وَمَآ أَرۡسَلۡنَا مِن قَبۡلِكَ إِلَّا رِجَالٗا نُّوحِيٓ إِلَيۡهِمۡۖ فَسَۡٔلُوٓاْ أَهۡلَ ٱلذِّكۡرِ إِن كُنتُمۡ لَا تَعۡلَمُونَ 43
A ko ran nisẹ siwaju rẹ - irẹ ojisẹ - ayaafi awọn ọkunrin kan ninu abara ti A fi imisi ransẹ si, bẹẹ ni A ko ran ojisẹ ninu awọn Malaika, eleyi si ni isesi wa gbogbo igba, ti ẹ ba tako eleyi, ki ẹ yaa beere lọwọ awọn ti A fun ni tira siwaju, wọn yoo fun yin niro wipe dajudaju awọn ojisẹ jẹ abara, wọn kii se awọn Malaika, ti ẹyin ko ba mọ wipe abara ni wọn.
بِٱلۡبَيِّنَٰتِ وَٱلزُّبُرِۗ وَأَنزَلۡنَآ إِلَيۡكَ ٱلذِّكۡرَ لِتُبَيِّنَ لِلنَّاسِ مَا نُزِّلَ إِلَيۡهِمۡ وَلَعَلَّهُمۡ يَتَفَكَّرُونَ 44
A ran awọn ojisẹ yii ninu abara pẹlu awọn itọka ti o fi oju han, ati pẹlu awọn tira ti A sọkalẹ, A si tun sọkalẹ fun ọ - ire ojise - Alukuraani ki o le se alaye fun awọn eniyan eyiti o ni bukaata si alaye ati wipe o seese ki wọn lo laakaye wọn, ki wọn le gba isiti pẹlu ohun ti o ko sinu.
أَفَأَمِنَ ٱلَّذِينَ مَكَرُواْ ٱلسَّئَِّاتِ أَن يَخۡسِفَ ٱللَّهُ بِهِمُ ٱلۡأَرۡضَ أَوۡ يَأۡتِيَهُمُ ٱلۡعَذَابُ مِنۡ حَيۡثُ لَا يَشۡعُرُونَ 45
Se awọn ti wọn yiri awọn ete yii fi ọkan balẹ ni lati kọdi oju ọna Allah nibi wipe Allah le tẹ wọn ri si inu ilẹ gẹgẹ bi O se tẹ awọn ijọ ti o ti re kọja lọ ri, tabi ki O mu iya waa ba wọn nibi ti wọn ko ti rankan wiwa rẹ.
أَوۡ يَأۡخُذَهُمۡ فِي تَقَلُّبِهِمۡ فَمَا هُم بِمُعۡجِزِينَ 46
Tabi ki iya waa ba wọn nigbati wọn nse irin ajo tabi ti wọn nwa ijẹ imu wọn, wọn kii se ẹniti o le bọ mọ wa lọwọ tabi ti o le daabobo ara rẹ kuro.
أَوۡ يَأۡخُذَهُمۡ عَلَىٰ تَخَوُّفٖ فَإِنَّ رَبَّكُمۡ لَرَءُوفٞ رَّحِيمٌ 47
Se wọn fi ọkan balẹ ni wipe iya Allah ko le waa ba wọn nibi ipaya wọn si i, Ọlọhun Ọba Allah lagbara nibi fifi iya jẹ wọn lori eyikeyi isesi, dajudaju Ọlọhun Ọba jẹ alaanu onikẹ, kii kanju lori iya toripe o seese ki ẹru Rẹ ronu piwada lọsi ọdọ Rẹ.
أَوَ لَمۡ يَرَوۡاْ إِلَىٰ مَا خَلَقَ ٱللَّهُ مِن شَيۡءٖ يَتَفَيَّؤُاْ ظِلَٰلُهُۥ عَنِ ٱلۡيَمِينِ وَٱلشَّمَآئِلِ سُجَّدٗا لِّلَّهِ وَهُمۡ دَٰخِرُونَ 48
Se awọn opurọ yii ko woye ni iwoye ironu jinlẹ lọsi awọn ẹda Rẹ ni, ti bojiirẹ nfi sọtun sosi ni ibamun si iyipada oorun ati irin rẹ lọsan ati fun osupa ni alẹ, ni ẹni ti ntẹriba fun Ọlọhun Ọba rẹ, ti o si nfi ori balẹ fun Un ni iforibalẹ tootọ, o si jẹ ẹni yẹpẹrẹ.
وَلِلَّهِۤ يَسۡجُدُۤ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِ مِن دَآبَّةٖ وَٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ وَهُمۡ لَا يَسۡتَكۡبِرُونَ 49
Ọlọhun Ọba Allah nikan ni gbogbo ohun ti nbẹ ni sanmọ ati ti nbẹ ni ilẹ ninu daaba nfi ori balẹ fun, Oun nikan si ni awọn Malaika nfi ori balẹ fun, wọn kii se igberaga lori ijọsin Allah ati titẹle asẹ Rẹ.
يَخَافُونَ رَبَّهُم مِّن فَوۡقِهِمۡ وَيَفۡعَلُونَ مَا يُؤۡمَرُونَ۩ 50
Awọn ni - pẹlu ohun ti wọn wa lori rẹ ninu ijọsin ati itẹle asẹ Rẹ lailai - ẹniti o npaya Ọlọhun Eyiti O wa loke wọn pẹlu bibẹ Rẹ ati bibori Rẹ ati ọla Rẹ, wọn si nse ohun ti Ọlọhun Ọba wọn pa wọn lasẹ ninu itẹle.
۞وَقَالَ ٱللَّهُ لَا تَتَّخِذُوٓاْ إِلَٰهَيۡنِ ٱثۡنَيۡنِۖ إِنَّمَا هُوَ إِلَٰهٞ وَٰحِدٞ فَإِيَّٰيَ فَٱرۡهَبُونِ 51
Allah ti mimọ nbẹ fun sọ fun gbogbo ẹru Rẹ: ẹ mase mu olujọsin ni meji, Oun jẹ olujọsin fun kan pẹlu ododo, ti ko si ẹnikeji tabi orogun fun, emi ni ki ẹ maa paya, ẹ ko gbọdọ paya ẹniti o yatọ si Mi.
وَلَهُۥ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَلَهُ ٱلدِّينُ وَاصِبًاۚ أَفَغَيۡرَ ٱللَّهِ تَتَّقُونَ 52
Oun nikan ni O ni ohun ti nbẹ ni sanmọ ati ilẹ niti dida ati ọla ati idari, Oun nikan si ni O ni itẹle ati itẹriba ati isafọmọ niti fifi rinlẹ, se ẹniti o yatọ si Allah ni ẹ npaya bi?! Rara, bikosepe Oun nikan ni ki ẹ yaa paya.
وَمَا بِكُم مِّن نِّعۡمَةٖ فَمِنَ ٱللَّهِۖ ثُمَّ إِذَا مَسَّكُمُ ٱلضُّرُّ فَإِلَيۡهِ تَجَۡٔرُونَ 53
Eyikeyi ti o ba wa pẹlu yin - ẹyin eniyan - ninu idẹkun ẹsin tabi ti ile aye jẹ lati ọdọ Allah ti mimọ nbẹ fun, ko wa lati ọdọ ẹlomiran, lẹyin naa igbati aluba ba kan yin tabi aarẹ tabi aini, ọdọ Rẹ nikan ni ki ẹ rawọ-rasẹ adua si; ki O le mu ohun ti o sẹlẹ si yin kuro, ẹniti o ba ta ọrẹ idẹkun, ti o si mu wahala kuro, Oun ni o yẹ ki wọn si ni Oun nikan.
ثُمَّ إِذَا كَشَفَ ٱلضُّرَّ عَنكُمۡ إِذَا فَرِيقٞ مِّنكُم بِرَبِّهِمۡ يُشۡرِكُونَ 54
Lẹyin naa, ti o ba gbọ ipepe yin, ti O si mu inira ti o wa pẹlu yin kuro, igbanaa ni apakan ninu yin yoo maa mu ẹbọ pẹlu Ọlọhun, ti wọn yoo si maa sin nkan miran ti O yatọ si I, iru omugọ wo ni eleyi?!
O di dandan fun ẹlẹsẹ ki o tiju Ọlọhun Ọba rẹ, ki idẹkun Allah le maa sọkalẹ fun un ni gbogbo isẹju, ti awọn ẹsẹ rẹ naa si ngoke lọsi ọdọ Ọlọhun rẹ ni gbogbo asiko.
O di dandan fun awọn keferi ati awọn opurọ ati awọn oniranran ẹsẹ lati paya Allah ti O ga julọ ki O maa ba fi iya gba wọn mu ni ojupọnna ijowu, ti wọn ko si nii fura.
Gbogbo idẹkun wa lati ọdọ Allah ti O ga boya eyiti o see fi oju ri ni gẹgẹ bi arisiki ati iyege ati alaafia tabi eyiti ko see fi oju ri gẹgẹ bi ifọkanbalẹ ati iyi ati ipo tabi ohun ti o jọ ọ.
Ọmọniyan ko le ri ibusasi lati mu inira kuro ni asiko ilekoko ju Allah ti ọla Rẹ ga lọ pẹlu ki wiwo mọ idirẹbẹ lọsi ọdọ Rẹ; nitori imọ Rẹ wipe ẹnikankan ko lagbara lati mu isoro kuro ju Oun naa lọ.