۞وَيَٰقَوۡمِ مَا لِيٓ أَدۡعُوكُمۡ إِلَى ٱلنَّجَوٰةِ وَتَدۡعُونَنِيٓ إِلَى ٱلنَّارِ 41
Ẹyin ijọ mi, ki lo se yin ti mo npe yin lọsi ibi ọla kuro nibi ofo ninu isẹmin aye ati ti ọrun pẹlu nini igbagbọ si Allah ati sise isẹẹre, ti ẹyin si npe mi lọsi ibi wiwọ ina lati bi ohun ti ẹ npe mi si gẹgẹ bi sise keferi si Allah ati yiyapa Rẹ?!
تَدۡعُونَنِي لِأَكۡفُرَ بِٱللَّهِ وَأُشۡرِكَ بِهِۦ مَا لَيۡسَ لِي بِهِۦ عِلۡمٞ وَأَنَا۠ أَدۡعُوكُمۡ إِلَى ٱلۡعَزِيزِ ٱلۡغَفَّٰرِ 42
Ẹ npemi sibi ibajẹ yin ki nle ba se keferi si Allah, ki nsi tun sin nkan miran mọ Ọ ninu ohun ti ko si imọ lilalaafia sisin In pẹlu Allah lọdọ mi, emi si npe yin lọsi ibi igbagbọ ninu Allah alagbara ti ẹnikankan ko le bori Rẹ alaforijin ti iforijin Rẹ tobi fun awọn ẹru Rẹ.
لَا جَرَمَ أَنَّمَا تَدۡعُونَنِيٓ إِلَيۡهِ لَيۡسَ لَهُۥ دَعۡوَةٞ فِي ٱلدُّنۡيَا وَلَا فِي ٱلۡأٓخِرَةِ وَأَنَّ مَرَدَّنَآ إِلَى ٱللَّهِ وَأَنَّ ٱلۡمُسۡرِفِينَ هُمۡ أَصۡحَٰبُ ٱلنَّارِ 43
Lododo ti ẹ ba pe mi lọsi ibi igbagbọ ati titẹle; ko si ipepe kan ti wọn le pe eniyan sibẹ ni ile aye tabi ni ọrun ti ko wa nii jẹpe ẹniti o ba pe e, ati wipe dajudaju ibusẹri si wa lapapọ jẹ ọdọ Allah nikan soso ati wipe dajudaju awọn olukọja ẹnu aala nibi keferi sise ati awọn ẹsẹ ni ẹni ina ati ti yoo dunni mọ wiwọ ọ ni ọjọ igbende.
فَسَتَذۡكُرُونَ مَآ أَقُولُ لَكُمۡۚ وَأُفَوِّضُ أَمۡرِيٓ إِلَى ٱللَّهِۚ إِنَّ ٱللَّهَ بَصِيرُۢ بِٱلۡعِبَادِ 44
Wọn tako isiti rẹ, o wa sọpe: ẹ o pada ranti isiti ti mo ti siwaju yin, ẹ o si pada gbarata lori aitẹwọ gba a, mo si fi gbogbo ọrọ mi lapapọ ti si ọdọ Allah nikan soso, dajudaju nkankan ko pamọ fun Allah ninu awọn isẹ awọn ẹru Rẹ.
فَوَقَىٰهُ ٱللَّهُ سَئَِّاتِ مَا مَكَرُواْۖ وَحَاقَ بَِٔالِ فِرۡعَوۡنَ سُوٓءُ ٱلۡعَذَابِ 45
Allah daabobo kuro nibi aburu ete wọn nigbati wọn gbero lati pa a, o si fi iya itẹri kari awọn ara ile fir'aona, paapaa Allah si tẹ ẹri oun ati awọn ọmọ ogun rẹ ni ile aye.
ٱلنَّارُ يُعۡرَضُونَ عَلَيۡهَا غُدُوّٗا وَعَشِيّٗاۚ وَيَوۡمَ تَقُومُ ٱلسَّاعَةُ أَدۡخِلُوٓاْ ءَالَ فِرۡعَوۡنَ أَشَدَّ ٱلۡعَذَابِ 46
Lẹyin iku wọn, wọn yoo tun sẹri wọn si inu ina ni inu saare ni akọkọ ọsan ati igbẹyin rẹ, ni ọjọ igbende wọn yoo sọpe: ẹ fi awọn ti o ntẹle fir'aona wọ inu iya ti o le koko ati eyiti o tobi ju; nitori keferi ati ipeni nirọ ati ikọdini kuro ni oju ọna Allah ti wọn wa lori rẹ.
وَإِذۡ يَتَحَآجُّونَ فِي ٱلنَّارِ فَيَقُولُ ٱلضُّعَفَٰٓؤُاْ لِلَّذِينَ ٱسۡتَكۡبَرُوٓاْ إِنَّا كُنَّا لَكُمۡ تَبَعٗا فَهَلۡ أَنتُم مُّغۡنُونَ عَنَّا نَصِيبٗا مِّنَ ٱلنَّارِ 47
Tun ranti - irẹ ojisẹ - nigbati awọn olutẹle ati awọn ti wọn ntẹle ninu ẹni ina ba nja, awọn olutẹle ti wọn jẹ ọlẹ yoo maa sọ fun awọn ti wọn ntẹẹle ti wọn jẹ onigberaga: dajudaju awa ti jẹ olutẹle ninu isina ni ile aye, njẹ ẹyin le rọ wa lọrọ abala kan kuro nibi iya Allah pẹlu ki ẹ ba wa gbe e bi?!
قَالَ ٱلَّذِينَ ٱسۡتَكۡبَرُوٓاْ إِنَّا كُلّٞ فِيهَآ إِنَّ ٱللَّهَ قَدۡ حَكَمَ بَيۡنَ ٱلۡعِبَادِ 48
Awọn ti wọn ntẹẹle, ti wọn jẹ onigberaga sọpe: dajudaju awa - boya a jẹ ẹniti nkọse tabi awọn ti a ntẹẹle - wa ninu ina, bẹẹni ẹnikankan ninu wa ko le gbe abala kan ninu iya ọrun, dajudaju Allah ti se idajọ laarin awọn ẹru naa, o si tun fun olukuluku ninu ohun ti o lẹtọ si ninu iya.
وَقَالَ ٱلَّذِينَ فِي ٱلنَّارِ لِخَزَنَةِ جَهَنَّمَ ٱدۡعُواْ رَبَّكُمۡ يُخَفِّفۡ عَنَّا يَوۡمٗا مِّنَ ٱلۡعَذَابِ 49
Awọn ti wọn njiya ninu ina ninu awọn alawokọse ati awọn ti wọn ntẹẹle yoo sọ fun awọn Malaaika ti wọn la imojuto ina bọ lọrun nigbati wọn ba jakan kuro nibi jijade ninu ina ati sisẹri lọsi ile aye lati ronu piwada: ẹ pe Ọlọhun yin ki o se fifuyẹ ọjọ kan fun wa nibi iya gbere yii.
Pataki igbarale Allah.
Lila olupepe lọsibi ododo kuro nibi ete awọn ọta rẹ.
Ririnlẹ iya agede meji.
Sisopọ awọn keferi mọ eyikeyi okunfa ti o le mu isimin ba wọn kuro nibi ina ki baa se asiko ti o ni aala, eleyi ko si le sẹlẹ lailai.