سَمَّٰعُونَ لِلۡكَذِبِ أَكَّٰلُونَ لِلسُّحۡتِۚ فَإِن جَآءُوكَ فَٱحۡكُم بَيۡنَهُمۡ أَوۡ أَعۡرِضۡ عَنۡهُمۡۖ وَإِن تُعۡرِضۡ عَنۡهُمۡ فَلَن يَضُرُّوكَ شَيۡٔٗاۖ وَإِنۡ حَكَمۡتَ فَٱحۡكُم بَيۡنَهُم بِٱلۡقِسۡطِۚ إِنَّ ٱللَّهَ يُحِبُّ ٱلۡمُقۡسِطِينَ 42
Awọn yahuudi wọnyi ni wọn ma ntẹti si irọ pipa ju, awọn ni wọn si pọ ni jijẹ dukia eewọ gẹgẹ bi riba, ti wọn ba gbe idajọ waa ba ọ - ire ojise - laarin wọn ti o ba fẹ, tabi ki o gbe idajọ sise ju silẹ laarin wọn, o jẹ ẹniti o le se ẹsa laarin alamọri mejeeji, ti o ba gbe atunse ju silẹ laarin wọn, wọn ko lee fi inira kankan kan ọ, ti o ba si se idajọ laarin wọn, ki o se pẹlu deede, koda bi wọn ba jẹ alabosi ati ọta, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah jẹ nifẹ oluse deede nibi idajọ wọn, koda bi awọn ti wọn ndajọ fun ba jẹ ọta si ẹniti nse idajọ.
وَكَيۡفَ يُحَكِّمُونَكَ وَعِندَهُمُ ٱلتَّوۡرَىٰةُ فِيهَا حُكۡمُ ٱللَّهِ ثُمَّ يَتَوَلَّوۡنَ مِنۢ بَعۡدِ ذَٰلِكَۚ وَمَآ أُوْلَٰٓئِكَ بِٱلۡمُؤۡمِنِينَ 43
Eemọ ni ọrọ awọn eniyan wọnyi, wọn nse aimoore si ọ, wọn si nwa ọ gẹgẹ bi oluse idajọ fun wọn, ni ẹniti nrankan idajọ rẹ pẹlu ohun ti yoo se deede ifẹ wọn, bẹẹ ni taoreeta nbẹ ni ọdọ wọn eyiti wọn lero wipe awọn nigbagbọ si, igbagbọ Ọlọhun Ọba Allah wa nibẹ, lẹyin eleyi ni wọn yoo sẹri kuro nibi idajọ rẹ nigbati ko ba se deede ifẹ inu wọn, wọn waa se akojọpọ sise keferi si iwe wọn ati igunri kuro nibi idajọ rẹ, isẹ awọn eniyan wọnyi kii se isẹ olugbagbọ ododo, ti oba ri bẹẹ, wọn kii se olugbagbọ ododo siọ ati si nkan ti o mu wa.
إِنَّآ أَنزَلۡنَا ٱلتَّوۡرَىٰةَ فِيهَا هُدٗى وَنُورٞۚ يَحۡكُمُ بِهَا ٱلنَّبِيُّونَ ٱلَّذِينَ أَسۡلَمُواْ لِلَّذِينَ هَادُواْ وَٱلرَّبَّٰنِيُّونَ وَٱلۡأَحۡبَارُ بِمَا ٱسۡتُحۡفِظُواْ مِن كِتَٰبِ ٱللَّهِ وَكَانُواْ عَلَيۡهِ شُهَدَآءَۚ فَلَا تَخۡشَوُاْ ٱلنَّاسَ وَٱخۡشَوۡنِ وَلَا تَشۡتَرُواْ بَِٔايَٰتِي ثَمَنٗا قَلِيلٗاۚ وَمَن لَّمۡ يَحۡكُم بِمَآ أَنزَلَ ٱللَّهُ فَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡكَٰفِرُونَ 44
Dajudaju Awa ni a sọ taoreeta kalẹ fun Muusa ki ọla maa ba, itọsọna wa ninu rẹ bẹẹ nii o tun jẹ itakasi daradara, ati imọlẹ ti a fi nriran, ti awọn Anọbi arọmọdọmọ isirẹla nse idajọ pẹlu rẹ, awọn ti wọn tẹriba fun ọba Allah pẹlu titẹleE, ti awọn onimimọ ati awọn ọlọgbọn ti wọn nre awọn eniyan nse idajọ pẹlu rẹ fun nkan ti Ọlọhun Ọba Allah ti ọla Rẹ ga pamọ si inu iwe naa, O si se wọn ni ẹni ifọkan balẹ le lori, wọn ndaaboobo kuro nibi iyipada ati ipaarọ, awọn ni olujẹri le lori ti o jẹ ododo, ọdọ wọn ni awọn eniyan yoo maa sẹri si nipa rẹ, ẹ mase jaya - ẹyin yahuudi - ẹyin eniyan, Emi nikan ni ki ẹ bẹru, bẹẹ ni ẹ mase gba owo perete bii idari tabi iyi tabi owo dipo idajọ pẹlu ohun ti Ọlọhun Ọba Allah sọkalẹ, ẹnikẹni ti ko ba se idajọ pẹlu nkan ti Ọlọhun Ọba Allah sọkalẹ, ni ẹniti o sọ di ohun ti o tọ, tabi o gbe ọla fun nkan miran le lori tabi o se ni dọgbandọgba pẹlu rẹ, awọn wọnyi ni keferi ododo.
وَكَتَبۡنَا عَلَيۡهِمۡ فِيهَآ أَنَّ ٱلنَّفۡسَ بِٱلنَّفۡسِ وَٱلۡعَيۡنَ بِٱلۡعَيۡنِ وَٱلۡأَنفَ بِٱلۡأَنفِ وَٱلۡأُذُنَ بِٱلۡأُذُنِ وَٱلسِّنَّ بِٱلسِّنِّ وَٱلۡجُرُوحَ قِصَاصٞۚ فَمَن تَصَدَّقَ بِهِۦ فَهُوَ كَفَّارَةٞ لَّهُۥۚ وَمَن لَّمۡ يَحۡكُم بِمَآ أَنزَلَ ٱللَّهُ فَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلظَّٰلِمُونَ 45
A se ni ọranyan fun yahuudi ninu taoreeta wipe ẹnikẹni ti o ba mọọmọ pa ẹmin kan, ni ailẹtọ, wọn yoo pa di, ẹniti o ba yọ oju kan niti imọọmọ, wọn yoo yọ oju tirẹ naa, ẹniti o ba re imu kan niti imọọmọ, wọn yoo re imu tirẹ naa, ẹniti o ba ge eti kan niti imọọmọ, wọn yoo ge eti tirẹ naa, ẹniti o ba yọ eyin kan niti imọọmọ, wọn yoo yọ eyin tirẹ naa, a se ni ọranyan le wọn lori nibi ọgbẹ wipe ijiya nbẹ fun ẹlẹsẹ ni deede ẹsẹ rẹ, ẹnikẹni ti o ba finufidọ se amoju kuro fun ẹlẹsẹ, amoju kuro rẹ yoo jẹ ipa ẹsẹ rẹ; nitori amoju kuro ti o se fun ẹniti o se abosi rẹ, ẹniti ko ba se idajọ pẹlu nkan ti Ọlọhun Ọba Allah sọkalẹ nibi alamọri ẹsan gbigba ati alamọri nkan miran, ẹni naa ti kọja ẹnu aala ti Ọlọhun Ọba Allah.
Kika onka apakan iroyin awọn yahuudi, gẹgẹ bi irọ, jijẹ riba, ninifẹ si sise idajọ pẹlu ohun ti o yatọ si ofin; lati le salaye ọna anu wọn ati ikilọ kuro nibẹ.
Sise alaye ofin gbigba ẹsan deede nipa ẹmin ati awọn oju ọgbẹ, eleyi jẹ alamọri kan ti Ọlọhun Ọba Allah se ni ọranyan fun awọn ti wọn ti siwaju wa.
Sise ni lojukokoro si ọla ti nẹb fun amojukuro nibi gbigba ẹsan, ati sise alaye ẹsan rẹ ti o tobi, ti o si han nibi pipa ẹsẹ rẹ.
Idẹrubani kuro nibi sise idajo pẹlu ohun ti yatọ si nkan ti Ọlọhun Ọba Allah sọkalẹ nipa alamọri ọrọ ẹsan gbigba ati ohun ti o yatọ sii.