وَيَقُولُ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لَسۡتَ مُرۡسَلٗاۚ قُلۡ كَفَىٰ بِٱللَّهِ شَهِيدَۢا بَيۡنِي وَبَيۡنَكُمۡ وَمَنۡ عِندَهُۥ عِلۡمُ ٱلۡكِتَٰبِ 43
Awọn keferi sọ wipe: iwọ kii se - irẹ Muhammad - ẹniti a ran lati ọdọ Allah, sọ fun wọn - ire ojise -: Allah to ni ẹlẹri ni aarin emi ati yin wipe ẹniti a ran lati ọdọ Ọlọhun Ọba mi si yin ni moo se, ati ẹniti imọ awọn tira sanmọ nbẹ ni ọdọ rẹ eyiti iroyin mi wa nibẹ, ẹniti Ọlọhun Ọba Allah ba si jẹ ẹlẹri lori ijododo rẹ, irẹ olupurẹ ko le ko inira ba a.
سورة (MAKIYYAH)
Fifi isẹ awọn ojisẹ rinlẹ pẹlu alaye ati ipolongo, ati didẹruba awọn ti ọ gunri lati tẹle wọn pẹlu iya.
الٓرۚ كِتَٰبٌ أَنزَلۡنَٰهُ إِلَيۡكَ لِتُخۡرِجَ ٱلنَّاسَ مِنَ ٱلظُّلُمَٰتِ إِلَى ٱلنُّورِ بِإِذۡنِ رَبِّهِمۡ إِلَىٰ صِرَٰطِ ٱلۡعَزِيزِ ٱلۡحَمِيدِ 1
(الٓر) (Alif, Lam, Rọọ) ọrọ ti re kọja lori ounti o jọ ni ibẹrẹ ọgba ọrọ bakọra, alukuraani yii jẹ iwe ti a sọkalẹ fun ọ - irẹ ojisẹ - ki o le mu awọn eniyan jade kuro ninu keferi ati aimọkan ati ọna anu lọsi inu igbagbọ ati imọ ati itọsọna pẹlu fifẹ Ọlọhun Allah ti ọla Rẹ ga ati iranlọwọ rẹ lọsi inu ẹsin Islam eyiti tii se oju ọna Ọlọhun Allah abiyi eyiti ẹnikankan ko le bori rẹ, ẹni ẹyin nibi gbogbo nkan.
ٱللَّهِ ٱلَّذِي لَهُۥ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِۗ وَوَيۡلٞ لِّلۡكَٰفِرِينَ مِنۡ عَذَابٖ شَدِيدٍ 2
Allah eyiti ikapani ohun ti nbẹ ni sanmọ jẹ tirẹ nikan, Oun naa nikan ni ikapani ohun ti nbẹ ni ilẹ jẹ tiRẹ, Oun ni ẹniti oO tọ lati jọsin fun nikan, wọn ko gbọdọ mu nkan miran mọ ninu ẹda Rẹ, iya ti o lagbara yoo si kan awọn keferi.
ٱلَّذِينَ يَسۡتَحِبُّونَ ٱلۡحَيَوٰةَ ٱلدُّنۡيَا عَلَى ٱلۡأٓخِرَةِ وَيَصُدُّونَ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِ وَيَبۡغُونَهَا عِوَجًاۚ أُوْلَٰٓئِكَ فِي ضَلَٰلِۢ بَعِيدٖ 3
Awọn keferi gbọla fun isẹmin aye ati idẹkun ti yoo yẹ ti o wa nibẹ lori ọrun ati idẹkun gbere ti o wa nibẹ wọn nyi awọn eniyan kuro ni oju ọna Allah, wọn si nwa iruju ati roiroi kuro nibi ododo ati yiyẹ kuro nibi iduro sinsin fun oju ọna Rẹ, ki ẹnikẹni ma ba rin in, awọn wọnyi ni ẹniti a fi iroyin naa royin ni ọna anu ti o jinna si ododo ati kongẹ.
وَمَآ أَرۡسَلۡنَا مِن رَّسُولٍ إِلَّا بِلِسَانِ قَوۡمِهِۦ لِيُبَيِّنَ لَهُمۡۖ فَيُضِلُّ ٱللَّهُ مَن يَشَآءُ وَيَهۡدِي مَن يَشَآءُۚ وَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ 4
A ko gbe ojisẹ kan dide ayaafi ki a gbe dide ni ẹniti yoo maa sọrọ pẹlu gbolohun ijọ rẹ; ki agbọye ohun ti o muwa lati ọdọ Ọlọhun Allah le rọrun, a ko gbe e dide lati jẹ wọn nipa lori igbagbọ si Allah, Ọlọhun Allah ma nfi ẹniti o ba wu U lati ibi deede rẹ, O si ma nfi ẹniti o ba wu U lati ibi ọla Rẹ, Oun ni alagbara ti ẹnikankan ko le bori Rẹ, ọjọgbọn nibi idẹda ati idari eto Rẹ.
وَلَقَدۡ أَرۡسَلۡنَا مُوسَىٰ بَِٔايَٰتِنَآ أَنۡ أَخۡرِجۡ قَوۡمَكَ مِنَ ٱلظُّلُمَٰتِ إِلَى ٱلنُّورِ وَذَكِّرۡهُم بِأَيَّىٰمِ ٱللَّهِۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّكُلِّ صَبَّارٖ شَكُورٖ 5
Paapaa a ti gbe Musa dide, a si kun lọwọ pẹlu awọn amin ti o ntọka si jijẹ ododo ati wipe dajudaju o jẹ ẹniti a ran lati ọdọ Ọlọhun Ọba, a si pa a lasẹ ki o mu ijọ rẹ kuro ninu keferi ati aimọkan lọsi igbagbọ ati imọ, a si tun pa a lasẹ ki o ran wọn leti awọn ọjọ Ọlọhun eyiti o se idẹkun fun wọn nibẹ, dajudaju nibi awọn ọjọ yii awọn amin ti o gbọngbọn nipa ọkan soso Allah ati titobi agbara Rẹ wa nibẹ ati idẹkun Rẹ lori awọn olugbagbọ ododo, eleyi ni awọn onisuuru yoo fi se anfaani lori itẹle Allah, awọn oludunni mọ ọpẹ lori idẹkun Rẹ ati awọn irọra Rẹ.
Dajudaju erongba lori sisọ Alukuraani kalẹ jẹ itọsọna pẹlu mimu awọn eniyan jade kuro ninu okunkun ibajẹ lọsi inu imọlẹ ododo.
Riran awọn ojisẹ nisẹ jẹ pẹlu ahọn awọn ijọ ni ati ede wọn; toripe ohun ni yoo mu agbọye de ọdọ wọn, ohun ni yoo si jẹ ki gbigbaa wọle ati lilo o le see se.
Isẹ awọn ojisẹ pari si ibi itọ awọn eniyan sọna ati didari lati jade kuro ninu okunkun lọ si inu imọlẹ.