ٱنفِرُواْ خِفَافٗا وَثِقَالٗا وَجَٰهِدُواْ بِأَمۡوَٰلِكُمۡ وَأَنفُسِكُمۡ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِۚ ذَٰلِكُمۡ خَيۡرٞ لَّكُمۡ إِن كُنتُمۡ تَعۡلَمُونَ 41
Ẹ maa rin jade - ẹyin olugbagbọ ododo - lati jagun si oju ọna ti Allah ni igba inira ati igba idẹkun, ọdọ ni ẹ jẹ nni tabi arugbo, ki ẹ si maa jagun pẹlu dukia yin ati ẹmin yin, dajudaju jijade ati jijagun pẹlu dukia ati ẹmin ni anfaani ti o pọ ninu isẹmin aye ati ni ọrun ju jijoko ati riropọ mọ lila dukia ati ẹmin lọ ti ẹ ba mọ bẹẹ, ki ẹ yara se oju kokoro si i.
لَوۡ كَانَ عَرَضٗا قَرِيبٗا وَسَفَرٗا قَاصِدٗا لَّٱتَّبَعُوكَ وَلَٰكِنۢ بَعُدَتۡ عَلَيۡهِمُ ٱلشُّقَّةُۚ وَسَيَحۡلِفُونَ بِٱللَّهِ لَوِ ٱسۡتَطَعۡنَا لَخَرَجۡنَا مَعَكُمۡ يُهۡلِكُونَ أَنفُسَهُمۡ وَٱللَّهُ يَعۡلَمُ إِنَّهُمۡ لَكَٰذِبُونَ 42
Ti o ba ja si wipe ohun ti ẹ npèpe sibẹ, awọn ti wọn yọnda fun ọ ninu awọn sọbẹ selu lati yapa jẹ ọrọ ti o rọrun ni ati irin ajo ti ko si idaamun nibẹ, wọn ko ba tẹle ọ - irẹ Anọbi - sugbọn alafo ti nbẹ pẹlu wọn jinna eyiti o ni ki wọn o rin lọsi ọdọ ọta, tori rẹ ni wọn se yapa, awọn ti wọn yọnda fun ọ ninu awọn sọbẹ selo wipe ki o yapa yii, yoo maa fi Allah bura nigbati o ba lọ ba wọn ni ẹniti yoo maa sọ wipe: ti a ba lagbara lati jade lati jagun pẹlu yin ni, awa ko ba jade, wọn npa ẹmin ara wọn run pẹlu wipe wọn nsẹri rẹ sibi iya Ọlọhun Ọba nitori iyapa wọn ati ibura irọ yii, Ọlọhun Ọba Allah mọ wipe opurọ ni wọn nibi ohun ti wọn npe mọ ara wọn yii ati nibi ibura wọn yii.
عَفَا ٱللَّهُ عَنكَ لِمَ أَذِنتَ لَهُمۡ حَتَّىٰ يَتَبَيَّنَ لَكَ ٱلَّذِينَ صَدَقُواْ وَتَعۡلَمَ ٱلۡكَٰذِبِينَ 43
Ọlọhun Ọba Allah yoo se amoju kuro fun ọ - ire ojise - igbiyanju rẹ nibi yiyọnda lati yapa, kilode ti o fi yọnda fun wọn nibẹ? Titi ti o fi han si ọ sootọ sootọ nibi awijare eyiti wọn ti siwaju ati olupurọ ninu wọn ti o yẹ ki o fi yọnda fun awọn olootọ dipo onirọ.
لَا يَسۡتَٔۡذِنُكَ ٱلَّذِينَ يُؤۡمِنُونَ بِٱللَّهِ وَٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِ أَن يُجَٰهِدُواْ بِأَمۡوَٰلِهِمۡ وَأَنفُسِهِمۡۗ وَٱللَّهُ عَلِيمُۢ بِٱلۡمُتَّقِينَ 44
Ko si ninu isesi awọn ti wọn nigbagbọ ninu Allah ati ninu ọjọ igbende ni igbagbọ tootọ ki wọn o maa wa ni ọdọ rẹ -ire ojise- iyọnda lati yapa kuro nibi igbiyanju si oju ọna ti Ọlọhun pẹlu dukia ati ẹmin wọn, bikose wipe isesi wọn ni ki wọn jade nigbati wọn ba beere fun jijade, ki wọn o si dukia ati ẹmin wọn se igbiyanju, Ọlọhun Ọba Allah jẹ onimimọ si olupaya ninu awọn ẹru Rẹ, ati ti wọn kii gba iyọnda ayaafi nitori awijare ti o le kọ fun wọn lati ma jade pẹlu rẹ.
إِنَّمَا يَسۡتَٔۡذِنُكَ ٱلَّذِينَ لَا يُؤۡمِنُونَ بِٱللَّهِ وَٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِ وَٱرۡتَابَتۡ قُلُوبُهُمۡ فَهُمۡ فِي رَيۡبِهِمۡ يَتَرَدَّدُونَ 45
Dajudaju awọn ti wọn nbeere lọdọ rẹ - ire ojise - yọnda lati yapa kuro sibi igbiyanju si oju ọna ti Ọlọhun, awọn wọnyi ni awọn sọbẹ selo ti ko nigbagbọ ninu Allah, wọn ko si nigbagbọ ninu ọjọ igbende, iyemeji ti ba wọn lọkan nibi ẹsin Allah, nibi iyemeji wọn, wọn nlọ wọn nbọ ti wọn ko mọna lọsi bi ododo.
۞وَلَوۡ أَرَادُواْ ٱلۡخُرُوجَ لَأَعَدُّواْ لَهُۥ عُدَّةٗ وَلَٰكِن كَرِهَ ٱللَّهُ ٱنۢبِعَاثَهُمۡ فَثَبَّطَهُمۡ وَقِيلَ ٱقۡعُدُواْ مَعَ ٱلۡقَٰعِدِينَ 46
Ti wọn ba jẹ olootọ nibi ohun ti wọn npe apemọra rẹ wipe awọn gbero lati jade pẹlu rẹ si oju ọna ti Ọlọhun, wọn ko ba mura silẹ niti ipese fun sugbọn Ọlọhun Ọba Allah ni o korira jijade pẹlu rẹ, ni jijade fi wuwo lara wọn, wọn gbọla fun jijoko sile.
Nigbati yiyapa awọn eniyan wọnyi yoo jẹ ibanujẹ fun awọn olugbagbọ ododo, Ọlọhun Ọba Allah wa fi wọn lọkan balẹ wipe jijade awọn eniyan naa ni inira ninu ju iyapa wọn lọ, O wa sọ wipe:
لَوۡ خَرَجُواْ فِيكُم مَّا زَادُوكُمۡ إِلَّا خَبَالٗا وَلَأَوۡضَعُواْ خِلَٰلَكُمۡ يَبۡغُونَكُمُ ٱلۡفِتۡنَةَ وَفِيكُمۡ سَمَّٰعُونَ لَهُمۡۗ وَٱللَّهُ عَلِيمُۢ بِٱلظَّٰلِمِينَ 47
Ninu oore ni ki awọn sọbẹ selu yii ma jade pẹlu yin toripe ti wọn ba jade pẹlu yin, wọn ko le le nkankan kun fun yin ju ibajẹ lọ, nitori idagunla si ati iruju ti wọn yoo maa se, wọn ko ba maa gbe ofofo kaakiri aarin lati pin yin yẹlẹyẹlẹ, o si wa ninu yin - ẹyin olugbagbọ ododo - ẹniti yoo maa gbọ ọrọ irọ wọn, ti yoo si gba wọle, ti yoo si maa fan ka, ti iyapa yoo fi wa maa gbilẹ laarin yin, Ọlọhun Ọba Allah si jẹ onimimọ si awọn alabosi ninu awọn sọbẹ selu, awọn ti wọn nju aidara ati iyemeji si aarin awọn olugbagbọ ododo.
Jijẹ dandan ijagun pẹlu ẹmin ati dukia nigbati bukaata ba beere fun un.
Ibura irọ ma nsọ iparun di ọranyan fun ni.
Jijẹ dandan sisọra kuro nibi ikanju ati jijẹ ọranyan iduro sinsin ati ifarada ati gbigbe gbigba itanjẹ pẹlu awọn nkan ti o han silẹ, ati sise iwadi ti o daju ati iwoye.
Ninu akiyesi Ọlọhun Ọba Allah si awọn olugbagbọ ododo ni sisọ awọn sọbẹ selu di ọlẹ ati kikọ fun wọn lati jade pẹlu awọn ẹru Rẹ ti o jẹ olugbagbọ ododo ki o le jẹ ikẹ fun awọn olugbagbọ ododo ati aanu lati ma jẹ ki awọn ti ko nii se wọn ni anfaani wọ le si wọn lara, bikose wipe yoo ni wọn lara ni.