مَا تَسۡبِقُ مِنۡ أُمَّةٍ أَجَلَهَا وَمَا يَسۡتَٔۡخِرُونَ 43
Eyikeyi ninu awọn ijọ opurọ ko le gbawaju asiko ti a fi aala si wiwa iparun rẹ tabi ki o kẹyin ju u lọ, bi o ti wulẹ ki oniranran itẹgun wa fun to.
ثُمَّ أَرۡسَلۡنَا رُسُلَنَا تَتۡرَاۖ كُلَّ مَا جَآءَ أُمَّةٗ رَّسُولُهَا كَذَّبُوهُۖ فَأَتۡبَعۡنَا بَعۡضَهُم بَعۡضٗا وَجَعَلۡنَٰهُمۡ أَحَادِيثَۚ فَبُعۡدٗا لِّقَوۡمٖ لَّا يُؤۡمِنُونَ 44
Lẹyin naa a gbe awọn ojisẹ Wa dide, ti ojisẹ kan si ntẹle ojisẹ ni sisẹntẹle, gbogbo igbati ojisẹ kan ti a gbe dide si ijọ kan ninu awọn ijọ ba wa, wọn yoo pe e nirọ, a o wa maa fi iparun ba apakan lẹyin apakan, ko nii si sisẹku fun wọn ayaafi ọrọ awọn eniyan nipa wọn, iparun ki o maa bẹ fun awọn ijọ ti ko nigbagbọ si ohun ti awọn ojisẹ wọn mu wa lati ọdọ Ọlọhun Ọba wọn.
ثُمَّ أَرۡسَلۡنَا مُوسَىٰ وَأَخَاهُ هَٰرُونَ بَِٔايَٰتِنَا وَسُلۡطَٰنٖ مُّبِينٍ 45
Lẹyin naa a gbe Musa ati ọmọ iya rẹ Haruna dide pẹlu awọn amin Wa mẹsan: (ọpa, ọwọ, tata, ina ori, ọpọlọ, ẹjẹ, omin okun tufaanu, ọdun ọda, dindinku awọn nkan eleso) ati pẹlu awijare ti o fi oju han.
إِلَىٰ فِرۡعَوۡنَ وَمَلَإِيْهِۦ فَٱسۡتَكۡبَرُواْ وَكَانُواْ قَوۡمًا عَالِينَ 46
A gbe awọn mejeeji dide si firiaona ati awọn ẹni iyi ninu awọn ijọ rẹ, wọn si se igberaga, wọn ko si tẹriba fun wọn nitori igbagbọ, wọn jẹ ijọ ti o se igberaga si awọn eniyan pẹlu ibori ati abosi.
فَقَالُوٓاْ أَنُؤۡمِنُ لِبَشَرَيۡنِ مِثۡلِنَا وَقَوۡمُهُمَا لَنَا عَٰبِدُونَ 47
Wọn si sọ wipe: se a o wa nigbagbọ si abara meji bii wa, ti ko si ẹsa kankan fun wọn le wa lori, awọn ijọ wọn (ọmọ isirẹli) jẹ olutẹle ati olutẹriba fun wa?!
فَكَذَّبُوهُمَا فَكَانُواْ مِنَ ٱلۡمُهۡلَكِينَ 48
Wọn pe nirọ nibi ohun ti wọn mu wa ni ọdọ Ọlọhun Allah, wọn di ẹni iparun ti a tẹri nitori irọ pipa wọn.
وَلَقَدۡ ءَاتَيۡنَا مُوسَى ٱلۡكِتَٰبَ لَعَلَّهُمۡ يَهۡتَدُونَ 49
Paapa a ti fun Musa ni taoreeta ni ireti ki awọn ijọ rẹ mọna lọ si ibi ododo, ki wọn si le maa lo o.
وَجَعَلۡنَا ٱبۡنَ مَرۡيَمَ وَأُمَّهُۥٓ ءَايَةٗ وَءَاوَيۡنَٰهُمَآ إِلَىٰ رَبۡوَةٖ ذَاتِ قَرَارٖ وَمَعِينٖ 50
A si sọ Isa ọmọ Maryam ati iya rẹ Maryam di amin ti yoo maa tọka si agbara Wa, o loyun rẹ laini baba, a si sẹri awọn mejeeji si aaye kan ti o ga lori ilẹ, ti o dọgba lati le tẹdo si, omin ti o nsan lọtunlọtun wa nibẹ.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلرُّسُلُ كُلُواْ مِنَ ٱلطَّيِّبَٰتِ وَٱعۡمَلُواْ صَٰلِحًاۖ إِنِّي بِمَا تَعۡمَلُونَ عَلِيمٞ 51
Mo pe ẹyin ojisẹ naa ẹ maa jẹ ninu ohun ti a se lẹtọ fun yin ninu ohun ti o dun ni jijẹ, ki ẹ si maa sise re ti o se kongẹ ofin, dajudaju Mo jẹ onimimọ pẹlu ohun ti ẹ nse ni isẹ, nkankan ninu isẹ yin ko pamọ fun Mi.
وَإِنَّ هَٰذِهِۦٓ أُمَّتُكُمۡ أُمَّةٗ وَٰحِدَةٗ وَأَنَا۠ رَبُّكُمۡ فَٱتَّقُونِ 52
Bẹẹ ni dajudaju oju ọna yin - ẹyin ojisẹ naa - oju ọna kan soso ni ohun si ni Islam, bẹẹ ni Emi ni Ọlọhun yin, ko si Ọlọhun miran yatọ si Mi, ki ẹ maa paya Mi pẹlu mimu awọn asẹ Mi sẹ ati jijinna si awọn nkan ti Mo kọ.
فَتَقَطَّعُوٓاْ أَمۡرَهُم بَيۡنَهُمۡ زُبُرٗاۖ كُلُّ حِزۡبِۢ بِمَا لَدَيۡهِمۡ فَرِحُونَ 53
Awọn olutẹle e wọn lẹyin wọn si pinya ninu ẹsin, wọn di ijọ ijọ ati ipin npin, gbogbo ijọ ni nkan ti o nigbagbọ si yoo maa jọ loju wipe dajudaju ohun ni ẹsin iyọnu ni ọdọ Allah, ti ko si gbọdọ bo oju wo ohun ti o wa lọdọ ẹlomiran.
فَذَرۡهُمۡ فِي غَمۡرَتِهِمۡ حَتَّىٰ حِينٍ 54
Gbe wọn ju silẹ -ire ojise- lori aimọkan ati idaamun ti wọn wa titi ti iya yoo fi sọkalẹ le wọn lori.
أَيَحۡسَبُونَ أَنَّمَا نُمِدُّهُم بِهِۦ مِن مَّالٖ وَبَنِينَ 55
Se awọn ijọ ti o ndunnu pẹlu ounti o wa lọdọ wọn yii nlero ni wipe ohun ti a fun wọn ninu awọn dukia ati awọn ọmọ ni isẹmin aye jẹ oore ikanju ti wọn lẹtọ si fun wọn?! ọrọ ko ri bi wọn se le ro, a kan fun wọn ni eleyi ki o le jẹ ilọlara ati idẹnilẹkẹ fun wọn ni sugbọn wọn ko fura mọ eleyi.
نُسَارِعُ لَهُمۡ فِي ٱلۡخَيۡرَٰتِۚ بَل لَّا يَشۡعُرُونَ 56
Se awọn ijọ ti o ndunnu pẹlu ounti o wa lọdọ wọn yii nlero ni wipe ohun ti a fun wọn ninu awọn dukia ati awọn ọmọ ni isẹmin aye jẹ oore ikanju ti wọn lẹtọ si fun wọn?! ọrọ ko ri bi wọn se le ro, a kan fun wọn ni eleyi ki o le jẹ ilọlara ati idẹnilẹkẹ fun wọn ni sugbọn wọn ko fura mọ eleyi.
إِنَّ ٱلَّذِينَ هُم مِّنۡ خَشۡيَةِ رَبِّهِم مُّشۡفِقُونَ 57
Dajudaju awọn ti wọn ba wa pẹlu igbagbọ wọn ati daadaa wọn yoo jẹ olubẹru Ọlọhun Ọba wọn.
وَٱلَّذِينَ هُم بَِٔايَٰتِ رَبِّهِمۡ يُؤۡمِنُونَ 58
Ati awọn ti wọn nigbagbọ ninu aayah iwe Rẹ.
وَٱلَّذِينَ هُم بِرَبِّهِمۡ لَا يُشۡرِكُونَ 59
Ati awọn ti wọn mu Ọlọhun Ọba lọkan, ti wọn ko sẹbọ pẹlu Rẹ.
Sise igberaga ma nkọ fun ni kuro nibi sise kongọ ododo.
Didara ounjẹ ni oripa ninu didara ọkan ati didara isẹ.
Mimu Ọlọhun Ọba lọkan jẹ oju ọna gbogbo awọn Anọbi ati ipepe wọn.
Sise idẹkun fun poki kii se apọnle fun un bikosepe o jẹ idẹlẹkẹ.