi ori balẹ fun Allah ni ile aye, wọn wa ni ipo ẹni amojukuro nibi ohun ti wọn ko si ni oni.
فَذَرۡنِي وَمَن يُكَذِّبُ بِهَٰذَا ٱلۡحَدِيثِۖ سَنَسۡتَدۡرِجُهُم مِّنۡ حَيۡثُ لَا يَعۡلَمُونَ 44
Fi mi silẹ - irẹ ojisẹ - pẹlu ẹniti o npe Alukuraani ti a sọkalẹ fun ọ nirọ, A o dari wọn sibi iya ni ipele ipele ti wọn ko nii mọ wipe ete si awọn ati idẹnilẹkẹ ni o jẹ.
وَأُمۡلِي لَهُمۡۚ إِنَّ كَيۡدِي مَتِينٌ 45
Lọ ki o si lọ wọn lara fun asiko kan ki wọn le tẹsiwaju nibi ẹsẹ wọn, dajudaju ete mi lagbara si awọn ẹni keferi ati irọ pipa, wọn ko le jabọ mọ mi lọwọ, wọn ko si la kuro nibi ijiya mi.
أَمۡ تَسَۡٔلُهُمۡ أَجۡرٗا فَهُم مِّن مَّغۡرَمٖ مُّثۡقَلُونَ 46
Njẹ o nbeere lọdọ wọn - irẹ ojisẹ - ẹsan kan lori ohun ti o npe wọn si, wọn yoo se amumọra alamọri ti o tobi nitori eleyi, eleyi jẹ okunfa igunri wọn kuro ni ọdọ Rẹ?! Ohun ti o sẹlẹ yapa si eleyi, iwọ ko beere ẹsan lọdọ wọn, kinni ohun ti o kọ fun lati ma kọ wọn?!
أَمۡ عِندَهُمُ ٱلۡغَيۡبُ فَهُمۡ يَكۡتُبُونَ 47
Tabi imọ kọkọ nbẹ fun wọn ti wọn kọ ohun ti o ba wu wọn ninu awọn awijare eyiti wọn yoo fi maa ja ọ niyan nibẹ ni?!
فَٱصۡبِرۡ لِحُكۡمِ رَبِّكَ وَلَا تَكُن كَصَاحِبِ ٱلۡحُوتِ إِذۡ نَادَىٰ وَهُوَ مَكۡظُومٞ 48
Ki o se suuru - irẹ ojisẹ - fun idajọ ti Ọlọhun rẹ se nipa didẹ wọn lẹkẹ ati ilọlara, mase da gẹgẹ bi ẹlẹja Yuunusu ẹniti ọla nbẹ fun nibi igbarata lọdọ awọn ijọ rẹ; nigbati o pe Ọlọhun rẹ, ti o si wa ninu ibanijẹ ninu okunkun odo ati okunkun inu ẹja.
لَّوۡلَآ أَن تَدَٰرَكَهُۥ نِعۡمَةٞ مِّن رَّبِّهِۦ لَنُبِذَ بِٱلۡعَرَآءِ وَهُوَ مَذۡمُومٞ 49
Ti kii ba se pe ikẹ Allah le pa ba a, ẹja ki ba pọ ọ si ilẹ gbẹnsẹsẹ ni ẹni eebu.
فَٱجۡتَبَٰهُ رَبُّهُۥ فَجَعَلَهُۥ مِنَ ٱلصَّٰلِحِينَ 50
Ọlọhun rẹ si sa a lẹsa, O si se ninu awọn ẹru Rẹ ẹni rere.
وَإِن يَكَادُ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لَيُزۡلِقُونَكَ بِأَبۡصَٰرِهِمۡ لَمَّا سَمِعُواْ ٱلذِّكۡرَ وَيَقُولُونَ إِنَّهُۥ لَمَجۡنُونٞ 51
Ti awọn ti wọn se keferi si Allah, ti wọn si pe ojisẹ Rẹ nirọ ba fẹẹ le fi oju wọn mu didaku ba ọ nitori lile koko mimu iriran wọn si ọ, nigbati wọn gbọ Alukuraani ti a sọkalẹ fun ọ yii, ti wọn si nsọ - niti titẹle ifẹ inu wọn, ati gigunri kuro nibi ododo -: dajudaju ojisẹ ti o mu wa jẹ were.
وَمَا هُوَ إِلَّا ذِكۡرٞ لِّلۡعَٰلَمِينَ 52
Kinni Alukuraani ti a sọkalẹ fun ọ jẹ bikose isiti ati iranileti fun eniyan ati alujannu.
سورة (MAKIYYAH)
Ifirinlẹ wipe dajudaju isẹlẹ igbende ati ẹsan ni ọjọ na ododo ti kosi iyemeji nibẹ ni.
ٱلۡحَآقَّةُ 1
Allah sọ nipa asiko igbende eyiti yoo tọ si gbogbo ẹda.
مَا ٱلۡحَآقَّةُ 2
Lẹyin naa o pataki alamọri rẹ pẹlu ibeere yii, ewo ni ohun ti yoo sẹlẹ naa?
وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا ٱلۡحَآقَّةُ 3
Kinni ohun ti yoo fi isẹlẹ yii mọ ọ?
كَذَّبَتۡ ثَمُودُ وَعَادُۢ بِٱلۡقَارِعَةِ 4
Ijọ Thamudu pe ijọ Sọlihu nirọ, 'Aadi naa si pe ijọ Hudu nirọ nipa igbende eyiti o nja ọmọniyan laya nitori lilekoko awọn ibẹrẹ rẹ.
فَأَمَّا ثَمُودُ فَأُهۡلِكُواْ بِٱلطَّاغِيَةِ 5
Paapaa Allah ti fi ijagbemọ eyiti o de ogongo nibi lile koko ati ibẹru pa Thamudu run.
وَأَمَّا عَادٞ فَأُهۡلِكُواْ بِرِيحٖ صَرۡصَرٍ عَاتِيَةٖ 6
Paapaa Allah ti pa 'Aadi run pẹlu atẹgun ti o tutu digidigi, ti o si le, ti o de ogongo nibi lile rẹ mọ wọn.
سَخَّرَهَا عَلَيۡهِمۡ سَبۡعَ لَيَالٖ وَثَمَٰنِيَةَ أَيَّامٍ حُسُومٗاۖ فَتَرَى ٱلۡقَوۡمَ فِيهَا صَرۡعَىٰ كَأَنَّهُمۡ أَعۡجَازُ نَخۡلٍ خَاوِيَةٖ 7
Allah ransẹ Rẹ si wọn fun oru meje ati ọsan mẹjọ, ti o mu iparun ba wọn ni apapọ wọn, iwọ yoo wa ri awọn ijọ naa ni ẹni iparun ti o ti ku ni ori ile ni awọn inu ile wọn, wọn da gẹgẹ bi ipilẹ ọpẹ ti o jabọ silẹ, ti o ti ju lẹyin iparun wọn.
فَهَلۡ تَرَىٰ لَهُم مِّنۢ بَاقِيَةٖ 8
Njẹ o yoo ri ẹmin kan ti o sẹku fun wọn lẹyin iya ti o sẹlẹ si wọn bi?!
Suuru jẹ iwa ẹyin ti o ma nwa fun awọn olupepe ati ẹniti o wa fun wọn.
Ironu piwada ma npa ohun ti o siwaju rẹ rẹ, o si wa ninu awọn okunfa ti Allah fi ma nsa ẹru Rẹ lẹsa, ti yoo si sọ ọ di ọkan ninu awọn ẹru Rẹ rere.
Sise oniranran ohun ti Allah ma nran si awọn keferi ati awọn ẹlẹsẹ gẹgẹ bi iya ti o ntọka si pipe agbara Rẹ ati pipe deede Rẹ.