مُهۡطِعِينَ مُقۡنِعِي رُءُوسِهِمۡ لَا يَرۡتَدُّ إِلَيۡهِمۡ طَرۡفُهُمۡۖ وَأَفِۡٔدَتُهُمۡ هَوَآءٞ 43
Nigbati awọn eniyan ba naro lati inu saara wọn ni jijẹpe olupepe kiakia ni ẹniti yoo maa gbe ori soke, ti wọn yoo si maa wo ni ẹniti o nkanra lọ si oke sanmọ, wọn ko nii da oju wọn pada bikose wipe yoo sẹku ni pako pako nitori ipaya nkan ti wọn nri, ọkan wọn yoo si pa lofo ti ko nii si laakaye nibẹ, ko si nii si agbọye nipa ipaya ohun ti wọn nri.
وَأَنذِرِ ٱلنَّاسَ يَوۡمَ يَأۡتِيهِمُ ٱلۡعَذَابُ فَيَقُولُ ٱلَّذِينَ ظَلَمُواْ رَبَّنَآ أَخِّرۡنَآ إِلَىٰٓ أَجَلٖ قَرِيبٖ نُّجِبۡ دَعۡوَتَكَ وَنَتَّبِعِ ٱلرُّسُلَۗ أَوَ لَمۡ تَكُونُوٓاْ أَقۡسَمۡتُم مِّن قَبۡلُ مَا لَكُم مِّن زَوَالٖ 44
Ki o si dẹru ba - irẹ ojisẹ - awọn ijọ rẹ kuro nibi iya Ọlọhun Ọba ọjọ igbende, ti awọn ti wọn jẹ alabosi si ẹmin ara wọn lati ibi keferi sise ati ẹbọ si I le maa sọ wipe: iwọ Ọlọhun Ọba wa, lọ wa lara, si mu iya jinna si wa, ki o si da wa pada si ile aye fun asiko diẹ ki a le nigbagbọ si Ọ, ki a si tun le tẹle awọn ojisẹ ti o gbe dide si wa, wọn yoo waa ma da wọn lohun niti eebu si wọn: se kii se wipe ẹ yin ni ẹ nbura ni isẹmin aye wipe ko si igbera kuro ninu isẹmin aye lọ si ọrun niti titako igbende lẹyin iku ni?!
وَسَكَنتُمۡ فِي مَسَٰكِنِ ٱلَّذِينَ ظَلَمُوٓاْ أَنفُسَهُمۡ وَتَبَيَّنَ لَكُمۡ كَيۡفَ فَعَلۡنَا بِهِمۡ وَضَرَبۡنَا لَكُمُ ٱلۡأَمۡثَالَ 45
Ti ẹ si sọkalẹ si aaye awọn ijọ alabosi isiwaju siwaju yin fun ẹmin ara wọn lati ibi keferi sise si Ọlọhun Ọba, bi apejuwe ijọ Hud ati ijọ sọlihu, o si han si yin iparun ti a jẹ ki o sẹlẹ si wọn, a si fi apejuwe lelẹ fun yin ninu tira Allah ki ẹ le gba isiti sugbọn ẹ ko gba isiti.
وَقَدۡ مَكَرُواْ مَكۡرَهُمۡ وَعِندَ ٱللَّهِ مَكۡرُهُمۡ وَإِن كَانَ مَكۡرُهُمۡ لِتَزُولَ مِنۡهُ ٱلۡجِبَالُ 46
Paapaa awọn eniyan ti o sọkalẹ si aaye awọn ijọ alabosi ti da awọn ete lati pa anọbi Muhammad ti ikẹ ati ọla nbẹ fun ati mimu opin ba ipepe rẹ, Ọlọhun Ọba Allah si mọ ete wọn, nkankan ko pamọ fun Un nibẹ, ete awọn eniyan wọnyi si lẹ, ko le mu oke kuro tabi nkan miran nitori lilẹ rẹ yatọ si ete ti Ọlọhun Ọba si wọn.
فَلَا تَحۡسَبَنَّ ٱللَّهَ مُخۡلِفَ وَعۡدِهِۦ رُسُلَهُۥٓۚ إِنَّ ٱللَّهَ عَزِيزٞ ذُو ٱنتِقَامٖ 47
Mase lero - irẹ ojisẹ - wipe dajudaju Ọlọhun Ọba ti O se adehun aranse fun awọn ojisẹ Rẹ ati sise afihan ẹsin yoo jẹ oluyapa adehun Rẹ ti O se fun awọn ojisẹ Rẹ, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah jẹ alagbara nkankan ko le bori Rẹ, Yoo si yun mu iyi ba awọn ẹni tiRẹ, O si jẹ olugbẹsan ti o le koko ni ara ọta Rẹ ati awọn ọta ojisẹ Rẹ.
يَوۡمَ تُبَدَّلُ ٱلۡأَرۡضُ غَيۡرَ ٱلۡأَرۡضِ وَٱلسَّمَٰوَٰتُۖ وَبَرَزُواْ لِلَّهِ ٱلۡوَٰحِدِ ٱلۡقَهَّارِ 48
Igbẹsan yii lara awọn keferi yoo jẹ ohun ti yoo sẹlẹ ni ọjọ igbende, ọjọ ti wọn yoo paarọ ile si ilẹ miran ti o jẹ funfun tonitoni, wọn yoo si tun paarọ sanmọ si sanmọ miran ti o yatọ si i, awọn eniyan yoo si hande ninu saare wọn pẹlu abara wọn ati awọn isẹ wọn lati le duro ni iwaju Ọlọhun Ọba Allah ẹniti oO jẹ aaso nibi ọla Rẹ ati titobi Rẹ, olubori tii maa bori, ti ẹnikankan ko le bori Rẹ.
وَتَرَى ٱلۡمُجۡرِمِينَ يَوۡمَئِذٖ مُّقَرَّنِينَ فِي ٱلۡأَصۡفَادِ 49
ki o tun ri - irẹ ojisẹ - ọjọ ti wọn yoo paarọ ile si ilẹ, wọn yoo si paarọ sanmọ naa; awọn keferi ati awọn ẹlẹbọ ti wọn ti so apakan wọn mọ apakan wọn nibi sẹkẹ sẹkẹ, wọn ti sun awọn ọwọ wọn mọ ẹsẹ wọn titi de ọrun wọn pẹlu ẹwọn, asọ wọn yii ti wọn yoo wọ nibẹ jẹ lati ibi ‘kọtiraani’ (ohun ni nkankan ti wọn ti ko ina mọ gidigidi), oju wọn ti o kọlẹ yoo si maa ga si ina.
سَرَابِيلُهُم مِّن قَطِرَانٖ وَتَغۡشَىٰ وُجُوهَهُمُ ٱلنَّارُ 50
ki o tun ri - irẹ ojisẹ - ọjọ ti wọn yoo paarọ ile si ilẹ, wọn yoo si paarọ sanmọ naa; awọn keferi ati awọn ẹlẹbọ ti wọn ti so apakan wọn mọ apakan wọn nibi sẹkẹ sẹkẹ, wọn ti sun awọn ọwọ wọn mọ ẹsẹ wọn titi de ọrun wọn pẹlu ẹwọn, asọ wọn yii ti wọn yoo wọ nibẹ jẹ lati ibi ‘kọtiraani’ (ohun ni nkankan ti wọn ti ko ina mọ gidigidi), oju wọn ti o kọlẹ yoo si maa ga si ina.
لِيَجۡزِيَ ٱللَّهُ كُلَّ نَفۡسٖ مَّا كَسَبَتۡۚ إِنَّ ٱللَّهَ سَرِيعُ ٱلۡحِسَابِ 51
Ki Ọlọhun Ọba Allah le san gbogbo ẹmin lẹsan nkan ti o se ninu daadaa ati aburu, dajudaju Ọlọhun Ọba jẹ oludara ni isiro isẹ.
هَٰذَا بَلَٰغٞ لِّلنَّاسِ وَلِيُنذَرُواْ بِهِۦ وَلِيَعۡلَمُوٓاْ أَنَّمَا هُوَ إِلَٰهٞ وَٰحِدٞ وَلِيَذَّكَّرَ أُوْلُواْ ٱلۡأَلۡبَٰبِ 52
Alukuraani yii eyiti wọn sọkalẹ fun anọbi wa Muhammad jẹ ifimọni lati ọdọ Ọlọhun Ọba fun awọn eniyan, ati lati le dẹru ba wọn nibi awọn nkan idẹrubani ati adehun iya ti o wa nibẹ, ki wọn si le ba mọ wipe ẹniti ijọsin tọsi ni Ọlọhun Ọba Allah nikan soso, ki wọn o maa sin In, ki wọn si ma se ẹbọ kankan pẹlu Rẹ, ki wọn si le ba gba ikilọ pẹlu rẹ, ki wọn le ba jẹ ẹni ikakun onilaakaye ti o mọ; toripe awọn ni wọn yoo se anfaani pẹlu isiti ati ariwoye.
Yiya aworan awọn isẹlẹ ọjọ igbende ati ikanran ẹda ati ipaya wọn ati ọlẹ wọn ati iwariri wọn ati ipaarọ ilẹ ati sanmọ.
Riroyin lile koko iya eyiti yoo ba awọn ẹlẹsẹ ati keferi ni ọjọ igbende.
Dajudaju ẹru wa ninu igbaaye alamọri ọrọ rẹ ninu isẹmin aye rẹ, dandan ni fun ki o gbiyanju lati tẹle asẹ, dajudaju Ọlọhun Ọba ti ọla Rẹ ga ko nii fun ni anfaani miran nigbati O ba gbe dide ni ọjọ igbende.